ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́
Kí Làwọn Èèyàn Ń Rí Nínú Eré Tó Léwu?
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
“Mò ń fi bàtà onítáyà sáré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ ojú irin kan bó ṣe ń bá eré lọ. Bí mo ṣe ń gbádùn eré náà ní àkókò yẹn jẹ́ kó dà bíi pé ìṣòro mi ti fò lọ.”—Leon. *
“Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá bẹ́ sódò láti orí òkè tó ga. Láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ yẹn, mo máa ń gbádùn ẹ̀ gan-an, àmọ́ nígbà míì àyà mi máa ń já.”—Larissa.
Bíi ti Leon àti Larissa, inú àwọn ọ̀dọ́ máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá ń ṣe irú àwọn eré báyìí, wọ́n máa ń fẹ́ fi hàn pé koko lara àwọn le bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe lè pa wọ́n lára. Ṣé ó máa ń wu ìwọ náà láti ṣe irú àwọn eré bẹ́ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
Irú eré bẹ́ẹ̀ lè di bárakú fún ẹ. Ó lè mú kí inú ẹ dùn fún ìgbà díẹ̀, lẹ́sẹ̀ kan náà, á tún wù ẹ́ pé kí inú ẹ dùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Marco tí òun náà fẹ́ràn láti máa fi bàtà onítáyà sáré bíi ti Leon sọ pé: “Béèyàn ṣe ń ṣe irú eré yìí tó láá máa wù ú pé kó tún ṣeré míì tó le ju ìyẹn lọ. Inú ẹ lè kọ́kọ́ dùn díẹ̀. Àmọ́ kò ní pẹ́ tí á fi máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o tún ṣeré míì tí á mú inú ẹ dùn ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
Justin náà máa ń fi bàtà onítáyà sáré lójú títì, àwọn mọ́tò tó ń lọ ni òun máa ń dìrọ̀ mọ́, ó sọ pé: “Bó ṣe máa ń dùn mọ́ mi máa ń mú kí n fẹ́ tún un ṣe. Mo fẹ́ kí àwọn èèyàn máa yẹ́ mi sí, àmọ́ ilé ìwòsàn ni mo gbẹ̀yìn sí.”
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè mú kó o ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Marvin sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń rọ̀ mí pé kí n pọ́n ilé kan tó ga, wọ́n ń sọ pé: ‘O lè ṣe é. Kò le.’ Àyà mi ń já, bẹ́ẹ̀ ni mò ń gbọ̀n bí mo ṣe ń pọ́n ògiri náà lọ.” Larissa tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe ni èmi náà ń ṣe. Èmi náà ń fara wé wọn.”
Àwọn kan tún máa ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì láti ti àwọn míì sí eré tó léwu, wọ́n máa ń yin àwọn tó ń ṣeré tó léwu. Tí àwọn tó ń ṣeré tó léwu yìí bá gbé fídíò ohun tí wọ́n ṣe sórí ìkànnì àjọlò, ńṣe ni àwọn èèyàn máa ń kan sáárá sí wọn, àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ yìí máa ń mórí wọn wú.
Bí àpẹẹrẹ, lóde òní, ọ̀pọ̀ fídíò ló ń gbé eré kan jáde tí àwọn èèyàn fẹ́ràn láti máa wò. Eré náà ni parkour. Ohun tí
wọ́n máa ń ṣe níbẹ̀ ni pé wọ́n á máa sáré wọ́n á sì máa fo ohunkóhun tó bá wà lọ́nà ì báà jẹ́ ilé, ògiri tàbí àtẹ̀gùn, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn kì í lo ohunkóhun tó lè dáàbò bò wọ́n. Èyí lè mú kéèyàn máa rò pé: (1) Kò fi bẹ́ẹ̀ léwu àti pé (2) Àwọn míì náà ń ṣe é. Tó bá yá, ìwọ náà á fẹ́ láti ṣe irú eré bẹ́ẹ̀.Àwọn nǹkan míì wà tó dáa tó o lè fi agbára rẹ ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.” (1 Tímótì 4:8) Ìwé Mímọ́ tún kìlọ̀ pé kó o máa “gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.” (Títù 2:12) Báwo lo ṣe lè ṣe é?
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Ronú lórí ewu tó wà níbẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ arìndìn yóò tan ìwà òmùgọ̀ káàkiri.” (Òwe 13:16) Kó o tó lọ́wọ́ sí ohunkóhun, kọ́kọ́ ronú lórí ewu tó wà níbẹ̀. Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé eré tí mo fẹ́ ṣe yìí lè gba ẹ̀mí mi tàbí ó lè pa mí lára?’—Ìlànà Bíbélì: Òwe 14:15.
Àwọn ọ̀rẹ́ tó mọyì ẹ̀mí ni kó o máa bá rìn. Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ kò ní tàn ẹ́ pé kó o ṣe eré tó léwu tàbí ohun tí o kò nífẹ̀ẹ́ sí. Larissa tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ gidi tí mò ń bá rìn ràn mí lọ́wọ́ láti yan eré tí ó dáa láti ṣe. Wọ́n ní ipa rere lórí ìgbésí ayé mi.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 13:20.
Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé eré tí mo fẹ́ ṣe yìí lè gba ẹ̀mí mi tàbí ó lè pa mí lára?’
Gbádùn àwọn ohun tó o fẹ́ràn láti ṣe láìfi ẹ̀mí ara ẹ wewu. Ìwé kan tó ń jẹ́ Adolescent Risk Behaviors sọ pé, ara ohun tó fi hàn pé ẹnìkan ti ń dàgbà ni bí onítọ̀hún ṣe ń “kọ́ bó ṣe lè gbé àwọn ìlànà kan kalẹ̀ fún ara rẹ̀, kó má sì kọjá àyè rẹ̀.” O lè dán ara rẹ wò láti mọ bó o ṣe mọ nǹkan pàtó kan ṣe sí, àmọ́ kó jẹ́ níbi tí kò sí ewu, kí o sì lo àwọn nǹkan tó lè dáàbò bò ẹ́.
Pọ́n ara rẹ lé. Kì í ṣe bó o ṣe ń ṣe eré tó léwu tó ló máa jẹ́ kí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ẹ, bí kò ṣe bí o ṣe ń fi ọgbọ́n borí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Larissa sọ pé: “Mi ò bá ti kú dà nù ní gbogbo àkókò tí mò ń ṣe bó ṣe wù mí tí mò ń bẹ́ látorí òkè tó ga. Ì bá dáa ká sọ pé mo ti sọ pé “mi ò ṣe” nígbà yẹn.”
Kókó ibẹ̀: Dípò tí wàá fi máa fi ẹ̀mí ara ẹ wewu láìnídìí, fi ọgbọ́n yan eré ìnàjú tó bójú mu tó o lè ṣe.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 15:24.
^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.