Ohun Tó Ń jẹ́ Kó Sàárò New York City Jù Lọ
Ohun Tó Ń jẹ́ Kó Sàárò New York City Jù Lọ
Láti àwọn ọdún 1950 ni àkọlé tó wà lókè yìí ti wà lójútáyé ní orí ilé ìtẹ̀wé Watchtower Society tó wà ní Brooklyn, New York. Àwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn, àwọn arìnrìn-àjò, àti àwọn mìíràn tó ń kọjá lọ la máa ń rán létí láti ka Bíbélì wọn lójoojúmọ́. Lẹ́tà yìí, táa rí gbà látọ̀dọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, fi hàn bí ìránnilétí yìí ti gbéṣẹ́ tó.
“Mò ń bá ọmọ kíláàsì mi kan sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo fẹ́ ṣe nígbà tí mo bá jáde ìwé mẹ́wàá. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa Bẹ́tẹ́lì, oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú rẹ̀ dùn púpọ̀. Ó sọ fún mi pé, New York City lòun ti lo gbogbo ìgbésí ayé òun. Ìdílé rẹ̀ kò já ẹ̀sìn kúnra rárá o, ṣùgbọ́n láràárọ̀, tó bá ti wòta látojú fèrèsé ilé wọn, àkọlé tó máa ń rí ni ‘Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Bíbélì Mímọ́ Lójoojúmọ́.’ Nítorí náà, ojoojúmọ́ ló máa ń ka Bíbélì kò tó lọ sílé ìwé.
“Lẹ́yìn tó kúrò ní ìlú yẹn, ó ní, ohun tó ń jẹ́ kí òun sàárò New York City jù lọ ni pé, nígbà tí òun bá jí, kò sí ohunkóhun tó máa ń rán òun létí láti ka Bíbélì. Ṣùgbọ́n àmì tó wà lórí ilé Watchtower ti jẹ́ kí Bíbélì kíkà mọ́ ọn lára, ó ṣì ń bá a lọ láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́!”
Kò tún sí ohun mìíràn tó dára ju pé, báa bá ti jí láàárọ̀ ká kọ́kọ́ ka apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé, wàá mọrírì ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà pé: “Ìwé mímọ́, . . . lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—2 Tímótì 3:15-17.