Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
Ta Ló Ṣe Iṣẹ́ Yìí?
1. Àwọn ọmọ Sébédè méjì wo ni wọ́n jẹ́ apẹja tí wọ́n sì tún jẹ́ àpọ́sítélì Jésù?
Kọ ìdáhùn rẹ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.
AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 4:21, 22.
․․․․․
2. Kí ni orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjì yòókù tí wọ́n jẹ́ apẹja?
AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 4:18.
․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa di “apẹja ènìyàn”? (Mátíù 4:19) Ọ̀nà wo lo rò pé pípẹja gidi àti pípẹja ènìyàn gbà jọra, kí sì ni ìyàtọ̀ méjèèjì?
KÍ LO MỌ̀ NÍPA ÀPỌ́SÍTÉLÌ ÁŃDÉRÙ?
3. Ọmọ ẹ̀yìn ta ni Áńdérù tẹ́lẹ̀ kó tó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
AMỌ̀NÀ: Ka Máàkù 1:4; Jòhánù 1:35-40.
․․․․․
4. Ta ni Áńdérù sọ̀rọ̀ nípa Jésù fún, kí ló sì wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
AMỌ̀NÀ: Ka Jòhánù 1:40-42.
․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Kí nìdí tó fi dára pé kó o sọ àwọn ohun tó o mọ̀ nípa Jésù fún àwọn ìbátan rẹ? Ṣùgbọ́n, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe lè rí lára àwọn kan nínú wọn?
AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 10:32-37.
NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
OJÚ ÌWÉ 3 Kí ni afọgbọ́nhùwà máa ń ṣe? Òwe 14:․․․
OJÚ ÌWÉ 8 Orúkọ wo ni Ọlọ́run fún ara rẹ̀? Sáàmù 83:․․․
OJÚ ÌWÉ 18 Kí ni “fífún ìbínú jáde” máa ń yọrí sí? Òwe 30:․․․
OJÚ ÌWÉ 22 Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ańgẹ́lì tó dẹ́sẹ̀? Júúdà:․․․
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ
1. Jákọ́bù àti Jòhánù.
2. Pétérù àti Áńdérù.
3. Jòhánù Olùbatisí.
4. Pétérù arákùnrin rẹ̀, ó sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù lẹ́yìn náà.