Ẹ̀KỌ́ 6
Ìdí Tí Ìwà Ọmọlúwàbí Fi Ṣe Pàtàkì
KÍ NI ÌWÀ ỌMỌLÚWÀBÍ?
Àwọn tó bá ní ìwà ọmọlúwàbí máa ń mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Kì í ṣe bí nǹkan ṣe rí lára wọn lásìkò kan ni wọ́n fi máa ń pinnu bóyá wọ́n máa hùwà tó dáa tàbí wọn ò ní hùwà tó dáa. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti ní ìlànà tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé, kódà táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ sí níbi tí wọ́n wà.
KÍ NÌDÍ TÍ ÌWÀ ỌMỌLÚWÀBÍ FI ṢE PÀTÀKÌ?
Oríṣiríṣi ohun tí kò dáa làwọn ọmọdé máa ń gbọ́ nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Ó lè jẹ́ látẹnu àwọn ọmọléèwé wọn, nínú orin tí wọ́n ń gbọ́ tàbí nínú fíìmù àti ètò orí tẹlifísọ̀n tí wọ́n ń wò. Irú àwọn nǹkan yìí lè mú kí wọ́n máa ṣìyeméjì nípa ohun táwọn òbí wọn ti kọ́ wọn.
Ìṣòro ńlá lèyí sábà máa ń jẹ́ fáwọn ọmọ tí ò tíì pé ogún ọdún. Ìwé kan tó ń jẹ́ Beyond the Big Talk, sọ pé “Lásìkò yìí, ó yẹ kó yé wọn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa fẹ́ kí wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan kan torí káwọn èèyàn lè gba ti wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n á ṣe dúró lórí ìpinnu wọn láti má ṣe hùwà tí kò tọ́, kódà táwọn ọ̀rẹ́ wọn ò bá tiẹ̀ fara mọ́ ìpinnu wọn.” Ó ṣe kedere pé àti kékeré ló yẹ káwọn òbí ti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn.
BÓ O ṢE LÈ KỌ́ ỌMỌ RẸ NÍ ÌWÀ ỌMỌLÚWÀBÍ
Jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Àwọn tó dàgbà . . . kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.
-
Máa lo ọ̀rọ̀ tó ń fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Máa tọ́ka sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ láti sọ ìyàtọ́ láàárín ohun tó dára àti ohun tí kò dára. Bí àpẹerẹ, o lè sọ pé: “Tó o bá ṣe báyìí olóòótọ́ ni ẹ́; tó o bá ṣe tọ̀hún o di aláìṣòótọ́ nìyẹn.” Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọmọ rẹ á dẹni tó lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtòhun tí kò tọ́.
-
Máa ṣàlàyé ìdí tí ohun kan fi dáa àti ìdí tí kò fi dáa. Bí àpẹẹrẹ, o lè béèrè lọ́wọ́ ọmọ rẹ pé: Kí nìdí tó fi dáa láti máa sọ òtítọ́? Tó o bá ń purọ́, ṣé àwọn èèyàn máa fẹ́ bá ẹ ṣọ̀rẹ́? Kí nìdí tí kò fi dáa láti máa jalè? Tó o bá ń béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí, wàá lè kọ́ ọmọ rẹ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́.
-
Jẹ́ kó mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ṣe ohun tó dáa. O lè sọ pé: “Tó o bá jẹ́ olóòótọ́, àwọn èèyàn á fọkàn tán ẹ,” tàbí “Tó o bá ń ṣe ohun rere, àwọn èèyàn á fẹ́ sún mọ́ ẹ.”
Jẹ́ kó mọ́ gbogbo ìdílé yín lára láti máa hùwà rere.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.”—2 Kọ́ríńtì 13:5.
-
Ran gbogbo ìdílé rẹ lọ́wọ láti máa hùwà rere, wàá lè lẹ́nu ọ̀rọ̀ láti sọ pé:
-
-
“A kì í bá èèyàn jà tàbí kígbe mọ́ àwọn èèyàn.”
-
“A kì í bú àwọn èèyàn.”
-
Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ torí pé o fi òfin sílẹ̀ làwọn ọmọ rẹ ṣe ń hùwà rere, àmọ́ á jẹ́ torí pé ohun tí gbogbo yín ń ṣe nínú ìdílé yín nìyẹn.
-
Máa sọ àwọn nǹkan tó dáa ti ìdílé yín máa ń ṣe. Jẹ́ kí wọ́n rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́. O lè sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwà rere tí ìdílé yín ń hù àti èyí tí wọ́n ń hù nílé ìwé tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n. Bi ọmọ rẹ láwọn ìbéèrè bíi: “Ká ní ìwọ ni, kí lo máa ṣe?” “Kí lo rò pé ìdílé wa máa ṣe nírú ipò yìí?”
Tì wọ́n lẹ́yìn láti máa hùwà rere.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn rere.”—1 Pétérù 3:16.
-
Yìn wọ́n fún ìwà rere wọn. Tí ọmọ rẹ bá ṣe ohun tó dáa, gbóríyìn fún un, kó o sì sọ ìdí tó o fi ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Inú mi dùn pé o sọ òtítọ́. O káre ọmọ dáadáa.” Tí ọmọ rẹ bá sì jẹ́wọ́ pé òun ti ṣe ohun tí kò dáa, gbóríyìn fún un pé ó sòótọ́ kó o sì tọ́ ọ sọ́nà.
-
Bá ọmọ rẹ wí tó bá hùwà tí kò dáa. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tí wọ́n bá gbìn ni wọ́n máa ká. Tí ọmọ rẹ bá ṣe ohun tí kò dáa ó yẹ kó o jẹ́ kó mọ̀, kó sì rí i pé ó yàtọ̀ sí ohun tẹ́ ẹ máa ń ṣe nínú ìdílé. Àwọn òbí kan kì í fẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dára torí pé wọn ò fẹ́ bà wọ́n nínú jẹ́. Àmọ́ tó o bá ń ṣàlàyé ìdí tí ohun tí wọ́n ṣe kò fi dáa, á jẹ́ kí wọ́n lè yẹra fún ìwà burúkú tí wọ́n bá dàgbà, wọ́n á sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.