ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́
Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Wí
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Òfin tẹ́ ẹ fi lélẹ̀ nínú ìdílé yín ni pé tó bá fi máa di aago mẹ́sàn-án alẹ́, kí kálukú ti pa fóònù rẹ̀, àmọ́ lọ́sẹ̀ yìí ẹ̀ẹ̀mejì lo ti ká ọmọ rẹ obìnrin tó ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù ní aago méjìlá kọjá lóru. O ti sọ fún ọmọ rẹ ọkùnrin pé kò gbọ́dọ̀ kọjá aago mẹ́wàá alẹ́ níta, àmọ́ lálẹ́ àná aago mọ́kànlá ti kọjá kó tó wọlé, kì í sì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó máa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.
Ohun kan ni pé ọmọ rẹ lè yíwà pa dà. Àmọ́ ó yẹ kó o kọ́kọ́ mọ ohun tó fà á tó fi máa ń tẹ òfin rẹ lójú. Bí ọmọ rẹ ṣe ń tẹ òfin rẹ lójú yìí lè mú kó o máa ronú pé ọmọ náà ti ya aláìgbọràn pátápátá, àmọ́ ọ̀rọ̀ lè máà rí bẹ́ẹ̀ rárá.
OHUN TÓ FÀ Á?
O kì í sọ ohun tó o máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn. Ìdí táwọn ọmọ kan fi máa ń tẹ òfin lójú ni pé, wọ́n fẹ́ wò ó bóyá àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀ káwọn sì mú un jẹ. Bí àpẹẹrẹ, tí òbí kan bá sọ fún ọmọ kan pé tó bá ṣàìgbọràn, ohun báyìí-báyìí lòun máa ṣe fún un, ọmọ náà lè fẹ́ wò ó bóyá òbí náà máa ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Ǹjẹ́ èyí fi hàn pé ọmọ náà ti wá yawọ́ pátápátá? Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Ohun kan tó yẹ káwọn òbí mọ̀ ni pé, àwọn ọmọ lè má fọwọ́ pàtàkì mú òfin wọn tó bá jẹ́ pé àwọn òbí kì í sábà bá wọn wí bó ṣe tọ́ tàbí táwọn òbí kò bá sọ ohun tí wọ́n máa ṣe tí ọmọ wọn bá ṣàìgbọràn.
Àpọ̀jù òfin. Àwọn òbí kan máa ń fi òfin rẹpẹtẹ ká ọmọ wọn lọ́wọ́ kò. Tí ọmọ náà bá sì ṣàìgbọràn, ńṣe làwọn òbí náà á bínú tí wọ́n á sì tún fi kún àwọn òfin náà. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni èyí máa ń dá kún ìṣòro náà. Ìwé kan tó ń jẹ́ Parent/Teen Breakthrough sọ pé: “Tó o bá fẹ́ máa darí gbogbo ohun tí ọmọ rẹ ń ṣe, òun náà ò ní fẹ́ máa gbọ́rọ̀ sí ẹ lẹ́nu.” Ìwé náà tún sọ pé: “Tí òbí bá ti le koko jù, ó máa ń mú kí ọmọ ya aláìgbọràn, tí wọ́n á sì fẹ́ máa ṣe tinú wọn.”
Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o bá ọmọ náà wí lọ́nà tó tọ́. Ìbáwí túmọ̀ sí kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ó sì yàtọ̀ sí fífi ìyà jẹni. Torí náà, báwo lo ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ láti máa ṣe ohun tó o bá sọ fún un?
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere. Àwọn ọmọ máa ń fẹ́ mọ ohun náà gan-an tó o fẹ́ kí àwọn ṣe àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá ṣàìgbọràn.—Ìlànà Bíbélì: Gálátíà 6:7.
Àbá: Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn òfin tó o fi lélẹ̀ nínú ìdílé yín. Kó o wá bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn òfin yìí ò pọ̀ jù? Ṣé àwọn òfin yìí ò kéré jù? Ṣé àwọn òfin kan wà tó yẹ kí n ti yọ kúrò? Ǹjẹ́ kò ní dára kí n ṣàwọn àyípadà kan nínú àwọn òfin náà níwọ̀n bí ìwà ọmọ mi ti ń fi hàn báyìí pé ó ti lè dá ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́?’
Dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Ohun kan wà tí kò yẹ kó o máa ṣe, torí pé tó o bá ṣe é, àwọn ọmọ rẹ kò ní mọ ohun tó o fẹ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, lọ́sẹ̀ tó kọjá, ọmọ rẹ ṣe ohun kan tó o ní kò gbọ́dọ̀ ṣe, o ò sì ṣe nǹkan kan fún un, àmọ́ nígbà tọ́mọ náà ṣe ohun kan náà lọ́sẹ̀ yìí, o bá a wí.—Ìlànà Bíbélì: Mátíù 5:37.
Àbá: Á dára kó o jẹ́ kí ìbáwí tó o máa fún ọmọ náà bá ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ mu. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ńṣe ni ọmọ rẹ pẹ́ níta, ìbáwí tó bá ẹ̀ṣẹ̀ náà mu ni pé kó o yí aago tí ọmọ náà gbọ́dọ̀ wọlé pa dà, kó o jẹ́ kó yá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Máa lo ìgbatẹnirò. Jẹ́ kí ọmọ rẹ rí i pé o kì í ṣe òbí tó máa ń rin kinkin. Ọ̀nà tó o sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa fún un ni òmìnira sí i nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 4:5.
Àbá: Pe ọmọ rẹ jókòó, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn òfin náà. O tiẹ̀ lè ní kí òun fúnra rẹ̀ sọ ohun tó ronú pé o yẹ kó o ṣe fún un tó bá tẹ òfin kan lójú. Àwọn ọmọ máa tẹ̀ lé òfin tẹ́yin òbí bá ṣe, tẹ́ ẹ bá jẹ́ kí wọ́n dá sí i nígbà tẹ́ ẹ̀ ń ṣe òfin náà.
Kọ́ ọmọ rẹ ní ìwà ọmọlúwàbí. Kì í ṣe bí ọmọ rẹ a ṣe máa tẹ̀ lé òfin tó o bá fi lélẹ̀ nìkan ló yẹ kó jẹ ọ́ lógún. Ó yẹ kó o ràn án lọ́wọ́ kó lè ní ẹ̀rí ọkàn tó dára, tó máa jẹ́ kó mọ ohun tó dára yàtọ̀ sí ohun tó burú. (Wo Àpótí náà “Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìwà Ọmọlúwàbí.”)—Ìlànà Bíbélì: 1 Pétérù 3:16.
Àbá: Jẹ́ kí Bíbélì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kò sí ibòmíì tó o ti lè rí “ìbáwí tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye” bí èyí tó wà nínú Bíbélì. Ọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀ lè “fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà,” ó sì lè “fún ọ̀dọ́kùnrin [tàbí ọ̀dọ́bìnrin] ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.”—Òwe 1:1-4.