Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Madagásíkà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Madagásíkà

AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ ni Sylviana, ó sì ti lé díẹ̀ lẹ́ni ogún ọdún, ó sọ pé: “Tí mo bá ń gbọ́ ìrírí àwọn ọ̀rẹ́ mi tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn aṣáájú-ọ̀nà púpọ̀ sí i, ó máa ń wu èmi náà pé kí n lọ.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò ní lè ṣe é.”

Ṣó ti ṣe ìwọ náà rí bíi ti Sylviana? Ṣó máa ń wu ìwọ náà láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, àmọ́ tó ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní lè ṣe é láéláé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fọkàn balẹ̀! Lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ti borí àwọn ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká lọ sórílẹ̀-èdè Madagásíkà tó jẹ́ ìkẹrin lára àwọn erékùṣù tó tóbi jù láyé, ká lè mọ bí Jèhófà ṣe ran àwọn ará yẹn lọ́wọ́.

Láti bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn akéde ògbóṣáṣá àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà tó lé ní àádọ́rin [70] láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlá * ti wá sìn lórílẹ̀-èdè Madagásíkà, nílẹ̀ Áfíríkà, àwọn èèyàn ibẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ Bíbélì gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà ló ti ṣí kúrò lágbègbè wọn, kí wọ́n lè lọ wàásù ìhìn rere jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí. Ẹ jẹ́ ká gbọ́rọ̀ láti ẹnu díẹ̀ lára wọn.

WỌ́N BORÍ ÌBẸ̀RÙ ÀTI ÌRẸ̀WẸ̀SÌ

Perrine àti Louis

Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Louis àti Perrine tí wọ́n ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n [30] ọdún ṣí lọ sí Madagásíkà láti ilẹ̀ Faransé. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti ń ronú àtiṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, àmọ́ àyà Perrine ń já. Ó sọ pé: “Àyà mi ń já láti lọ síbi tí mi ò dé rí. Mi ò mọ bó ṣe máa rí tá a bá fi àwọn ẹbí wa sílẹ̀, àwọn ará ìjọ wa, ilé wa àtàwọn nǹkan míì tó ti mọ́ wa lára. Kí n sòótọ́, àwọn nǹkan yìí gangan ni ìṣòro tí mo ní.” Àmọ́ lọ́dún 2012, Perrine ṣọkàn akin, àwọn méjèèjì sì gbéra. Báwo ló ṣe wá rí lára rẹ̀ nísinsìnyí? Ó ní: “Tí mo bá ń rántí àwọn ìrírí tá a ti ní, ó máa ń fún ìgbàgbọ́ mi lókun torí pé à ń rọ́wọ́ Jèhófà lára wa.” Louis wá sọ pé: “Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó nígbà tí mẹ́wàá lára àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ wá sí Ìrántí Ikú Kristi tá a kọ́kọ́ bá wọn ṣe ní Madagásíkà!”

Kí ló ran tọkọtaya yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ nígbà ìṣòro? Wọ́n bẹ Jèhófà pé kó fún àwọn ní okun káwọn lè fara da ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú. (Fílí. 4:13) Louis sọ pé: “A rí i pé Jèhófà dáhùn àdúrà wa, ó sì mú ká ní ‘àlàáfíà Ọlọ́run.’ Ìyẹn ló jẹ́ ká lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, tá ò sì gbé àwọn ìṣòro yẹn sọ́kàn. Àwọn ọ̀rẹ́ wa nílé náà ò fi wá sílẹ̀, wọ́n ń kọ lẹ́tà sí wa lórí kọ̀ǹpútà, wọ́n sì ń fún wa níṣìírí pé ká máa tẹ̀ síwájú.”​—Fílí. 4:​6, 7; 2 Kọ́r. 4:7.

Jèhófà bù kún Louis àti Perrine torí pé wọn ò jẹ́ kó sú àwọn. Louis sọ pé: “Ní October 2014, a lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya * nílẹ̀ Faransé. A gbà pé Jèhófà ló fún wa lẹ́bùn yìí, a ò sì ní gbàgbé rẹ̀ láé.” Nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege, inú wọn dùn gan-an nígbà tí ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n máa bá iṣẹ́ wọn lọ lórílẹ̀-èdè Madagásíkà.

“ÀÁ MỌYÌ YÍN GAN-AN!”

Nadine àti Didier

Nígbà tí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Didier àti Nadine ṣí kúrò nílẹ̀ Faransé lọ sí Madagásíkà lọ́dún 2010, wọ́n ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún nígbà yẹn. Didier sọ pé: “Aṣáájú-ọ̀nà ni wá ká tó bí àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n tójú bọ́, a bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àtilọ sìn lórílẹ̀-èdè míì.” Nadine sọ pé: “Ẹ̀rù àtilọ ń bà mí torí mi ò fẹ́ fi àwọn ọmọ wa sílẹ̀. Àmọ́ àwọn ọmọ wa sọ fún wa pé: ‘Àá mọyì yín gan-an tẹ́ ẹ bá lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀!’ Ohun tí wọ́n sọ yìí wú wa lórí gan-an, a sì pinnu láti lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tá à ń gbé jìnnà síbi táwọn ọmọ wa wà, inú wa dùn pé à ń rí wọn bá sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo.”

Kò rọrùn rárá fún Didier àti Nadine láti kọ́ èdè Malagasy. Nadine sọ pé: “A kì í ṣe ọmọdé mọ́, torí náà kò rọrùn fún wa láti kọ́ èdè tuntun.” Kí ni wọ́n wá ṣe? Wọ́n kọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Faransé. Nígbà tó yá, wọ́n pinnu pé àwọn á kọ́ èdè náà, bí wọ́n ṣe lọ síjọ tó ń sọ èdè Malagasy nìyẹn. Nadine sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń pàdé lóde ẹ̀rí ló fẹ́ ká máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà wọ́n tiẹ̀ máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa pé a wá sọ́dọ̀ àwọn, ṣe ló dà bí àlá lójú mi nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀. Ká sòótọ́, mò ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbí. Tí mo bá jí láàárọ̀, mo máa ń sọ fúnra mi pé, ‘Ó yá gbéra ńlẹ̀, bíṣẹ́ ò bá pẹ́ni, a kì í pẹ́ṣẹ́!’ ”

Didier rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe ń sọ àwọn ìrírí tó ní nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Malagasy. Ó ní: “Torí pé mi ò gbédè tí wọ́n ń sọ, tí mo bá ń darí ìpàdé, ṣe ni mo kàn máa ń sọ pé ẹ ṣé gan-an tí wọ́n bá ti dáhùn tán. Lọ́jọ́ kan, lẹ́yìn tí arábìnrin kan dáhùn tán, mo ní ‘Ẹ ṣeun.’ Làwọn tó jókòó sẹ́yìn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́jú sí mi pé ìdáhùn náà kò tọ̀nà, ni mo bá pe arákùnrin míì tó wá sọ ìdáhùn tó bọ́ sójú ẹ̀, bí mi ò tiẹ̀ lóye ohun tó sọ.”

Ó GBÀ LÁTI WÁ

Ní àpéjọ àgbègbè tá a ṣe lọ́dún 2005, Thierry àti ìyàwó rẹ̀ Nadia wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Ẹ Máa Lépa Ohun Tó Máa Gbórúkọ Ọlọ́run Ga.” Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn dá lórí Tímótì, ó wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àtilọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Thierry sọ pé: “Bí àwòkẹ́kọ̀ọ́ yẹn ṣe ń parí lọ, táwọn èèyàn sì ń pàtẹ́wọ́, mo fẹnu ko ìyàwó mi létí pé, ‘Ibo ni ká lọ?’ Ìyàwó mi sọ pé ohun tóun náà ń rò nìyẹn.” Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ láti lọ. Nadia sọ pé, “A bẹ̀rẹ̀ sí í dín àwọn ohun ìní wa kù títí gbogbo ohun tá a ní kò fi gbà ju báàgì mẹ́rin lọ!”

Apá òsì: Nadia àti Marie-Madeleine Apá ọ̀tún: Thierry

Wọ́n dé Madagásíkà lọ́dún 2006, gbàrà tí wọ́n débẹ̀ ni wọ́n ti ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù. Nadia sọ pé “Àwọn tá à ń wàásù fún máa ń múnú wa dùn gan-an.”

Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n gbọ́ pé ara màmá Nadia tó ń jẹ́ Marie-Madeleine ò yá. Ilẹ̀ Faransé ni màmá náà ń gbé, àmọ́ lọ́jọ́ kan ó ṣubú, ló bá kán lápá ó sì ṣèṣe lórí. Lẹ́yìn tí Nadia àti ọkọ rẹ̀ bá dókítà tó ń tọ́jú màmá rẹ̀ sọ̀rọ̀, wọ́n ní kó máa wá gbé lọ́dọ̀ àwọn ní Madagásíkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni ọgọ́rin [80] ọdún ni màmá yìí nígbà yẹn, tayọ̀tayọ̀ ló fi gbà láti lọ. Báwo ló ṣe wá rí lára rẹ̀? Ó ní: “Àwọn nǹkan tó wà níbí kò tètè mọ́ mi lára àti pé ara mi ò fi bẹ́ẹ̀ le, síbẹ̀ inú mi dùn pé mo ṣì wúlò nínú ìjọ. Àmọ́, ohun tó ń fún mi láyọ̀ jù ni pé bí mo tiẹ̀ wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ mi, wọ́n ń bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ.”

“MO RÍ ỌWỌ́ JÈHÓFÀ LÁRA MI”

Riana ń sọ àsọyé lédè Tandroy

Arákùnrin Riana ti lé díẹ̀ lẹ́ni ogún ọdún. Ìlú Alaotra Mangoro tó wà lápá ìlà-oòrùn Madagásíkà ló dàgbà sí. Ó mọ̀wé gan-an, ó sì wù ú pé kó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga. Àmọ́, lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yí ìpinnu rẹ̀ pa dà. Ó sọ pé: “Mo sapá kí n lè parí ilé ẹ̀kọ́ girama mi lásìkò, mo sì ṣèlérí fún Jèhófà pé, ‘Tí mo bá yege ìdánwò àṣekágbá mi, màá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.’ ” Lẹ́yìn tí Riana kẹ́kọ̀ọ́ yege, ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó kó lọ sọ́dọ̀ arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan, ó gba iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó wá sọ pé, “Ìpinnu tó dáa jù tí mo ṣe láyé mi nìyẹn.”

Àmọ́, àwọn ẹbí rẹ̀ ò lóye ìdí tó fi sọ pé òun ò ní lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga. Riana sọ pé: “Bàbá mi, àbúrò wọn ọkùnrin àti àbúrò màmá mi àgbà ń rọ̀ mí pé kí n lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga. Àmọ́ mi ò fẹ́ kí ohunkóhun gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ mi.” Nígbà tó yá, Riana ronú pé á dáa kóun lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Kí ló mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Àwọn olè wọlé wa, wọ́n sì kó mi lẹ́rù lọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ohun tí Jésù sọ pé ká máa ‘to ìṣúra jọ sí ọ̀run.’ Torí náà, mo pinnu pé màá túbọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí n lè ní àwọn ìṣúra tẹ̀mí.” (Mát. 6:​19, 20) Bó ṣe kúrò níbi tó wà nìyẹn, ó sì lọ sí aṣálẹ̀ kan tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Ibẹ̀ tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] máìlì (1,300 km) síbi tó wà tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn Antandroy ló sì ń gbébẹ̀. Àmọ́ kí nìdí tó fi jẹ́ pé ibẹ̀ yẹn ló lọ?

Ní oṣù kan káwọn olè tó wá sílé wọn, Riana ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọkùnrin méjì kan lẹ́kọ̀ọ́, ọmọ ìbílẹ̀ Antandroy sì làwọn méjèèjì. Ó kọ́ èdè wọn díẹ̀, ìyẹn èdè Tandroy, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn èèyàn Antandroy tí kò tíì gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run rí. Riana sọ pé, “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè lọ síbi táwọn tó ń sọ èdè Tandroy wà.”

Kò pẹ́ tí Riana débẹ̀ ni ìṣòro kan yọjú. Kò ríṣẹ́ táá fi máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ọkùnrin kan wá sọ fún un pé: “Kí lo wá ṣe níbí? Àwọn èèyàn wa ń tibí lọ sọ́dọ̀ yín lọ wáṣẹ́, ìwọ wá ń bọ̀ ńbí!” Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, owó tán lọ́wọ́ Riana, kò sì mọ ohun tó máa ṣe nípa rẹ̀, síbẹ̀ ó lọ sí àpéjọ àgbègbè. Ní ọjọ́ tí àpéjọ àgbègbè náà máa parí, arákùnrin kan ki nǹkan kan bọ àpò ẹ̀wù Riana. Nígbà tó máa wo nǹkan náà, owó ni! Owó náà pọ̀ débi pé ó máa gbé Riana pa dà sílùú Antandroy, ó sì máa tó láti bẹ̀rẹ̀ òwò yúgọ́ọ̀tì. Riana sọ pé: “Mo rí ọwọ́ Jèhófà lára mi lásìkò tí mo nílò rẹ̀ gan-an, ìyẹn sì mú kí n lè máa bá iṣẹ́ ìsìn mi lọ! Ọ̀sẹ̀ méjì méjì ni mo máa ń sọ àsọyé. Ó dá mi lójú pé Jèhófà ń dá mi lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ètò rẹ̀,” torí iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe nínú ìjọ. Títí di bá a ṣe ń sọ yìí, Riana ṣì wà láàárín àwọn tó ń sọ èdè Tandroy, ó sì ń kọ́ wọn nípa Jèhófà.

ỌLỌ́RUN BÙ KÚN MI

Jèhófà fi dá wa lójú pé téèyàn bá ń wá ìbùkún òun láyé yìí, òun máa bù kún onítọ̀hún. (Aísá. 65:16) Tá a bá ń sapá láti borí àwọn ìṣòro tó ń dí wa lọ́wọ́ àtiṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà máa bù kún wa. Ẹ wo àpẹẹrẹ Sylviana tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ẹ rántí pé ó ní ó máa ń ṣe òun bíi pé òun ò ní lè lọ síbi tí àìní gbé pọ̀. Kí nìdí tó fi ronú bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Ẹsẹ̀ mi ọ̀tún gùn ju tòsì lọ, torí náà ṣe ni mo máa ń tiro, ó sì máa ń tètè rẹ̀ mí.”

Sylviana (lápá òsì) àti Sylvie Ann (lápá ọ̀tún) pẹ̀lú Doratine lọ́jọ́ tó ṣèrìbọmi

Àmọ́ nígbà tó dọdún 2014, Sylviana àti Arábìnrin Sylvie Ann tí wọ́n jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà nínú ìjọ kan náà ṣí lọ sí abúlé kékeré kan tó tó nǹkan bíi máìlì mẹ́tàléláàádọ́ta [53] (tàbí 85 km) sí ìlú wọn. Ní báyìí, ọwọ́ Sylviana ti tẹ ohun tó ń lé láìka àwọn ìṣòro tó ní sí, ìbùkún ńlá sì nìyẹn. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún kan péré tí mo débí, mo kọ́ Doratine, ìyẹn ọ̀dọ́bìnrin kan tó ti bímọ lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká tá a ṣe.”

“ÈMI YÓÒ RÀN Ọ́ LỌ́WỌ́”

Bá a ṣe rí i nínú ìrírí àwọn tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ yìí, ó gba pé ká sapá láti borí àwọn ìṣòro tí kì í jẹ́ kéèyàn lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á ràn wá lọ́wọ́, torí ó sọ pé: “Èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.” (Aísá. 41:10) Bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ máa mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ gún régé. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá yọ̀ǹda ara wa tinútinú láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ yálà lórílẹ̀-èdè wa tàbí lórílẹ̀-èdè míì, ṣe là ń múra sílẹ̀ fáwọn iṣẹ́ àgbàyanu tá a máa ṣe nínú ayé tuntun. Bí Didier tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣe sọ, “téèyàn bá lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, ṣe ló ń kọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú!” Torí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ò tíì ṣe bẹ́ẹ̀ pé kẹ́ ẹ gbé ìgbésẹ̀ báyìí!

^ ìpínrọ̀ 4 Ibi táwọn ará yìí ti wá ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Czech Republic, ilẹ̀ Faransé, Guadeloupe, Jámánì, Kánádà, Luxembourg, New Caledonia, Sweden, Switzerland àti United Kingdom.

^ ìpínrọ̀ 8 A ti fi Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run rọ́pò ilé ẹ̀kọ́ yìí. Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó ń sìn lórílẹ̀-èdè míì tí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n lè gba fọ́ọ̀mù ilé ẹ̀kọ́ náà kí wọ́n sì lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì tó ń sọ èdè wọn.