ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | TỌKỌTAYA
Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Yan Odì
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Báwo ni ọ̀rọ̀ ṣe lè le láàárín tọkọtaya tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfẹ́ fún ara wọn débi pé wọn kò ní bá ara wọn sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí tàbí àìmọye ọjọ́? Ó ṣeé ṣe kí àwọn méjèèjì máa rò pé àwọn kàn ń yan odì ni, àwọn ò kúkú bára àwọn jà. Àmọ́ wọn ò yanjú ìṣòro tó wà láàárín wọn, inú wọn ò sì dùn.
OHUN TÓ FÀ Á
Àwọn kan máa ń yan odì láti gbẹ̀san lára ẹnì kejì. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọkọ ṣètò pé kí òun àti aya rẹ̀ ṣe nǹkan kan lópin ọ̀sẹ̀, àmọ́ kò sọ fún ìyàwó rẹ̀. Nígbà tí ìyàwó rẹ̀ wá mọ̀, inú bí i débi tó fi sọ pé ọkọ òun kò ka oùn sí. Ni ọkọ náà bá fún un lésì pé gbogbo nǹkan ló máa ń gbà sí ìbínú. Ìyàwó bá bínú kúrò níwájú rẹ̀, kò sì bá a sọ̀rọ̀ mọ́. Ohun tí ìyàwó yẹn ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ tó o sọ yẹn dùn mí, mo sì máa gbẹ̀san.”
Torí kọ́wọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́ làwọn kan ṣe máa ń yan ẹnì kejì wọn lódì. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé tọkọtaya kan fẹ́ rin ìrìn-àjò kan, aya sì fẹ́ kí àwọn òbí òun tẹ̀ lé àwọn. Àmọ́ ọkọ rẹ̀ kò fara mọ́ ọn. Ó wá sọ pé, “Ìwọ ni mo fẹ́ sílé, kì í ṣàwọn òbí ẹ.” Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá aya rẹ̀ yan odi, kò bá a sọ̀rọ̀ kankan mọ́ nírètí pé ìyẹn á jẹ́ kí ìyàwó náà fara mọ́ ohun tóun sọ.
Òótọ́ ni pé bí tọkọtaya bá dákẹ́ fúngbà díẹ̀, èyí lè mú kí inú tó ń bí wọn rọlẹ̀. Kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Bíbélì sọ pé, “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” máa ń wà. (Oníwàásù 3:7) Àmọ́ tó bá jẹ́ láti fi gbẹ̀san tàbí torí kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni tọkọtaya kan ṣe ń yan ara wọn lódì, ìjà wọn kò ní tán bọ̀rọ̀, wọn ò sì ní lè bọ̀wọ̀ fún ara wọn bó ṣe yẹ. Kí lo lè ṣe tọ́rọ̀ ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kò fi ní di iṣu ata yán-an yàn-an?
OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE
Ohun àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ni pé bíbá ara yín yan odì kò lè tán ìṣòro yín. Òótọ́ ni pé tó o bá dákẹ́ tí o kò fọhùn, ó lè dà bíi pé o ti gbẹ̀san tàbí kó mú kí ẹnì kejì rẹ ṣe ohun tó o fẹ́. Àmọ́ ṣé ohun tó yẹ kó o ṣe nìyẹn sí ẹni tó o ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún pé o máa nífẹ̀ẹ́ títí ayé? Àwọn nǹkan míì wà tó sàn ju ìyẹn lọ tó o lè ṣe tó o bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yanjú.
Máa fọgbọ́n hùwà. Bíbélì sọ pé a “kì í tán [ìfẹ́] ní sùúrù.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Torí náà bí ẹnì kejì rẹ bá tiẹ̀ sọ pé, “Tara ẹ nìkan lo mọ̀,” tàbí tó sọ pé “Gbogbo ìgbà lo máa ń pẹ́ lẹ́yìn,” ṣe ni kó o fara balẹ̀, má ṣe fara ya. Kó o gbìyànjú láti fòye mọ ohun tó ní lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kejì rẹ bá sọ pé “Tara ẹ nìkan lo mọ̀,” ó lè jẹ́ ohun tó ní lọ́kàn ni pé ‘o kì í ka ọ̀rọ̀ òun sí pàtàkì.’—Ìlànà Bíbélì: Òwe 14:29.
Ṣe ni kẹ́ ẹ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro dípò kẹ́ ẹ máa bá ara yín fa ọ̀rọ̀
Máa fi ohùn tútù sọ̀rọ̀. Béèyàn ò bá tètè fòpin sí iyàn jíjà, ńṣe ló máa ń le sí i. Torí náà, o lè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń bára yín fà, kó má bàa di ariwo. Kí lo lè ṣe? Ìwé Fighting for Your Marriage, tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí tọkọtaya lè ṣe tí ìjà bá wáyé, sọ pé: “Tó o bá fẹ́ kí ìbínú àti ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ̀ ń bára yín fà rọlẹ̀, ohun kan tó o lè lò sí i ni pé kó o fi ohùn tútù sọ̀rọ̀, kó o sì fara mọ́ ohun tí ẹnì kejì rẹ bá sọ. Lọ́pọ̀ ìgbà kò jù bẹ́ẹ̀ lọ.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 26:20.
Má ṣe ro tara rẹ nìkan. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Ṣe ni kẹ́ ẹ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro dípò kẹ́ ẹ máa bára yín fa ọ̀rọ̀. Ìyẹn kò ní jẹ́ kẹ́ ẹ máa bínú síra yín jù, kò sì ní jẹ́ kẹ́ ẹ máa bára yín jiyàn débi pé ẹ máa wá yan ara yín lódì.—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 7:9.
Tẹ́ ẹ bá ń bára yín yan odì, a jẹ́ pé ẹ kò ṣe ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ò ṣe kúkú jọ fohùn ṣọ̀kan pé ẹ ò ní bára yín yan odì rárá?