KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÁ A ṢE BORÍ ÌṢÒRO ÈDÈ
Bá A Ṣe Borí Ìṣòro Àtayébáyé
ORÍṢIRÍṢI èdè ló wà kárí ayé, kódà ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èdè tàwọn èèyàn ń sọ báyìí. Àmọ́, bí èdè ṣe díjú kì í sábà mú kí nǹkan rọrùn nínú káràkátà, nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́, nínú ìjọba tàbí lẹ́nu ìrìn àjò. Bó sì ṣe rí nìyẹn látọdúnmọ́dún. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọdún 475 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà ìṣàkóso Ọba Ahasuwérúsì (tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Atasásítà I), àwọn ará Páṣíà máa ń fi àṣẹ ọba ránṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ wọn, “láti Íńdíà títí dé Etiópíà, ẹ̀tà-dín-láàádóje [127] àgbègbè abẹ́ àṣẹ, sí àgbègbè abẹ́ àṣẹ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà-ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí olúkúlùkù ènìyàn ní ahọ́n tirẹ̀.” *
Lóde òní, ọ̀pọ̀ àjọ tàbí ìjọba kì í sapá láti túmọ̀ èdè fún àwọn èèyàn wọn. Àmọ́, ètò kan wà tó ti ṣe èyí láṣeyọrí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ìwé ìròyìn, ìtẹ̀jáde tá a gbóhùn rẹ̀ sílẹ̀, fídíò àti ọ̀pọ̀ ìwé míì títí kan Bíbélì, ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta [750]. Nǹkan bí ọgọ́rin [80] èdè àwọn adití wà lára wọn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún ń ṣe onírúurú ìwé tó wà fáwọn afọ́jú, ìyẹn Braille.
Pabanbarì rẹ̀ ni pé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí nítorí owó. Kódà, àwọn tó ń bá wa ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè àtàwọn míì tó ń bá wa ṣiṣẹ́ kì í gba owó. Kí nìdí tá a fi ń ṣiṣẹ́ kára láti túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè, báwo la sì ṣe ń ṣe é?
^ ìpínrọ̀ 3 Wo Ẹ́sítérì 8:9 nínú Bíbélì.