JÍ! No. 5 2017 | Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa múra sílẹ̀ ṣáájú kí àjálù tó dé?
Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà tí ó ti rí ìyọnu àjálù ti fi ara rẹ̀ pa mọ́; aláìní ìrírí tí ó ti gba ibẹ̀ kọjá ti jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 27:12.
Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe kí àjálù tó wáyé, nígbà àjálù àti lẹ́yìn tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là
Àwọn àbá yìí lè gba ẹ̀mí ẹ àti tàwọn mí ì là.
Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Nǹkan Lò
Wo àwọn ọ̀nà tó o lè gbà máa ṣọ́ àwọn nǹkan lò nínú ilé, tó o bá ń rìnrìn àjò àti nínú ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́.
OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ogun
Ní ayé àtijọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń jagun ní orúkọ Ọlọ́run wọn Jèhófà. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun táwọn èèyàn ń jà lónìí?
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Kí Làwọn Èèyàn Ń Rí Nínú Eré Tó Léwu?
Inú àwọn ọ̀dọ́ máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá ń ṣe irú àwọn eré báyìí, wọ́n máa ń fẹ́ fi hàn pé koko lara àwọn le bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe lè pa wọ́n lára. Ṣé ó máa ń wu ìwọ náà láti ṣe irú àwọn eré bẹ́ẹ̀?
ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN
Ẹ Já Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan
Láyé àtijọ́, darandaran ni àwọn èèyàn ilẹ̀ Kazakhstan inú ilé kan tó rí roboto ni wọ́n sábà máa ń gbé. Báwo wa ni ìgbé ayé wọn nísìnyí ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa àṣà ìbílẹ̀ wọn?
Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì
Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Jagun?
Jákèjádò ayé ni wọ́n ti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé a kì í lọ́wọ́ sí ogun. Kọ́ nípa ìdí tí a kì í fi í lọ́wọ́ sí ogun.
Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀, Ìfẹ́ Máa Ń Mú Ká Ṣèrànwọ́
Onírúurú orílẹ̀-èdè làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù.