Gbígba Ìkìlọ̀ Lè Kó Ẹ Yọ Nínú Ewu!
NÍ December 26 ọdún 2004, ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ okùn tó lágbára ṣẹlẹ̀ ní erékùṣù Simeulue. Erékùṣù yìí wà ní àríwá ìlú Sumatra lórílẹ̀-èdè Indonesia. Gbogbo àwọn tó wà ní erékùṣù yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí òkun náà. Wọ́n wá rí i pé òkun náà ti ń fà kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń pariwo pé “Omi o! Omi ń ya bọ̀!” Láàárín ọgbọ́n [30] ìṣẹ́jú péré, ìgbì òkun tó lágbára bẹ̀rẹ̀ sí í ya lu etíkun, ó sì ba ọ̀pọ̀ ilé àtàwọn abúlé tó wà níbẹ̀ jẹ́.
Erékùṣù Simeulue ni ibi tí àkúnya omi tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2004 yẹn kọ́kọ́ dé. Nínú ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gọ́rin [78,000] èèyàn tó ń gbé níbẹ̀, èèyàn méje [7] péré ló pàdánù ẹ̀mí wọn. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi là á já? * Ọ̀rọ̀ kan tó wọ́pọ̀ lẹ́nu àwọn tó ń gbé ní erékùṣù náà ni pé: ‘Tí ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára bá wáyé, tí òkun sì ń fà, sá lọ sórí àwọn òkè torí òkun tó fà máa tó ya pa dà wọ̀lú.’ Àwọn tó ń gbé ní erékùṣù Simeulue ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí pé tí òkun bá ti fà, àkúnya omi fẹ́ ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Bí wọ́n ṣe fiyè sí ìkìlọ̀ yìí ló kó wọn yọ.
Bíbélì sọ nípa àjálù kan tó ń bọ̀, ó ní “ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn máa pa ayé rẹ́ tàbí pé àjálù burúkú kan máa pa ayé run, torí pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí ayé wà títí láé. (Oníwàásù 1:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìpọ́njú ńlá yìí ni Ọlọ́run máa lò láti “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló máa fòpin sí ìwà ìkà àti ìyà táwọn èèyàn ń jẹ. (Ìṣípayá 11:18; Òwe 2:22) Ìbùkún ńlá mà lèyí o!
Bákan náà, ìparun yìí kò ní dà bí àkúnya omi, ìmìtìtì ilẹ̀ tàbí àjálù míì tó ń ṣẹlẹ̀ láyé torí pé kò ní gbẹ̀mí àwọn aláìṣẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ọlọ́run tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà sì ṣèlérí pé “àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (1 Jòhánù 4:8; Sáàmù 37:29) Báwo lo ṣe lè la ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ já, kó o sì gbádùn àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ṣèlérí? Àṣírí ẹ̀ ni pé kó o gba ìkìlọ̀!
MÁA KÍYÈ SÍ ÀWỌN ÀYÍPADÀ TÓ Ń ṢẸLẸ̀ NÍNÚ AYÉ
A ò lè sọ ọjọ́ tí ìparun tí Ọlọ́run sọ yìí máa dé torí Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” Síbẹ̀ Jésù gbà wá níyànjú pé ká máa “bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Mátíù 24:36; 25:13) Fún kí ni? Bíbélì ṣàlàyé bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé ṣáájú kí Ọlọ́run tó mú ìparun wa. Bí omi okùn ṣe fa ní ìlú Simeulue tó sì mú kí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ fura pé àkúnya omi fẹ́ wáyé, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa pé òpin ayé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. Àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ díẹ̀ lára àwọn àyípadà òjijì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Òótọ́ ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kan yìí ti wáyé láwọn ìgbà kan sẹ́yìn. Àmọ́, Jésù sọ pé tá a bá ti rí “gbogbo nǹkan wọ̀nyí,” a óò mọ̀ pé òpin ayé ti wọlé dé tán. (Mátíù 24:33) Bi ara rẹ pé, ‘Ìgbà wo nínú ìtàn ni àwọn ohun tí Jésù sọ yìí (1) wáyé jákèjádò ayé, (2) tó ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, (3) tó sì ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́?’ Ó ṣe kedere pé àsìkò yìí gan-an ló ń ṣẹlẹ̀.
Ẹ̀RÍ PÉ ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́ WA
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà kan sọ pé: ‘Tá a bá ṣe ẹ̀rọ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé jàǹbá fẹ́ ṣẹlẹ̀, ó máa dín ẹ̀mí tó ń ṣòfò kù.’ Lẹ́yìn àkúnya omi tó wáyé yẹn, wọ́n ṣe ẹ̀rọ kan sí àwọn àgbègbè tí àkúnya omi náà ti ṣẹlẹ̀. Ẹ̀rọ náà máa ta wọ́n lólobó tí jàǹbá bá fẹ́ wáyé, èyí máa jẹ́ kí wọ́n lè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run ti ṣètò pé kí àwọn èèyàn gbọ́ ìkìlọ̀ ṣáájú kí òpin tó dé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Lọ́dún tó kọjá nìkan, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì wákàtí láti fi wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun fún àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè igba ó lé ogójì [240], a sì ń wàásù ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún méje [700] lọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ẹ̀rí tó lágbára jù lọ tó fi hàn pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Ìfẹ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní fún àwọn aládùúgbò wa ló mú ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń yára sún mọ́lé yìí. (Mátíù 22:39) Ti pé ò ń ka ìwé yìí jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ. Rántí pé, “[Ọlọ́run] kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ṣé ìwọ náà á gba ìkìlọ̀, kó o lè fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún ẹ?
SÁ LỌ SÍ IBI ÀÀBÒ!
Ṣé o kò gbàgbé pé nígbà tí àwọn èèyàn ìlú Simeulue rí i pé omi òkun fà, kíá ni wọ́n sá lọ sí orí òkè, láìdúró de ìgbà tí omi náà máa ya pa dà. Bí wọ́n ṣe gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara ni kò jẹ́ kí wọ́n bá omi lọ. Tí ìwọ náà ò bá fẹ́ bá ìparun ayé yìí lọ, o gbọ́dọ̀ sá lọ sí ibi ààbò kó tó pẹ́ jù. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti ṣe àkọsílẹ̀ ìkésíni kan tó kan gbogbo èèyàn “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn àkókò tá a wà yìí. Ó sọ pé: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, . . . Òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.”—Aísáyà 2:2, 3.
Tó o bá wà lórí òkè, wàá ríran jìnnà, ọkàn rẹ á sì balẹ̀ pé ewu kò lè wu ẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Ọlọ́run ṣe ń ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé lóde òní láti ṣe àwọn àyípadà tó máa ṣe wọ́n láǹfààní nígbèésí ayé wọn. (2 Tímótì 3:16, 17) Èyí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa “rìn ní àwọn ipa ọ̀nà [Ọlọ́run],” èyí sì ń mú kí wọ́n rí ojúure àti ààbò rẹ̀.
Ṣé ìwọ náà á gba ìkésíni yìí, kó o sì rí bí Ọlọ́run á ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ẹ, táá sì dáàbò bò ẹ́ ní àwọn àkókò tí nǹkan le koko tá a wà yìí? A rọ̀ ẹ́ pé kó o wo àwọn ẹ̀rí tó wà nínu Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” gan-an la wà báyìí. Àwọn ẹ̀rí yìí wà nínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ á dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ lóye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ, wọ́n á sì tún jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè fi wọ́n sílò. O tún lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ tó o bá lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn www.isa4310.com/yo. Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ..
^ ìpínrọ̀ 3 Àkúnya omi yìí to ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2004 gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó jú ọ̀kẹ́ mọ́kànlá [220,000] lọ. Àkúnya omi yìí wà lára àkúnya omi tó burú jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀.