Àwọn Tó Ń Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún
Wòlíì Mósè sọ pé tá a bá ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, a máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Diutarónómì 10:13; 11:27) Kì í ṣe torí kí Ọlọ́run má bàa fìyà jẹ wá la ṣe ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Àwọn ohun rere tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run ló ń mú ká máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu, a sì tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a ò sì fẹ́ ṣe ohunkóhun tó lè bà á nínú jẹ́. “Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 Jòhánù 5:3.
Àmọ́, ọ̀nà wo la lè gbà rí ìbùkún Ọlọ́run tá a bá ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu? Jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì yìí.
1. TÁ A BÁ Ń ṢÈGBỌRÀN SÍ ỌLỌ́RUN A MÁA DI ỌLỌ́GBỌ́N
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, . . . tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.”—ÀÌSÁYÀ 48:17.
Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ wá, ó sì ń pèsè ìtọ́sọ́nà tá a nílò. Tá a bá fẹ́ káwọn ohun tó ń kọ́ wa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó dáa, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú Ìwé Mímọ́ ká lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe ká sì máa fi àwọn ohun tó ń kọ́ wa ṣèwà hù.
2. TÁ A BÁ Ń ṢÈGBỌRÀN A MÁA LÁYỌ̀
“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—LÚÙKÙ 11:28.
Lónìí, àìmọye àwọn èèyàn ló ní ayọ̀ gidi torí wọ́n ń ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan wà nílùú Sípéènì tó máa ń bínú fùfù tó sì máa ń kanra mọ́ àwọn èèyàn, títí kan ìyàwó rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ó ka ìwé wòlíì Mósè nípa bí Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù ṣe jẹ́ oníwà tútù. Wọ́n ta Jósẹ́fù bí ẹrú, wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n láì jẹ̀bi; síbẹ̀ ó jẹ́ oníwà tútù àti èèyàn àlàáfíà, ó sì dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ ẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 37-45) Ọkùnrin ará Sípéènì náà sọ pé: “Bí mo ṣe ń ronú nípa àpẹẹrẹ Jósẹ́fù mú kí n ní ìwà tútù, inúure àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Ní báyìí, ọkàn mi balẹ̀ mo sì ń láyọ̀.”
Ìwé Mímọ́ kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, wàá rí oríṣiríṣi ọ̀nà tó o lè gbà ṣe é.