Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà—Ànímọ́ Tó Ń gbé Àlàáfíà Lárugẹ

Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà—Ànímọ́ Tó Ń gbé Àlàáfíà Lárugẹ

Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà—Ànímọ́ Tó Ń gbé Àlàáfíà Lárugẹ

Ayé yìí ì bá mà dùn-ún gbé o, tó bá jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ló jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà. Àwọn èèyàn yóò dín ohun tí wọ́n fẹ́ ká ṣe fún wọn kù, àwọn mẹ́ńbà ìdílé yóò dín aáwọ̀ kù, àwọn ilé iṣẹ́ yóò dín bíbára wọn díje kù, àwọn orílẹ̀-èdè kò ní fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ aríjàgbá mọ́. Ṣé wàá fẹ́ gbé ní irú àyíká yẹn?

ÀWỌN olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ń múra sílẹ̀ fún ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, níbi tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yóò ti jẹ́ ohun tí à ń fẹ́ káàkiri àgbáyé, tí a kò ní kà á sí àìlera, ṣùgbọ́n tí a ó kà á sí ànímọ́ tó dára àti ìwà rere. (2 Pétérù 3:13) Àní, wọ́n ti ń mú ànímọ́ tí à ń pè ní ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yìí dàgbà nísinsìnyí. Èé ṣe? Ìdí pàtàkì ni pé èyí ni ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa. Wòlíì rẹ̀ Míkà kọ̀wé pé: “Ó ti sọ fún ọ, ìwọ ará ayé, ohun tí ó dára. Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—Míkà 6:8.

Ohun tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà túmọ̀ sí pọ̀, lára rẹ̀ ni jíjẹ́ ẹni tí kò jọra rẹ̀ lójú, ẹni tí kì í gbéra ga, ẹni tí kì í fi òye tó ní, àṣeyọrí tó ṣe, àti ohun ìní rẹ̀ yangàn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ ti sọ, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tún túmọ̀ sí “kéèyàn má kọjá àyè ẹ̀.” Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà yóò máa hùwà ọmọlúwàbí. Yóò mọ̀ pé ó níbi tó yẹ kí òun ṣe é dé, ó sì níbi tí agbára òun mọ. Ó mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tí òun ò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Dájúdájú, ó máa ń wù wá láti fà mọ́ àwọn èèyàn tó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Joseph Addison, akéwì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, kọ̀wé pé: “Kò tún sóhun tó fani mọ́ra láyé yìí ju ìmẹ̀tọ́mọ̀wà lọ.”

Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà kì í ṣe ànímọ́ àwa ènìyàn aláìpé. A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi ká tó lè mú ànímọ́ yìí dàgbà. Láti lè fún wa níṣìírí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíi mélòó kan tó fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn ní onírúurú ọ̀nà.

Àwọn Ọba Méjì Tí Wọ́n Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà

Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ adúróṣinṣin jù lọ ni Dáfídì, ọ̀dọ́mọkùnrin ni nígbà táa fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la fún Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn ìyẹn ni Sọ́ọ̀lù Ọba, ẹni tó wà lórí oyè nígbà yẹn gbógun ńlá ti Dáfídì, ó fẹ́ pa á, ó sì tún mú kó máa sá káàkiri.—1 Sámúẹ́lì 16:1, 11-13; 19:9, 10; 26:2, 3.

Àní lábẹ́ àwọn ipò yẹn pàápàá, Dáfídì mọ̀ pé ohun tí òun lè ṣe láti dáàbò bo ẹ̀mí òun níwọ̀n. Nígbà kan, nínú aginjù, Dáfídì kò jẹ́ kí Ábíṣáì ṣe Sọ́ọ̀lù Ọba tó ti sùn fọnfọn léṣe, ó sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, láti na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Jèhófà!” (1 Sámúẹ́lì 26:11) Dáfídì mọ̀ pé kò tọ́ sóun láti rọ Sọ́ọ̀lù lóyè. Nípa báyìí, Dáfídì fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn ní àkókò yìí nípa mímọ ìwọ̀n ara rẹ̀. Bákan náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí mọ̀ pé “ní ojú ìwòye Jèhófà,” àwọn nǹkan kan wà táwọn ò gbọ́dọ̀ ṣe, kódà bí ẹ̀mí ènìyàn bá wà nínú ewu.—Ìṣe 15:28, 29; 21:25.

Sólómọ́nì, ọmọ Dáfídì Ọba fi hàn pé òun mẹ̀tọ́mọ̀wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tó gbà ṣe tiẹ̀ yàtọ̀. Nígbà tí Sólómọ́nì gorí ìtẹ́, ó gbà pé òun ò tóó rẹrù ọba. Ló bá gbàdúrà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi, ìwọ fúnra rẹ ni ó fi ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dáfídì baba mi, ọmọdékùnrin kékeré sì ni èmi. Èmi kò mọ bí a ti ń jáde lọ àti bí a ti ń wọlé.” Ó ṣe kedere pé, Sólómọ́nì mọ̀ pé òun ò lóye, òun ò sì ní ìrírí. Ó mẹ̀tọ́mọ̀wà, kò jọra rẹ̀ lójú, kò sì gbéra ga. Sólómọ́nì ní kí Jèhófà fún òun ni ìfòyemọ̀, ó sì fún un.—1 Àwọn Ọba 3:4-12.

Mèsáyà àti Ẹni Táa Rán Ṣáájú Rẹ̀

Ó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ọjọ́ Sólómọ́nì, ni Jòhánù Oníbatisí ṣe iṣẹ́ títún ọ̀nà ṣe fún Mèsáyà náà. Gẹ́gẹ́ bí ẹni táa rán ṣáájú Ẹni Àmì Òróró náà, Jòhánù mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Ká lẹ́lòmíì ni, ì bá ti máa fi àǹfààní yẹn yangàn. Jòhánù ì bá sì ti máa bọlá fún ara rẹ̀ nítorí pé mọ̀lẹ́bí Mèsáyà náà ló jẹ́. Ṣùgbọ́n Jòhánù sọ fún àwọn èèyàn pé òun ò tiẹ̀ tóó tú okùn bàtà Jésù. Nígbà tí Jésù sì wá láti ṣe batisí ní Odò Jọ́dánì, Jòhánù wí pé: “Èmi ni ó yẹ kí a batisí láti ọwọ́ rẹ, ìwọ ha sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ mi bí?” Èyí fi hàn pé Jòhánù kì í ṣe agbéraga. Ó jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà.— Mátíù 3:14; Málákì 4:5, 6; Lúùkù 1:13-17; Jòhánù 1:26, 27.

Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ó dáwọ́ lé iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù jẹ́ ẹni pípé, ó wí pé: “Èmi kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe tí ara mi . . . kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mo ń wá, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” Síwájú sí i, Jésù kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ó fi ògo gbogbo ohun tó ṣe fun Jèhófà. (Jòhánù 5:30, 41-44) Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tirẹ̀ mà tún ga o!

Nígbà náà, ó ṣe kedere pé àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà, irú àwọn bíi Dáfídì, Sólómọ́nì, Jòhánù Oníbatisí, àti ọkùnrin pípé nì pàápàá, Jésù Kristi, fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn. Wọn ò ṣe fọ́ńté, wọn ò gbéra ga, wọn ò jọra wọn lójú, wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn. Àwọn àpẹẹrẹ wọn ti tó fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní láti mú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà dàgbà, kí wọ́n sì fi í hàn. Síbẹ̀, àwọn ìdí mìíràn ṣì wà láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Nínú àkókò onídààmú tí aráyé ń gbé lónìí, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ló jẹ́ ànímọ́ tó ṣe pàtàkì gidigidi fún àwọn Kristẹni tòótọ́. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, àti pé ó ń jẹ́ kí àwa pàápàá ní ìbàlẹ̀-ọkàn.

Wíwà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run

A lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà kìkì tí a ò bá ti kọjá ààlà tó là sílẹ̀ fún ìjọsìn tòótọ́. Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, kọjá ààlà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀, wọ́n di ènìyàn àkọ́kọ́ tó di aláìmẹ̀tọ́mọ̀wà. Wọ́n ba ìdúró rere tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, wọ́n ba ilé wọn jẹ́, wọ́n ṣe ọjọ́ ọ̀la wọn báṣubàṣu, wọ́n fọ́ ìgbésí ayé wọn yángá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5, 16-19) Áà, wọ́n mà sọ nǹkan gidi nù o!

Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára ìṣubú Ádámù àti Éfà, nítorí ìjọsìn tòótọ́ jẹ́ ká mọ ìwà tó yẹ ká máa hù. Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé, “kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Nítorí àǹfààní ara wa ni Jèhófà ṣe fi ọgbọ́n gbé ìlànà wọ̀nyí kalẹ̀, báa bá tẹ̀ lé e, yóò fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n. (Aísáyà 48:17, 18) Òwe orí kọkànlá, ẹsẹ kejì sọ fún wa pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”

Ṣùgbọ́n, ká ní ètò ẹ̀sìn kan sọ fún wa pé a lè ré ìlànà wọ̀nyí kọjá, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run ńkọ́? Ètò àjọ yẹn ń ṣì wá lọ́nà ni o. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run.

Wíwà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Ènìyàn Ẹlẹgbẹ́ Wa

Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tún máa ń gbé àjọṣe alálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lárugẹ. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn òbí bá fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti jíjẹ́ ẹni tó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun kòṣeémánìí wọn, tí wọ́n sì tún ń fi àwọn ohun tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́, kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ wọn yóò fẹ́ mú irú ìwà kan náà dàgbà. Yóò wá rọrùn fún àwọn ọmọdé láti ní ìtẹ́lọ́rùn, kódà bí ohun tí wọ́n ń fẹ́ ò tiẹ̀ fìgbà gbogbo tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, ìgbésí ayé ìdílé wọn yóò sì jẹ́ èyí tó lálàáfíà.

Àwọn tó di ipò aláàbójútó mú ní láti kíyè sára gidigidi, kí wọ́n jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà, kí wọ́n má sì ṣe ṣi ọlá àṣẹ wọn lò. Fún àpẹẹrẹ, a fún àwọn Kristẹni nítọ̀ọ́ni pé: “Má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 4:6) Àwọn alàgbà ìjọ mọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti sọ pé òun tó wu àwọn ló gbọ́dọ̀ wu àwọn ẹlòmíì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọn yóò gbé ìmọ̀ràn tí wọ́n ń fúnni kà, nípa ìwà híhù, ìwọṣọ, ìmúra, tàbí eré ìnàjú. (2 Tímótì 3:14-17) Nígbà tí àwọn mẹ́ńbà ìjọ bá ń ṣàkíyèsí pé àwọn alàgbà ń tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, èyí yóò jẹ́ kí wọ́n lè bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, yóò sì fi kún ọ̀yàyà, ìfẹ́, àti ẹ̀mí àlàáfíà tó wà nínú ìjọ náà.

Ìbàlẹ̀-Ọkàn

Àwọn tí wọ́n jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń ní ìbàlẹ̀-ọkàn. Ẹni tó jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà kì í ní ẹ̀mí nǹkan gígagíga. Kì í ṣe pé kò ní ní góńgó tirẹ̀ o. Fún àpẹẹrẹ, ó lè fẹ́ àwọn àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, ṣùgbọ́n yóò dúró de Ọlọ́run, gbogbo àǹfààní ti Kristẹni tó bá sì rí gbà, Jèhófà ni yóò máa fi ògo rẹ̀ fún. Kò ní kà á sí mímọ̀ọ́ṣe tirẹ̀. Èyí ń mú kí ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, “Ọlọ́run àlàáfíà.”—Fílípì 4:9.

Ká ní a máa ń rò pé àwọn èèyàn ń fojú pa wá rẹ́ nígbà míì. Ǹjẹ́ kò ní dára káwọn èèyàn fojú pa wá rẹ nítorí pé a jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà dípò tí a ó fi máa pe àfiyèsí sí ara wa lọ́nà tó fi hàn pé a ò mẹ̀tọ́mọ̀wà? Ọkàn àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà kì í ga jù. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń ní ìbàlẹ̀-ọkàn, èyí sì ń ṣàǹfààní fún ìlera wọn nípa tara àti ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan.

Mímú Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Dàgbà àti Bíbá Ìwà Náà Nìṣó

Ádámù àti Éfà di aláìmẹ̀tọ́mọ̀wà—wọ́n sì tàtaré ìwà yìí sí àtọmọdọ́mọ wọn. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣe? Báwo la ṣe lè mú ànímọ́ àtàtà yìí tí à ń pè ní ìmẹ̀tọ́mọ̀wà dàgbà?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, táa bá lóye ipò táa wà sí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àgbáyé dáadáa, yóò ràn wá lọ́wọ́. Àwọn àṣeyọrí wo la lè sọ pé a ti ṣe ná táa wá lè fi wé àṣeyọrí Ọlọ́run? Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀? Sọ fún mi, bí o bá mòye.” (Jóòbù 38:4) Jóòbù ò lè dáhùn. Ǹjẹ́ kò níbi tí ìmọ̀, òye, àti ìrírí tiwa náà mọ bíi ti ọkùnrin yìí? Ǹjẹ́ kò ṣàǹfààní fún wa pé ká mọ̀wọ̀n ara wa?

Síwájú sí i, Bíbélì sọ fún wa pé: “Ti Jèhófà ni ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀, ilẹ̀ eléso àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.” “Gbogbo ẹran inú igbó, àwọn ẹranko tí ń bẹ lórí ẹgbẹ̀rún òkè ńlá” wà lára ohun tí à ń sọ yìí. Jèhófà sọ pé: “Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà.” (Sáàmù 24:1; 50:10; Hágáì 2:8) Kí la lè ní táa wá le fi wé ohun tí Jèhófà ní? Kódà, èèyàn tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé yìí pàápàá kò gbọ́dọ̀ fi ohun tó ní yangàn! Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn onímìísí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni ní Róòmù pé: “Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.”—Róòmù 12:3.

Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ mú ẹ̀mí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà dàgbà, ó yẹ ká gbàdúrà fún èso ti ẹ̀mí—ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu. (Lúùkù 11:13; Gálátíà 5:22, 23) Èé ṣe? Nítorí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ànímọ́ yìí yóò jẹ́ kó rọrùn fún wa láti jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà. Fún àpẹẹrẹ, ìfẹ́ táa ní fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbógun ti ẹ̀mí ìgbéraga tàbí ìṣe-fọ́ńté. Níní ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu yóò sì mú kí a sinmẹ̀dọ̀, ká ronú ká tó hùwà bí ẹni tí kò mẹ̀tọ́ mọ̀wà.

Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra! Ìgbà gbogbo ló yẹ ká wà lójúfò ká má bàa jìn sí kòtò àìmẹ̀tọ́mọ̀wà. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni méjì nínú àwọn ọba táa mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà. Dáfídì Ọba kò kíyè sára, ó ṣètò ìkànìyàn ní Ísírẹ́lì, ohun kan tí inú Jèhófà ò dùn sí. Ọba Sólómọ́nì di aláìmẹ̀tọ́mọ̀wà dórí pé ó lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké.—2 Sámúẹ́lì 24:1-10; 1 Àwọn Ọba 11:1-13.

Níwọ̀n ìgbà tí ètò àwọn ènìyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí bá ṣì ń bá a lọ, ó béèrè pé ká wà lójúfò nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n, ìsapá èyíkéyìí táa bá ṣe kì í ṣe lórí asán. Nínú ètò tuntun Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà ni yóò para pọ̀ jẹ́ àwùjọ ènìyàn tí yóò wà níbẹ̀. Wọ́n yóò ka ìmẹ̀tọ́mọ̀wà sí okun, wọn kò ní kà á sí àìlera. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó nígbà tí gbogbo ènìyàn àti ìdílé bá di ẹni táa fi àlàáfíà tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ń mú wá bù kún!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà mú kí Jésù fi ògo gbogbo ohun tó ṣe fún Jèhófà