OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ìgbàgbọ́
Àwọn kan máa ń sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run, àmọ́ ó ṣòro fún wọn láti mọ ohun tí “ìgbàgbọ́” jẹ́. Kí ni ìgbàgbọ́, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
Kí ni ìgbàgbọ́?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Èrò àwọn kan ni pé ńṣe ni ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ kàn máa ń gba gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún un gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ẹnì kan tó sọ pé “Mo ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.” Tí wọ́n bá béèrè lọ́wọ́ onítọ̀hún pé, “Kí nìdí tó o fi gbà gbọ́?” Ó lè sọ pé, “Bí wọ́n ṣe tọ́ mi dàgbà nìyẹn” tàbí “Ohun tí wọ́n fi kọ́ mi láti kékeré nìyẹn.” A lè rí i pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò mọ ìyàtọ̀ ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́ àti kéèyàn kàn gba ohun tí wọ́n sọ fún un gbọ́ láìwádìí.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Kí ohun tí ẹnì kan ń retí tó lè dá a lójú, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé ọwọ́ òun máa tẹ nǹkan ọ̀hún. Kódà, ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú” kọjá ìmọ̀lára èèyàn tàbí ohun kan tí èèyàn kàn fẹ́. Ó gba pé kéèyàn ní ìdánilójú téèyàn gbé ka ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀.
“Nítorí àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.”—Róòmù 1:20.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
‘Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.’—Hébérù 11:6.
Bá a ṣe sọ lókè, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run torí pé àwọn kan kọ́ wọ́n bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè sọ pé ‘Bí wọ́n ṣe tọ́ mí dàgbà nìyẹn.’ Àmọ́, Ọlọ́run fẹ́ kó dá àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lójú pé òun wà àti pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìyẹn jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí Bíbélì fi tẹnu mọ́ ọn pé ká fi taratara wá Ọlọ́run, ká lè mọ̀ ọ́n dunjú.
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Kí lo lè ṣe kó o lè ní ìgbàgbọ́?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Torí náà, ohun àkọ́kọ́ téèyàn máa ṣe kó tó lè nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ni pé kó “gbọ́” ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:16) Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa jẹ́ kó o rí ìdáhùn tó tọ̀nà sí àwọn ìbéèrè pàtàkì, irú bíi: Ta ni Ọlọ́run? Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Ọlọ́run wà? Ǹjẹ́ Ọlọ́run kà mí sí pàtàkì? Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe lọ́jọ́ iwájú?
Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Apá kan lórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org, sọ pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ a kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti wọ ẹ̀sìn wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn, torí a gbà pé kálukú ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó máa gbà gbọ́.”
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìgbàgbọ́ rẹ gbọ́dọ̀ dá lórí àwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere tí ìwọ fúnra rẹ rí nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Lọ́nà yẹn, wà á fi hàn pé ò ń fara wé àpẹẹrẹ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí wọ́n “gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:11.
“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.