Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò
Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
Tó bá jẹ́ pé báwọn kan ṣe yàtọ̀ sí wa là ń rò ṣáá, ìyàtọ̀ tá a rí yẹn lè wá di àbùkù. Àá wá máa ṣe ẹ̀tanú sáwọn tó yàtọ̀ sí wa torí pé a gbà pé èèyàn tí kò dáa ni wọ́n. Èrò tí kò dáa tá a ní nípa wọn yìí á wá mú kó ṣòro fún wa láti máa gba tiwọn rò. Èyí fi hàn pé tá ò bá lẹ́mìí ìgbatẹnirò, ó lè mú ká ní ẹ̀tanú sáwọn èèyàn tàbí ká kórìíra wọn.
Ìlànà Bíbélì
“Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.”—RÓÒMÙ 12:15.
Kí la rí kọ́? Ohun tí ìlànà Bíbélì yìí ń kọ́ wa ni pe ká máa gba tàwọn èèyàn rò. Ohun tí ìgbatẹnirò túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fi ara ẹ̀ sípò àwọn ẹlòmíì, kó sì fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara ẹ̀ wò.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò
Tá a bá fi ara wa sípò ẹlòmíì, àá rí bí ọ̀rọ̀ àwa àti ẹni náà ṣe jọra. A lè wá rí i pé bákan náà ni nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Ta a bá ń gba tàwọn ẹlòmíì rò, á jẹ́ ká rí i pé inú ìdílé kan náà ni gbogbo èèyàn ti wá láìka ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà sí. Tá a bá ń ronú lórí bí ọ̀rọ̀ wa ṣe jọra, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa fojú burúkú wò àwọn èèyàn.
Tá a bá ń gba tàwọn èèyàn rò á jẹ́ ká lè máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Anne-Marie tó wá láti Senegal máa ń fojú burúkú wo àwọn èèyàn kan táwọn èèyàn ò kà sí. Ó ṣàlàyé pé ìgbà tóun bẹ̀rẹ̀ sí í gba tiwọn rò lèrò òun yí pa dà, ó ní: “Nígbà tí mo rí ìyà tó ń jẹ àwọn tí wọn ò kà sí yìí, mo bi ara mi pé, ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi tó bá jẹ́ pé èmi ni irú ìyà yìí ń jẹ?’ ” Èyí mú kí n wá rí i pé mi ò sàn jù wọ́n lọ àti pé gbogbo ohun tí mo ní kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe mi. Ó dájú pé tá a bá ń sapá láti mọ ìṣòro táwọn kan ní, ńṣe làá máa bá wọn dárò, a ò ní máa dá wọn lẹ́jọ́.
Ohun To O Lè Ṣe
Tó o bá ń fojú burúkú wo àwọn ẹ̀yà kan, sapá láti wo bí ọ̀rọ̀ ìwọ àtàwọn èèyàn náà ṣe jọra. Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wo bó ṣe máa rí lára wọn:
Tá a bá ń gba tàwọn ẹlòmíì rò, á jẹ́ ká rí i pé inú ìdílé kan náà ni gbogbo èèyàn ti wá
tí wọ́n bá ń jẹun pẹ̀lú ìdílé wọn
tí wọ́n bá parí iṣẹ́ àṣekára ọjọ́ kọ̀ọ̀kan
tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn
tí wọ́n bá ń gbọ́ orin tí wọ́n fẹ́ràn gan-an
Lẹ́yìn náà, kó o wá fi ara ẹ sípò wọn. Bi ara ẹ pé:
‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi tẹ́nì kan bá fojú ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan wò mí?’
‘Báwo ló ṣe má rí lára mi táwọn èèyàn bá dá mi lẹ́bi láì tíì mọ irú ẹni tí mo jẹ́?’
‘Tó bá jẹ́ pé èmi ni mo wá látinú ẹ̀yà táwọn èèyàn ń fojú burúkú wò yẹn, irú ìwà wo ni màá fẹ́ káwọn èèyàn máa hù sí mi?’