Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà

Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà

Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà

Láàárín ọdún 1997 sí ọdún 2011, ó yani lẹ́nu pé ó tó ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́wàá [1,710] ewéko àti ẹranko tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí. Lára wọn ni ejò paramọ́lẹ̀ ẹlẹ́yinjú pupa rẹ́súrẹ́sú kan tí wọ́n rí ní odò Greater Mekong. Àwọn ìlú tí odò yìí là kọjá ni ìlú Kàǹbódíà, Laos, Myanmar, Thailand, Vietnam àti àgbègbè Yunnan, lórílẹ̀-èdè Ṣáínà. Lọ́dún 2011 nìkan, wọ́n ṣàwárí àwọn ẹ̀dá tuntun tí iye wọn jẹ́ mẹ́rìndínláàádóje [126]. Nínú wọn la ti rí ewéko méjìlélọ́gọ́rin, ẹranko mọ́kànlélógún, ẹja mẹ́tàlá, ẹran jomi-jòkè márùn-ún àti ẹranko afọ́mọlọ́mú márùn-ún.

Yúróòpù

Ìròyìn kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Moscow Times sọ pé, ó ti wá di ìṣòro ńlá ní “gbogbo Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-èdè Ilẹ̀ Yúróòpù” báyìí, pé kí wọ́n máa ta àwọn èèyàn sí ìlú míì. Wọ́n máa ń fi wọ́n ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó, wọ́n máa ń lò wọ́n nílò ẹrú, wọ́n sì “máa ń ta ẹ̀yà ara wọn.” Ohun tí wọ́n fi ń rí àwọn èèyàn mú ni ipò òṣì, àìníṣẹ́lọ́wọ́ àti àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba láàárín tọkùnrin tobìnrin.

New Zealand

Àwọn tó ṣèwádìí lórí ipa tí tẹlifíṣọ̀n ń ní lórí àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ sọ pé, wíwo tẹlifíṣọ̀n láwòjù wà lára “ohun tí kì í jẹ́ káwọn tó ń ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di àgbàlagbà mọ béèyàn ṣe ń hùwà láwùjọ.” Àwọn tó ṣèwádìí yìí sọ pé àwọn fara mọ́ àbá kan tó sọ nípa àkókò tó yẹ káwọn ọmọdé fi máa wo tẹlifíṣọ̀n pé, “kò yẹ kó ju wákàtí kan sí méjì lọ lójúmọ́ tí wọ́n á fi máa wo ètò tó gbámúṣé lórí tẹlifíṣọ̀n.”

Alaska

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo “abúlé tó wà nílùú Alaska” ló wà ní etí òkun tàbí etí odò, ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn abúlé yìí sì ni àkúnya omi àti ọ̀gbàrá ń yọ lẹ́nu. Ìwádìí fi hàn pé àpọ̀jù ooru ni kò jẹ́ kí òkìtì yìnyín tó máa ń wà létí òkun lè dì gbagidi, èyí sì máa ń fa jàǹbá fún àwọn ará abúlé náà nígbà tí ìjì líle tó máa ń jà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn bá dé.

Kárí Ayé

Owó ribiribi ni ìjọba ń ná lórí lílo agbára ìjì àti oòrùn gẹ́gẹ́ bí ohun àmúṣagbára, èyí tí wọ́n gbà pé kò ní dá kún ìbàyíkájẹ́. Ṣùgbọ́n, Maria van der Hoeven, tó jẹ́ olùdarí àgbà ti Àjọ Tó Ń Rí sí Àwọn Ohun Àmúṣagbára Lágbàáyé sọ pé: “Nǹkan bí ìdajì lára àwọn ohun àmúṣagbára tá à ń mú jáde lóde òní ló jẹ́ pé ńṣe ló ṣì ń ba àyíká jẹ́ bíi ti ogun ọdún sẹ́yìn.”