Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 27

“Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”

“Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”

“Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà; ní ìgboyà, kí o sì mọ́kàn le.” ​—SM. 27:14.

ORIN 128 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. (a) Kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún wa láìpẹ́? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà”? (Wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀.”)

 JÈHÓFÀ sọ pé lọ́jọ́ iwájú, òun máa ṣe ohun rere fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òun. Láìpẹ́, Jèhófà máa mú àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú kúrò. (Ìfi. 21:3, 4) Ó máa ran “àwọn oníwà pẹ̀lẹ́” tó gbẹ́kẹ̀ lé e lọ́wọ́ láti sọ ayé di Párádísè. (Sm. 37:9-11) Ó tún máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ju ohun tá à ń gbádùn báyìí lọ. Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa ni Jèhófà fẹ́ fún wa! Àmọ́ kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ? Ìdí ni pé Jèhófà kì í sọ̀rọ̀ kó má ṣẹ. Torí náà, ó yẹ ká “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” * (Sm. 27:14) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ la gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó yẹ ká mú sùúrù, kí inú wa sì máa dùn pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ láìpẹ́.​—Àìsá. 55:10, 11.

2. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe?

2 Jèhófà ti jẹ́ ká mọ̀ pé òun máa ń mú ìlérí òun ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Nínú ìwé Ìfihàn, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa kó àwọn èèyàn jọ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n, òun á sì jẹ́ kí wọ́n jọ máa ṣe ìjọsìn mímọ́. Lónìí, àwùjọ àwọn èèyàn yìí la wá mọ̀ sí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” (Ìfi. 7:9, 10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra ló wà nínú àwùjọ yìí, wọ́n jẹ́ ẹni àlàáfíà, wọ́n sì wà níṣọ̀kan kárí ayé. (Sm. 133:1; Jòh. 10:16) Àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí tún máa ń fìtara wàásù. Gbogbo ìgbà ni wọ́n ṣe tán láti sọ̀rọ̀ nípa ayé tuntun fún àwọn tó bá fẹ́ gbọ́. (Mát. 28:19, 20; Ìfi. 14:6, 7; 22:17) Tó o bá wà lára àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí, ó dájú pé o máa mọyì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú.

3. Kí ni Sátánì ń fẹ́ ká ṣe?

3 Èṣù fẹ́ ká máa rò pé a ò nírètí kankan. Ohun tó fẹ́ ká máa rò ni pé Jèhófà ò rí tiwa rò àti pé Jèhófà ò ní mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Tá a bá jẹ́ kí Sátánì mú ká sọ̀rètí nù, a ò ní nígboyà mọ́, kódà a lè má sin Jèhófà mọ́. Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, Èṣù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú kí Jóòbù sọ̀rètí nù, kó má bàa sin Jèhófà mọ́.

4. Àwọn nǹkan wo la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Jóòbù 1:9-12)

4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì lò láti mú kí Jóòbù má sin Jèhófà mọ́. (Ka Jóòbù 1:9-12.) A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára Jóòbù àti ìdí tó fi yẹ ká máa rántí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ.

SÁTÁNÌ FẸ́ KÍ JÓÒBÙ SỌ̀RÈTÍ NÙ

5-6. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù láàárín àkókò díẹ̀?

5 Nǹkan ń lọ dáadáa fún Jóòbù. Ó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó bímọ tó pọ̀, ìdílé ẹ̀ wà níṣọ̀kan, ó sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Jóòbù 1:1-5) Àmọ́ ní ọjọ́ kan ṣoṣo, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun tó ní ló pàdánù. Ohun àkọ́kọ́ tó pàdánù ni ọrọ̀ ẹ̀. (Jóòbù 1:13-17) Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀ kú. Ẹ̀yin náà ẹ wo bó ṣe máa rí lára Jóòbù. Ọkàn àwọn òbí máa ń gbọgbẹ́ tí ọ̀kan péré lára àwọn ọmọ wọn bá kú. Ẹ wá wo ìbànújẹ́ àti ọgbẹ́ ọkàn tó máa bá Jóòbù àti ìyàwó ẹ̀ àti bó ṣe máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé kì í ṣe ọmọ wọn kan péré ló kú, àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Jóòbù fa aṣọ ẹ̀ ya, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì dákú lọ!​—Jóòbù 1:18-20.

6 Lẹ́yìn ìyẹn, Sátánì mú kí àìsàn tó ń dójú tini kọ lu Jóòbù. (Jóòbù 2:6-8; 7:5) Kó tó dìgbà yẹn, àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún Jóòbù gan-an. Kódà, àwọn èèyàn máa ń wá gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jóòbù 31:18) Àmọ́ ní báyìí, àwọn èèyàn ti ń yẹra fún un. Wọ́n ta á nù, àwọn arákùnrin ẹ̀ pa á tì, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ fi í sílẹ̀, kódà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ò sún mọ́ ọn!​—Jóòbù 19:13, 14, 16.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lónìí ló ń dojú kọ irú àwọn àdánwò tó dé bá Jóòbù (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. (a) Kí ni Jóòbù gbà pé ó fa ìṣòro òun, àmọ́ kí ni kò ṣe? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni kan tó máa jọ ohun tó wà nínú àwòrán yìí?

7 Sátánì fẹ́ kí Jóòbù gbà pé ìdí tí ìyà fi ń jẹ ẹ́ ni pé Ọlọ́run ń bínú sí i. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì mú kí ìjì tó lágbára wó ilé tí àwọn ọmọ Jóòbù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti jọ ń jẹun. (Jóòbù 1:18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí iná sọ láti ọ̀run, ó sì jó àwọn ẹran ọ̀sìn Jóòbù títí kan àwọn ìránṣẹ́ tó ń bójú tó wọn. (Jóòbù 1:16) Torí pé kì í ṣe àwọn èèyàn ló fa ìjì àti iná yẹn, Jóòbù gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. Ìyẹn mú kó rò pé òun ti ṣẹ Jèhófà. Síbẹ̀, Jóòbù ò bú Jèhófà Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Ó gbà pé ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan rere fún òun. Torí náà, tí nǹkan tí ò dáa bá ṣẹlẹ̀ sí òun, ó yẹ kóun fara mọ́ ọn. Ó wá sọ pé: “Ká máa yin orúkọ Jèhófà títí lọ.” (Jóòbù 1:20, 21; 2:10) Ní gbogbo àsìkò tí Jóòbù pàdánù àwọn ọmọ ẹ̀ àti ọrọ̀ ẹ̀, tó sì tún ń ṣàìsàn tó le, kò sọ̀rọ̀ òdì sí Jèhófà. Àmọ́, Sátánì ò dẹ̀yìn lẹ́yìn ẹ̀.

8. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì tún lò fún Jóòbù lẹ́yìn ìyẹn?

8 Sátánì tún lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan fún Jóòbù. Ó mú káwọn mẹ́ta tó pe ara wọn ní ọ̀rẹ́ Jóòbù sọ ohun tó máa mú kó gbà pé òun ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Àwọn ọkùnrin yìí sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí Jóòbù dá ló jẹ́ kó máa jìyà. (Jóòbù 22:5-9) Wọ́n tún fẹ́ kó gbà pé bó ti wù kó sapá tó láti máa ṣe rere, kò ní jọ Ọlọ́run lójú. (Jóòbù 4:18; 22:2, 3; 25:4) Lédè míì, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé kò sóhun tí Jóòbù lè ṣe táá jẹ́ kí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tàbí táá jẹ́ kí Ọlọ́run dáàbò bò ó àti pé kò sí àǹfààní kankan nínú kéèyàn máa sin Ọlọ́run. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ fún Jóòbù yìí lè mú kó máa rò pé kò sírètí fún òun mọ́.

9. Kí ló mú kí Jóòbù ṣọkàn akin, kó má sì bẹ̀rù?

9 Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ná. Jóòbù jókòó sínú eérú, ara sì ń ro ó gan-an. (Jóòbù 2:8) Àwọn tó pe ara wọn ní ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń sọ fún un ṣáá pé èèyàn burúkú ni àti pé kò ṣe ohun tó dáa rí. Àwọn ìṣòro tó dé bá Jóòbù ò rọrùn fún un rárá, ṣe ló dà bíi pé wọ́n di ẹrù tó wúwo kan lé e lórí, ikú àwọn ọmọ ẹ̀ náà sì ń kó ìdààmú tó lé kenkà bá a. Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, Jóòbù ò sọ nǹkan kan. (Jóòbù 2:13–3:1) Táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù bá rò pé bó ṣe dákẹ́ yẹn, ó ti gba ohun táwọn sọ, ó sì ti kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá ẹ̀, irọ́ ni wọ́n pa. Nígbà tó dójú ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Jóòbù gbójú sókè wo àwọn tó pe ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ ẹ̀ nígbà tó sọ fún wọn pé: “Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!” (Jóòbù 27:5) Kí ló mú kí Jóòbù ṣọkàn akin, kó má sì bẹ̀rù láìka gbogbo ìṣòro yìí sí? Nígbà tọ́rọ̀ náà tojú sú u, kò ronú pé Ọlọ́run ò ní ran òun lọ́wọ́. Ó gbà pé tóun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí òun dìde.​—Jóòbù 14:13-15.

BÁWO LA ṢE LÈ FARA WÉ JÓÒBÙ?

10. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù?

10 Ìtàn Jóòbù kọ́ wa pé Sátánì ò lè fipá mú ká fi Jèhófà sílẹ̀ àti pé kò sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa tí Jèhófà ò rí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù tún jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí Sátánì ṣe ń ta ko Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, tó sì ń fẹ̀sùn kàn wá pé a ò lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀kọ́ kan tá a rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù.

11. Kí ló máa yọrí sí tá a bá ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nìṣó? (Jémíìsì 4:7)

11 Jóòbù fi hàn pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kò sí àdánwò tá ò ní lè fara dà, àá sì fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Kí nìyẹn máa yọrí sí? Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó dá wa lójú pé Èṣù máa sá kúrò lọ́dọ̀ wa.​—Ka Jémíìsì 4:7.

12. Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe fún Jóòbù lókun?

12 Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé tá a bá kú, Jèhófà máa jí wa dìde. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Sátánì sábà máa ń fi ikú dẹ́rù bà wá, ká lè sọ pé a ò sin Jèhófà mọ́. Nínú ìtàn Jóòbù, Sátánì sọ pé gbogbo nǹkan tó bá gbà ni Jóòbù máa ṣe kódà tó bá gba pé kó fi Jèhófà sílẹ̀ kó má bàa kú. Àmọ́, irọ́ ni Sátánì pa. Nígbà tí gbogbo nǹkan dojú rú fún Jóòbù, tó sì jọ pé kò ní pẹ́ kú, Jóòbù ò fi Jèhófà sílẹ̀. Ohun tó jẹ́ kó fara dà á ni pé ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa ṣojú rere sí òun àti pé Jèhófà máa fún òun lókun láti kojú àdánwò náà. Jóòbù mọ̀ pé tí Jèhófà ò bá mú ìṣòro náà kúrò lójú ẹ̀mí òun, ó máa jí òun dìde lọ́jọ́ iwájú. Ó dá Jóòbù lójú háún-háún pé Jèhófà máa jí òun dìde. Tó bá dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa jí wa dìde tá a bá tiẹ̀ kú, ẹ̀rù ikú ò ní bà wá débi tá a máa fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà ìṣòro.

13. Kí la kọ́ nínú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì lò láti dán Jóòbù wò?

13 Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì lò fún Jóòbù torí irú àwọn ọgbọ́n yẹn náà ló ń lò fún wa lónìí. Ẹ wo ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan gbogbo wa, ó ní: “Gbogbo ohun tí èèyàn [kì í ṣe Jóòbù nìkan] bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.” (Jóòbù 2:4, 5) Lédè míì, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé a ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé tá a bá kojú ìṣòro tó lè gbẹ̀mí wa, a ò ní sin Jèhófà mọ́. Sátánì tún sọ pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé gbogbo nǹkan tá a bá ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀ ò já mọ́ nǹkan kan lójú ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti mọ àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Sátánì ń lò, a ò ní jẹ́ kó fi mú wa.

14. Báwo ni àdánwò ṣe lè jẹ́ ká rí ibi tá a kù sí? Ṣàpèjúwe.

14 Tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò kan, ó yẹ ká lo àkókò yẹn láti túbọ̀ mọ irú ẹni tá a jẹ́. Àwọn àdánwò tí Jóòbù dojú kọ jẹ́ kó rí àwọn ibi tó kù sí, ó sì ṣàtúnṣe tó yẹ. Ọ̀kan lára àwọn ohun tó kọ́ ni pé ó yẹ kóun túbọ̀ nírẹ̀lẹ̀. (Jóòbù 42:3) Àwa náà lè rí àwọn ibi tá a kù sí tá a bá ń dojú kọ àdánwò. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi arákùnrin kan tó ń jẹ́ Nikolay * sẹ́wọ̀n bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣàìsàn tó le gan-an. Arákùnrin náà sọ pé: “Ọgbà ẹ̀wọ̀n dà bíi maṣíìnì kan tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò ara. Tí wọ́n bá ju èèyàn sẹ́wọ̀n, ó máa jẹ́ kó túbọ̀ rí àwọn ìwà Kristẹni tó yẹ kóun ní.” Tá a bá ti rí ibi tá a kù sí, á rọrùn láti ṣàtúnṣe.

15. Ta ló yẹ ká máa tẹ́tí sí, kí sì nìdí?

15 Jèhófà ló yẹ ká máa tẹ́tí sí, kì í ṣe àwọn ọ̀tá wa. Jóòbù tẹ́tí sí ohun tí Jèhófà sọ fún un. Jèhófà bá Jóòbù fèròwérò, ṣe ló dà bí ìgbà tí Ọlọ́run ń sọ fún un pé: ‘Ṣé o rí bí agbára tí mo fi dá àwọn nǹkan ṣe pọ̀ tó? Mo mọ gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Ṣé o rò pé mi ò ní lè yọ ẹ́ nínú ìṣòro yẹn ni?’ Jóòbù fi ìrẹ̀lẹ̀ dá Jèhófà lóhùn, ó sì fi hàn pé òun mọyì àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún òun. Ó sọ pé: “Etí mi ti gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ ní báyìí, mo ti fi ojú mi rí ọ.” (Jóòbù 42:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ inú eérú ni Jóòbù jókòó sí nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn, eéwo bò ó látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀ sì ti kú. Síbẹ̀, Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé inú òun dùn sí i.​—Jóòbù 42:7, 8

16. Kí làwọn nǹkan tó yẹ ká fi sọ́kàn nínú Àìsáyà 49:15, 16 tá a bá ń dojú kọ àdánwò?

16 Lónìí, àwọn èèyàn lè bú wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ hùwà sí wa bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Wọ́n lè fẹ́ bà wá lórúkọ jẹ́ tàbí kí wọ́n gbìyànjú láti ba orúkọ ètò Ọlọ́run jẹ́, kí wọ́n sì “parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́” wa. (Mát. 5:11) Ìtàn Jóòbù kọ́ wa pé Jèhófà fọkàn tán wa pé a máa jẹ́ olóòótọ́ sí òun lójú àdánwò. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì ní fi àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e sílẹ̀ láé. (Ka Àìsáyà 49:15, 16.) Má ṣe tẹ́tí sí irọ́ táwọn ọ̀tá Ọlọ́run ń pa! Arákùnrin kan tó ń jẹ́ James tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Tọ́kì, tí ìdílé ẹ̀ dojú kọ àdánwò tó le gan-an sọ pé: “A rí i pé tá a bá ń tẹ́tí sí irọ́ táwọn èèyàn ń pa mọ́ àwa èèyàn Ọlọ́run, a máa rẹ̀wẹ̀sì. Torí náà, àwọn nǹkan tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun la gbájú mọ́, a sì ń fìtara sin Jèhófà nìṣó. Ìpinnu tá a ṣe yìí ló jẹ́ ká máa láyọ̀.” Bíi ti Jóòbù, ó yẹ káwa náà máa tẹ́tí sí Jèhófà! Kò sí irọ́ táwọn ọ̀tá wa lè pa tó lè mú ká sọ̀rètí nù.

ÌRÈTÍ TÓ O NÍ MÁA JẸ́ KÓ O FARA DÀ Á

Jèhófà bù kún Jóòbù torí pé ó jẹ́ olóòótọ́. Òun àti ìyàwó ẹ̀ sì gbádùn àwọn ohun rere tí Jèhófà fún wọn fún àkókò tó gùn (Wo ìpínrọ̀ 17) *

17. Kí lo kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àtobìnrin olóòótọ́ tó wà nínú Hébérù orí 11?

17 Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ tó sì nígboyà ni Jóòbù. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó pe ọ̀pọ̀ àwọn míì ní “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tó pọ̀ gan-an.” (Héb. 12:1) Gbogbo wọn ló dojú kọ àdánwò tó le gan-an, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ olóòótọ́ títí dópin. (Héb. 11:36-40) Ṣé bí wọ́n ṣe fara dà á àti ohun tí wọ́n ṣe fún Jèhófà já sásán? Rárá o! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìlérí Ọlọ́run ló ṣẹ lójú wọn, wọn ò sọ̀rètí nù nínú Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, torí wọ́n mọ̀ pé inú Jèhófà dùn sí wọn, ó dá wọn lójú pé àwọn máa rí àwọn ìlérí Jèhófà nígbà tó bá ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 11:4, 5) Àpẹẹrẹ wọn lè mú káwa náà túbọ̀ pinnu pé a ò ní sọ̀rètí nù láé.

18. Kí lo pinnu pé wàá ṣe? (Hébérù 11:6)

18 Nǹkan túbọ̀ ń burú sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nínú ayé tá à ń gbé yìí. (2 Tím. 3:13) Sátánì ò sì tíì ṣíwọ́ láti máa dán àwa ìránṣẹ́ Jèhófà wò. Ìṣòro yòówù kó dé bá wa lọ́jọ́ iwájú, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa lo gbogbo okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, torí a mọ̀ pé “a ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè.” (1 Tím. 4:10) Ẹ rántí ibi tí ọ̀rọ̀ Jóòbù já sí, ó jẹ́ ká rí i pé “Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jém. 5:11) Ẹ jẹ́ káwa náà jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kó sì dá wa lójú pé ó máa san èrè “fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.”​—Ka Hébérù 11:6.

ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

^ Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó dojú kọ àdánwò tó le gan-an, ẹni tó sábà máa ń wá sí wa lọ́kàn ni Jóòbù. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin olóòótọ́ yẹn? A kẹ́kọ̀ọ́ pé Sátánì ò lè fipá mú wa pé ká má sin Jèhófà mọ́. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí Jèhófà ṣe gba Jóòbù lọ́wọ́ àwọn àdánwò tó dojú kọ, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa gbà wá sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Táwọn nǹkan yìí bá dá wa lójú, á jẹ́ pé àwa náà wà lára àwọn tó “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà” nìyẹn.

^ ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “gbẹ́kẹ̀ lé” sábà máa ń túmọ̀ sí kéèyàn “dúró de” nǹkan, kó sì nírètí pé ọwọ́ òun máa tẹ nǹkan ọ̀hún. Ó tún lè túmọ̀ sí kéèyàn fọkàn tán ẹnì kan tàbí kó gbára lé onítọ̀hún.​—Sm. 25:2, 3; 62:5.

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ÀWÒRÁN: Jóòbù àti ìyàwó ẹ̀ rí ibi tí ilé ti wó pa àwọn ọmọ wọn.

^ ÀWÒRÁN: Jóòbù fara da àwọn àdánwò tó dé bá a. Òun àti ìyàwó ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe bù kún ìdílé wọn.