Ojú Ìwòye Bíbélì
Párádísè
Kí ni Párádísè?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Àwọn kan máa ń rò pé ìtàn àròsọ lásán lọ̀rọ̀ nípa Párádísè jẹ́. Àwọn míì gbà pé Párádísè jẹ́ ọgbà ìdẹ̀ra níbi tí gbogbo nǹkan á ti máa lọ bó ṣe yẹ, tàwọn èèyàn rere á máa gbé títí láé, tí wọ́n á sì máa ṣe àwọn nǹkan tí yóò máa fún wọn láyọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ibùgbé tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá fún àwa èèyàn, ìyẹn ọgbà Édẹ́nì, ni Bíbélì pè ní “Párádísè.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7-15) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọgbà yẹn wà lóòótọ́. Ibẹ̀ ni Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́ sí. Kò sí àìsàn àti ikú níbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Nígbà tí wọ́n ṣàìgbọràn, Ọlọ́run lé wọn jáde nínú Párádísè yẹn. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, àwa èèyàn ṣì máa pa dà gbé nínú Párádísè.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI KÀN Ọ́
Tí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa, a jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ láti gbà pé yóò san àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olódodo lẹ́san iṣẹ́ rere wọn nínú Párádísè. Ó tún bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run yóò sọ ohun táwa èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe ká lè rí ojú rere rẹ̀ fún wa. Bíbélì sọ pé ìwọ náà lè rí ojú rere Ọlọ́run tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, tó o sì ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.—Jòhánù 17:3; 1 Jòhánù 5:3.
“Jèhófà Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì, . . . ibẹ̀ ni ó sì fi ọkùnrin tí ó ti ṣẹ̀dá sí.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:8.
Ibo ni Párádísè wà?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ìgbàgbọ́ àwọn kan ni pé ọ̀run ni Párádísè wà. Àwọn míì sì gbà gbọ́ pé ó di ọjọ́ iwájú kí Ọlọ́run tó dá Párádísè sórí ilẹ̀ ayé.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Orí ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run dá Párádísè àkọ́kọ́ sí. Torí náà, ó ṣe kedere pé orí ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbé. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí ilẹ̀ ayé wà títí láé. (Sáàmù 104:5) Bíbélì tún sọ pé: “Ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”—Sáàmù 115:16.
Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé Párádísè máa wà lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run yóò fún gbogbo àwọn èèyàn tó máa gbé nínú Párádísè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àlàáfíà àti ìṣọ̀kan máa jọba láàárín àwa èèyàn. Ìrora àti ìyà kò ní sí mọ́. A máa gbádùn gbogbo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.—Aísáyà 65:21-23.
“Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, . . . ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Àwọn wo ló máa gbé nínú Párádísè?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ọ̀pọ̀ ìsìn ló máa ń kọ́ àwọn èèyàn pé àwọn ẹni rere nìkan ló máa wà nínú Párádísè. Ṣùgbọ́n, oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn máa ń sọ nípa irú ẹni tá a lè pè ní ẹni rere. Àwọn míì gbà pé táwọn bá ti ń ṣe ìsìn déédéé, táwọn sì ń gba àdúrà àkọ́sórí, àwọn ti di ẹni rere nìyẹn.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ pé “àwọn olódodo” ló máa gbé nínú Párádísè. Àmọ́ irú àwọn èèyàn wo ni Ọlọ́run kà sí olódodo? A ò lè sọ pé ẹni tó ń ṣe ìsìn déédéé àmọ́ tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ.” (1 Sámúẹ́lì 15:22) Ká má fọ̀rọ̀ gùn, àwọn olódodo tó máa gbé títí láé nínú Párádísè làwọn tó bá ń ṣe ohun tí òfin Ọlọ́run sọ bó ṣe wà nínú Bíbélì.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Kéèyàn máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ kọjá ká kàn máa ṣe ẹ̀sìn déédéé. Ohun tó o bá ń ṣe lójoojúmọ́ lè múnú Ọlọ́run dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́. Tó o bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, àfi kó o máa ka Bíbélì. Kò sì ṣòro rárá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́. Bíbélì sọ pé “àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Inú Ọlọ́run máa dùn láti san ọ́ lẹ́san iṣẹ́ rere rẹ bó o ṣe ń pa òfin rẹ̀ mọ́, yóò sì mú ọ dénú Párádísè.
“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.