Ìkórìíra Máa Dópin!
Àìmọye èèyàn ló ti sapá gidigidi láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tá a sọ nínú ìwé yìí, wọ́n sì ti mú ìkórìíra kúrò lọ́kàn wọn dé ìwọ̀n tó ga gan-an. Àmọ́ ká sòótọ́, ó kọjá agbára àwa èèyàn láti mú gbogbo ìkórìíra kúrò. Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ẹ̀tanú àti ìkórìíra mọ́?
Ìjọba Tó Dáa Jù Lọ
Ìjọba èèyàn ti sapá gan-an láti mú ìkórìíra kúrò, àmọ́ pàbó ni gbogbo wàhálà wọn já sí. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí ìjọba kankan tó lè mú ẹ̀tanú àti ìkórìíra kúrò ni?
Àwọn ohun tí ìjọba tó máa mú ẹ̀tanú àti ìkórìíra kúrò máa ṣe rèé:
-
1. Á mú káwọn èèyàn máa ní èrò rere sí ọmọnìkejì wọn.
-
2. Á mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn tí wọ́n ti ṣàìdáa sí kúrò.
-
3. Á ní àwọn olórí tó jẹ́ olóòótọ́ tí àwọn fúnra wọn ò sì ní ẹ̀tanú àti ẹ̀mí ìkórìíra.
-
4. Á mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wà níṣọ̀kan.
Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run ti ṣètò ìjọba tó máa ṣe gbogbo nǹkan yìí. Ó pè é ní “Ìjọba Ọlọ́run.”—Lúùkù 4:43.
Wo àwọn ohun tí aráyé máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
1. Ẹ̀kọ́ Ìwà Rere
“Àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà máa kọ́ òdodo.”—ÀÌSÁYÀ 26:9.
“Àlàáfíà ni òdodo tòótọ́ máa mú wá, èso òdodo tòótọ́ sì máa jẹ́ ìparọ́rọ́ àti ààbò tó máa wà pẹ́ títí.”—ÀÌSÁYÀ 32:17.
Kí la rí kọ́? Ìjọba Ọlọ́run máa kọ́ àwọn èèyàn ni ohun tó tọ́. Nígbà tí gbogbo èèyàn bá mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, èrò rere ni wọ́n á máa ní sí ọmọnìkejì wọn. Gbogbo èèyàn á mọ̀ pé ohun tó tọ́ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ onírúurú èèyàn.
2. Kò Ní Sí Ẹ̀dùn Ọkàn Mọ́
Ọlọ́run “máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—ÌFIHÀN 21:4.
Kí la rí kọ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ní ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn torí pé wọ́n ti hùwà ìkà sí wọn. Gbogbo ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora yìí ni Ìjọba Ọlọ́run máa mú kúrò. Àwọn tí wọ́n ti hùwà ìkà sí kò sì ní lẹ́mìí ìkórìíra mọ́.
3. Aṣáájú Rere
“Kò ní gbé ìdájọ́ rẹ̀ ka ohun tó fojú rí, kò sì ní gbé ìbáwí rẹ̀ ka ohun tó fetí gbọ́ lásán. Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́, ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé.”—ÀÌSÁYÀ 11:3, 4.
Kí la rí kọ́? Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso ayé látọ̀run. Ó máa ṣẹ̀tọ́ fún gbogbo èèyàn, kò sì ní ṣojúsàájú. Jésù kì í gbè sẹ́yìn orílẹ̀-èdè kan, kó wá ta ko orílẹ̀-èdè míì, ó sì máa rí sí i pé àwọn òfin òdodo rẹ̀ làwọn èèyàn ń tẹ̀ lé kárí ayé.
4. Ìṣọ̀kan
Ìjọba Ọlọ́run máa kọ́ àwọn èèyàn láti jẹ́ ‘kí èrò wọn àti ìfẹ́ wọn ṣọ̀kan kí wọ́n wà níṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀, kí wọ́n sì ní èrò kan náà lọ́kàn.’—FÍLÍPÌ 2:2.
Kí la rí kọ́? Ìṣọ̀kan gidi ló máa wà láàárín àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n máa “wà níṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀” torí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénúdénú.