ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Láyọ̀ Pé Mò Ń Lo Ara Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ọlọ́run
ỌMỌ ọdún méjìlá ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ mọ̀ pé mo lẹ́bùn kan tí mo lè fáwọn èèyàn. Lọ́jọ́ kan tá a wà ní àpéjọ, arákùnrin kan bi mí pé ṣé màá fẹ́ wàásù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì wàásù rí mo dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Bí àwa méjèèjì ṣe lọ síbi tá a ti máa wàásù nìyẹn. Ó kó àwọn ìwé kékeré tó ń sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún mi, ó wá sọ fún mi pé: “Ìwọ lọ bá àwọn èèyàn tó wà lápá ọ̀hún yẹn sọ̀rọ̀, èmi á ṣe apá ibí.” Bí mo ṣe ń lọ, ṣe làyà mi ń lù kì kì, síbẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn èèyàn láti ilé kan síkejì. Kí n tó mọ̀, mo ti pín gbogbo ìwé tó wà lọ́wọ́ mi tán. Ó ya èmi alára lẹ́nu, àmọ́ ó ṣe kedere pé inú àwọn èèyàn dùn láti gba ohun tí mo mú wá fún wọn.
Ọdún 1923 ni wọ́n bí mi nílùú Chatham, lágbègbè Kent, lórílẹ̀-èdè England. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ni nǹkan tojú sú torí wọ́n rò pé Ogun Àgbáyé Kìíní máa máyé dẹrùn, àmọ́ ṣe ni nǹkan burú sí i. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ àwọn àlùfáà Ìjọ Onítẹ̀bọmi sú àwọn òbí mi torí wọn ò mọ̀ ju tara wọn lọ. Bí màámi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a wá mọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Inú Gbọ̀ngàn kan ni wọ́n ti ń ṣèpàdé, ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tó wà nípàdé náà sì máa ń fi Bíbélì àti ìwé Duru Ọlọrun kọ́ àwa ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́. Nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí nígbà yẹn, mo sì nífẹ̀ẹ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ wa gan-an.
MO KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN ARÁKÙNRIN TÓ NÍRÌÍRÍ
Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo gbádùn kí n máa fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn nípa ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fáráyé. Lóòótọ́ mo sábà máa ń dá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, àmọ́ mo tún rí ẹ̀kọ́ kọ́ bí mo ṣe ń bá àwọn míì ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan tí mo bá arákùnrin kan tó nírìírí ṣiṣẹ́, a gun kẹ̀kẹ́ kọjá lára àlùfáà kan, ni mo bá ní: “Ẹ ẹ̀ rí i, ewúrẹ́ kan ló ń lọ yẹn.” Arákùnrin náà wá ní ká dúró díẹ̀, ó ní ká jókòó sórí igi gẹdú kan. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ta ló fún ẹ láṣẹ láti máa pèèyàn ní ewúrẹ́? Jèhófà ló máa ṣèyẹn, tiwa ni pé ká wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn.” Ẹ̀kọ́ míì tí mo kọ́ ni pé èèyàn máa ń láyọ̀ gan-an tó bá ń lo ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run.—Mát. 25:31-33; Ìṣe 20:35.
Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ lára arákùnrin míì pé téèyàn bá fẹ́ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, àfi kó máa ní sùúrù, kó sì ní ìfaradà. Ìyàwó arákùnrin yẹn kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin náà ní kí n yà nílé òun lẹ́yìn òde ẹ̀rí ká jọ wá nǹkan jẹ. Lẹ́yìn tá a délé, inú bí ìyàwó rẹ̀ gan-an pé ó lọ sóde ẹ̀rí débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í ju páálí tíì lù wá. Kàkà kí arákùnrin náà kanra mọ́
ìyàwó rẹ̀, ṣe ló rọra ṣa àwọn tíì náà, ó sì kó wọn pa dà sáyè wọn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, sùúrù rẹ̀ sèso rere torí pé ìyàwó ẹ̀ ṣèrìbọmi, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.Bí mo ṣe ń dàgbà sí i, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń wù mí pé kí n máa sọ̀rọ̀ ìtùnú nípa ọjọ́ ọ̀la fáwọn èèyàn. Nígbà tó di oṣù March ọdún 1940, èmi àti mọ́mì mi ṣèrìbọmi nílùú Dover. Ní September ọdún 1939, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wọ̀jà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Jámánì, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni mí nígbà yẹn. Ní June ọdún 1940, iwájú ilé wa ni mo wà táwọn ọkọ̀ akẹ́rù ń kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn sójà kọjá, ẹni bá rí wọn á mọ̀ pé ojú wọn ti rí màbo. Ìwọ̀nba àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó lọ jagun nílùú Dunkirk ni wọ́n. Bí mo ṣe rí wọn, mo rí i pé ayé ti sú wọn, ó sì wù mí kí n sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Bọ́dún yẹn ṣe ń parí lọ, òjò bọ́ǹbù bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Alaalẹ́ làwọn ọmọ ogun Jámánì máa ń rọ̀jò bọ́ǹbù sádùúgbò wa látinú ọkọ̀ òfúúrufú. Mo máa ń gbọ́ báwọn bọ́ǹbù yẹn ṣe ń já ṣòòròṣò, tí wọ́n bá sì bú gbàù, ẹ̀rù máa ń bà wá gan-an. Tá a bá wá jáde láàárọ̀ ọjọ́ kejì, àá rí i tí ilé sùn lọ bẹẹrẹ bẹ. Ó wá túbọ̀ ṣe kedere sí mi pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé.
MO BẸ̀RẸ̀ SÍ Í LO AYÉ MI LẸ́NU IṢẸ́ ỌLỌ́RUN
Ọdún 1941 ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í fayé mi ṣe ohun tó fún mi láyọ̀ gan-an. Tẹ́lẹ̀, iléeṣẹ́ Royal Dockyard tó wà nílùú Chatham tí wọ́n ti ń ṣe ọkọ̀ ojú omi ni mo ti ń ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ wọ iléeṣẹ́ yìí torí pé àwọn àjẹmọ́nú àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ń fún wa pọ̀. Ó pẹ́ táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti mọ̀ pé kò yẹ ká máa gbè sẹ́yìn orílẹ̀-èdè kankan nígbà tí wọ́n bá ń jagun. Lọ́dún 1941, ètò Ọlọ́run mú kó túbọ̀ ṣe kedere pé a ò lè máa ṣiṣẹ́ níléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe ohun ìjà ogun. (Jòh. 18:36) Torí pé ọkọ̀ ogun tó ń rìn lábẹ́ omi là ń ṣe nílé iṣẹ́ yẹn, mo fiṣẹ́ sílẹ̀ mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìlú Cirencester tó wà lágbègbè Cotswolds ni ètò Ọlọ́run kọ́kọ́ rán mi lọ.
Nígbà tí mo pọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18], ìjọba jù mí sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́sàn-án torí pé mi ò gbà láti wọṣẹ́ ológun. Ẹ̀rù bà mí nígbà tí mo dénú ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sì ti ilẹ̀kùn mọ́ mi, mo wọ̀tún mo wòsì, kò sẹ́nì kan. Nígbà tó yá, àwọn wọ́dà àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n míì ń béèrè ohun tó gbé mi dẹ́wọ̀n. Inú mi dùn gan-an pé mo ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ fún wọn.
Lẹ́yìn tí ìjọba dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ bá Arákùnrin Leonard Smith * ká lè jọ máa wàásù láwọn ìlú tó wà lágbègbè Kent tí mo dàgbà sí. Ìpínlẹ̀ ìwàásù wa wà láàárín ibi táwọn ọmọ ogun Násì wà àti ìlú London. Lọ́dún 1944, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀jò bọ́ǹbù sí àgbègbè Kent. Lọ́tẹ̀ yìí àwọn ọkọ̀ òfúúrufú tí wọ́n kó bọ́ǹbù kúnnú wọn ni wọ́n lò. Ìró àwọn bọ́ǹbù yẹn máa ń bani lẹ́rù gan-an. Lákòókò yẹn, ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún kan wà tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà míì, abẹ́ tábìlì onírin la máa ń sá sí tọ́rọ̀ bá di bóò-lọ-yàá-mi, kí ilé má bàa wó lé wa lórí. A dúpẹ́ pé gbogbo ìdílé náà ló pa dà ṣèrìbọmi.
A LỌ WÀÁSÙ LÁWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ MÍÌ
Lẹ́yìn tógun parí, mo lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Ireland fún ọdún méjì. A ò mọ̀ pé ìlú yìí yàtọ̀ pátápátá sórílẹ̀-èdè England. Ṣe là ń lọ láti ilé kan sí òmíì tá à ń sọ fún wọn pé míṣọ́nnárì ni wá, a sì ń wá ilé, a tún ń fáwọn èèyàn ní ìwé wa lójú ọ̀nà. Ohun tá à ń ṣe yìí kò bọ́gbọ́n mu rárá torí pé àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló kún orílẹ̀-èdè yìí. Nígbà tí ọkùnrin kan halẹ̀ mọ́ wa, a lọ fẹjọ́ ẹ̀ sun ọlọ́pàá kan. Àmọ́, ọlọ́pàá náà sọ fún wa pé, “Ṣé ẹ̀yin náà ò mọ ibi tẹ́ ẹ wà ni?” A ò mọ̀ pé àwọn àlùfáà lẹ́nu gan-an níbẹ̀, wọ́n máa ń dá àwọn èèyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n bá gbàwé wa. Kódà, wọ́n lé àwa náà kúrò nílé wa.
Kò pẹ́ tá a fi wá mọ̀ pé tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ìlú kan, ohun tó dáa jù ni pé ká lọ bẹ̀rẹ̀ ìwàásù níbi tó jìn síbi tá a wà, tí àlùfáà tó wà lágbègbè wọn sì yàtọ̀ sí àlùfáà tó wà níbi tá à ń gbé. Tó bá wá yá, àá lọ wàásù fáwọn tó ń gbé nítòsí wa. Lágbègbè Kilkenny, ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ là ń kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ láìka tàwọn jàǹdùkú tó ń halẹ̀ mọ́ wa sí. Mo fẹ́ràn àtimáa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìdí nìyẹn tí mo fi pinnu láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì kí n lè di míṣọ́nnárì.
Wọ́n pè mí sílé ẹ̀kọ́ yẹn, oṣù márùn-ún la sì fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ New York. Lẹ́yìn tá a parí, wọ́n ní kí mẹ́rin lára wa lọ sí àwọn erékùṣù kéékèèké tó wà ní Òkun Caribbean. Ọkọ̀ ojú omi tó ń jẹ́ Sibia la wọ̀ nígbà tá a gbéra nílùú New York City ní November ọdún 1948. Inú mi dùn gan-an torí pé mi ò wọ ọkọ̀ ojú omi rí. Ó ti pẹ́ tí ọ̀kan nínú wa tó ń jẹ́ Gust Maki ti ń wa ọkọ̀ ojú omi. Ó sì kọ́ wa láwọn nǹkan díẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀ ojú omi. Lára ohun tó kọ́ wa ni bá a ṣe lè ta aṣọ tó máa ń wà lórí ọkọ̀, bá ò ṣe ní yà bàrá kúrò lójú ọ̀nà ibi tá à ń lọ àti bí ìjì ò ṣe ní sojú ọkọ̀ dé. Arákùnrin Gust ló wa ọkọ̀ yìí fún ọgbọ́n ọjọ́ títí tá a fi dé orílẹ̀-èdè Bahamas láìka ti ìjì tó ń bì lù wá.
Ẹ SỌ Ọ̀RỌ̀ JÈHÓFÀ FÚN ÀWỌN TÓ WÀ NÍ ERÉKÙṢÙ
A wàásù láwọn erékùṣù kéékèèké Bahamas fún oṣù mélòó kan, lẹ́yìn náà a kọjá sí erékùṣù Leeward àti erékùṣù Windward. Àwọn erékùṣù yìí fẹ̀ gan-an, tá a bá mú un láti àwọn erékùṣù tó wà nítòsí Puerto Rico sí orílẹ̀-èdè Trinidad, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn mẹ́jọ [800] kìlómítà. Ọdún márùn-ún gbáko la fi wàásù láwọn erékùṣù tí kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀. Àwọn erékùṣù náà jìnnà sígboro, ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ sì lè kọjá tá ò ní rí lẹ́tà gbà táwa náà ò sì ní lè fi lẹ́tà ránṣẹ́. Àmọ́ inú wa máa ń dùn pé à ń sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn tó wà láwọn erékùṣù yẹn.—Jer. 31:10.
Tá a bá ti dé erékùṣù kan, ńṣe làwọn èèyàn máa ń kóra jọ sí etídò, wọ́n á máa wò wá tìyanutìyanu. Àwọn míì lára wọn kò tíì rí irú ọkọ̀ ojú omi wa yìí rí, àwọn míì ò sì rí òyìnbó rí. Àmọ́ o, àwọn èèyàn náà kóòyàn mọ́ra, wọ́n sì fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, torí náà wọ́n máa ń ka Bíbélì gan-an. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń fún wa ní ẹja tútù, èso píà àti ẹ̀pà. Kò fi bẹ́ẹ̀ sáyè nínú ọkọ̀ ojú omi wa láti sùn, láti dáná tàbí láti fọ àwọn aṣọ wa, síbẹ̀ a rọ́gbọ́n ẹ̀ dá.
Lẹ́yìn tá a bá ti gúnlẹ̀, àá bọ́ sínú ìlú, àá sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. A sábà máa ń sọ fún wọn pé àsọyé Bíbélì máa wà lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Tó bá dọwọ́ ìrọ̀lẹ́, a máa ń lu aago inú ọkọ̀ ojú omi wa, àwọn èèyàn náà á sì bẹ̀rẹ̀ sí í dé. Wọ́n á gbé àtùpà elépo wọn dání, iná àtùpà náà á wá máa ṣe yẹ-yẹ̀-yẹ. Nígbà míì, àwọn bí ọgọ́rùn-ún lè wá, wọ́n sì lè dalẹ́ lọ́dọ̀ wa, wọ́n á máa bi wá ní
ìbéèrè. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gbádùn kí wọ́n máa kọrin gan-an. Torí náà, a máa ń tẹ àwọn ọ̀rọ̀ orin wa síwèé fún wọn. Nígbà táwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin bá gbé ohùn orin náà, ká tó mọ̀ wọ́n ti ń bá wa kọ ọ́. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, àwọn èèyàn náà lóhùn orin. A mà gbádùn àsìkò yẹn o!Tá a bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn kan tán, wọ́n máa ń tẹ̀ lé wa dé ọ̀dọ̀ ìdílé tó kàn, wọ́n á sì dara pọ̀ mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn yẹn náà. A kì í lò ju ọ̀sẹ̀ mélòó kan ní abúlé kọ̀ọ̀kan. Torí náà, tá a bá ti fẹ́ kúrò, a máa ń fa àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lé àwọn tó ti tẹ̀ síwájú dáadáa lára wọn lọ́wọ́ títí dìgbà tá a tún máa pa dà lọ síbẹ̀. Inú wa dùn gan-an pé ọ̀pọ̀ wọn ló ṣe iṣẹ́ náà bí iṣẹ́.
Lóde òní, àwọn erékùṣù yẹn ti di ibi àpéwò táwọn èèyàn ti máa ń fójú lóúnjẹ. Àmọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún, abúlé táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ nípa wọn làwọn erékùṣù náà. Àwọn ohun tẹ́ ẹ máa rí nígbà yẹn ò ju omi tó lọ salalu, yanrìn tó lọ bẹẹrẹ bẹ àtàwọn igi àgbọn. Alaalẹ́ la sábà máa ń ti erékùṣù kan lọ sí òmíì. Gbogbo nǹkan á pa lọ́lọ́, àyàfi ìró ọkọ̀ ojú omi wa tó ń lọ lójú omi. A máa ń rí àwọn ẹja Dolphin tí wọ́n máa ń tọ sókè sódò tí wọ́n á sì máa kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú ọkọ̀ wa, àyíká á sì mọ́ lóló torí pé rokoṣo ni òṣùpá máa ń ràn.
Lẹ́yìn ọdún márùn-ún, a gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè Puerto Rico ká lè pààrọ̀ ọkọ̀ ojú omi wa pẹ̀lú ọkọ̀ ojú omi tó ń lo ẹ́ńjìnnì. Nígbà tá a débẹ̀, mo pàdé arábìnrin kan tó ń jẹ́ Maxine Boyd. Míṣọ́nnárì ni, ó sì rẹwà gan-an, bí mo ṣe rí i lọkàn mi ti fà sí i. Àtikékeré ló ti ń fìtara wàásù, nígbà tó sì dàgbà ó lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Dominican Republic kó tó di pé àwọn aláṣẹ tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì lé e kúrò níbẹ̀ lọ́dún 1950. Torí pé mo wà lára àwọn tó ń tukọ̀ ojú omi, ìjọba orílẹ̀-èdè Puerto Rico gbà mí láyè láti lò tó oṣù kan. Tá a bá sì ti kúrò, á tó ọdún mélòó kan kí n tó tún lè pa dà sí orílẹ̀-èdè náà. Ìdí nìyẹn tí mo fi ronú pé á dáa kí n tètè sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún arábìnrin náà. Lẹ́yìn tá a lo ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo kọnu ìfẹ́ sí i, ó sì gbà. Ìgbà tó máa di ọ̀sẹ̀ kẹfà, a ṣègbéyàwó. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, ètò Ọlọ́run ní káwa méjèèjì máa sìn lórílẹ̀-èdè Puerto Rico, bó ṣe di pé mi ò bá wọn pa dà nínú ọkọ̀ ojú omi tuntun tá a pààrọ̀ nìyẹn.
Lọ́dún 1956, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká, a sì ń bẹ àwọn ìjọ wò. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ni ò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ, àmọ́ a máa ń gbádùn wọn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ní abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Potala Pastillo, ìdílé méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ ará, tí wọ́n sì láwọn ọmọ tó pọ̀. Tá a bá bẹ ìjọ wọn wò, mo máa ń fi fèrè kọrin fún àwọn ọmọ náà. Lọ́jọ́ kan, mo bi ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin wọn tó ń jẹ́ Hilda bóyá á fẹ́ bá wa jáde òde ẹ̀rí. Ó ní: “Ó wù mí kí n lọ àmọ́ mi ò ní lè lọ torí mi ò ní bàtà.” A ra bàtà fún un, ó sì bá wa jáde. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, èmi àtìyàwó mi ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn lọ́dún 1972. Bí arábìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣe wá kí wa nìyẹn, ó ń múra àtilọ sí orílẹ̀-èdè Ecuador tí wọ́n ti ní kó lọ máa sìn. Ó wá bi wá pé: “Ẹ ò mọ̀ mí mọ́ o? Ṣé ẹ rántí ọmọ kan ní abúlé Pastillo tí kò ní bàtà? Ọmọ ọjọ́sí ọ̀hún rèé.” Àbẹ́ ò rí nǹkan, Hilda ọmọbìnrin àtàtà! Ṣe lomijé ayọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú wa.
Lọ́dún 1960, wọ́n pè wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Puerto Rico. Ilé alájà méjì kan tó wà lágbègbè Santurce, nílùú San Juan ni ọ́fíìsì náà wà. Níbẹ̀rẹ̀, èmi àti Arákùnrin Lennart Johnson la máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ náà. Arákùnrin yìí àtìyàwó rẹ̀ ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà àkọ́kọ́ tó wàásù lórílẹ̀-èdè Dominican Republic. Àmọ́ lọ́dún 1957, wọ́n gbé wọn wá sí orílẹ̀-èdè Puerto Rico. Nígbà tó yá, ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó àsansílẹ̀ ìwé ìròyìn, ó máa ń ṣe èyí tó ju ẹgbẹ̀rún kan lọ láàárín ọ̀sẹ̀ kan péré. Síbẹ̀, ó gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an torí pé ó máa ń ronú nípa àwọn tó ń jàǹfààní oúnjẹ tẹ̀mí yẹn.
Mo gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì gan-an torí pé ó jẹ́ kí n lè lo ara mi lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́, iṣẹ́ ìsìn yìí náà níṣòro tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a ṣe àpéjọ àgbáyé àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè Puerto Rico lọ́dún 1967. Iṣẹ́ mímúra àpéjọ yẹn wọ̀ mí lọ́rùn gan-an. Nígbà tí Arákùnrin Nathan Knorr tó ń múpò iwájú láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn wá sí Puerto Rico, ó rò pé mi ò ṣètò ọkọ̀ kankan fáwọn míṣọ́nnárì tó wá sórílẹ̀-èdè náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó pè mí, ó bá mi wí gan-an, ó ní mi ò mọṣẹ́ mi níṣẹ́. Ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí wọ eegun, kódà mo gbé e sára fúngbà díẹ̀ torí pé Arákùnrin Knorr kò gbọ́ tẹnu mi, síbẹ̀ mi ò bá a jiyàn. Bó ti wù kó rí, nígbà témi àtìyàwó mi tún pa dà rí Arákùnrin Knorr, ó ní ká wá sí yàrá òun ó sì dáná fún wa.
Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ti Puerto Rico lọ kí àwọn ìdílé mi lórílẹ̀-èdè England. Èmi àti mọ́mì mi nìkan la rí òtítọ́, dádì mi ò ṣètò. Àmọ́, táwọn ará láti Bẹ́tẹ́lì bá
wá sọ àsọyé, mọ́mì mi máa ń gbà kí wọ́n dé sílé wa. Ìyẹn mú kí dádì mi kíyè sí i pé àwọn arákùnrin yẹn yàtọ̀ pátápátá sáwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ tẹ́lẹ̀. Àwọn àlùfáà yẹn ò mọ̀ ju tara wọn lọ, àmọ́ onírẹ̀lẹ̀ làwọn arákùnrin yẹn. Nígbà tó fi máa dọdún 1962, Dádì ṣèrìbọmi, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.Ó dùn mí gan-an pé Maxine ìyàwó mi ṣaláìsí lọ́dún 2011. Àmọ́ ọkàn mi balẹ̀ pé màá rí i nígbà àjíǹde. Ìrètí àgbàyanu gbáà ni! Ní gbogbo ọdún méjìdínlọ́gọ́ta [58] témi àtìyàwó mi jọ gbé pọ̀, ojú wa làwọn èèyàn Jèhófà lórílẹ̀-èdè Puerto Rico di ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26,000] láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ààbọ̀ [650] tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀. Nígbà tó dọdún 2013, ètò Ọlọ́run sọ ẹ̀ka ọ́fíìsì Puerto Rico àti ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà di ọ̀kan, wọ́n sì ní kí n wá máa sìn ní ọ́fíìsì wa ní Wallkill, ìpínlẹ̀ New York. Èyí ò rọrùn fún mi torí pé ọgọ́ta [60] ọdún gbáko ni mo ti lò lórílẹ̀-èdè Puerto Rico. Ibẹ̀ sì ti di ilé mi. Àmọ́ ní báyìí, ètò Ọlọ́run ní àsìkò tó láti kúrò níbẹ̀.
“ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́ OLÙFÚNNI ỌLỌ́YÀYÀ”
Mò ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún [90] báyìí. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni pé kí n máa fáwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì níṣìírí. Kódà, wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé ó ti lé lọ́gọ́rùn-ún mẹ́fà [600] mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí mo ti gbà níyànjú látìgbà tí mo ti dé sí Wallkill. Àwọn kan tó máa ń wá sọ́dọ̀ mi máa ń fẹ́ kí n gbà wọ́n níyànjú nípa ọ̀rọ̀ ìdílé àtàwọn ìṣòro tí wọ́n ní. Àwọn míì máa ń béèrè ohun táwọn lè ṣe káwọn lè gbádùn iṣẹ́ ìsìn wọn ní Bẹ́tẹ́lì. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó máa ń wá gbàmọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe lè ṣàṣeyọrí. Àwọn míì sì wà tí ètò Ọlọ́run ti ní kí wọ́n máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ ní pápá. Mo máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ohun táwọn èèyàn bá fẹ́ bá mi sọ, nígbà tó bá sì yẹ, mo sábà máa ń sọ fún wọn pé: “‘Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.’ Torí náà, jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ máa múnú ẹ dùn. Jèhófà lò ń ṣe é fún.”—2 Kọ́r. 9:7.
Ohun tó yẹ kéèyàn ṣe táá fi láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì náà lèèyàn á ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn míì. Ohun náà sì ni pé: O gbọ́dọ̀ mọ ìdí tí ohun tó ò ń ṣe fi ṣe pàtàkì, kó o sì jẹ́ kíyẹn máa wà lọ́kàn rẹ. Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ni gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì. Ìrànwọ́ ni gbogbo wa ń ṣe fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kí wọ́n lè máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé. (Mát. 24:45) Ibi yòówù ká ti máa sin Jèhófà, gbogbo wa la láǹfààní láti máa yìn ín lógo. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa yọ̀ pé à ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n fún wa, torí pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”
^ ìpínrọ̀ 13 Ìtàn ìgbésí ayé Leonard Smith wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2012.