‘Ọlọ́run, Rán Ìmọ́lẹ̀ Rẹ Jáde’
‘Ọlọ́run, Rán Ìmọ́lẹ̀ Rẹ Jáde’
“Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde. Kí ìwọ̀nyí máa ṣamọ̀nà mi.”—SÁÀMÙ 43:3.
1. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣí àwọn ète rẹ̀ payá?
JÈHÓFÀ jẹ́ agbatẹnirò gan-an, ní ti bó ṣe ń jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ ète rẹ̀. Dípò tí yóò fi ṣí gbogbo òtítọ́ payá lẹ́ẹ̀kan náà, bí ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tó lè fọ́ni lójú, ńṣe ló ń là wá lóye ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. A lè fi ìrìn wa lójú ọ̀nà ìyè wé ti àgbẹ̀ kan tó ń lọ sóko tó jìnnà sílé. Ilẹ̀ ò tíì mọ́ rárá, tó ti jí sọ́nà, ó lè rí nǹkan fírífírí. Bí ọ̀yẹ̀ ti ń là díẹ̀díẹ̀, yóò lè máa rí ohun tó wà láyìíká rẹ̀ dáadáa. Àmọ́ kò ní lè rí àwọn ohun yòókù dáadáa. Ṣùgbọ́n bí oòrùn ṣe túbọ̀ ń yọ, bẹ́ẹ̀ ló lè túbọ̀ rọ́ọ̀ọ́kán dáadáa. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí Ọlọ́run pèsè ṣe rí. Ó ń jẹ́ ká lè rí ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ní sáà kan. Ọ̀nà kan náà sì ni Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Kristi, gbà pèsè ìlàlóye tẹ̀mí. Ẹ jẹ́ ká ronú lórí bí Jèhófà ṣe la àwọn ènìyàn rẹ̀ lóye láyé ọjọ́un àti bó ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóde òní.
2. Báwo ni Jèhófà ṣe la àwọn ènìyàn lóye ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé?
2 Àfàìmọ̀ ni ò fi jẹ́ pé àwọn ọmọ Kórà ló kọ Sáàmù kẹtàlélógójì. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Léfì, wọ́n láǹfààní láti kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run. (Málákì 2:7) Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ni Atóbilọ́lá tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, òun sì ni wọ́n ń wò gẹ́gẹ́ bí Orísun ọgbọ́n gbogbo. (Aísáyà 30:20) Onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, . . . rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde. Kí ìwọ̀nyí máa ṣamọ̀nà mi.” (Sáàmù 43:1, 3) Níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó máa ń kọ́ wọn ní ọ̀nà rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Jèhófà fi ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ tó pabanbarì jù lọ ṣojú rere sí wọn. Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé.
3. Ọ̀nà wo ni ẹ̀kọ́ Jésù gbà dán àwọn Júù wò?
3 Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin náà Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run ti jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòhánù 8:12) Ó fi “àpèjúwe kọ́ [àwọn ènìyàn] ni ohun púpọ̀”—ìyẹn ni àwọn ohun tuntun. (Máàkù 4:2) Ó sọ fún Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Lójú àwọn ará Róòmù àti àwọn Júù tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn bí nǹkan míì, èrò tuntun lèyí jẹ́, nítorí ohun tí wọ́n ń ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ ni pé Mèsáyà yóò mú kí Ilẹ̀ Ọba Róòmù túúbá, tí yóò sì wá dá ògo tí Ísírẹ́lì ní tẹ́lẹ̀ padà fún un. Ìmọ́lẹ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà ni Jésù ń fi hàn, àmọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò tà létí àwọn alákòóso Júù, àwọn tí “wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo ènìyàn ju ògo Ọlọ́run pàápàá.” (Jòhánù 12:42, 43) Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn náà ló yàn láti rọ̀ mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn ènìyàn dípò títẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí àti òtítọ́ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.—Sáàmù 43:3; Mátíù 13:15.
4. Báwo la ṣe mọ̀ pé òye àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yóò máa pọ̀ sí i?
4 Àmọ́ ṣá o, a rí àwọn ọkùnrin àtobìnrin mélòó kan tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni. Wọ́n tẹ̀ síwájú gidigidi nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà lóye àwọn ète Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, bí òpin ìwàláàyè Olùkọ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé ti ń sún mọ́lé, wọ́n ṣì ní ohun púpọ̀ láti kọ́. Jésù sọ fún wọn pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.” (Jòhánù 16:12) Bẹ́ẹ̀ ni, òye òtítọ́ Ọlọ́run tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ní, yóò máa pọ̀ sí i.
Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
5. Ìbéèrè wo ló wáyé ní ọ̀rúndún kìíní, iṣẹ́ àwọn wo ló jẹ́ láti yanjú rẹ̀?
5 Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, ìmọ́lẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tún wá mọ́lẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nínú ìran kan tí Jèhófà fi han Pétérù, ó jẹ́ kó mọ̀ pé láti ìgbà náà lọ, àwọn Kèfèrí aláìkọlà láǹfààní láti di ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìṣe 10:9-17) Ìṣípayá ńlá lèyí o! Síbẹ̀síbẹ̀, ìbéèrè kan wáyé pé: Ǹjẹ́ Jèhófà pa á láṣẹ pé kí àwọn Kèfèrí wọ̀nyẹn kọlà lẹ́yìn tí wọ́n di Kristẹni? A ò dáhùn ìbéèrè yẹn nínú ìran ọ̀hún, ọ̀ràn náà sì fa arukutu láàárín àwọn Kristẹni. Iná ò ṣeé fi sórí òrùlé sùn, wọ́n gbọ́dọ̀ yanjú ẹ̀, kí ìjọ má bàa fọ́. Nítorí náà, ní Jerúsálẹ́mù, “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin . . . kóra jọpọ̀ láti rí sí àlámọ̀rí yìí.”—Ìṣe 15:1, 2, 6.
6. Ìlànà wo ni àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n ń ronú lórí ìbéèrè nípa ìkọlà?
6 Báwo làwọn tó pésẹ̀ sí ìpàdé náà yóò ṣe pinnu ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn Kèfèrí onígbàgbọ́ ṣe? Jèhófà kò rán áńgẹ́lì kan láti lọ ṣalága àpérò náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fi ìran han àwọn tó wà níbẹ̀. Síbẹ̀, kò fi àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin wọ̀nyẹn sílẹ̀ láìsí ìtọ́sọ́nà. Wọ́n gbé ìrírí àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ Júù yẹ̀ wò, àwọn tí wọ́n ti rí bí Ọlọ́run ti ṣe ń bá àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè lò, nípa títú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sí àwọn Kèfèrí aláìkọlà lórí. Wọ́n tún wánú Ìwé Mímọ́ fún ìtọ́sọ́nà. Nígbà tí wọ́n rò ó lọ, rò ó bọ̀, ni ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù bá dábàá kan tó gbé ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó là wọ́n lóye. Bí wọ́n ti ń ronú lórí ẹ̀rí yìí, ó wá yé wọn yéké pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni. Kò pọndandan kí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè kọlà kí wọ́n tó rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin kò fàkókò ṣòfò rárá, kíá ni wọ́n kọ ìpinnu wọn ránṣẹ́ sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn, kí ó lè tọ́ àwọn náà sọ́nà.—Ìṣe 15:12-29; 16:4.
7. Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà tẹ̀ síwájú?
7 Láìdà bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù, àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba ńlá wọn, ọ̀pọ̀ Júù tó jẹ́ Kristẹni ní inú wọn dùn nígbà tí wọ́n rí òye tuntun tó ga lọ́lá nípa ète Ọlọ́run yìí gbà, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé fífara mọ́ ọn lè béèrè pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò tó yàtọ̀ nípa àwọn Kèfèrí ní gbogbo gbòò. Jèhófà bù kún ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọn, “àwọn ìjọ [sì] ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Ìṣe 15:31; 16:5.
8. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé a lè máa retí ọ̀pọ̀ ìmọ́lẹ̀ sí i lẹ́yìn tí ọ̀rúndún kìíní parí? (b) Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
8 Ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ń mọ́lẹ̀ sí i jálẹ̀ ọ̀rúndún kìíní. Ṣùgbọ́n Jèhófà ò fi gbogbo ète rẹ̀ han àwọn Kristẹni ìjímìjí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Nísinsìnyí àwa ń ríran nínú àwòrán fírífírí nípasẹ̀ dígí tí a fi irin ṣe.” (1 Kọ́ríńtì 13:12) Irú dígí bẹ́ẹ̀ kò lè rí nǹkan rekete. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó níbi tí òye ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí yóò yé wọn dé. Lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì kú tán, ìmọ́lẹ̀ náà di bàìbàì fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ ti wá pọ̀ rẹpẹtẹ. (Dáníẹ́lì 12:4) Báwo ni Jèhófà ṣe ń la àwọn ènìyàn rẹ̀ lóye lónìí? Báwo ló sì ṣe yẹ ká hùwà nígbà tó bá mú òye wa nípa Ìwé Mímọ́ gbòòrò sí i?
Ìmọ́lẹ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀-Lé
9. Ọgbọ́n ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò láfiwé, tó sì gbéṣẹ́ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìbẹ̀rẹ̀ lò?
9 Lóde òní, ìmọ́lẹ̀ táa kọ́kọ́ rí fírífírí jẹ́ ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó kẹ́yìn ọ̀rúndún kọkàndínlógún, nígbà tí àwùjọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin Kristẹni kan bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lójú méjèèjì. Wọ́n ṣètò ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹnì kan yóò béèrè ìbéèrè; lẹ́yìn èyí, àwùjọ yóò wá máa ṣàlàyé gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tan mọ́ ọn. Bó bá dà bíi pé ẹsẹ Bíbélì kan tako òmíràn, àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí yóò sapá láti rí i pé méjèèjì fohùn ṣọ̀kan. Láìdà bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àkókò yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn) pinnu láti jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ jẹ́ atọ́nà wọn, wọ́n láwọn ò ní tẹ̀ lé òfin tàbí ẹ̀kọ́ tí ènìyàn gbé kalẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé gbogbo ẹ̀rí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò, wọn yóò wá kọ ìparí èrò tí wọ́n dé sílẹ̀. Lọ́nà yẹn, wọ́n wá lóye ọ̀pọ̀ lájorí ẹ̀kọ́ Bíbélì yékéyéké.
10. Àwọn ìwé tó lè ranni lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wo ni Charles Taze Russell kọ?
10 Ògúnná gbòǹgbò kan láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn ni Charles Taze Russell. Ó kọ̀wé mẹ́fà tó ranni lọ́wọ́ láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn, ó pè wọ́n ní Studies in the Scriptures. Arákùnrin Russell ní in lọ́kàn láti kọ ìdìpọ̀ keje tí yóò ṣàlàyé nípa ìwé Ìsíkíẹ́lì àti Ìṣípayá. Ó wí pé: “Nígbàkigbà tí mo bá rí ojútùú rẹ̀, màá kọ Ìdìpọ̀ Keje.” Ṣùgbọ́n, ó fi kún un pé: “Bó bá sì jẹ́ ẹlòmíràn ni Olúwa jẹ́ kó mọ ojútùú rẹ̀, onítọ̀hún ni yóò kọ ọ́.”
11. Ìsopọ̀ wo ló wà láàárín àkókò àti báa ṣe lè lóye àwọn ète Ọlọ́run?
11 Ọ̀rọ̀ tí C. T. Russell sọ yìí ṣàpèjúwe kókó pàtàkì kan tó ní í ṣe pẹ̀lú báa ṣe lè lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì kan—ìyẹn ni ọ̀ràn àkókò. Arákùnrin Russell mọ̀ pé òun kò lè fagbára mú ìmọ́lẹ̀ náà tàn sórí ìwé Ìṣípayá, gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ kan tó ń lọ sóko ní kòríni-kòmọni kò ti lè fagbára mú kí ọ̀yẹ̀ tètè là nígbà tí àkókò rẹ̀ kò tíì tó.
A Ṣí I Payá—Nígbà Tí Ó Tó Àkókò Lójú Ọlọ́run
12. (a) Ìgbà wo ni a máa ń lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lọ́nà tó dára jù lọ? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé agbára wa láti lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sinmi lórí àkókò tí Ọlọ́run yàn pé kí nǹkan ṣẹlẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
12 Gẹ́gẹ́ bó ṣé jẹ́ pé lẹ́yìn ikú Jésù àti àjíǹde rẹ̀ ni àwọn àpọ́sítélì tó lóye ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ Mèsáyà náà, àwọn Kristẹni lónìí máa ń lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kìkì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ní ìmúṣẹ. (Lúùkù 24:15, 27; Ìṣe 1:15-21; 4:26, 27) Ìwé Ìṣípayá jẹ́ ìwé àsọtẹ́lẹ̀, nítorí náà, bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó sọ bá ṣe ń ṣẹ ni a ó túbọ̀ máa lóye rẹ̀ dáradára. Fún àpẹẹrẹ, kò sí bí C. T. Russell ṣe lè lóye ìtumọ̀ ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀ dòdò tí ìwé Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún, ẹsẹ ìkẹsàn-án sí ìkọkànlá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, nítorí pé àwọn ètò àjọ tí ẹranko ẹhànnà náà ń ṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n jẹ́, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kò sí nígbà ayé rẹ̀, ó ti kú kí wọ́n tó yọjú. a
13. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìmọ́lẹ̀ bá bù yẹ̀rì sórí kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì kan?
13 Nígbà tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbọ́ pé àwọn Kèfèrí aláìkọlà lè di onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, ìyípadà yẹn yọrí sí ìbéèrè tuntun tó dá lórí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè kọlà. Èyí ló sún àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin láti ṣàyẹ̀wò gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìkọlà. Ọ̀nà kan náà yìí la ṣì ń lò lónìí. Bí ìmọ́lẹ̀ bá bù yẹ̀rì sórí kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, ó máa ń sún àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” láti ṣàyẹ̀wò àwọn kókó tó jẹ mọ́ ọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn àpẹẹrẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ti fi hàn.—Mátíù 24:45.
14-16. Báwo ni àtúnṣe tí ó dé bá èrò táa ní nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ṣe nípa lórí òye wa nípa Ìsíkíẹ́lì orí ogójì sí ìkejìdínláàádọ́ta?
14 Ní 1971, a ṣàlàyé kan lórí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, “The Nations Shall Know That I Am Jehovah”—How? Orí kan nínú ìwé yẹn jíròrò ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa tẹ́ńpìlì ní ṣókí. (Ìsíkíẹ́lì, orí 40-48) Nígbà yẹn, ohun táa darí gbogbo àfiyèsí sí ni bí ìran Ìsíkíẹ́lì nípa tẹ́ńpìlì náà yóò ṣe nímùúṣẹ nínú ayé tuntun.—2 Pétérù 3:13.
15 Ṣùgbọ́n, àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì táa tẹ̀ jáde nínú Ile-Iṣọ Na August 15, 1973, nípa lórí òye táa ní nípa ìran Ìsíkíẹ́lì. Wọ́n jíròrò tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe nínú Hébérù orí kẹwàá. Ile-Iṣọ Na ṣàlàyé pé ibi Mímọ́ àti àgbàlá inú lọ́hùn-ún nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà ní í ṣe pẹ̀lú ipò tí àwọn ẹni àmì òróró wà nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà táa wá ṣàgbéyẹ̀wò ìwé Ìsíkíẹ́lì orí ogójì sí ìkejìdínláàádọ́ta lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, a lóye pe gẹ́gẹ́ bí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ṣe ń ṣiṣẹ́ lónìí, bẹ́ẹ̀ náà ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà lẹ́nu iṣẹ́ lónìí. Lọ́nà wo?
16 Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, a rí àwọn àlùfáà tí ń rìn nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì náà bí wọ́n ṣe ń sin àwọn ẹ̀yà tí kì í ṣe àlùfáà. Lọ́nà tó ṣe kedere, àwọn àlùfáà wọ̀nyí ń ṣojú fún, “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé,” àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà. (1 Pétérù 2:9) Ṣùgbọ́n, kò ní jẹ́ pé jálẹ̀ gbogbo Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi ni wọn yóò fi sìn nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì ti orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 20:4) Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò yẹn, bí kò bá tilẹ̀ ní jẹ́ gbogbo rẹ̀, ni àwọn ẹni àmì òróró yóò fi sin Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà, Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ìyẹn ni “ọ̀run.” (Hébérù 9:24) Níwọ̀n bí a ti rí àwọn àlùfáà tí wọ́n ń lọ, tí wọ́n ń bọ̀, nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé ìran yẹn ń nímùúṣẹ lónìí, nígbà tí àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Bákan náà gẹ́lẹ́, ni ẹ̀dà ti March 1, 1999, ìwé ìròyìn yìí ṣe gbé èrò tí a tún ṣe lórí kókó yìí jáde. Nípa báyìí, títí dé ìparí ọ̀rúndún ogún yìí, a ṣì ń tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí sórí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì.
Múra Tán Láti Tún Èrò Rẹ Ṣe
17. Látìgbà tóo ti mọ òtítọ́, kí làwọn àtúnṣe tóo ti ṣe nípa èrò tóo ní tẹ́lẹ̀, báwo sì ni wọ́n ti ṣe ṣe ọ́ láǹfààní?
17 Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti ní ìmọ̀ òtítọ́ gbọ́dọ̀ ṣe tán láti mú “gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 10:5) Ìyẹn kìí fìgbà gbogbo rọrùn, pàápàá jù lọ nígbà tí èrò bẹ́ẹ̀ bá ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lọ́kàn ẹni. Fún àpẹẹrẹ, kí o tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, o ti lè máa gbádùn lílọ bá àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣe àwọn ọdún kan tó jẹ́ ti ìsìn. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tóo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o wá rí i pé àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí pilẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà. Lákọ̀ọ́kọ́, o lè máa lọ́ra láti fi ohun tóo kọ́ sílò. Ṣùgbọ́n, nígbẹ̀yìn, ìfẹ́ tóo ní fún Ọlọ́run wá lágbára ju ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn lọ, lo bá jáwọ́ nínú ṣíṣọdún tí kò wu Ọlọ́run. Ǹjẹ́ Jèhófà kò ti bù kún ìpinnu rẹ?—Fi wé Hébérù 11:25.
18. Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí a bá mú òye wa nípa òtítọ́ Bíbélì ṣe kedere?
18 Táa bá ń ṣe nǹkan ní ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́, ó sábà máa ń ṣeni láǹfààní. (Aísáyà 48:17, 18) Nítorí náà, nígbà tí a bá mú èrò táa ní lórí ẹsẹ Bíbélì kan ṣe kedere sí wa, ẹ jẹ́ kí inú wa dùn láti mú òtítọ́ náà tẹ̀ síwájú! Ká sòótọ́, bíbá tí à ń bá a nìṣó láti máa gba ìlàlóye ń jẹ́rìí sí i pé a wà lójú ọ̀nà tòótọ́. Ohun ni “ipa ọ̀nà àwọn olódodo” tó “dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Lóòótọ́, ní báyìí, a ń rí díẹ̀ nínú àwọn ète Ọlọ́run “fírífírí.” Ṣùgbọ́n, nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, a óò rí òtítọ́ kedere, ìyẹn táa bá dúró ṣinṣin ní “ipa ọ̀nà” náà. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa yọ̀ nínú àwọn òtítọ́ tí Jèhófà ti mú kí ó ṣe kedere, kí á sì máa retí ìlàlóye lórí àwọn èyí tí kò tí ì yé wa dáadáa.
19. Kí ni ọ̀nà kan táa lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?
19 Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ wa fún ìmọ́lẹ̀ náà hàn lọ́nà tó gbéṣẹ́? Ọ̀nà kan ni nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé—bó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe ká máa kà á lójoojúmọ́. Ǹjẹ́ o ń tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà déédéé? Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tún ń fún wa ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí láti gbádùn. Bákan náà, ẹ tún ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn táa ti ṣètò fún àǹfààní wa. Ìròyìn afúnni-níṣìírí tí à ń tẹ̀ jáde nínú ìwé Yearbook of Jehovah’s Witnesses, èyí tó ń sọ nípa ìgbòkègbodò Ìjọba náà ńkọ́?
20. Ìsopọ̀ wo ló wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà àti lílọ́ tí à ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni?
20 Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́nà àgbàyanu, Jèhófà ti dáhùn àdúrà táa gbà nínú Sáàmù kẹtàlélógójì, ẹsẹ, ìkẹta. Ní òpin ẹsẹ yìí, a kà pé: “Kí [ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ] mú mi wá sí òkè ńlá mímọ́ rẹ àti sí àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá.” Ṣé ìwọ náà ń wọ̀nà fún ìgbà tí ìwọ àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíràn yóò lè jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀? Ìtọ́ni nípa tẹ̀mí táa pèsè ní àwọn ìpàdé jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí Jèhófà gbà ń pèsè ìlàlóye lónìí. Kí la lè ṣe láti jẹ́ kí ìmọrírì wa fún àwọn ìpàdé Kristẹni jinlẹ̀ sí i? A ké sí ọ láti gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́yìn ikú C. T. Russell, a ṣètò ìwé kan táa pè ní ìdìpọ̀ keje ti Studies in the Scriptures láti pèsè àlàyé lórí ìwé Ìsíkíẹ́lì àti Ìṣípayá. Lápá kan, a gbé ìwé yẹn ka àwọn ọ̀rọ̀ tí Russell kọ nípa àwọn ìwé Bíbélì wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n, àkókò àtiṣí ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà payá kò tí ì tó, ní gbogbo gbòò, àlàyé táa ṣe nínú ìdìpọ̀ Studies in the Scriptures kò kún. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé ti jẹ́ kí àwọn Kristẹni fòye mọ ìtumọ̀ àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn lọ́nà tó péye.
Ṣé O Lè Dáhùn?
• Èé ṣe tí Jèhófà fi ń ṣí àwọn ète rẹ̀ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé?
• Báwo ni àwọn àpọ́sítélì àti àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù ṣe yanjú ọ̀ràn ìkọlà?
• Ọgbọ́n ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìbẹ̀rẹ̀ lò, kí ló sì mú kó jẹ́ aláìláfiwé?
• Ṣàkàwé bí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ṣe tàn nígbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Charles Taze Russell mọ̀ pé ìmọ́lẹ̀ yóò tàn sórí ìwé Ìṣípayá nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run