ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Mi Ò Ní Apá
Téèyàn bá gba ilẹ̀ tó ń yọ̀ kọjá, á fẹ́ di nǹkan mú kó má báa yọ̀ ṣubú. Àmọ́ èmi ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí mi ò ní ọwọ́, mi ò sì lápá. Ọmọ ọdún méje ni mí nígbà tí wọ́n gé apá mi kí n má báa kú.
Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ni màmá mi nígbà tí wọ́n bí mi lọ́dún 1960. Inú oyún ni mo ṣì wà nígbà tí bàbá mi fi wá sílẹ̀. Màmá mi ṣì ní ìyà àti bàbá, ọ̀dọ̀ wọn lèmi àti màmá mi wá ń gbé ní ìlú Burg, tó jẹ́ ìlú kékeré kan ní German Democratic Republic tẹ́lẹ̀, tàbí East Germany. Ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú yìí ni kò gbà pé Ọlọ́run wà, ohun tí ìdílé mi náà sì gbà gbọ́ nìyẹn. Ọlọ́run kò jámọ́ nǹkan kan lójú wa.
Bí mo ṣe ń dàgbà, èmi àti bàbá ìyá mi la jọ sábà máa ń wà papọ̀. Oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n kọ́ mi láti ṣe, bíi kí wọ́n ní kí n pọ́n igi lọ sókè láti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, mo gbádùn àwọn nǹkan yẹn. Mo máa ń ṣe bó ṣe wù mí, mo sì láyọ̀.
ÌJÀǸBÁ TÓ YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ
Ohun burúkú kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sí kíláàsì kejì ni. Bí mo ṣe ń bọ̀ nílé, mo bá pọ́n òpó iná kan. Nígbà tí mo gùn ún dókè, bí iná ṣe gbé mi nìyẹn lójijì. Ilé ìwòsàn ni mo ti lajú, tí mi ò sì lè gbé apá mi méjèèjì mọ́. Apá méjèèjì jóná débi pé wọ́n ní láti gé wọn sọnù, kí n máa báa tibẹ̀ kó àrùn míì. Ọ̀rọ̀ yìí kó ìbànújẹ́ bá ìyá mi àti ìyá ìyá mi. Àmọ́ torí pé ọmọdé ni mí, mi ò mọ ìpalára tí ṣíṣàìní apá máa ṣe fún mi nígbèésí ayé.
Nígbà tí mo kúrò nílé ìwòsàn, mo pa dà síléèwé. Àwọn ọmọléèwé máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á máa tì mí kiri, wọ́n á sì máa ju nǹkan bà mí, torí pé mi ò lè gbèjà ara mi. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa ń dùn mí wọra. Níkẹyìn, wọ́n wá rán mi lọ sí Birkenwerder School for the Disabled, tó jẹ́ iléèwé àwọn aláàbọ̀ ara, ibẹ̀ sì ni mò ń gbé. Torí pé iléèwé náà jìnnà sílé wa, ìyá mi àtàwọn òbí mi àgbà kò lágbára láti wá máa wò mí. Àkókò họlidé nìkan la máa ń ríra. Fún ọdún mẹ́wàá gbáko, ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń rí màmá mi àtàwọn òbí mi àgbà.
BÍ MO ṢE Ń DÀGBÀ LÁÌSÍ ỌWỌ́ ÀTI APÁ
Mo kọ́ láti máa fi ẹsẹ̀ mi ṣe gbogbo nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe. Ǹjẹ́ ẹ mọ bó ṣe máa ń rí kéèyàn fi ọmọ ìka ẹsẹ̀ mú ṣíbí, kó sì máa fi bu oúnjẹ sẹ́nu? Lọ́nà kan ṣá, mo kọ́ bí mo ṣe lè ṣe é. Mo tún kọ́ bí mo ṣe lè máa fi ẹsẹ̀ mi mú búrọ́ọ̀ṣì láti fi fọnu àti kóòmù láti
fi yarun. Kódà mo tún máa ń fi ẹsẹ̀ mi ṣe àpèjúwe tí mo bá ń sọ̀rọ̀. Bí ẹsẹ̀ mi ṣe di ọwọ́ mi nìyẹn.Bí mo ṣe ń dàgbà, mo fẹ́ràn kí n máa ká àwọn ìtàn àròṣọ tó dá lórí sáyẹ́ǹsì. Nígbà míì, mo máa ń ronú pé kí n ní apá àràmàǹdà, tó máa jẹ́ kí n lè máa ṣe gbogbo nǹkan. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá [14]. Mo ronú pé èyí máa jẹ́ kí n dá ara mi lójú, kí n sì máa ṣe bíi gbogbo èèyàn tó kù. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí mò ń sọ pé: ‘Bí mi ò tiẹ̀ lọ́wọ́, èmi náà lè mu sìgá. Ó ṣe tán mi ò kì í ṣe ọmọdé mọ́.’
Mi ò jókòó gẹlẹtẹ, mo máa ń gbafẹ́ jáde. Bí àpẹẹrẹ, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Free German Youth, ìyẹn ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kan tí ìjọba ń ṣagbátẹrù rẹ̀. Èmi sì ni akọ̀wé ẹgbẹ́, èyí tó jẹ́ ipò pàtàkì kan nínú ẹgbẹ́ náà. Mo tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ olórin, mo máa ń kéwì, mo sì tún ń ṣe eré ìdárayá tó wà fáwọn aláàbọ̀ ara. Nígbà tí mo kọ́ṣẹ́ tán, mo ríṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ kan nílùú wa. Bí mo ṣe ń dàgbà, mo máa ń wọ apá àtọwọ́dá, kí n lè jọ èèyàn gidi.
MO KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
Lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe ń dúró de ọkọ̀ ojú irin tó máa gbé mi lọ sí ibiṣẹ́, ọkùnrin kan wá bá mi. Ó bi mí pé ṣé mo mọ̀ pé Ọlọ́run lè ṣe é kí n tún máa lo apá mi méjèèjì. Ohun tó sọ kò kọ́kọ́ yé mi. Ohun tó dájú ni pé mo fẹ́ máa lo ọwọ́ mi pa dà, àmọ́ lójú mi ọ̀rọ̀ náà dà bí nǹkan tí kò lè ṣeé ṣe láé! Torí pé ó dá mi lójú pé kò sí Ọlọrun níbì kankan. Láti ìgbà yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í sá fún ọkùnrin náà.
Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ní kí n wá kí òun nílé. Bá a ṣe ń mu kọfí, àwọn òbí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí màá gbọ́ pé Ọlọ́run lórúkọ. (Sáàmù 83:18) Àmọ́ mò ń sọ lọ́kàn mi pé: ‘Ohun yòówù kí wọ́n pe orúkọ rẹ̀, kò sí Ọlọ́run níbì kankan. Màá sì fi hàn wọ́n pé irọ́ ni wọ́n ń pa.’ Torí pé èrò mi dá mi lójú, mo fara mọ́ ọn pé ká jọ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ṣùgbọ́n, ó yà mí lẹ́nu pé mi ò ní ẹ̀rí kankan láti fi hàn pé kò sí Ọlọ́run.
Bá a ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì, èrò tí mo ní nípa Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ ló ti ṣẹ, bẹ́ẹ̀ sì rè é, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tó ṣe ní wọ́n ti sọ ọ́. Nígbà kan tá à ń jíròrò Bíbélì, a fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí wéra pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Mátíù orí 24, Lúùkù orí 21, àti 2 Tímótì orí 3. Bí onírúurú àmì àrùn ṣe lè jẹ́ kí dókítà kan mọ irú àìsàn tó ń ṣe ẹnì kan, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe jẹ́ kí n mọ̀ pé àkókò tí Bíbélì pè ní “ìkẹyìn ọjọ́” la wà yìí. * Ẹnu yà mí gan-an. Gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló ń ṣẹlẹ̀ lójú mi kòró.
Ó dá mi lójú pé òótọ́ ni ohun tí mò ń kọ́. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, mi ò sì mu sìgá mọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá tí mo ti ń mu sìgá gan-an. Mò ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ fún nǹkan bí ọdún kan. Ní April 27, 1986, mo
ṣe ìrìbọmi ní bòókẹ́lẹ́ nínú ọpọ́n ìwẹ̀ kan, torí pé wọ́n fi òfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní East Germany nígbà yẹn.MÒ Ń RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́
Torí pé wọ́n fi òfin dè wá, ìwọ̀nba làwa tá a máa ń ṣèpàdé nílé àwọn ará, torí náà àwọn díẹ̀ ni mo mọ̀. Láìro tẹ́lẹ̀, àwọn aláṣẹ gbà mí láyè láti lọ sí West Germany níbi tí wọn ò ti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí. Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi, mọ lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi. Inú mi dùn gan-an lọ́jọ́ tá à ń wí yìí.
Lẹ́yìn tí Odi Ìlú Berlin wó lulẹ̀, wọ́n mú òfin tí wọ́n fi de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò. Ní báyìí, a wá lómìnira láti sin Jèhófà Ọlọ́run wa. Ó wù mí kí n túbọ̀ máa lo àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ẹrù máa ń bà mí láti bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀. Mo máa ń wo ara mi bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan àti pé ilé àwọn aláàbọ̀ ara ni mo ti lo èyí tó pọ̀ jù nígbà ọmọdé mi. Àmọ́ lọ́dún 1992, mo gbìyànjú láti lo ọgọ́ta [60] wákàtí lóṣù kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Èyí múnú mi dùn gan-an torí pé mo ṣe dáadáa. Torí náà, mo pinnu láti máa ṣe ọgọ́ta wákàtí lóṣooṣù, mo sì ṣe é fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta.
Mi ò gbàgbé ọ̀rọ̀ Bíbélì: “Ta ní jẹ́ aláìlera, tí èmi kò sì jẹ́ aláìlera?” (2 Kọ́ríńtì 11:29) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lápá, mo ṣì lè ronú, mo sì ń sọ̀rọ̀. Torí náà, mo gbìyànjú láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Bí mi ò ṣe ní apá máa ń jẹ́ kí n fọ̀rọ̀ àwọn aláàbọ̀ ara ro ara mi wò, mo sì máa ń káàánú wọn. Torí pé mo mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá fẹ́ ṣe nǹkan, àmọ́ tí kò lè ṣe é. Èyí ló jẹ́ kí n máa sapá láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ní irú ìṣòro yìí. Bí mo sì ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà yìí máa ń múnú mi dùn.
JÈHÓFÀ Ń RÀN MÍ LỌ́WỌ́ LÓJOOJÚMỌ́
Kí n má parọ́, àwọn ìgbà míì wà tí mo máa ń rẹ̀wẹ̀sì. Ó ṣá máa ń wù mí kí gbogbo ẹ̀yà ara mi pé. Mo máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fúnra mi, àmọ́ ó máa ń gba àkókò, ìsapá àti agbára ju bó ṣe yẹ lọ. Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí ni mo fi ń tu ara mi nínú lójoojúmọ́: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Ojoojúmọ́ ni Jèhófà ń fún mi lágbára tí mo nílò láti ṣe àwọn ohun tí mo ní ín ṣe. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ọ̀rọ̀ mi kò tíì sú Jèhófà. Ìdí nìyẹn témi náà ò fi ní fi Jèhófà sílẹ̀.
Jèhófà tún ti fi ìdílé aláyọ̀ tí mi ò ní nígbà ọmọdé jíǹkí mi. Mo ní ìyàwó tó dáa, Elke lorúkọ ẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì máa ń gba tèmi rò. Láfikún sí i, omilẹgbẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti di ìdílé mi nípa tẹ̀mí, lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
Ìlérí Párádísè tí Ọlọ́run ṣe tún máa ń tù mí nínú, nígbà yẹn Ọlọ́run á sọ “ohun gbogbo di tuntun,” títí kan apá mi. (Ìṣípayá 21:5) Àwọn ìlérí yìí máa ń túbọ̀ wọ̀ mí lọ́kàn tí mo bá ronú lórí ohun tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló mú arọ kan lára da, ó sì lẹ etí ọkùnrin kan tí wọ́n gé pa dà. (Mátíù 12:13; Lúùkù 22:50, 51) Àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe àtàwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù ti mú kó dá mi lójú pé mo máa pa dà ní apá.
Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni àǹfààní tí mo ní láti mọ Jèhófà Ọlọ́run. Ó ti di bàbá mi àti ọ̀rẹ́ mi, ó ń tù mí nínú ó sì ń fún mi lókun. Ńṣe lọ̀rọ̀ mi dà bí ti Ọba Dáfídì, tó sọ pé: “Jèhófà ni okun mi . . . A sì ti ràn mí lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà mi ń yọ ayọ̀ ńláǹlà.” (Sáàmù 28:7) Òtítọ́ àgbàyanu yìí ni mo fẹ́ rọ̀ mọ́ jálẹ̀ ọjọ́ ayé mi. Mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ní apá.
^ ìpínrọ̀ 17 Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn, wo orí 9, “Ṣé ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ La Wà Yìí?” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì wa www.isa4310.com/yo.