Ṣé Jèhófà Lo Tẹjú Mọ́?
“Ìwọ ni mo gbé ojú mi sókè sí, ìwọ tí ń gbé ní ọ̀run.”—SM. 123:1.
1, 2. Báwo la ṣe lè máa wo ojú Jèhófà?
“ÀWỌN àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. (2 Tím. 3:1) Nǹkan á sì máa burú sí i títí dìgbà tí Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run táá sì mú kí àlàáfíà wà kárí ayé. Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Ojú ta ni mò ń wò fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa dáhùn pé, “Jèhófà ni,” bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn.
2 Báwo la ṣe lè máa wo ojú Jèhófà? Kí ló sì yẹ ká ṣe ká má bàa yíjú kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà nígbà tí ìṣòro bá dé? Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, onísáàmù kan sọ ìdí tó fi yẹ ká máa wojú Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé. (Ka Sáàmù 123:1-4.) Ó sọ pé bí ìránṣẹ́ kan ṣe máa ń wojú ọ̀gá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa wojú Jèhófà. Kí ni onísáàmù yìí ní lọ́kàn? Ìránṣẹ́ kan máa ń wojú ọ̀gá rẹ̀ kí ọ̀gá náà lè fún un ní oúnjẹ, kó sì dáàbò bò ó, àmọ́ ìránṣẹ́ kan tún gbọ́dọ̀ máa wojú ọ̀gá rẹ̀ kó lè fòye mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń fẹ́, kó sì ṣe é. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò lójoojúmọ́, ká lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣe, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ìgbà yẹn lọ́kàn wa tó lè balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé.—Éfé. 5:17.
3. Kí ló lè pín ọkàn wa níyà débi tá ò fi ní wojú Jèhófà mọ́?
3 Lóòótọ́, a mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká máa wojú Jèhófà nígbà gbogbo, àmọ́ nígbà míì, àwọn nǹkan kan lè pín ọkàn wa níyà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màtá tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù gan-an nìyẹn. Bíbélì sọ pé Màtá “ní ìpínyà-ọkàn nítorí bíbójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe.” (Lúùkù 10:40-42) Tí obìnrin olóòótọ́ yìí bá lè ní ìpínyà ọkàn láìka pé Jésù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Torí náà, kí ló lè pín ọkàn wa níyà débi tá ò fi ní wojú Jèhófà mọ́? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí ìwà àti ìṣe àwọn míì ṣe lè pín ọkàn wa níyà. A sì máa rí ohun tá a lè ṣe ká lè máa wojú Jèhófà nígbà gbogbo.
ỌKÙNRIN OLÓÒÓTỌ́ KAN PÀDÁNÙ ÀǸFÀÀNÍ ŃLÁ KAN
4. Kí nìdí tó fi yani lẹ́nu pé Mósè ò wọ Ilẹ̀ Ìlérí?
4 Gbogbo ìgbà ni Mósè máa ń wojú Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà. Kódà, Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Ka Hébérù 11:24-27.) Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “kò tíì sí wòlíì kan rí, tí ó tíì dìde ní Ísírẹ́lì bí Mósè, ẹni tí Jèhófà mọ̀ lójúkojú.” (Diu. 34:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè sún mọ́ Jèhófà gan-an, síbẹ̀ ó pàdánù àǹfààní tó ní láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Núm. 20:12) Kí ló fà á?
5-7. Ìṣòro wo ló jẹyọ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, báwo sì ni Mósè ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà?
5 Kò pé oṣù méjì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì ni ìṣòro ńlá kan jẹyọ, kódà wọn ò tíì dé Òkè Sínáì tí wàhálà náà fi ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé kò sómi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè. Ọ̀rọ̀ yẹn le débi pé Mósè ké jáde sí Jèhófà pé: “Kí ni èmi yóò ti ṣe ti àwọn ènìyàn yìí sí? Ní ìgbà díẹ̀ sí i, wọn yóò sọ mí lókùúta!” (Ẹ́kís. 17:4) Jèhófà dá Mósè lóhùn, ó sì fún un ní ìtọ́ni tó ṣe kedere. Jèhófà sọ pé kó mú ọ̀pá rẹ̀, kó lu àpáta tó wà ní Hórébù, omi á sì jáde nínú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ ní ojú àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mu omi débi tó tẹ́ wọn lọ́rùn, ìṣòro náà sì yanjú.—Ẹ́kís. 17:5, 6.
6 Ìwé Mímọ́ tún sọ pé Mósè “pe orúkọ ibẹ̀ ní Másà àti Mẹ́ríbà, nítorí aáwọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti nítorí dídán tí wọ́n dán Jèhófà wò, pé: ‘Jèhófà ha wà ní àárín wa tàbí kò sí?’ ” (Ẹ́kís. 17:7) Àwọn orúkọ yẹn sì bá a mu gan-an torí wọ́n túmọ̀ sí “Ìdánwò” àti “Aáwọ̀.”
7 Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ ní Mẹ́ríbà ṣe rí lára Jèhófà? Lójú Jèhófà, kì í ṣe Mósè làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùn sí, òun gan-an ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí. (Ka Sáàmù 95:8, 9.) Ó hàn gbangba pé ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kò dáa rárá. Mósè sì ṣe ohun tó tọ́ ní ti pé, ojú Jèhófà ló wò fún ìtọ́sọ́nà, ó sì tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jèhófà fún un.
8. Ìṣòro wo ló jẹyọ nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí lẹ́yìn nǹkan bí ogójì ọdún?
8 Kí ni Mósè ṣe nígbà tí irú ìṣòro yìí tún jẹyọ lẹ́yìn nǹkan bí ogójì [40] ọdún? Àgbègbè kan nítòsí Kádéṣì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà, ibẹ̀ sì sún mọ́ Ilẹ̀ Ìlérí. Nígbà tó yá, wọ́n pe àgbègbè yìí * Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ráhùn níbẹ̀ pé àwọn ò rómi mu. (Núm. 20:1-5) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Mósè ṣàṣìṣe, ohun tó sì gbẹ̀yìn ẹ̀ ò dáa rárá.
náà ní Mẹ́ríbà.9. Ìtọ́ni wo ni Jèhófà fún Mósè, àmọ́ kí ni Mósè ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
9 Kí ni Mósè ṣe nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn? Ó yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí Jèhófà ò sọ fún un pé kó lu àpáta náà. Ohun tó sọ fún Mósè ni pé kó mú ọ̀pá rẹ̀, kó pe àwọn èèyàn náà jọ níwájú àpáta náà, kó sì bá àpáta náà sọ̀rọ̀. (Núm. 20:6-8) Àmọ́ Mósè ò bá àpáta náà sọ̀rọ̀. Inú tó ń bí i sí àwọn èèyàn náà mú kó pariwo mọ́ wọn pé: “Ẹ gbọ́, nísinsìnyí, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀! Ṣé láti inú àpáta gàǹgà yìí ni kí a ti mú omi jáde fún yín?” Lẹ́yìn ìyẹn, ó lu àpáta náà, kódà kò fi mọ sórí ẹ̀ẹ̀kan, ẹ̀ẹ̀mejì ló lu àpáta yẹn.—Núm. 20:10, 11.
10. Báwo lohun tí Mósè ṣe ṣe rí lára Jèhófà?
10 Inú bí Jèhófà gan-an sí ohun tí Mósè ṣe. (Diu. 1:37; 3:26) Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú? Onírúurú nǹkan ló lè fà á. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ó ṣeé ṣe kí inú bí Jèhófà torí pé Mósè ò tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fún un.
11. Bí Mósè ṣe lu àpáta yẹn, kí ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn yẹn máa rò nípa iṣẹ́ ìyanu náà?
11 Ohun míì tún wà tó ṣeé ṣe kó fà á. Akọ òkúta làwọn àpáta tó wà ní Mẹ́ríbà àkọ́kọ́. Kò sí béèyàn ṣe lè lù ú tó tí omi máa jáde nínú rẹ̀. Àmọ́ òkúta ẹfun tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára làwọn àpáta tó wà ní Mẹ́ríbà kejì. Torí pé òkúta ẹfun kì í fi bẹ́ẹ̀ lágbára, omi sábà máa ń wà nínú rẹ̀, àwọn èèyàn sì lè fa omi náà jáde. Bí Mósè ṣe lu àpáta tí kò lágbára yẹn lẹ́ẹ̀mejì, ṣé kò ní dà bíi pé àpáta yẹn ló mú omi inú rẹ̀ jáde fúnra rẹ̀, pé kì í ṣe Jèhófà ló ṣe iṣẹ́ ìyanu náà? Bí Mósè ṣe lu àpáta yẹn dípò kó bá a sọ̀rọ̀, ṣé àwọn èèyàn náà máa gbà pé Jèhófà ló ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí? * A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ.
BÍ MÓSÈ ṢE ṢỌ̀TẸ̀
12. Kí ni nǹkan míì tó ṣeé ṣe kó fà á tí Jèhófà fi bínú sí Mósè àti Áárónì?
12 Ohun míì tún wà tó ṣeé ṣe kó fà á tí Jèhófà fi bínú sí Mósè àti Áárónì. Ẹ kíyè sóhun tí Mósè sọ fáwọn èèyàn náà, ó ní: “Ṣé láti inú àpáta gàǹgà yìí ni kí a ti mú omi jáde fún yín?” Nígbà tí Mósè lo ọ̀rọ̀ náà “kí a,” ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí òun àti Áárónì. Ohun tó sọ yẹn ju ẹnu ẹ̀ lọ torí pé kò fún Jèhófà tó ṣe iṣẹ́ ìyanu náà ní ọ̀wọ̀ tó yẹ ẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn torí pé Sáàmù 106:32, 33 sọ pé: “Síwájú sí i, wọ́n fa ìtánni-ní-sùúrù níbi omi Mẹ́ríbà, tí ó fi jẹ́ pé nǹkan burú fún Mósè nítorí wọn. Nítorí pé wọ́n mú ẹ̀mí rẹ̀ korò, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà ìwàǹwára.” * (Núm. 27:14) Èyí ó wù kó jẹ́, Mósè ò fi ògo fún Jèhófà. Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ̀yin méjèèjì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni mi.’ (Núm. 20:24) Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá nìyẹn lóòótọ́!
13. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún Mósè tọ̀nà, ó sì bá ìdájọ́ òdodo mu?
13 Jèhófà ò retí pé Mósè àti Áárónì ló máa hu irú ìwà yẹn, ìdí ni pé aṣáájú ni wọ́n jẹ́ fún àwọn èèyàn náà. (Lúùkù 12:48) Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, Jèhófà ò sì jẹ́ kí odindi ìran náà wọ Ilẹ̀ Ìlérí fún ìwà ọ̀tẹ̀ wọn. (Núm. 14:26-30, 34) Torí náà, ó tọ̀nà, ó sì bá ìdájọ́ òdodo mu pé irú ìdájọ́ kan náà ni Jèhófà ṣe fún Mósè torí ìwà ọ̀tẹ̀ tó hù. Bíi tàwọn ọlọ̀tẹ̀ yòókù, Jèhófà ò jẹ́ kí Mósè wọ Ilẹ̀ Ìlérí.
OHUN TÓ FA ÌṢÒRO NÁÀ
14, 15. Kí ló mú kí Mósè ṣọ̀tẹ̀?
14 Kí ló mú kí Mósè ṣọ̀tẹ̀? Ẹ kíyè sí ohun tí Sáàmù 106:32, 33 sọ lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní: “Síwájú sí i, wọ́n fa ìtánni-ní-sùúrù níbi omi Mẹ́ríbà, tí ó fi jẹ́ pé nǹkan burú fún Mósè nítorí wọn. Nítorí pé wọ́n mú ẹ̀mí rẹ̀ korò, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà ìwàǹwára.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ̀, Mósè lẹni tó ń bínú. Dípò kó kó ara rẹ̀ níjàánu, ṣe ló sọ̀rọ̀ láìronú nípa ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ.
15 Mósè jẹ́ kí ohun táwọn míì ṣe pín ọkàn rẹ̀ níyà, kò sì wojú Jèhófà mọ́. Òótọ́ ni pé Mósè ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ yẹn kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. (Ẹ́kís. 7:6) Àmọ́ bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àìmọye ìgbà ni Mósè fara da ìwà ọ̀tẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù, ó ṣeé ṣe kéyìí ti mú kí nǹkan sú u, kára sì máa kan án. Ó tún lè jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ ló gbà á lọ́kàn dípò kó máa ronú nípa bó ṣe máa fògo fún Jèhófà.
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú lórí ohun tí Mósè ṣe?
16 Tí irú wòlíì olóòótọ́ bíi Mósè bá lè ní ìpínyà ọkàn, kó sì kọsẹ̀, kò sí àní-àní pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Bíi ti Mósè, àwa náà ò ní pẹ́ wọ ilẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ kan, ìyẹn ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí. (2 Pét. 3:13) Ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kí irú àǹfààní yìí bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. Àmọ́, tá ò bá fẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà bá a ṣe ń wojú Jèhófà, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo. (1 Jòh. 2:17) Kí la lè kọ́ látinú àṣìṣe Mósè?
MÁ ṢE JẸ́ KÍ OHUN TÁWỌN MÍÌ ṢE MÚ Ẹ KỌSẸ̀
17. Kí lá jẹ́ ká kó ara wa níjàánu tínú bá ń bí wa?
17 Máa kó ara rẹ níjàánu tínú bá ń bí ẹ. Kódà tó bá jẹ́ pé ìṣòro kan náà là ń kojú léraléra, “ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” (Gál. 6:9; 2 Tẹs. 3:13) Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó bí wa nínú tàbí tí ìwà rẹ̀ máa ń múnú bí wa, ṣé a máa ń ronú ká tó sọ̀rọ̀? Ṣé a sì máa ń kora wa níjàánu? (Òwe 10:19; 17:27; Mát. 5:22) Tẹ́nì kan bá múnú bí wa, Bíbélì sọ pé ká “yàgò fún ìrunú.” Àmọ́ ìrunú ta ni ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ? Ti Jèhófà ni. (Ka Róòmù 12:17-21.) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Dípò ká bínú tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, ṣe ló yẹ ká ṣe sùúrù, ká jẹ́ kí Jèhófà bójú tó ọ̀rọ̀ náà nígbà tó bá tó àsìkò lójú rẹ̀. Àmọ́ tá a bá ń wá bá a ṣe máa gbẹ̀san, a jẹ́ pé a ò wojú Jèhófà mọ́, a ò sì bọ̀wọ̀ fún un nìyẹn.
18. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tí Jèhófà bá fún wa ní ìtọ́ni?
Héb. 13:17) Lẹ́sẹ̀ kan náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká “má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.” (1 Kọ́r. 4:6) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà, à ń wojú Jèhófà nìyẹn.
18 Máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó dé kẹ́yìn. Ṣé a máa ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà tó dé kẹ́yìn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní máa ronú pé bá a ṣe ń ṣe nǹkan tẹ́lẹ̀ sàn ju ìtọ́ni tuntun tá a gbà lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làá máa tẹ̀ lé ìtọ́ni èyíkéyìí tí Jèhófà bá fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀. (19. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí àṣìṣe àwọn míì ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?
19 Má ṣe jẹ́ kí àṣìṣe àwọn míì ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Tá a bá ń wojú Jèhófà, a ò ní máa bínú nítorí àṣìṣe àwọn míì, a ò sì ní jẹ́ kíyẹn ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Èyí ṣe pàtàkì pàápàá tó bá jẹ́ pé àwa náà ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run bíi ti Mósè. Òótọ́ ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ‘máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀ yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.’ (Fílí. 2:12) Síbẹ̀ ká fi sọ́kàn pé bí àǹfààní tá a ní bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa ṣe máa pọ̀ tó. (Lúùkù 12:48) Àmọ́ tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, kò sóhun tó máa fa ìkọ̀sẹ̀ fún wa, kò sì sóhun táá mú ká fi Jèhófà sílẹ̀.—Sm. 119:165; Róòmù 8:37-39.
20. Kí la pinnu láti ṣe?
20 Nǹkan ò rọrùn rárá lásìkò tá à ń gbé yìí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wojú Ẹni “tí ń gbé ní ọ̀run” nígbà gbogbo, ká lè fòye mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà àti ìṣe àwọn míì ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Dípò ká fìbínú hùwà táwọn míì bá ṣàṣìṣe, ṣe ló yẹ ká pinnu láti jẹ́ kí ‘ojú wa máa wo Jèhófà Ọlọ́run wa, títí yóò fi fi ojú rere hàn sí wa.’—Sm. 123:1, 2.
^ ìpínrọ̀ 8 Mẹ́ríbà yìí yàtọ̀ sí Mẹ́ríbà tó wà nítòsí Réfídímù. Àkọ́kọ́ wà nítòsí Másà, ìkejì yìí sì wà nítòsí Kádéṣì. Wọ́n sọ àgbègbè méjèèjì yìí ní Mẹ́ríbà nítorí aáwọ̀ tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.—Wo àwòrán ilẹ̀ tó wà ní Apá 7 nínú ìwé Àfikún Ìsọfúnni Láti Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
^ ìpínrọ̀ 11 Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n John A. Beck ń sọ nípa ìtàn yìí, ó ní: “Ìtàn àtẹnudẹ́nu àwọn Júù kan sọ pé, àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn ráhùn sí Mósè pé: ‘Mósè mọ̀ pé àpáta yìí ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára! Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìyanu, kó mú omi jáde látinú àpáta míì.’ ” Àmọ́ ìtàn àtẹnudẹ́nu lásán lèyí.
^ ìpínrọ̀ 12 Wo Ilé-ìṣọ́nà, October 15, 1987, “Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe.”