Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Amòfin Kan Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Amòfin Kan Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Amòfin Kan Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

AGBẸJỌ́RÒ kan tó ń jẹ́ Les Civin tó tún jẹ́ ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ àwọn amòfin kan ní orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Ohun tí mo mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò pọ̀ rárá. Kí nìdí tó fi ṣèwádìí nípa ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Lẹ́yìn àyẹ̀wò náà, kí ló wá sọ nípa àwọn ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Ohun tó sọ fún àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn Jí! rèé:

Inú ẹ̀sìn wo ni wọ́n bí ẹ sí?

Inú ẹ̀sìn Júù ni wọ́n bí mi sí, àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn ọdún 1970, mo fẹ́ Carol tó jẹ́ ọmọ ìjọ Áńgílíkà. Ìyàwó mi kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn rárá, ẹ̀sìn tá à ń ṣe kò sì ní ipa kankan nígbèésí ayé wa. Àmọ́, nígbà tí ọmọkùnrin wa tó ń jẹ́ Andrew pé ọmọ ọdún mẹ́jọ, ìyàwó mi sọ pé ó yẹ ká fojú ọmọ náà mọ ẹ̀sìn kan. Olùkọ́ ẹ̀sìn Júù kan sọ fún mi pé bí ìyàwó mi bá lè ṣe ẹ̀sìn Júù, ọmọ wa á tipa báyìí di ẹlẹ́sìn Júù, wọ́n á sì ṣe ààtò ẹ̀sìn kan tí wọ́n máa ń ṣe fún ọmọkùnrin ẹlẹ́sìn Júù fún un tó bá pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ààtò yìí ni wọ́n ń pè ní Bar Mitzvah. Torí náà, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ a bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kan tó dá lé bí ìyàwó mi àti ọmọ wa ṣe máa di ẹlẹ́sìn Júù.

Báwo lo ṣe mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ti wá sílé wa, ńṣe ni mo máa ń dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. Ohun tí mo máa ń sọ fún wọn ni pé “Ẹlẹ́sìn Júù ni mí, mi ò sì gba Májẹ̀mú Tuntun gbọ́.” Nígbà tó yá, ìyàwó mi sọ fún mi pé òun ní ọ̀rẹ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì mọ Bíbélì dáadáa. Ìyàwó mi wá sọ pé á dáa ká mọ Bíbélì sí i. Mi ò fi gbogbo ara gbà pé ká ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ mo ṣáà gbà pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Bawo lo ṣe rí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn sí?

Ńṣe ló rẹ̀ mí ní ipò wálẹ̀. Emi tí mo ti wá túbọ̀ gba ẹ̀sìn Júù gan-an, tí mo sì gbà pé mo jẹ́ ara ìràn tí Ọlọ́run yàn. Mo ronú pé, ‘Kí làwọn aráabí yìí fẹ́ kọ́ mi?’ Nígbà ìjíròrò àkọ́kọ́ pẹ̀lú ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá sílé wa, mo sọ fún un pé: “Inú Ẹ̀sìn Júù ni wọ́n bí mi sí. Mo ti rí ẹ̀sìn tèmi, inú ẹ̀sìn Júù ni mo sì máa kú sí. Kò sí ohun tó o lè sọ tó lè mú kí n yí pa dà.” Ọkùnrin náà kò bá mi jiyàn rárá. Torí náà, ní alaalẹ́ Friday àti Monday a máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Júù, tó bá sì di ọjọ́ Sunday (bí mi ò bá ríbi yẹ̀ ẹ́ sí) a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba owó fún ẹ̀kọ́ Bíbélì, àmọ́ a máa ń san owó fún ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ní Sínágọ́gù.

Bíbélì tá à ń lò nínú ẹ̀sìn Júù ni èmi ń lò, torí mo rò pé ìtumọ̀ Bíbélì tó bá èrò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mu ni wọ́n ń lò. Àmọ́, ó yà mí lẹ́nu pé kò sí ìyàtọ̀ nínú Bíbélì tiwọn àti tèmi. Èyí gan-an ló tiẹ̀ wá mú kí n pinnu pé màá fi yé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń sọ rárá.

Lẹ́yìn tá a ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ olùkọ́ ẹ̀sìn Júù fún ìgbà díẹ̀, ìyàwó mi sọ fún mi pé, lérò ti òun, olùkọ́ ẹ̀sìn Júù yẹn kò mọ Bíbélì dáadáa. Ó wá sọ pé òun ò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Júù mọ́ àti pé òun gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi. Ọ̀rọ̀ yìí bí mi nínú débi tí mo fi ronú pé àfi kí àwa méjèèjì kọra wa sílẹ̀. Àmọ́, nígbà tí ara mi wá balẹ̀, mo ronú nípa ọgbọ́n míì tí màá lò, mo pinnu pé màá lo ìmọ̀ tí mo ní nípa òfin láti jẹ́ kí ìyàwó mi mọ̀ pé àwọn ‘agbawèrèmẹ́sìn’ tí wọ́n pe ara wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí kò tọ̀nà.

Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

Olùkọ́ ẹ̀sìn Júù kan fún mi ní ìwé kan tó dá lórí pé Jésù kì í ṣe Mèsáyà. Ọdún kan àbọ̀ ni èmi àtìyàwó mi fi kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà pa pọ̀. Lásìkò yìí, a ṣì tún ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà nínú ìwé rábì náà, ara mi kì í balẹ̀ mọ́. Ohun tó wà nínú ìwé yẹn yàtọ̀ sí ti Bíbélì pátápátá, ìwé yẹn sọ pé Jésù Kristi kọ́ ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ń tọ́ka sí, àmọ́ léraléra ni Bíbélì ń fi hàn pé Jésù Kristi nìkan ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ń tọ́ka sí. Ọ̀rọ̀ náà wá dójú ẹ̀ nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 9:24-27, èyí tó sọ pé Mèsáyà máa fara hàn ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. a Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ wá fún wa ní Bíbélì lédè Hébérù, èyí tí wọ́n fi èdè Gẹ̀ẹ́sì túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù kọ̀ọ̀kan tó wà nínú rẹ̀. Mo wo àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, mo sì ṣe àwọn ìṣirò àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà lẹ́sẹẹsẹ, mo wá sọ pé: “Mo rí i pé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń sọ̀ nípa rẹ̀. Báwo nìyẹn wá ṣe kan Jésù?”

Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn wá sọ fún mi pé: “Ọdún yẹn ni Jésù ṣe ìrìbọmi.”

Ọ̀rọ̀ yìí yà mí lẹ́nu gan-an ni! Ẹnu tún yà mí láti rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe péye tí wọ́n sì bára mu láìkù síbì kan.

Kí làwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣe nígbà tí wọ́n rí i pé o ti yí èrò rẹ pa dà?

Ọ̀rọ̀ yìí dun àwọn kan lára wọn, wọ́n sì ṣèlérí fún mi pé àwọn máa mú èmi àti ìyàwó mi lọ sọ́dọ̀ àwọn tó máa jẹ́ ká rí i pé ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ra wá níyè. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ra wá níyè, kàkà bẹ́ẹ̀ ìwádìí tá a fẹ̀sọ̀ ṣe àti bá a ṣe ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé òótọ́ ni wọ́n ń sọ.

Kí ló mú kó o pinnu láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Mo kọ́kọ́ máa ń lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìyàwó mi. Nígbà yẹn, ìyàwó mi ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. b Ó wú mi lórí gan-an bí gbogbo wọn ṣe ń kí ara wọn pẹ̀lú ọ̀yàyà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọmọ ìlú kan náà. Kò sí irú nǹkan báyìí nínú ẹ̀sìn tèmi. Torí náà, lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ sí i fún ọdún mẹ́ta, mo ṣe ìrìbọmi.

Báwo ló ṣe rí lára rẹ ní báyìí tó o ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ohun iyì ló jẹ́ fún mi láti sọ pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.” Àmọ́, nígbà tí mo bá rántí bí mo ṣe tako ẹ̀kọ́ òtítọ́ nígbà kan rí, mo máa ń ronú pé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ sí àwọn ìbùkún tí mò ń rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Mi ò lè kábàámọ̀ láé pé mo di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn Ìbùkún wo lò ń rí báyìí?

Àwọn ìbùkún tí mo rí pọ̀ o. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, inú mi dùn pé mo jẹ́ ọkàn lára àwọn alàgbà tàbí olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí àti olùkọ́ nínú ìjọ tí mo wà. Bákan náà, mo tún máa ń ṣèrànwọ́ fún Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè South Africa. Àmọ́, ìbùkún tó ga jù lọ ni pé, ó dá mi lójú pé mo mọ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, mo mọ bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó, mo sì tún mọ ìdí tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó ń ṣẹlẹ̀ layé fi ń ṣẹlẹ̀.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ kà nípa àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa Mèsáyà, wo ojú ìwé 197, nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

b Carol kú lọ́dún 1994, Les Civin sì ti fẹ́ ìyàwó míì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Ẹnu . . . yà mí láti rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe péye tí wọ́n sì bára mu láìkù síbì kan