Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ Orúkọ Ọlọ́run

Wọ́n Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ Orúkọ Ọlọ́run

Wọ́n Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ Orúkọ Ọlọ́run

● Tó o bá rìn yíká erékùṣù Orleans, tó rẹwà gan-an, nítòsí ìlú Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà, wàá rí i pé àwọn tó tẹ erékùṣù yẹn dó kì í fọ̀rọ̀ ìjọsìn ṣeré rárá. Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ọ̀nà tó yí erékùṣù náà ká, wàá rí àwọn ilé ìjọsìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́, tó ń jẹ́ kéèyàn rántí àwọn ohun àtijọ́. Àdúgbò kọ̀ọ̀kan ló ní ṣọ́ọ̀ṣì tirẹ̀.

Ṣọ́ọ̀ṣì àtijọ́ tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ ní ìlú Quebec, tí wọ́n ti kọ́ láti ọdún 1717, wà ní àgbègbè Saint-Pierre. Wọ́n ti sọ ṣọ́ọ̀ṣì náà di ibi tí wọ́n ń kó àwọn iṣẹ́ ọnà sí, ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sì wà nínú rẹ̀. Wọ́n kọ àwọn lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run tá a rí nínú Bíbélì, ìyẹn Jèhófà, sí òkè pèpéle tó wà nínú ilé náà.

Lóde òní, bóyá ni èèyàn lè gbọ́ kí wọ́n pe orúkọ Ọlọ́run nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ká rí i kí wọ́n kọ ọ́ síbẹ̀. Kódà, ìsọfúnni kan tí àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì gbé jáde lọ́dún 2008 sọ pé, póòpù ti fún wọn ní ìtọ́ni pé “wọn kò gbọ́dọ̀ lo” orúkọ Ọlọ́run, wọn kò sì gbọ́dọ̀ “pe” orúkọ náà nínú ìjọ Kátólíìkì nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìsìn, tí wọ́n bá ń kọrin tàbí tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Àmọ́, Bíbélì sọ ní kedere pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká ‘polongo orúkọ òun ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’—Ẹ́kísódù 9:16.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé, ṣíṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí kọjá kéèyàn wulẹ̀ kọ orúkọ Ọlọ́run sínú ilé kan. Kárí ayé, wọ́n máa ń lo ohun tó ju bílíọ̀nù kan ààbọ̀ wákàtí lọ, ní ọdọọdún, lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe. Kódà, wọ́n ti dá orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, pa dà sí ibi tó yẹ kó wà. Nínú Bíbélì tí wọ́n ṣe jáde, ìyẹn Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ náà Jèhófà fara hàn níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà gẹ́lẹ́ nínú èdè tí wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì. Ní báyìí, iye Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun tí wọ́n ti tẹ̀ jáde, yálà lápá kan tàbí lódindi ti lé ní mílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́jọ [165,000,000], ní èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83]. Ká sòótọ́, tọ́rọ̀ bá kan lílo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, kò yẹ ká máa ronú pé, Kí nìdí tá a fi ń lò ó? Àmọ́ ohun tó yẹ ká máa bi ara wa ni pé, Kí nìdí tí a fi lò ó?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ó ti di èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] tí wọ́n ti fi tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun nínú èyí tí orúkọ náà, Jèhófà ti fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà