Ẹ̀kọ́ Táá Jẹ́ Kó O Di Ọlọ́gbọ́n
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Ohun tí “mí sí” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run Olódùmarè fi èrò rẹ̀ sọ́kàn àwọn tó kọ Bíbélì.
Ọlọ́run Fẹ́ Kó O Jàǹfààní Látinú Ọgbọ́n Òun
“Èmi, Jèhófà, ni . . . Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn. Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni! Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—ÀÌSÁYÀ 48:17, 18.
Ńṣe ni kó o wò ó pé ìwọ gangan ni Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ yìí fún. Ó fẹ́ kó o ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀ tòótọ́, ó sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ káyé ẹ lè dùn.
O Lè Ní Ọgbọ́n Ọlọ́run
“A ní láti . . . wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.”—MÁÀKÙ 13:10.
Lára “ìhìn rere” tí ẹsẹ̀ Bíbélì yìí ń sọ ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé, pé òun máa sọ ayé di Párádísè àti pé òun máa jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde. Ìhìn rere tó wá látinú Bíbélì yìí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀ kárí ayé.