Ṣé O Ní Ìkórìíra?
Ẹ̀tanú tàbí ìkórìíra dà bíi kòkòrò àrùn. Àwọn tó ní in lè má mọ̀ rárá pé àwọn ní in. Ìyà ńlá ló sì máa ń jẹ ẹni tí wọ́n bá ń ṣe ẹ̀tanú sí.
Àwọn èèyàn máa ń kórìíra àwọn tí orílẹ̀-èdè wọn, ẹ̀yà wọn àti èdè wọn yàtọ̀ sí tiwọn. Bákan náà, wọ́n tún máa ń kórìíra àwọn tí ẹ̀sìn wọn àti ipò tí wọ́n wà láwùjọ yàtọ̀ sí tiwọn, wọ́n sì tún lè kórìíra àwọn míì torí pé wọ́n jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Àwọn kan máa ń fojú tí kò dáa wo àwọn èèyàn kan nítorí ọjọ́ orí wọn, bí wọ́n ṣe kàwé tó, àbùkù ara wọn tàbí ìrísí wọn. Síbẹ̀ wọ́n rò pé àwọn ò ní ẹ̀tanú tàbí ìkórìíra.
Ṣé o ní ẹ̀tanú? Ọ̀pọ̀ lára wa ló máa ń sọ pé àwọn kan ní ẹ̀tanú. Ṣùgbọ́n, a lè má mọ̀ pé àwa náà máa ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn kan. Ká sòótọ́, gbogbo wa la máa ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn èèyàn lọ́nà kan tàbí òmíì. Ọ̀jọ̀gbọ́n David Williams tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé tẹ́nì kan bá ń fojú burúkú wo àwọn ọmọ ìlú kan, tó bá wá pàdé ẹnì kan tó wá láti ìlú náà, “kò ní hùwà tó dáa sí onítọ̀hún, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó lè má mọ̀ rárá pé òun hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.”
Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀yà kékeré kan wà ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jovica ń gbé. Jovica sọ pé: “Mo gbà pé kò séèyàn dáadáa kankan lára àwọn ẹ̀yà náà. Àmọ́ mi ò tiẹ̀ rò pé ẹ̀tanú ló jẹ́ kí n nírú èrò yẹn. Torí mo rò ó lọ́kàn mi pé ‘kò kúkú séèyàn gidi lára wọn lóòótọ́.’”
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti ṣòfin pé àwọn ò fàyè gba kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìkórìíra. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ṣì lẹ́mìí ìkórìíra. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé ńṣe ni wọ́n kàn ṣe àwọn òfin yẹn káwọn èèyàn má bàa hùwà tí kò dáa. Wọn ò ṣe é káwọn èèyàn má bàa ní èrò tí kò dáa. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, inú ọkàn ni ẹ̀tanú àti ìkórìíra ti ń bẹ̀rẹ̀. Ṣé ohun kan wà tá a lè ṣe láti borí ẹ̀mí ìkórìíra? Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ìkórìíra mọ́?
Nínú ìwé yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìlànà márùn-ún tó ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn borí ẹ̀tanú àti ìkórìíra.