ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 47
Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ìfẹ́ Tá A Ní Sáwọn Ará Túbọ̀ Lágbára
“Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.”—1 JÒH. 4:7.
ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1-2. (a) Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé ìfẹ́ ló “tóbi jù lọ”? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́, ohun tó fi parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni pé “èyí tó tóbi jù lọ nínú [àwọn ànímọ́ yìí] ni ìfẹ́.” (1 Kọ́r. 13:13) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé lọ́jọ́ iwájú, kò ní sídìí fún wa mọ́ láti nígbàgbọ́ nínú àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe nínú ayé tuntun tàbí ká máa retí pé ó máa mú àwọn ìlérí náà ṣẹ torí pé gbogbo ẹ̀ ló ti máa ṣẹ. Àmọ́ ìgbà gbogbo làá máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Kódà, títí ayé làá máa nífẹ̀ẹ́ wọn.
2 Kò sígbà tá ò ní máa fìfẹ́ hàn, torí náà a máa jíròrò ìbéèrè mẹ́ta yìí. Àkọ́kọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa? Ìkejì, báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará? Ìkẹta, báwo la ṣe lè mú kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará túbọ̀ lágbára?
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ?
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará?
3 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará? Ìdí ni pé ìfẹ́ wà lára ohun tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:35) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, a máa wà níṣọ̀kan. Pọ́ọ̀lù sọ pé ìfẹ́ ni “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:14) Àmọ́, ìdí pàtàkì míì wà tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.” (1 Jòh. 4:21) Torí náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ìyẹn máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
4-5. Ṣàpèjúwe bí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe kan ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará.
4 Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe kan ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará? Àpèjúwe kan rèé: Wo bí ọkàn wa àtàwọn ẹ̀yà ara wa yòókù ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Tí dókítà kan bá fẹ́ mọ̀ bóyá ọkàn wa ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ó máa fi ọwọ́ ẹ̀ sí ọrùn ọwọ́ wa láti mọ̀ bóyá à ń mí bó ṣe yẹ, ìyẹn sì máa jẹ́ kó mọ̀ bóyá ọkàn wa ń ṣiṣẹ́ dáadáa tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ẹ̀kọ́ wo ni àpèjúwe yìí kọ́ wa nípa bó ṣe yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará?
5 Tí dókítà kan bá fọwọ́ sí ọrùn ọwọ́ wa, ó máa mọ̀ bóyá ọkàn wa ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Lọ́nà kan náà, tá a bá wo bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tó, ìyẹn máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó. Tá a bá kíyè sí i pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará mọ́, ìyẹn lè fi hàn pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà mọ́. Àmọ́ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará ní gbogbo ìgbà, ìyẹn máa jẹ́ ká mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an.
6. Tá a bá rí i pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará mọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká wá nǹkan ṣe sí i? (1 Jòhánù 4:7-9, 11)
6 Tá a bá rí i pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará mọ́, ó yẹ ká wá nǹkan ṣe sí i. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà máa bà jẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ká rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ tó rí, kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.” (1 Jòh. 4:20) Kí la rí kọ́? Inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá “nífẹ̀ẹ́ ara wa.”—Ka 1 Jòhánù 4:7-9, 11.
BÁWO LA ṢE LÈ FI HÀN PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ?
7-8. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará?
7 Nínú Bíbélì, léraléra ni Jèhófà pa á láṣẹ fún wa pé ká “nífẹ̀ẹ́ ara wa.” (Jòh. 15:12, 17; Róòmù 13:8; 1 Tẹs. 4:9; 1 Pét. 1:22; 1 Jòh. 4:11) Àmọ́ inú ọkàn ni ìfẹ́ ti ń wá, kò sì séèyàn kankan tó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Torí náà, báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Ohun tá à ń sọ àtohun tá à ń ṣe ló máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀.
8 Onírúurú ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ rèé: “Ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́.” (Sek. 8:16) ‘Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín yín.’ (Máàkù 9:50) Ẹ máa fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ “nínú bíbu ọlá fún ara yín.” (Róòmù 12:10) “Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín.” (Róòmù 15:7) “Ẹ máa . . . dárí ji ara yín.” (Kól. 3:13) “Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù tó wúwo.” (Gál. 6:2) ‘Ẹ máa tu ara yín nínú.’ (1 Tẹs. 4:18) “Ẹ máa . . . gbé ara yín ró.” (1 Tẹs. 5:11) ‘Ẹ máa gbàdúrà fún ara yín.’—Jém. 5:16.
9. Tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fìfẹ́ hàn bá a ṣe sọ nínú ìpínrọ̀ kẹjọ. A máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, ó ní: ‘Ẹ máa tu ara yín nínú.’ Tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò tí wọ́n tú sí ‘tù nínú’ nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “kí ẹnì kan dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹni tó níṣòro tó le gan-an, kó sì fún un níṣìírí.” Tá a bá tu arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú, ńṣe là ń ràn án lọ́wọ́ kó lè máa rìn ní ọ̀nà ìyè nìṣó. Torí náà, gbogbo ìgbà tá a bá dúró ti àwọn ará là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.—2 Kọ́r. 7:6, 7, 13.
10. Báwo ni ojú àánú àti ìtùnú ṣe jọra wọn?
10 Ẹni tó lójú àánú àti ẹni tó máa ń tu àwọn èèyàn nínú ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹni tó lójú àánú máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì máa ń fẹ́ yanjú ìṣòro wọn. Torí náà, tá a bá lójú àánú, àá máa tu àwọn èèyàn nínú. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé olójú àánú ni Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi máa ń tu àwọn èèyàn nínú. Ó pe Jèhófà ní “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́r. 1:3) Nínú àlàyé tá a ṣe lórí ẹsẹ yìí nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì, Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà “àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” láti ṣàlàyé bí àánú àwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe wá. Torí náà, “Ọlọ́run ni Baba tàbí Orísun àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ torí pé ọ̀dọ̀ ẹ̀ ni àánú ti wá.” Àánú tó ní yìí ló máa ń jẹ́ kó tù wá nínú “nínú gbogbo àdánwò wa.” (2 Kọ́r. 1:4) Bí omi tó mọ́ lóló tó ń sun jáde látinú ìsun omi kan ṣe máa ń tu àwọn tí òùgbẹ ń gbẹ lára, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń tu àwọn tó níṣòro nínú, kára lè tù wọ́n. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà bó ṣe ń ṣàánú àwọn èèyàn, tó sì ń tù wọ́n nínú? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká láwọn ànímọ́ táá jẹ́ ká máa tu àwọn èèyàn nínú. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ náà?
11. Àwọn ànímọ́ míì wo ni Kólósè 3:12 àti 1 Pétérù 3:8 sọ pé a gbọ́dọ̀ ní táá jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará, ká sì máa tù wọ́n nínú?
11 Kí lá jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn, ká sì ‘máa tu ara wa nínú’ lójoojúmọ́? Ohun táá jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa bára wa kẹ́dùn, ká ní ìfẹ́ ará àti inú rere. (Ka Kólósè 3:12; 1 Pétérù 3:8.) Báwo làwọn ànímọ́ yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? Tá a bá lójú àánú, tá a sì tún láwọn ànímọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí, kò sí bá ò ṣe ní máa tu àwọn tó níṣòro nínú. Jésù sọ pé “ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ. Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere rẹ̀.” (Mát. 12:34, 35) Torí náà, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni pé ká máa tù wọ́n nínú.
BÁWO LA ṢE LÈ MÚ KÍ ÌFẸ́ TÁ A NÍ SÁWỌN ARÁ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA?
12. (a) Kí nìdí tí ò fi yẹ ká jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará tutù? (b) Ìbéèrè wo la máa dáhùn báyìí?
12 Gbogbo wa ló wù pé “ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.” (1 Jòh. 4:7) Àmọ́, ó yẹ ká rántí ìkìlọ̀ Jésù pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù.” (Mát. 24:12) Jésù ò sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun ò ní fìfẹ́ hàn síra wọn mọ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká ṣọ́ra, ká má fìwà jọ àwọn èèyàn ayé tí wọn kì í fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí: Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará ò tíì tutù?
13. Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú?
13 Ọ̀nà kan tá a lè fi mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú ni pé ká wo ohun tá a máa ń ṣe tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀ láàárín wa. (2 Kọ́r. 8:8) Àpọ́sítélì Pétérù sọ ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká ṣe, ó ní: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín, torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pét. 4:8) Torí náà, ohun tá a bá ṣe nígbà táwọn ará bá ṣẹ̀ wá tàbí tá a bá rí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú.
14. Irú ìfẹ́ wo ni 1 Pétérù 4:8 sọ pé ó yẹ ká ní? Ṣàpèjúwe.
14 Ẹ jẹ́ ká ronú dáadáa nípa ohun tí Pétérù sọ. Apá àkọ́kọ́ nínú ẹsẹ kẹjọ sọ irú ìfẹ́ tó yẹ ká ní, ìyẹn “ìfẹ́ tó jinlẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tí Pétérù lò nínú ẹsẹ yìí, ìyẹn “jinlẹ̀” túmọ̀ sí kéèyàn “na nǹkan.” Apá kejì nínú ẹsẹ yẹn wá sọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sáwọn èèyàn. Ó sọ pé ó máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará mọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Téèyàn bá fi ọwọ́ méjèèjì di aṣọ kan mú tó sì fẹ́ fi bo nǹkan, ńṣe lá bẹ̀rẹ̀ sí í nà án títí á fi bo gbogbo ohun tó fẹ́ bò. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa fi ìfẹ́ bo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará mọ́lẹ̀, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ẹyọ kan tàbí méjì, àmọ́ “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” A lè fi béèyàn ṣe ń bo nǹkan wé béèyàn ṣe ń dárí ji àwọn ẹlòmíì. Bí aṣọ ṣe máa ń bo àbùkù ara, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa fi ìfẹ́ bo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará.
15. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dáadáa, kí la máa ṣe? (Kólósè 3:13)
15 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, àá dárí jì wọ́n, kódà tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Kólósè 3:13.) Tá a bá ń dárí ji àwọn ará, ìyẹn máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Nǹkan míì wo ló máa jẹ́ ká dárí ji àwọn ará, kódà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe tàbí ṣe ohun tó múnú bí wa?
16-17. Nǹkan míì wo ló máa jẹ́ ká gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àwọn ará? Ṣàpèjúwe. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ibi táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dáa sí ló yẹ kó o máa wò, kì í ṣe ibi tí wọ́n kù sí. Wo àpèjúwe yìí. Ká sọ pé ìwọ àtàwọn ará wà níbi ìkórajọ kan tẹ́ ẹ̀ ń gbádùn ara yín, lẹ́yìn tẹ́ ẹ ṣe tán, o ya fọ́tò gbogbo yín. Kódà, o ya fọ́tò méjì míì torí ó ṣeé ṣe kí tàkọ́kọ́ má dáa. Ní báyìí, o ti ní fọ́tò mẹ́ta. Àmọ́, o kíyè sí pé arákùnrin kan lejú koko nínú ọ̀kan lára àwọn fọ́tò yẹn. Kí lo máa ṣe sí fọ́tò náà? Ńṣe lo máa yọ ọ́ kúrò torí o ṣì ní fọ́tò méjì míì tí gbogbo yín ti rẹ́rìn ín, títí kan arákùnrin yẹn.
17 A lè fi àwọn fọ́tò tá ò yọ kúrò yẹn wé àwọn nǹkan rere tá a fi ń rántí àwọn ará wa. A máa ń rántí àwọn nǹkan dáadáa táwa àtàwọn ará jọ ṣe. Àmọ́, ká sọ pé nígbà kan, ọ̀kan lára wọn sọ tàbí ṣe ohun tí ò dáa sí ẹ. Ṣé ó yẹ kó o gbé e sọ́kàn? O ò ṣe gbé e kúrò lọ́kàn, bí ìgbà tó o yọ fọ́tò tí ò dáa yẹn kúrò? (Òwe 19:11; Éfé. 4:32) Ó yẹ ká gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí ò tó nǹkan tẹ́ni tá a jọ ń sin Jèhófà ṣẹ̀ wá torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere làwa àtẹni náà ti jọ ṣe tá a lè fi máa rántí ẹ̀. Irú àwọn nǹkan dáadáa táwọn ará ti ṣe yìí ló yẹ ká máa rántí, ká sì mọyì ẹ̀.
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ LÁSÌKÒ YÌÍ
18. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la kọ́ nípa ìfẹ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
18 Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará? Àwọn nǹkan tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? Ọ̀nà kan tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a máa ń tù wọ́n nínú. Tá a bá lójú àánú, àá ‘máa tu ara wa nínú.’ Báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ara wa? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dárí ji àwọn ará, kódà tó bá nira fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀.
19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará lásìkò yìí?
19 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará lásìkò tá a wà yìí? Kíyè sí ohun tí Pétérù sọ, ó ní: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Torí náà, . . . ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín.” (1 Pét. 4:7, 8) Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe ń sún mọ́lé, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wa? Nígbà tí Jésù ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ó ní: “Gbogbo orílẹ̀-èdè sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.” (Mát. 24:9) Ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ká sì fara da ìkórìíra náà, a gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ìsapá Sátánì máa já sásán, kò sì ní lè dá ìyapa sáàárín wa torí pé ìfẹ́ ló so wá pọ̀, ìyẹn “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kól. 3:14; Fílí. 2:1, 2.
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
a Ó ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì, báwo la sì ṣe lè túbọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn?