Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irú àpẹẹrẹ wo lò ń fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ?

ÒBÍ

8: Àpẹẹrẹ Rere

8: Àpẹẹrẹ Rere

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Ohun tí àwọn òbí bá fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn máa ṣe làwọn náà máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ṣòro fún ọmọ rẹ láti máa sọ òótọ́ tó bá gbọ́ tó ò ń sọ pé, “Sọ fẹ́ni yẹn pé mi ò sí nílé,” nígbà tó jẹ́ pé o wà nílé.

“Àwọn kan máa ń sọ pé ‘Ohun tí mo sọ ni kó o ṣe, má wo ìwà mi.’ Èèyàn ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn ọmọdé, torí ohun tá a bá ṣe làwọn náà máa ṣe. Gbogbo ohun táwa òbí ń ṣe ni wọ́n ń rí, wọ́n sì ń gbọ́ wa, wọ́n máa sọ fún wa tá a bá ṣe ohun tó yàtọ̀ sí nǹkan tá a sọ fún wọn.”​—David.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé “Má jalè,” ìwọ ha ń jalè bí?”​—Róòmù 2:21.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ohun tí àwọn òbí bá ṣe làwọn ọmọ máa ń tẹ̀lé, ìwà àwọn òbí sì máa ń nípa lórí àwọn ọmọ ju ti àwọn ọ̀rẹ́ wọn lọ. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé ohun tó o bá sọ lọmọ rẹ máa ṣe, ìyẹn tíwọ fúnra rẹ bá ń ṣe ohun tó ò ń kọ́ ọmọ rẹ.

“A lè máa sọ ohun kan náà fún ọmọ wa lọ́pọ̀ ìgbà, ká sì máa rò ó pé bóyá ló gbọ́ ohun tá à ń sọ. Àmọ́ lọ́jọ́ tá a bá ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tá a sọ fún wọn, wọ́n máa sọ fún wa. Gbogbo nǹkan tá à ń ṣe lọmọ wa ń rí, kódà tá a bá rò pé wọn ò rí wa.”​—Nicole.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . kì í ṣe àgàbàgebè.”​—Jákọ́bù 3:17.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Yẹ ara rẹ wò. Irú fíìmù wo lo máa ń wò? Báwo lo ṣe máa ń hùwà sí ẹnì kejì rẹ àti àwọn ọmọ rẹ? Irú àwọn ọ̀rẹ́ wo lo ní? Ṣé o máa ń ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tìẹ? Ká kúkú béèrè pé, ṣó o fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ fìwà jọ ẹ́?

“Èmi àti ọkọ mi kì í fi dandan mú àwọn ọmọ wa láti ṣe nǹkan tí àwa fúnra wa kì í ṣe.” ​—Christine.

Tó o bá ṣe àṣìṣe, tọrọ àforíjì. Àwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé o kì í ṣe ẹni pípé. Tó o bá ń sọ fún ẹnì kejì rẹ àti àwọn ọmọ rẹ pé “Má bínú” nígbà tó bá yẹ, ṣe lò ń kọ́ wọn pé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.

“Ó yẹ káwọn ọmọ wa rí i pé a máa ń gbà àṣìṣe wa, a sì máa n tọrọ àforíjì. Tá ò bá kí ń ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tá à ń kọ́ wọn ni pé kí wọ́n máa wá àwáwí tí wọ́n bá ti ṣe àṣìṣe.”​—Robin.

“Àwa òbí ni àwọn ọmọ ń wò, àpẹẹrẹ wa ni wọ́n sì ń tẹ̀ lé torí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n ń rí wa. Àwa ni ìwé tí wọ́n ń kà, ohun tí wọ́n bá sì kọ́ lára wa ni wọ́n máa ṣe.”​—Wendell.