ÒBÍ
5: Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ
Ó túmọ̀ sí pé kí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ máa bá ara yín sọ ohun tó wà lọ́kàn yín gẹ́lẹ́ bó ṣe rí lára yín láì fi ohunkóhun pa mọ́.
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
Kì í rọrùn fún àwọn ọmọ tó ń bàlágà láti bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀. Ìwé kan tó ń jẹ́ Breaking the Code sọ pé: “Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ṣì kéré, gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n máa ń sọ fún ẹ, àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti ń bàlágà, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ bá ẹ sọ̀rọ̀ mọ́, oò sì mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Ní báyìí, ńṣe ló dà bí ìgbà tí odò ńlá kan wà láàárín ẹ̀yin méjéèjì.” Àmọ́, má wo ìyẹn rárá, àkókò yìí gan-an ló yẹ kí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ jọ máa sọ̀rọ̀!
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Nígbàkigbà tí ọmọ rẹ bá fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀, fún un láyè. Kódà kó jẹ́ pé ilẹ̀ ti ṣú gan-an.
“Má ṣe sọ pé, ‘Nígbà tí ilẹ̀ ṣú yìí ló fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀, ṣèbí inú ilé yìí la jọ wà látàárọ̀?’ Kò yẹ ká máa ṣàwáwí tí àwọn ọmọ wa bá fẹ́ bá wa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. O ṣe tán, gbogbo òbí ló fẹ́ kí àwọn ọmọ máa sọ tinú wọn jáde.”—Lisa.
“Mi ò kì í fi oorun mi ṣeré, tí ilẹ̀ bá ti ṣú, oorun yá nìyẹn. Àmọ́ àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé alẹ́ pátápátá ni èmi àti àwọn ọmọ mi jọ máa ń sọ̀rọ̀, a sì gbádùn ẹ̀ gan-an.”—Herbert.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.
Yẹra fún ohun tí kò ní jẹ́ kó o pọkàn pọ̀. Bàbá kan sọ pé: “Nígbà míì tí àwọn ọmọ mi bá ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ńṣe ni ọkàn mi á máa ro oríṣiríṣi nǹkan tí mo fẹ́ ṣe. Wọ́n sì máa ń mọ̀ pé mi ò pọkàn pọ̀!”
Kó o lè pọkàn pọ̀ tẹ́ ẹ bá fẹ́ sọ̀rọ̀, o lè pa tẹlifíṣọ̀n, fóònù, tablet àti kọ̀ǹpútà, tàbí kó o gbé wọn sí ipò tí kò ní dí ẹ lọ́wọ́. Fọkàn sí ohun tí ọmọ rẹ ń sọ, kó o sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí pàtàkì, má ṣe ka ọ̀rọ̀ èyíkéyìí sí ohun tí kò tó nǹkan.
“A gbọ́dọ̀ fi dá àwọn ọmọ wa lójú pé a ka gbogbo ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn sí pàtàkì. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè rò pé ohun táwọn ń sọ kò ṣe pàtàkì sí wa. Wọ́n lè má sọ tinú wọn fún wa mọ́, kí wọ́n sì wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ ẹlòmíì.”—Maranda.
“Má ṣe kanra mọ́ ọn, má sì ṣe bú u, kódà tó bá jẹ́ pé èrò rẹ̀ kò tọ̀nà rárá.”—Anthony.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.”—Lúùkù 8:18.
Lo àǹfààní àwọn àkókò tẹ́ ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀pẹ́. Nígbà míì, àwọn ọmọ máa ń sọ̀rọ̀ fàlàlà ní irú àkókò bẹ́ẹ̀ ju ìgbà tẹ́ ẹ bá dìídì pè wọ́n jókòó láti bá wọn sọ̀rọ̀.
“A máa ń sọ̀rọ̀ tá a bá wà nínú mọ́tò. Dípò tá a fi máa jókòó lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, a máa ń jókòó pa pọ̀, ìyẹn sì ti mú ká ní àwọn ìjíròrò tó nítumọ̀.”—Nicole.
Ẹ tún lè jọ sọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ bá ń jẹun.
“Tá a bá ń jẹun alẹ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń sọ àwọn nǹkan tó mú inú wa dùn lọ́jọ́ yẹn, a sì tún máa ń sọ àwọn nǹkan tí kò dáa tó ṣẹlẹ̀. Èyí ti jẹ́ ká sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá ní ìṣòro, a lè pawọ́ pọ̀ yanjú ẹ̀.”—Robin.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́ kó sì lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.’—Jákọ́bù 1:19.