Sísọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Èèyàn ní Ítálì
Àwa Ni Irú Àwọn Ẹni Tó Nígbàgbọ́
Sísọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Èèyàn ní Ítálì
JÈHÓFÀ ni “Ọlọ́run ìtùnú.” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ “lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú” nípa fífara wé e. (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Éfésù 5:1) Èyí jẹ́ ọ̀kan lára lájorí ète iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe.
A Ṣèrànwọ́ fún Obìnrin Kan Tó Nílò Ìrànlọ́wọ́
Ní pàtàkì, ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ipò òṣì, ogun, àti ìfẹ́ àtigbé ìgbésí ayé tó rọrùn ti mú kí àwọn kan ṣí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Àmọ́ kì í rọrùn láti tètè mú ara ẹni bá ipò tuntun mu. Manjola pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Albanian ló jọ ń gbé ní ìlú Borgomanero. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé kò níwé àṣẹ láti máa gbé ní Ítálì lọ́wọ́, kì í fẹ́ bá Wanda tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, níkẹyìn, Wanda ṣètò láti bá Manjola fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀, kíá ló sì fi ìfẹ́ hàn nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìgbédè ara wọn kọ́kọ́ fẹ́ fa ìṣòro. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìbẹ̀wò díẹ̀, Wanda kò bá ẹnikẹ́ni nílé mọ́. Kí ló ṣẹlẹ̀? Wanda gbọ́ pé gbogbo àwọn tó ń gbélé yẹn ti bẹ́sẹ̀ wọn sọ̀rọ̀ nítorí pé, àwọn agbófinró ń wá ọ̀kan lára wọn—ìyẹn ni ọ̀rẹ́kùnrin Manjola—wọ́n ló pààyàn!
Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, Wanda tún rí Manjola. Wanda rántí pé, nígbà tí òun rí i “ó ti funfun, ó sì ti gbẹ, kò dìgbà tó bá sọ fún ẹ kóo tó mọ̀ pé ìgbésí ayé ò rọrùn fún un.” Ni Manjola bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní ọ̀rẹ́kùnrin òun ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ tí òun sì lọ bá pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́ ni wọ́n já òun kulẹ̀ pátápátá. Nígbà tọ́ràn náà wá sú u pátápátá, ló bá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó dákun ran òun lọ́wọ́. Ìgbà yẹn ló wá rántí Wanda, ẹni tó ti bá a sọ̀rọ̀ rí nípa Bíbélì. Nígbà tí Manjola fojú kan Wanda, bí wọ́n bá gẹṣin nínú ẹ̀ kò lè kọsẹ̀!
Ni wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká tó wí ká tó fọ̀, Manjola ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé àwọn Kristẹni. Èyí táa ń wí yìí pẹ́, ó ti rí ìwe àṣẹ gbà láti máa gbé ní Ítálì. Lẹ́yìn ọdún kan, Manjola ti di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi. Nítorí tí àwọn ìlérí Ọlọ́run tù ú nínú, ó ti padà sí Albania báyìí, ó fẹ́ lọ máa sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fún àwọn aráàlú rẹ̀.
Jíjẹ́rìí ní Ibùdó Àwọn Aṣíwọ̀lú
Ọ̀pọ̀ ìjọ tó wà ní Ítálì ló ti ṣètò láti jẹ́rìí fún àwọn tó ṣí wọ̀lú wọn, ìyẹn ni àwọn èèyàn bíi Manjola. Fún àpẹẹrẹ, ìjọ kan ní ìlú kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Florence ṣètò láti máa ṣèbẹ̀wò sí ibùdó àwọn aṣíwọ̀lú déédéé.
Onírúurú ìyà ló ń jẹ àwọn tó ń gbé ibùdó yìí, púpọ̀ lára wọn ló sì wá láti Ìlà Oòrùn Yúróòpù, Makedóníà, àti Kosovo. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé jíjoògùnyó tàbí mímu ọtí àmujù nìṣòro tiwọn. Àwọn míì sì rèé, iṣẹ́ gbéwiri ni wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn.Wíwàásù ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Ìwé Mímọ́ fún àwọn tó wà ní àdúgbò yìí jẹ́ ìpèníjà. Ṣùgbọ́n, ẹnì kan tó jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Paola bá Jaklina tó jẹ́ obìnrin ará Makedóníà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Lẹ́yìn ìjíròrò díẹ̀, Jaklina rọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Susanna láti yẹ Bíbélì wò. Ni Susanna náà tún gbéra, tó lọ bá àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ mìíràn sọ̀rọ̀. Kò pẹ́, kò jìnnà, ẹni márùn-ún nínú ìdílé náà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, wọ́n ti ń lọ sípàdé àwọn Kristẹni déédéé, wọ́n sì ti ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dojú kọ ìṣòro, wọ́n rí ìtùnú lọ́dọ̀ Jèhófà àti láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkàngbé Rí Ìtùnú Gbà Lọ́dọ̀ Jèhófà
Ní ìlú kan tó ń jẹ́ Formia, ajíhìnrere alákòókò kíkún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Assunta bá obìnrin kan, tó jẹ́ pé agbára káká ló fi ń rìn, sọ̀rọ̀. Ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé lobìnrin yìí, ẹ̀sìn kan tó ń tọ́jú àwọn aláìsàn àti àwọn abirùn nílé ìwòsàn àti nílé àdáni ló sì ń bá ṣiṣẹ́.
Assunta sọ fún ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé náà pé: “Ìyà ń jẹ ìwọ náà o, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó mà ṣe o, kò sẹ́ni tí kò níṣòro.” Bí ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé náà ṣe gbọ́ gbólóhùn yìí, ló bá bú sẹ́kún, ló bá ṣàlàyé pé, àìsàn burúkú kan ń ṣe òun. Ni Assunta bá rọ̀ ọ́ pé, kó ṣara gírí, pé Ọlọ́run tó ni Bíbélì yóò tù ú nínú. Ni obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé yìí bá gba àwọn ìwé ìròyìn táa gbé ka Bíbélì tí Assunta fi lọ̀ ọ́.
Nígbà tí wọ́n tún jọ sọ̀rọ̀, ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé yìí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Palmira, gbà pé ìyà gidi ń jẹ òun. Ó ti pẹ́ tó ti ń gbé ní ilé iṣẹ́ kan tí àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé ń bójú tó. Ìgbà tí ara rẹ̀ ò yá, tó sáré lọ tọ́jú ara rẹ̀, ni wọn ò gbà á padà síbẹ̀ mọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, Palmira dúró ti ẹ̀jẹ́ tó ti bá Ọlọ́run jẹ́, láti máa gbé ìgbésí ayé ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé. Ló bá wá “ìtọ́jú” lọ sọ́dọ̀ àwọn oníwòsàn, lẹ́nu èyí ni ọpọlọ rẹ̀ ti dà rú. Palmira gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì lọ sí ìpàdé àwọn Kristẹni fún odindi ọdún kan. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá kó lọ sí àgbègbè mìíràn, tí àwọn Ẹlẹ́rìí kò sì mọ ibi tó ń gbé mọ́. Ọdún méjì kọjá kí Assunta tún tó fojú kàn án. Palmira dojú kọ àtakò gbígbóná látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀ àti àwọn àlùfáà. Síbẹ̀síbẹ̀, ó padà sídìí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ nínú Bíbélì, ó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ èèyàn la ti fún níṣìírí látinú ọ̀rọ̀ “Ọlọ́run tí ń pèsè ìtùnú.” (Róòmù 15:4, 5) Ìdí rèé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ítálì fi pinnu láti máa báa nìṣó ní fífarawé Ọlọ́run nípa mímú ọ̀rọ̀ ìtùnú àgbàyanu rẹ̀ tọ àwọn èèyàn lọ.