Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń dáhùn?

KÍ LÈRÒ RẸ?

  • Ó máa ń dáhùn àdúrà gbogbo èèyàn

  • Àdúrà àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa ń dáhùn

  • Kì í dáhùn àdúrà ẹnì kankan

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo . . . àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́.”​—Sáàmù 145:18.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Ọlọ́run kì í dáhùn àdúrà àwọn tó ń ṣe ohun tí kò fẹ́. (Aísáyà 1:15) Ṣùgbọ́n, wọ́n lè “mú àwọn ọ̀ràn tọ́” pẹ̀lú Ọlọ́run nípa yíyí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn pa dà sí rere.​—Aísáyà 1:18.

  • Kí Ọlọ́run tó lè dáhùn àdúrà ẹnì kan, ẹni náà gbọ́dọ̀ gbà á ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì.​—1 Jòhánù 5:14.

Ṣé ó ní ipò kan tá a gbọ́dọ̀ wà ká tó lè gbàdúrà?

ÀWỌN KAN GBÀ GBỌ́ PÉ àwọn gbọ́dọ̀ kúnlẹ̀ tàbí kí àwọn tẹrí ba tàbí kí wọ́n pa ọwọ́ pọ̀ nígbà tí àwọn bá ń gbàdúrà. Kí lèrò rẹ?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà àwọn tó “jókòó” àti tàwọn tó “dìde dúró” nígbà tí wọ́n ń gbàdúrà. Ó sì ti gbọ́ àdúrà àwọn tó “wólẹ̀” àti tàwọn tó ‘tẹ eékún wọn ba.’ (1 Kíróníkà 17:16; 2 Kíróníkà 30:27; Ẹ́sírà 10:1; Ìṣe 9:40) Kò béèrè pé ká wà nípò kan pàtó nígbà tí a bà ń gbàdúrà kí òun tó lè gbọ́ wa.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?