OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ
Kárí Ayé
Àjọ Save the Children International tó máa ń rí sí ọ̀ràn àwọn ọmọdé sọ pé: “Lọ́dọọdún, àwọn ọmọ ọwọ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta ni wọ́n máa ń kú láàárín oṣù kan tí wọ́n bí wọn. Kódà ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn ọmọ náà ló máa ń kú lọ́jọ́ tí wọ́n bí wọn gan-an. Ẹ̀rí sì fi hàn pé, ọ̀pọ̀ ohun tó ń fa ikú àwọn ọmọ náà ṣeé dènà.”
Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Ní ọdún 2011, Àjọ tó ń bójú tó Ìlera Ará Ìlú nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, ní àwọn àgbègbè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] nílùú London, iye àwọn tó ń kú nítorí tí wọ́n ń mí afẹ́fẹ́ olóró símú, ti pọ̀ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé epo dísù làwọn èèyàn gbà pé ó dáa jù torí pé afẹ́fẹ́ olóró tí wọ́n ń pè ní carbon dioxide tó ń jáde nínú ẹ̀rọ tó ń lo epo dísù kéré gan-an, epo náà kì í sì náni lówó púpọ̀. Síbẹ̀, ohun tó ju ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá afẹ́fẹ́ olóró tó ń pa èèyàn láwọn àgbègbè yìí ń jáde látara àwọn ọkọ̀ tó ń lo epo dísù.
Rọ́ṣíà
Ìwádìí tí àjọ kan tó ń rí sí Èrò Àwọn Aráàlú nílẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ní ọdún 2013 fi hàn pé ohun tó ju ìdajì àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó jẹ́ Kristẹni tó sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni kò tiẹ̀ ka Bíbélì rí, kódà àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá sọ pé bóyá làwọn gbàdúrà rí.
Áfíríkà
Ìròyìn kan láti Báńkì Àgbáyé fi hàn pé àwọn tó ń jà sí ilẹ̀ ò jẹ́ káwọn èèyàn ráyè ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ dáadáa, èyí sì ń fa àìríná àti àìrílò tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìdajì nínú ilẹ̀ tó ṣeé gbin nǹkan sí lágbàáyé àmọ́ táwọn èèyàn pa tì ló wà ní Áfíríkà, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún mílíọ̀nù [500,000,000] éékà. Kódà ìdá kan péré nínú mẹ́rin ohun ọ̀gbìn tí ilẹ̀ Áfíríkà lè mú jáde gan-an ló ń mú jáde.
Amẹ́ríkà
Àwọn iléèwé kan ti fi ẹ̀rọ alágbèéká tí wọ́n ń pè ní tablet rọ́pò àwọn ìwé tó yẹ káwọn ọmọléèwé máa kà. Ohun tí wọ́n ṣe ni pé, wọ́n gbé oríṣiríṣi ìwé àtàwọn ètò kọ̀ǹpútà míì tí àwọn ọmọléèwé máa nílò sórí àwọn ẹ̀rọ alágbèéká náà. Àmọ́ àwọn kan ti ń ṣàríwísí pé bóyá ni ètò yìí ò ní wọ́nwó ju ìwé tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ lọ.