Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÀTIJỌ́

Ignaz Semmelweis

Ignaz Semmelweis

IGNAZ SEMMELWEIS, orúkọ yìí kì í ṣe orúkọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀, síbẹ̀ iṣẹ́ tó ṣe ń ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ ìdílé lóde òní. Ìlú Buda (Budapest báyìí) lórílẹ̀-èdè Hungary, ni wọ́n ti bí i. Ó gboyè jáde ní Yunifásítì tó wà nílùú Vienna lọ́dún 1844 gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn òyìnbó. Lọ́dún 1846, ó ríṣẹ́ sí ilé ìwòsàn kan tí wọ́n ń pè ní First Maternity Clinic of Vienna’s General Hospital, ó sì di igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n kan níbẹ̀. Semmelweis dojú kọ ìṣòro kan, ìyẹn ni bí àìsàn kan tí wọ́n ń pè ní childbed fever ṣe ń gbẹ̀mí àwọn obìnrin tó wá bímọ sílé ìwòsàn náà.

Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ti sọ nípa ohun tó ń fa àrùn náà, àmọ́ kò tíì sẹ́nì kankan tó rí ojútùú rẹ̀. Gbogbo ìsapá láti dín bí àrùn náà ṣe ń pa àwọn èèyàn kù ló já sí pàbó. Bí àrùn náà ṣe ń fojú àwọn obìnrin ráre tó sì ń pa wọ́n ń kọ Semmelweis lóminú, torí náà ó pinnu láti wá ohun tó ń fa àrùn náà àti ọ̀nà láti yẹra fún un.

Wọ́ọ̀dù méjì ni wọ́n ti ń gbẹ̀bí fáwọn aláboyún ní ilé ìwòsàn tí Semmelweis ti ń ṣiṣẹ́, àmọ́ àwọn èèyàn máa ń kú ní wọ́ọ̀dù kìíní ju ìkejì lọ. Bẹ́ẹ̀ ìyàtọ̀ tó kàn wà nínú wọ́ọ̀dù méjèèjì kò ju pé wọ́n máa ń dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn lẹ́kọ̀ọ́ níbì àkọ́kọ́, wọ́n sì ń dá àwọn agbẹ̀bí lẹ́kọ̀ọ́ níbì kejì. Kí ló wá fà á tí àrùn náà fi ń pa àwọn èèyàn níbì kan ju ibì kan lọ? Semmelweis ṣèwádìí ohun tó ṣeé ṣe kó fa àìsàn náà, síbẹ̀ kò rí ohun tó ń ṣokùnfà rẹ̀.

Lọ́dún 1847, Semmelweis rí ohun pàtàkì kan tó tọ́ ọ sọ́nà. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ìyẹn Jakob Kolletschka, kú nítorí àìsàn tó kó látinú ẹ̀jẹ̀ nígbà tó ń ṣèwádìí nǹkan tó pa ẹnì kan. Nígbà tí Semmelweis ka àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa ohun tó ṣokùnfà ikú Kolletschka, ó rí i pé láwọn ọ̀nà kan ohun tí wọ́n rí jọ ohun tí wọ́n máa ń rí lára àwọn obìnrin tí àrùn childbed fever pa. Torí náà, Semmelweis ronú pé nǹkan kan tó dà bí májèlé látara àwọn òkú náà ló ń ran àwọn aláboyún tó sì ń fa àrùn childbed fever. Àwọn dókítà àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó máa ń ṣàyẹ̀wò ara àwọn òkú kí wọ́n tó lọ sí wọ́ọ̀dù àwọn aláboyún láti ṣàyẹ̀wò wọn tàbí láti lọ gbẹ̀bí fún wọn ló máa ń kó àìsàn náà ran àwọn tó fẹ́ bímọ láìmọ̀ọ́mọ̀! Àwọn tó ń kú ní wọ́ọ̀dù kejì kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ torí pé àwọn nọ́ọ̀sì tó ń kọ́ṣẹ́ agbẹ̀bí kì í ṣàyẹ̀wò ara àwọn òkú.

Semmelweis wá ṣòfin pé kí ẹnikẹ́ni tó ṣàyẹ̀wò àwọn aláboyún, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi àwọn oògùn apakòkòrò fọ ọwọ́ rẹ̀. Àbájáde tó kàmàmà ló sì tìdí ẹ̀ yọ. Láàárín oṣù mẹ́jọ péré, àwọn aláboyún tó ń kú tí wọ́n bá ń rọbí dínkù gan-an.

“Àfojúsùn mi ni láti gba àwọn ilé ìwòsàn agbẹ̀bí lọ́wọ́ ìṣòro, kí n dá ẹ̀mí ìyàwó sí fún ọkọ rẹ̀, kí n sì dá ẹ̀mí ìyá sí fún ọmọ rẹ̀.”—Ignaz Semmelweis

Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló fara mọ́ àṣeyọrí tí Semmelweis ṣe yìí. Ìdí ni pé ìwádìí tó ṣe ta ko èrò táwọn ọ̀gá rẹ̀ ní nípa ohun tó ń ṣokùnfà àrùn childbed fever. Inú tún bí wọn sí bí Semmelweis ṣe ń mú àwọn èèyàn lọ́ranyàn pé kí wọ́n máa fọwọ́. Bíṣẹ́ ṣe bọ́ lọ́wọ́ Semmelweis nílùú Vienna nìyẹn, ó sì pa dà sí orílẹ̀-èdè Hungary. Nígbà tó débẹ̀, ó ríṣẹ́ sí ilé ìwòsàn St. Rochus Hospital nílùú Pest, ó sì di ọ̀gá àgbà ẹ̀ka tó ń ṣàyẹ̀wò àwọn aláboyún níbẹ̀. Ọ̀nà tó sì ń gbà ṣètọ́jú mú kí àwọn aláboyún tí àrùn childbed fever ń pa dín kù gan-an.

Lọ́dún 1861, Semmelweis tẹ ìwé kan jáde, ó pè é ní The Cause, Concept, and Prophylaxis of Childbed Fever. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí àwọn èèyàn tó ka ìwádìí tó ṣe sí pàtàkì. Ní gbogbo àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kú.

Semmelweis ń rí sí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé ètò ìmọ́tótó tó gbé kalẹ̀ ní àwọn ilé ìwòsàn.—Robert Thom ló ya àwòrán yìí

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn èèyàn wá gbà pé Semmelweis jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó dá ọgbọ́n lílo oògùn apakòkòrò. Ìwádìí tó ṣe wà lára ohun tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn kòkòrò tínńtín tí a kò fojú rí máa ń fa àrùn. Kò sí bí wọ́n ṣe máa sọ ìtàn nípa ìwádìí nípa kòkòrò àrùn tí wọn ò ní dárúkọ Semmelweis. Àwárí tí òun nìkan ṣe wúlò gan-an ó sì ṣàǹfààní fún ìmọ̀ ìṣègùn. Ó gba àfiyèsí pé ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún ṣáájú àkókò yìí, Òfin Mósè, tó wà di apá kan Bíbélì, ti pèsè ìtọ́sọ́nà tó gbéṣẹ́ nípa ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyìí.