TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Ìrù Aláǹgbá Adárípọ́n
ALÁǸGBÁ adárípọ́n máa ń fò láti ibi pẹrẹsẹ sí ara ògiri láìfarapa. Àmọ́ tí kì í bá ṣe ti ìrù tó ní, tó bá fò látorí ibi tó ń yọ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní ranlẹ̀, ó sì lè jábọ́.
Rò ó wò ná: Tí aláǹgbá adárípọ́n bá wà lórí ibi tó rí ṣákaṣàka, ẹsẹ̀ rẹ̀ máa ń múlẹ̀ dáadáa. Tó bá fò kúrò níbẹ̀, ó máa kọ́kọ́ kọrí ìrù rẹ̀ sísàlẹ̀ kó lè fò dáadáa. Àmọ́ tó bá fẹ́ fò látorí ibi tó ń yọ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní múlẹ̀ dáadáa, ara rẹ̀ kò ní balẹ̀, kò sì ní lè fò bó ṣe yẹ. Nígbà tó bá wà lófuurufú, á kọrí ìrù rẹ̀ sókè kí ara rẹ̀ lè wà bó ṣe yẹ. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ṣe kó tó balẹ̀. Ìwé kan tí wọ́n gbé jáde ní Yunifásítì kan ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Àwọn aláǹgbá máa ń tún ìrù wọn ṣe kó lè wà bó ṣe yẹ, kí ara wọn sì lè nàró ṣánṣán nígbà tí wọ́n bá máa balẹ̀.” Bí ojú ibi tí wọ́n ti fẹ́ fò kúrò bá ṣe ń dán tó ló máa pinnu bí wọ́n á ṣe na ìrù wọn sókè tó, kí wọ́n lè balẹ̀ sórí ẹsẹ̀ wọn.
Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ti rí i pé bí ìrù aláǹgbá yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ lè jẹ́ kí àwọn mọ bí àwọn ṣe máa ṣe ọkọ̀ rọ́bọ́ọ̀tì tí ẹsẹ̀ rẹ̀ máa ranlẹ̀ dáadáa tí wọ́n á lè máa fi wá àwọn èèyàn tó fara pa nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì bá wáyé. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Thomas Libby sọ pé: “Àwọn rọ́bọ́ọ̀tì kò lè ṣe kánmọ́-kánmọ́ bíi tàwọn ẹranko. Torí náà, ohunkóhun tá a bá lè ṣe láti mú kí ẹsẹ̀ àwọn rọ́bọ́ọ̀tì túbọ̀ máa ranlẹ̀ dáadáa yóò fi hàn pé a ti tẹ̀ síwájú gan-an.”
Kí lèrò rẹ? Ṣé ìrù ìdí aláǹgbá adárípọ́n yìí kàn dédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?