Bí O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Bí O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
● Ohun tí ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! kọ́ wa nìyẹn. Lára àwọn àkòrí tó fani mọ́ra nínú ìwé náà ni, “Ọlọ́run Ń Pè Ọ́ Pé Kí O Wá Di Ọ̀rẹ́ Òun” àti “Ọlọ́run Lọ̀rẹ́ Tó Dára Jù Lọ Tóo Lè Ní.” À ṣe ìwé yìí láti ran àwọn tó bá kà á lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì.
Nínú àkòrí náà “Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Gbé Inú Párádísè,” ìwé náà ṣàlàyé kedere nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ayé. Àmọ́, tá a bá fẹ́ gbádùn Párádísè tí Bíbélì ṣèlérí, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa sin òun. Àwọn àkòrí bíi, “Bí O Ṣe Lè Rí Ẹ̀sìn Tòótọ́” àti “Kọ Ẹ̀sìn Èké Sílẹ̀!” yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kó o sì lè rí ojú rere rẹ̀. Ó dájú pé o máa jàǹfààní gan-an tó o bá ka ìwé yìí.
Tó o bá fẹ́ kí ẹnì kan máa wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó o sì fẹ́ gba ẹ̀dà ìwé yìí, kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.