Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Bọ̀ Wá Dáa?

Kí Ló Ń Bọ̀ Wá Dáa?

Kí Ló Ń Bọ̀ Wá Dáa?

“Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè.”

“Kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”

“Ikú kì yóò . . . sí mọ́.”

ÀWỌN ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí lè dà bí àsọdùn lásán. Àmọ́, ó dá wa lójú pé wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ àsọdùn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé àwọn ìlérí yìí yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ìlérí tí kò ṣeé gbára lé táwọn olóṣèlú sábà máa ń ṣe, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn kò lágbára láti tún ayé yìí ṣe. Inú Bíbélì la ti rí àwọn ọ̀rọ̀ tá a kọ sókè yìí. a

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé ìwé àtijọ́ kan tí kò bá ìgbà mu ni Bíbélì. Ṣé ohun tí ìwọ náà gbà gbọ́ nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò ṣe gbìyànjú láti túbọ̀ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Bíbélì ni ìwé mímọ́ kan ṣoṣo tó sọ ìtàn ẹ̀dá èèyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Ó ṣàlàyé nípa:

● Bí ìran èèyàn ṣe kó sínú wàhálà.—Róòmù 5:12.

● Ohun tí Ọlọ́run ṣe láti fi yanjú ìṣòro náà.—Jòhánù 3:16.

● Ìdí tí àwọn ìjọba kò fi lè tún ayé yìí ṣe.—Jeremáyà 10:23.

● Ìdí tá a fi lè gbára lé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa tún ayé ṣe.​—Jóṣúà 23:14.

Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run máa fòpin sí ebi, ogun, àìsàn àti ikú tó ń pa aráyé? Kò lè ṣòro fún ẹ láti gbà pé ó máa ṣe é, tó o bá gba àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí gbọ́:

1. Ọlọ́run ló dá wa.

2. Ọlọ́run bìkítà fún wa.

3. Ọlọ́run lágbára láti tún ayé ṣe.

4. Ó ti ṣètò bó ṣe máa tún ayé yìí ṣe.

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu pé ká gba ọ̀rọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí gbọ́? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ìwọ náà lè mọ̀ nípa ohun tá a sọ yìí.

Bóyá o tiẹ̀ ní Bíbélì tó o máa ń kà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí o kì í ráyè kà á rárá. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ka Bíbélì ló sọ pé kò yé àwọn dáadáa. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n wá kọ́ ẹ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló ń jàǹfààní ètò ẹ̀kọ́ yìí. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é?

Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹnì kan tàbí méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè wá sí ilé rẹ tàbí ibòmíì tó o bá fẹ́ láti wá bá ọ jíròrò nípa Bíbélì láìgba kọ́bọ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn máa jẹ́ kó o lè dáhùn àwọn ìbéèrè bíi, Kí nìdí tá a fi ń jìyà? Kí nìdí táwọn ìjọba èèyàn kò fi lè tún ayé ṣe? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe máa ṣe ohun tí ìjọba èèyàn kò lè ṣe? b

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè jàǹfààní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o lọ wo Ìkànnì wa, ìyẹn www.isa4310.com. O sì lè kọ̀wé sí èyí tó o bá fẹ́ lára àwọn àdírẹ́sì tó wà lójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ọ̀rọ̀ tá a kọ sókè yìí wà nínú ìwé Aísáyà 2:4; Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:4.

b Tún ka àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ta Ló Lè Bá Wa Tún Ayé Ṣe?” ní ojú ìwé 26 àti 27 nínú ìwé yìí.