ÀPILẸ̀KỌ TÓ DÁ LÓRÍ ÀKÒRÍ Ẹ̀YÌN ÌWÉ
Ṣé Ìwọ́de Ló Máa Yanjú Ìṣòro Ayé?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé ìròyìn yìí. A kì í dá sí ìṣèlú. (Jòhánù 17:16; 18:36) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nínú àwọn àpilẹ̀kọ tá a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò yìí, a sọ̀rọ̀ nípa báwọn kan ṣe ń da ìgboro rú nítorí pé ìjọba ò ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, síbẹ̀ a kò fi àpilẹ̀kọ yìí gbé orílẹ̀-èdè kan ga ju èkejì lọ, a ò sì fara mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan.
NÍ December 17, ọdún 2010, agara dá ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mohamed Bouazizi. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ni, àwọn èso bíi píà, ọ̀gẹ̀dẹ̀, àti ápù ló sì ń tà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títí, ní ìlú kan lórílẹ̀-èdè Tùníṣíà. Gbogbo nǹkan tojú sú u nítorí pé kò níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Ó tún rí i pé àwọn ọ̀gá kan lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba máa ń gba rìbá. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, àwọn ọlọ́pàá gba ọjà Mohamed. Àwọn kan tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn sọ pé ọlọ́pàá obìnrin kan gbá Mohamed lójú nígbà tí kò jẹ́ kí wọ́n gba ohun tó fi ń wọn ọjà rẹ̀.
Àbùkù tí wọ́n fi kan Mohamed yìí mú kí inú bí i gidigidi, ó wá lọ sí ọ́fíìsì ìjọba kan tó wà nítòsí láti lọ fẹjọ́ sùn, àmọ́ kò sẹ́ni tó rí tiẹ̀ rò rárá. Ìròyìn sọ pé, ńṣe ni Mohamed bọ́ síwájú ìta ọ́fíìsì náà ó sì kígbe pé, “Báwo lẹ ṣe fẹ́ kí n máa bọ́ ìdílé mi báyìí?” Lẹ́yìn náà ó da epo sí gbogbo ara rẹ̀, ó mú ìṣáná, ó sì dáná sun ara rẹ̀. Kò tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà tí Mohamed kú.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mohamed Bouazizi yìí ká àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Tùníṣíà àti ọ̀pọ̀ àwọn míì lára gan-an. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọ̀rọ̀ Mohamed yìí ló fa wàhálà ńlá tó dojú ìjọba tó wà nígbà yẹn dé. Kò sì pẹ́ rárá táwọn èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́de láwọn orílẹ̀-èdè Arébíà tó kù. Lọ́dún 2011, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ilẹ̀ Yúróòpù fún Bouazizi àtàwọn mẹ́rin míì ní àmì ẹ̀yẹ pàtàkì kan fún bí wọ́n ṣe sọ èrò wọ́n jáde fàlàlà. Ìwé ìròyìn The Times ti ìlú London náà sì gbóṣùbà fún Mohamed gẹ́gẹ́ bí akọni ọdún 2011.
Àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé, fífi ẹ̀hónú hàn tàbí ìwọ́de máa ń ní ipa tó lágbára gan-an. Àmọ́, kí ló ń ti àwọn èèyàn débi tí wọ́n fi ń fi ẹ̀hónú hàn tí ìwọ́de sì ń pọ̀ sí i lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí? Ǹjẹ́ ọ̀nà míì wà tí wọ́n lè gbà yanjú ìṣòro láìjẹ́ pé wọ́n wọ́de?
Kí Nìdí Tí Ìwọ́de Fi Gbòde Kan?
Àwọn nǹkan tó máa ń mú káwọn èèyàn wọ́de rèé:
-
Bí nǹkan ò bá lọ bí wọ́n ṣe fẹ́ nílùú. Ká ní àwọn èèyàn rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú ló ń jẹ àwọn tó ń ṣèjọba lógún, àwọn èèyàn ò ní máa wọ́de, ṣe ni wọ́n á wulẹ̀ tẹ̀ lé ọ̀nà tí ìjọba ti là kalẹ̀ láti bójú tó àwọn ìṣòro wọn. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ńṣe làwọn tó ń ṣèjọba ń kówó jẹ, tí ìwọ̀nba èèyàn ń gbádùn, nígbà tó jẹ́ pé ojú ń pọ́n àwọn mẹ̀kúnnù, èyí lè mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀hónú hàn kí wọ́n sì máa wọ́de.
-
Ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ló sábà máa ń mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́de. Bí wọ́n bá tiẹ̀ ti gba kámú tẹ́lẹ̀, ó máa ń mú kí wọ́n fẹ́ láti ṣe nǹkan kan kí wọ́n lè yanjú ìṣòro náà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Mohamed Bouazizi ló bẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn ńlá tó wáyé lórílẹ̀-èdè Tùníṣíà. Lórílẹ̀-èdè Íńdíà, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kan tó ń jẹ́ Anna Hazare yan oúnjẹ lódì láti fi ẹ̀hónú rẹ̀ hàn nítorí ìwà ìbàjẹ́ àwọn tó ń ṣèjọba. Èyí ló mú káwọn alátìlẹyìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́de ní àwọn ìlú ńláńlá àtàwọn ìlú kéékèèké tó jẹ́ irinwó lé àádọ́ta [450].
Ó pẹ́ tí Bíbélì ti sọ pé, “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìrẹ́jẹ ti wá tàn kálẹ̀ báyìí ju ti ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì lọ. Kódà ní báyìí, ojú àwọn èèyàn ti wá túbọ̀ ń là sí ìwà ìbàjẹ́ tó wà láàárín àwọn olóṣèlú àti bí ètò ọ̀rọ̀ ajé kò ṣe láyọ̀lé mọ́. Àwọn fóònù ìgbàlódé, Íńtánẹ́ẹ̀tì àti ìròyìn tí wọ́n ń gbé jáde tọ̀sán-tòru tí mu káwọn èèyàn tètè máa mọ ohun tó ń lọ lágbàáyé. Bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan bá sì wáyé, kódà láwọn ìlú tó jẹ́ àdádó, kíá làwọn èèyàn tó wà nígboro á ti rí i tí wọ́n sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́de.
Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn ti ṣàṣeyọrí kankan?
Téèyàn bá bi àwọn tó ń fi ẹ̀hónú hàn bóyá àǹfààní kankan tiẹ̀ wà nínú bí wọ́n ṣe máa ń wọ́de, wọ́n á sọ pé ó ti mú káwọn ṣe àwọn àṣeyọrí yìí:
-
Wọ́n mú kí ìgbé ayé dẹra fáwọn òtòṣì. Láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1939 tó jẹ́ àkókò tí ọrọ̀ ajé lọ sílẹ̀ lọ́nà tó bùáyà kárí ayé, ohun kan ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nílùú Chicago, ìpínlẹ̀ Illinois. Owó ilé tó ga sókè lákòókò yẹn mú kí àwọn aráàlú bẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn tí wọ́n sì ń wọ́de. Èyí ló mú kí àwọn aláṣẹ ìjọba tó wà nílùú náà rí sí i pé àwọn onílé ò lé ẹnikẹ́ni síta mọ́, wọ́n sì tún wáṣẹ́ fáwọn kan lára àwọn tó dá rògbòdìyàn náà sílẹ̀. Nígbà tí irú ìṣòro ilé gbígbé bẹ́ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ nílùú New York City, ìwọ́de táwọn èèyàn ṣe ló mú kí ìjọba rí sí i pé àwọn ìdílé tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77,000] pa dà sílé wọn.
-
Wọ́n fòpin sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Bí àwọn èèyàn ṣe kọ̀ láti wọ ọkọ̀ èrò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, láàárín ọdún 1955 sí 1956, ló mú kí ìjọba ṣe àyípadà sí òfin tó ṣe nígbà kan pé kí ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ má ṣe jókòó pa pọ̀ nínú ọkọ̀ èrò nílùú Montgomery, ní ìpínlẹ̀ Alabama.
-
Wọ́n dá iṣẹ́ ìkọ́lé dúró. Lóṣù December ọdún 2011, nítòsí ìlú Hong Kong, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló wọ́de láti fi ẹ̀hónú wọn hàn nítorí àkóbá tí ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti fẹ́ máa fi èédú mú iná mànàmáná jáde máa ṣe fáwọn aráàlú. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ìwọ́de táwọn èèyàn ṣe yẹn ló mú kí ìjọba wọ́gi lé iṣẹ́ ìkọ́lé náà.
Èyí kò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni àwọn èèyàn máa ń rí ẹ̀tọ́ wọn gbà torí pé wọ́n wọ́de. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé dípò kí àwọn aláṣẹ ṣe ohun táwọn èèyàn fẹ́, ṣe ni wọ́n á fìyà jẹ àwọn tó ń wọ́de. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí àwọn kan wọ́de lórílẹ̀-èdè kan ní apá Àárín Ìlà Oòrùn ayé, ààrẹ orílẹ̀-èdè náà sọ nípa àwọn tó ń wọ́de náà pé: “A ò gbọ́dọ̀ gbojúbọ̀rọ̀ fún wọn rárá.” Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló sì ti ṣòfò ẹ̀mí báyìí látàrí ìwọ́de náà.
Kódà, tọ́wọ́ àwọn tó wọ́de bá tiẹ̀ tẹ ohun tí wọ́n ń wá, lọ́pọ̀ ìgbà ṣe ni èyí máa ń mú kí àwọn ìṣòro míì tún yọjú. Ọ̀gbẹ́ni kan tó wà lára àwọn tó yọ olórí orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà kúrò nípò sọ fún ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Time nípa ìjọba tuntun tó wa gorí àlééfà pé: “Ìjọba àjùmọ̀ni táwọn èèyàn ronú pé á mú kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn náà ló tún pa dà dá rògbòdìyàn sílẹ̀.”
Kí ni ojútùú sáwọn ìṣòro wa?
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ló gbà pé ó yẹ kéèyàn wọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn nígbà tí ìjọba bá ń han àwọn aráàlú léèmọ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀gbẹ́ni Václav Havel, tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Czech nígbà kan. Ọ̀pọ̀ ọdún ni ọ̀gbẹ́ni yìí lò lẹ́wọ̀n nígbà ayé rẹ̀ torí ó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Lọ́dún 1985, ó kọ̀wé pé: “[Àwọn tó ń fi ẹ̀hónú hàn] kò kọ ohunkóhun tó lè ná wọn láti jà fẹ́tọ̀ọ́ wọn, ì báà tiẹ̀ já sí ikú pàápàá.
Ìdí sì ni pé wọ́n gbà pé kò sí ọ̀nà míì táwọn lè fi jà fún ohun táwọn gbà pé ó tọ́.”Ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Havel yìí wá jẹ́ ká rí ìdí tí Mohamed Bouazizi àtàwọn míì kò fi kọ ikú nígbà tí wọ́n ń jà fún ẹ̀tọ́ wọn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló dáná sun ara wọn láti fi ẹ̀hónú wọn hàn fún bí àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn olóṣèlú ṣe ń fayé ni àwọn aráàlú lára lórílẹ̀-èdè náà. Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni kan ń sọ ohun tó mú kí wọ́n gbé irú ìgbésẹ̀ tó lágbára bẹ́ẹ̀, ó sọ fún ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Newsweek lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “A ò ní ìbọn. A ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa pa àwọn míì lára. Kí la tún lè ṣe jù ìyẹn lọ?”
Bíbélì sọ ohun tó máa yanjú ìṣòro ìwà ìrẹ́jẹ, ìwà ìbàjẹ́, àti ìnilára. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìjọba kan tí Ọlọ́run ti ṣètò ní ọ̀run, tó máa rọ́pò ìjọba èèyàn àti ètò ọ̀rọ̀ ajé tí kò lè yanjú ìṣòro àwọn èèyàn, èyí tó ń mú kí wọ́n máa wọ́de láti jà fún ẹ̀tọ́ wọn. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Ọba ìjọba tá à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. . . . Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:12, 14.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa mú àlàáfíà wá fún aráyé. (Mátíù 6:9, 10) Ìdí nìyẹn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ sí ìwọ́de èyíkéyìí. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni pé Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú gbogbo ìṣòro tó ń mú káwọn èèyàn máa wọ́de? Ó lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe lóòótọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá fọkàn tán Ìjọba Ọlọ́run pé òun ló máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. A rọ̀ ẹ́ pé kí ìwọ náà ka ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa yanjú ìṣòro aráyé.