Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo ni àwọn bíríkì tí wọ́n rí ní Bábílónì àtijọ́ tó ti di àwókù àti bí wọ́n ṣe ṣe bíríkì náà ṣe jẹ́rìí sí i pé àkọsílẹ̀ Bíbélì jóòótọ́?
ÀWỌN awalẹ̀pìtàn ti wú àìmọye bíríkì tí wọ́n sun jáde nílùú Bábílónì àtijọ́, àwọn bíríkì yẹn ni wọ́n sì fi kọ́ ìlú náà. Awalẹ̀pìtàn kan tó ń jẹ́ Robert Koldewey sọ pé wọ́n ṣe àwọn bíríkì yẹn nínú iná ìléru tó wà ní “ẹ̀yìn ìlú náà níbi tí amọ̀ tó dáa wà, tí igi tí wọ́n fi ń dáná sì pọ̀ níbẹ̀.”
Nǹkan míì táwọn awalẹ̀pìtàn yẹn rí ni pé àwọn ìjòyè ìlú Bábílónì tún máa ń lo iná ìléru láti ṣe nǹkan tó burú jáì. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní University of Toronto tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Paul-Alain Beaulieu mọ̀ nípa ìtàn àwọn ará Ásíríà dáadáa, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé ìtàn Bábílónì fi hàn pé ọba máa ń pàṣẹ pé kí wọ́n ju ẹni tí ò bá gbọ́ràn sí i lẹ́nu tàbí tí ò bọ̀wọ̀ fún un sínú iná ìléru, kó sì jóná kú.” Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Ọba Nebukadinésárì, wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan ránṣẹ́ tó sọ pé: “Ẹ pa wọ́n, ẹ sun wọ́n, ẹ yan wọ́n, . . . ẹ jù wọ́n sínú ààrò . . . ẹ jẹ́ kí wọ́n rú èéfín lọ sókè nínú iná kí wọ́n lè jóná kú.”
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ káwọn tó ń ka Bíbélì rántí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wà lákọọ́lẹ̀ ní Dáníẹ́lì orí 3. Ìtàn yẹn sọ pé Ọba Nebukadinésárì fi wúrà ṣe ère gíga kan sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà tó wà lẹ́yìn odi ìlú Bábílónì. Nígbà táwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta tí wọ́n ń jẹ́ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò forí balẹ̀ fún ère náà, Nebukadinésárì bínú gan-an, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú iná ìléru náà “gbóná ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ,” lẹ́yìn náà ó ní kí wọ́n “jù wọ́n sínú iná ìléru tó ń jó.” Áńgẹ́lì alágbára kan ni ò jẹ́ kí wọ́n kú.—Dán. 3:1-6, 19-28.
Àwọn bíríkì tí wọ́n rí nílùú Bábílónì tún jẹ́rìí sí i pé àkọsílẹ̀ Bíbélì jóòótọ́. Ọ̀pọ̀ lára àwọn bíríkì náà ní àkọlé tí wọ́n fi yin ọba. Ọ̀kan lára wọn kà pé: “Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì . . . Ààfin, ìyẹn ibùgbé Ọlá Ńlá mi tí mo kọ́ . . . Kí àwọn àtọmọdọ́mọ mi máa ṣàkóso nínú rẹ̀ títí láé.” Àkọlé yìí jọ gbólóhùn tó wà ní Dáníẹ́lì 4:30 gan-an. Ọba Nebukadinésárì fọ́nnu níbẹ̀ pé: “Ṣebí Bábílónì Ńlá nìyí, tí mo fi agbára mi àti okun mi kọ́ fún ilé ọba àti fún ògo ọlá ńlá mi?”