Ẹ Máa Fìfẹ́ Yanjú Aáwọ̀
“Ẹ . . . pa àlàáfíà mọ́ láàárín ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—MÁÀKÙ 9:50.
ORIN: 39, 77
1, 2. Àwọn aáwọ̀ wo ni Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn nínú Jẹ́nẹ́sísì, kí sì nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí wọn?
ṢÉ O ti fìgbà kan rí ronú lórí àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní aáwọ̀ láàárín ara wọn? Àwọn àpẹẹrẹ kan wà nínú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì. Kéènì pa Ébẹ́lì (Jẹ́n. 4:3-8); Lámékì pa ọ̀dọ́kùnrin kan torí pé ó gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ (Jẹ́n. 4:23); aáwọ̀ wà láàárín àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ábúráhámù (Ábúrámù) àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn Lọ́ọ̀tì (Jẹ́n. 13:5-7); Hágárì fi Sárà (Sáráì) ṣẹ̀sín, Sárà náà sì tún bínú sí Ábúráhámù (Jẹ́n. 16:3-6); Íṣímáẹ́lì ń bá gbogbo èèyàn jà, gbogbo èèyàn sì ń bá òun náà jà.—Jẹ́n. 16:12.
2 Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn aáwọ̀ tó wáyé yìí? Ìdí ni pé ó máa jẹ́ kí àwa èèyàn aláìpé rí ìdí tó fi yẹ ká máa bára wa gbé ní àlàáfíà. Ó tún jẹ́ ká mọ báa ṣe lè máa wá àlàáfíà. Tá a bá kà nípa bí àwọn èèyàn bíi tiwa ṣe yanjú aáwọ̀, ìyẹn máa jẹ́ káwa náà mọ ohun tó yẹ ká ṣe. A máa mọ ohun tí ìsapá wọn yọrí sí, àwa náà á sì lè fi ohun tí wọ́n ṣe yẹn yanjú àwọn ìṣòro kan tá à ń dojú kọ nígbèésí ayé wa. Gbogbo èyí máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí kò yẹ ká ṣe táwa náà bá ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.—Róòmù 15:4.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi gbọ́dọ̀ máa yanjú aáwọ̀ àti bí wọ́n ṣe lè ṣe é yọrí. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu ohun tá a máa ṣe tá a bá ní aáwọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan àti bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa àti pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run.
ÌDÍ TÓ FI PỌN DANDAN KÁWỌN ÌRÁNṢẸ́ ỌLỌ́RUN MÁA YANJÚ AÁWỌ̀
4. Èrò burúkú wo ló ti tàn kálẹ̀ lónìí, kí ló sì ti yọrí sí?
4 Sátánì ló dá wàhálà àti aáwọ̀ tó ń wáyé láàárín àwọn èèyàn sílẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nínú ọgbà Édẹ́nì, ohun tó sọ ni pé Ọlọ́run kọ́ ló yẹ kó máa pinnu ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan á ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló yẹ kó máa dá pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Jẹ́n. 3:1-5) Ohun tírú èrò bẹ́ẹ̀ máa yọrí sí ṣe kedere. Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí ló máa ń gbéra ga, onímọtara-ẹni-nìkan ni wọ́n, wọ́n sì máa ń figa gbága. Ohun tí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa darí òun ń sọ ni pé ohun tí Sátánì sọ mọ́gbọ́n dání, àti pé kò burú téèyàn bá rọ́ gbogbo èèyàn sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kọ́wọ́ ẹ̀ ṣáá lè tẹ ohun tó ń lé. Irú ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ kì í bímọọre, gbọ́nmi-si omi-ò-to ló máa ń yọrí sí. Ó sì yẹ ká rántí pé “ènìyàn tí ó fi ara fún ìbínú ń ru asọ̀ sókè, ẹnikẹ́ni tí ó sì fi ara fún ìhónú ní ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá.”—Òwe 29:22.
5. Kí ni Jésù sọ pé kí àwọn tó ń tẹ́tí sí i ṣe kí aáwọ̀ má bàa máa wáyé?
5 Ohun tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn yàtọ̀ pátápátá síyẹn, ó ní kí wọ́n máa wá àlàáfíà kódà bí ìyẹn ò bá tiẹ̀ rọrùn pàápàá. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ ohun tó yẹ ká ṣe kí aáwọ̀ má bàa máa wáyé tàbí tá a bá ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ onínú tútù, kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kí wọ́n má máa gba ìbínú láyè, kí wọ́n máa tètè yanjú aáwọ̀, kí wọ́n sì máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Mát. 5:5, 9, 22, 25, 44.
6, 7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè máa yanjú aáwọ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà bi ara wa?
6 Tá ò bá wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, asán ni ìjọsìn wa máa já sí. Àdúrà tá à ń gbà, ìpàdé tá à ń lọ, òde ẹ̀rí àtàwọn nǹkan míì tá à ń ṣe ò sì ní já mọ́ nǹkan kan. (Máàkù 11:25) Tá ò bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, a ò lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Ka Lúùkù 11:4; Éfésù 4:32.
7 Ó pọn dandan kí àwa Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ronú jinlẹ̀ ká sì bi ara wa bóyá òótọ́ là ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn tá a sì lẹ́mìí ìdáríjì. Ṣé o máa ń dárí ji àwọn ará látọkàn wá? Ṣé inú rẹ máa ń dùn tí ẹ bá jọ wà nípàdé? Jèhófà retí pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́mìí ìdáríjì. Tí ẹ̀rí ọkàn rẹ bá sọ fún ẹ pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, ṣe ni kó o bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe irú àwọn àtúnṣe bẹ́ẹ̀. Baba wa ọ̀run máa gbọ́ irú àdúrà tá a fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ gbà.—1 Jòh. 5:14, 15.
ṢÉ O LÈ GBÓJÚ FO ÀṢÌṢE?
8, 9. Kí ló yẹ ká ṣe tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá?
8 Torí pé aláìpé ni wá, bópẹ́ bóyá ẹnì kan ṣì máa sọ ohun tó máa bí wa nínú tàbí kó ṣe ohun tó máa dùn wá. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. (Oníw. 7:20; Mát. 18:7) Àmọ́, kí lo máa ṣe? Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ná: Níbi àpèjẹ kan táwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò, arábìnrin kan kí àwọn arákùnrin méjì kan, inú ọ̀kan lára wọn ò dùn sí bó ṣe kí wọn. Lẹ́yìn tí arábìnrin náà ti lọ tán, arákùnrin tínú rẹ̀ ò dùn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí sí ohun tí arábìnrin náà sọ. Síbẹ̀, arákùnrin kejì rán arákùnrin tó ń bínú náà létí pé arábìnrin náà ti ń fòtítọ́ sin Jèhófà láìka ìṣòro sí láti ogójì ọdún [40] sẹ́yìn, àti pé kì í ṣe pé arábìnrin náà mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ mú un bínú. Lẹ́yìn tí arákùnrin tó ń bínú náà ronú díẹ̀ lórí ohun tó gbọ́ yìí, ó sọ pé: “Òótọ́ lo sọ.” Bí wọ́n sì ṣe yanjú rẹ̀ nìyẹn.
9 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Àwa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe tọ́rọ̀ kan tó lè fa aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ìfẹ́ máa ń mú kéèyàn dárí ji àwọn ẹlòmíì ni. (Ka Òwe 10:12; 1 Pétérù 4:8.) Lójú Jèhófà, “ẹwà” ló jẹ́ tó o bá le “gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11; Oníw. 7:9) Torí náà, nǹkan tó yẹ kó o kọ́kọ́ bi ara ẹ téèyàn bá ṣẹ̀ ọ́ ni pé, ‘Ṣé mo lè gbójú fò ó? Ṣó tiẹ̀ yẹ kí n sọ ọ̀rọ̀ náà di bàbàrà?’
10. (a) Báwo lọ̀rọ̀ àbùkù tí wọ́n sọ nípa arábìnrin kan ṣe rí lára rẹ̀? (b) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló ran arábìnrin yìí lọ́wọ́?
10 Ó lè má rọrùn fún wa láti gbójú fo ọ̀rọ̀ àbùkù téèyàn kan sọ sí wa. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Lucy. Àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ tí ò da nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti bó ṣe ń lo àkókò rẹ̀. Inú bí Lucy, ló bá lọ sọ̀rọ̀ náà fáwọn arákùnrin tó dàgbà dénú. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tí wọ́n sọ fún mi látinú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kí n mọ̀ pé kò yẹ kí n jẹ́ kọ́rọ̀ táwọn èèyàn ń sọ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, ó sì ti jẹ́ kí n pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Jèhófà, torí tiẹ̀ ló jà jù.” Ohun tó wà nínú Mátíù 6:1-4 fún Lucy níṣìírí gan-an. (Kà á.) Ẹsẹ Bíbélì yẹn rán an létí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù fún un ni pé kó máa múnú Jèhófà dùn. Ó wá sọ pé: “Báwọn èèyàn tiẹ̀ ń sọ ohun tí ò dáa nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, mi ò ní jẹ́ kíyẹn sorí mi kodò, torí mo mọ̀ pé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti múnú Jèhófà dùn.” Lẹ́yìn tí Lucy ti pinnu pé ohun tóun máa ṣe nìyẹn, ó kúkú gbójú fo ọ̀rọ̀ àbùkù tí wọ́n sọ nípa rẹ̀.
TÓ BÁ ṢÒRO FÚN Ẹ LÁTI GBÓJÚ FO ÀṢÌṢE NÁÀ ŃKỌ́?
11, 12. (a) Kí ló yẹ kí Kristẹni kan ṣe tó bá rò pé arákùnrin òun ‘ní ohun kan lòdì sí òun’? (b) Kí la lè rí kọ́ nínú bí Ábúráhámù ṣe yanjú aáwọ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
11 “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Ják. 3:2) Tó o bá gbọ́ pé ohun tó o ṣe tàbí ohun tó o sọ bí ẹnì kan nínú, kí lo yẹ kó o ṣe? Jésù sọ pé: “Bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mát. 5:23, 24) Níbàámu pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ yìí, kọ́kọ́ lọ bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀ ná. Má sì gbà gbé ohun tó o fẹ́ torí ẹ̀ lọ. Kì í ṣe torí kó o lè di ẹ̀bi rù ú lo ṣe fẹ́ lọ bá a, ṣe ni kó o bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú kí ẹ sì yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa.
12 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa báwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe yanjú ọ̀rọ̀ kan tó lè dá aáwọ̀ sílẹ̀ láàárín wọn, ọ̀kan lára rẹ̀ ni ti Ábúráhámù àti ìbátan rẹ̀ Lọ́ọ̀tì. Àwọn méjèèjì ní ẹran ọ̀sìn, àmọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ń bá ara wọn jà lórí ilẹ̀ táwọn ẹran náà ń jẹ̀ sí. Torí pé Ábúráhámù ò fẹ́ wàhálà, ó ní kí Lọ́ọ̀tì kọ́kọ́ mú apá ibi tóun àti ìdílé rẹ̀ máa wà. (Jẹ́n. 13:1, 2, 5-9) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere ló fi lélẹ̀ fún wa! Bí wọ́n ṣe máa wà lálàáfíà ni Ábúráhámù ń wá, kì í ṣe bó ṣe máa tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ṣé ó wá jìyà ohun tó ṣe yẹn? Rárá. Kété lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, Jèhófà ṣèlérí ìbùkún rẹpẹtẹ fún Ábúráhámù. (Jẹ́n. 13:14-17) Ọlọ́run ò ní jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jìyà àjẹgbé torí pé wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ láti fìfẹ́ yanjú aáwọ̀. [1]
13. Kí ni alábòójútó kan ṣe nígbà tẹ́nì kan fìbínú sọ̀rọ̀ sí i, kí la sì lè rí kọ́ nínú ohun tí alábòójútó náà ṣe?
13 Àpẹẹrẹ tòde òní kan rèé: Nígbà tí wọ́n yan alábòójútó tuntun kan láti máa bójú tó ẹ̀ka kan ní àpéjọ àgbègbè, ó pe arákùnrin kan lórí fóònù, ó sì bi í bóyá á lè yọ̀ǹda ara ẹ̀ fún iṣẹ́, àmọ́ ṣe ni arákùnrin tó pè yìí fìbínú sọ̀rọ̀, ó sì pa fóònù. Ohun tí alábòójútó tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe fún un ló ṣì ń dùn ún. Alábòójútó tuntun yìí ò jẹ́ kí ohun tí arákùnrin yìí ṣe bí òun nínú, síbẹ̀ kò lè gbójú fò ó dá. Ní wákàtí kan lẹ́yìn náà, ó tún pe arákùnrin yìí, ó sì sọ fún un pé àwọn ò tíì ríra rí àti pé á dáa káwọn jọ yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì pà dé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Lẹ́yìn tí wọ́n gbàdúrà tán, wákàtí kan gbáko ni wọ́n fi sọ̀rọ̀, arákùnrin náà sì sọ gbogbo ohun tó ń dùn ún lọ́kàn. Alábòójútó yìí tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, ó fi Ìwé Mímọ́ ràn án lọ́wọ́, tayọ̀tayọ̀ làwọn méjèèjì sì fi kúrò níbẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, arákùnrin náà yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àgbègbè, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ alábòójútó yẹn torí bí wọ́n ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí.
ṢÓ YẸ KÓ O PE ÀWỌN ALÀGBÀ SÍ I?
14, 15. (a) Àwọn ìgbà wo la lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Mátíù 18:15-17 sílò? (b) Ìgbésẹ̀ mẹ́ta wo ni Jésù ní ká gbé, kí ló sì yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ lọ bá ẹni tó ṣẹ̀ wá?
14 Bí aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwa Kristẹni, àárín ara wa ló ti yẹ ká yanjú ẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Àmọ́, Jésù sọ pé àwọn Mátíù 18:15-17.) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí ẹni tó ṣẹ̀ bá kọ̀ láti tẹ́tí sí arákùnrin rẹ̀, tí kò tẹ́tí sáwọn ẹlẹ́rìí tó wá bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ náà, tí kò sì tún tẹ́tí sí ìjọ? Ó yẹ kí a ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí “ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí lóde òní ni pé kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Pé ohun tí ẹni yìí ṣe lè la ìyọlẹ́gbẹ́ lọ fi hàn pé “ẹ̀ṣẹ̀” náà kì í wulẹ̀ ṣe èdè àìyedè tí kò tó nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ (1) ẹ̀ṣẹ̀ táwọn méjèèjì lè yanjú láàárín ara wọn, (2) ó tún jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì débi pé ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́ tí wọn ò bá yanjú ẹ̀. Irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè ní ẹ̀tàn tàbí èrú nínú, ó sì lè ba èèyàn lórúkọ jẹ́, táwọn èèyàn bá ń tàn án kálẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí báyìí nìkan la máa gbé àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí Jésù sọ. Àmọ́, tó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bíi panṣágà, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ìpẹ̀yìndà, ìbọ̀rìṣà tàbí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó burú jáì ni, àwọn alàgbà ló máa bójú tó o.
ọ̀rọ̀ kan wà tó yẹ káwọn alàgbà dá sí. (Ka15 Ìdí tí Jésù fi fún wa nímọ̀ràn yìí ni pé ó fẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fìfẹ́ ran arákùnrin wa lọ́wọ́. (Mát. 18:12-14) Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ká kọ́kọ́ yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú onítọ̀hún láì pe ẹlòmíì sí i. Ó lè gbà pé ká bá ẹni tó ṣẹ̀ wá sọ̀rọ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ nígbà míì. Tí ọ̀rọ̀ náà ò bá níyanjú, o lè ní kí àwọn tọ́rọ̀ náà ṣojú wọn bá yín dá sí i tàbí kó o ké sí àwọn tó o mọ̀ pé wọ́n lè sọ bóyá ẹni náà tiẹ̀ ṣe nǹkan tí kò dáa tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Tọ́rọ̀ náà bá wá yanjú, ó túmọ̀ sí pé o ti “jèrè arákùnrin rẹ” nìyẹn. Tọ́rọ̀ kan ò bá yanjú lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsapá la máa tó lọ sọ fáwọn alàgbà.
16. Kí ló fi hàn pé ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ lohun tí Jésù ní ká ṣe àti pé ó máa ń jẹ́ kí aáwọ̀ tètè yanjú?
16 Kì í sábàá ṣẹlẹ̀ pé ká gbé ìgbésẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà nínú Mátíù 18:15-17 kọ́rọ̀ tó níyanjú. Ìyẹn sì wúni lórí gan-an torí pé ọ̀rọ̀ ti sábà máa ń yanjú kó tó di pé wọ́n á yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ torí pé kò ronú pìwà dà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó ṣẹ̀ náà á ti rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa, á sì ti ṣàtúnṣe. Ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ náà sì lè rí i pé kò sídìí fóun láti máa wá ẹ̀sùn sí onítọ̀hún lẹ́sẹ̀, kó sì dárí jì í. Èyí ó wù kó jẹ́, ohun tí Jésù sọ fi hàn pé kò yẹ káwọn alàgbà máa dá sí ọ̀rọ̀ tí ò tíì yẹ kí wọ́n dá sí. Tọ́rọ̀ náà ò bá lójútùú lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ẹ̀rí tó ṣe gúnmọ́ sì wà pé nǹkan ọ̀hún ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ làwọn alàgbà tó lè dá sí i.
17. Àwọn ìbùkún wo la máa gbádùn tá a bá ń “wá àlàáfíà” pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?
17 Níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì wà nínú ètò àwọn nǹkan yìí, aláìpé làwa èèyàn á ṣì máa jẹ́, kò sì sí bá ò ṣe ní máa ṣẹra wa. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ni ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù ṣe sọ ọ́ pé: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Ják. 3:2) Tá a bá fẹ́ yanjú aáwọ̀, ó yẹ ká máa ‘wá àlàáfíà, kí a sì máa lépa rẹ̀.’ (Sm. 34:14) Tá a bá jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, àá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará wa, àá sì máa pa kún ìṣọ̀kan ìjọ. (Sm. 133:1-3) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà.” (Róòmù 15:33) Àwọn tó bá sì ń fìfẹ́ parí aáwọ̀ ló máa lè gbádùn irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀.
^ [1] (ìpínrọ̀ 12) Àwọn míì tó tún fìfẹ́ yanjú aáwọ̀ ni: Jékọ́bù àti Ísọ̀ (Jẹ́n. 27:41-45; 33:1-11); Jósẹ́fù àtàwọn arákùnrin rẹ̀ (Jẹ́n. 45:1-15); àti Gídíónì pẹ̀lú àwọn èèyàn Éfúráímù. (Oníd. 8:1-3) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ronú nípa àwọn àpẹẹrẹ míì tó wà nínú Bíbélì.