Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun tó ń fa Ẹ̀tanú àti Àìbánilò-Lọ́gbọọgba

Ohun tó ń fa Ẹ̀tanú àti Àìbánilò-Lọ́gbọọgba

Ohun tó ń fa Ẹ̀tanú àti Àìbánilò-Lọ́gbọọgba

“Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti ẹ̀tọ́ kọ̀ọ̀kan sì dọ́gba. Wọ́n ní ẹ̀bùn ti làákàyè àti ti ẹ̀rí-ọkàn, ó sì yẹ kí wọn ó máa hùwà sí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá.”—Abala kìíní Ìkéde Kárí Ayé fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.

BÍ ÌKÉDE yìí ṣe dáa tó, ńṣe ni ẹ̀tanú àti àìbánilò-lọ́gbọọgba túbọ̀ ń gbilẹ̀ láwùjọ. Èyí wá jẹ́ ká rí bí àkókò tá à ń gbé yìí ṣe le koko tó, àti ọṣẹ́ tí àìpé ẹ̀dá ń ṣe. (Sáàmù 51:5) Àmọ́, ìrètí ṣì wà pé àwọn nǹkan á pa dà bọ̀ sípò. Bá ò tiẹ̀ lè fòpin sí àìbánilò-lọ́gbọọgba tá à ń rí láwùjọ, olúkúlùkù wa lè mú ẹ̀tanú tó bá wà lọ́kàn wa kúrò.

Ohun tá a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ ni pé kò sẹ́ni tí ò lè ṣẹ̀tanú. Ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tanú, ìyẹn Understanding Prejudice and Discrimination sọ pé: “Lẹ́yìn tá a ti ṣèwádìí, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè sọ nípa ẹ̀tanú rèé: (1) kò sí ẹ̀dá tó ń ronú tó sì ń sọ̀rọ̀ tí kò lè ṣẹ̀tanú, (2) ó sábà máa ń gba pé kéèyàn sapá látọkàn wá, kó sì máa wà lójú fò, kó tó lè dín ẹ̀tanú kù, àti (3) béèyàn bá ń rí ìṣítí gbà déédéé, ó ṣeé borí.”

Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé ẹ̀kọ́ ni “ohun tó lágbára jù lọ” téèyàn lè fi gbógun ti ẹ̀tanú. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀kọ́ tó jíire lè jẹ́ ká mọ ohun tó ń fa ẹ̀tanú, ká mọ ibi táwa fúnra wa kù sí, á sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe bí wọ́n bá ṣe ẹ̀tanú sí wa.

Bá A Ṣe Lè Mọ Ohun Tó Ń Fa Ẹ̀tanú

Bí ohun kan bá ti yàtọ̀ sí ohun táwọn míì ń rò lọ́kàn, ẹ̀tanú lè mú kí wọ́n dojú ọ̀rọ̀ rú, kí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ gba ibòmíràn, tàbí kí wọ́n kọtí ikún sí òtítọ́. Ẹ̀tanú lè bẹ̀rẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ báwọn nǹkan ò bá lọ bó ṣe yẹ nínú ìdílé, ó sì lè bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tí kò tọ́ nípa ẹ̀yà tàbí àṣà ìbílẹ̀ àwọn míì. Nígbà míì ẹ̀wẹ̀, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ẹ̀kọ́ ìsìn èké lè fa ẹ̀tanú. Ìgbéraga sì tún máa ń fà á. Bó o ṣe ń ronú lórí àwọn kókó tá a fẹ́ jíròrò báyìí àtàwọn ìlànà míì tó jẹ mọ́ ọn, èyí tó wá látinú Bíbélì, o ò ṣe wo ibi tíwọ fúnra rẹ kù sí lórí ọ̀rọ̀ yìí, bóyá ó máa dáa kó o ṣàwọn àtúnṣe kan?

Alábàákẹ́gbẹ́. Ọlọ́run dá àwa èèyàn pé káa máa bára wa gbé pọ̀ bí ọmọ ìyá, kò sì sóhun tó burú nínú ìyẹn. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan” yóò sì ta kété sí ọgbọ́n gbígbéṣẹ́. (Òwe 18:1) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ fọgbọ́n yan ọ̀rẹ́, torí pé wọ́n máa nípa púpọ̀ lórí wa. Torí náà, àwọn òbí tó gbọ́n máa ń fẹ́ mọ àwọn tọ́mọ wọn ń bá kẹ́gbẹ́. Ìwádìí fi hàn pé báwọn ọmọ tí ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́ta lọ bá kíyè sí báwọn míì ṣe ń hùwà, bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, àti bí wọ́n ṣe ń ṣe, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra àwọn ẹ̀yà kan. Àmọ́ ṣá o, àwọn òbí fúnra wọn gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wọn láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ọmọ wọn, kí wọ́n má sì ṣe gbàgbé pé àpẹẹrẹ tiwọn ló máa nípa tó pọ̀ jù lọ lórí àwọn ọmọ, tó sì máa pinnu ohun tí wọ́n á máa hù níwà.

Kí ni Bíbélì sọ? “Tọ́ ọmọdékùnrin [tàbí ọmọdébìnrin] ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Bó o bá jẹ́ òbí, o lè bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ọ̀nà tó dáa tó sì tọ́ lójú Ọlọ́run ni mò ń darí àwọn ọmọ mi gbà? Ṣé àwọn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún mi ni mò ń bá kẹ́gbẹ́? Ṣé àpẹẹrẹ rere ni mo jẹ́ fáwọn míì?’—Òwe 2:1-9.

Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni túmọ̀ sí “kéèyàn jẹ́ kọ́rọ̀ orílẹ̀-èdè ẹni jẹni lógún débi táá fi máa gbé orílẹ̀-èdè kan ga ju àwọn yòókù lọ, táá sì máa fìgbà gbogbo gbé àṣà àtàwọn nǹkan tó jẹ mọ́ orílẹ̀-èdè tiẹ̀ ga ju ti orílẹ̀-èdè yòókù lọ.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Ivo Duchacek, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò òṣèlú, sọ nínú ìwé rẹ̀ náà, Conflict and Cooperation Among Nations pé: “Ńṣe ni ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni máa ń pín àwọn èèyàn sí ẹgbẹẹgbẹ́ tí èrò wọn ò ṣọ̀kan, tí wọn kì í sì í gbà fúnra wọn. Nítorí èyí, àwọn èèyàn kọ́kọ́ máa ń ronú gẹ́gẹ́ bí ará Amẹ́ríkà, ará Rọ́ṣíà, ará Ṣáínà, ará Íjíbítì, tàbí ọmọ orílẹ̀-èdè Peru, kí wọ́n tó wá ronú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, ìyẹn bí wọ́n bá tiẹ̀ máa ronú bí èèyàn rárá.” Ẹnì kan tó jẹ́ Ọ̀gá àgbà àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́lẹ̀ rí, sọ pé: “Ìwà tí kò dáa ló fa ọ̀pọ̀ ìṣòro tá a ní lóde ìwòyí, ọ̀pọ̀ ò sì fura tó fi wọlé sí wọn lára. Lára irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ni èrò ọmọdé táwọn kan máa ń ní nípa orílẹ̀-èdè wọn, pé ‘kò sórílẹ̀-èdè tó dà bíi tàwọn, yálà ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lorílẹ̀-èdè wọn dáa tàbí kò dáa.’”

Kí ni Bíbélì sọ? “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [gbogbo aráyé] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Bi ara rẹ pé, ‘Bó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, tó kó èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́ra, títí kan èmi, ṣé kò wá yẹ kí n sapá láti fára wé e, pàápàá jù lọ bí mo bá gbà pé mo ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un?’

Ẹ̀yà tèmi lọ̀gá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè kan ṣe sọ, àwọn tó ń sọ pé ẹ̀yà tàwọn lọ̀gá gbà gbọ́ pé “nítorí ẹ̀yà táwọn èèyàn ti wá ni ìwà wọn tàbí ohun tí wọ́n lè gbé ṣe fi yàtọ̀ síra àti pé ẹ̀yà kan sàn ju ẹ̀yà mìíràn lọ.” Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia, ṣe sọ àwọn tó ń ṣèwádìí “ò tíì ṣàwárí ohunkóhun tó bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu tó fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n ń sọ pé ẹ̀yà kan sàn ju ẹ̀yà míì lọ.” Onírúurú ìwà ìrẹ́jẹ tó bùáyà tí èrò pé ẹ̀yà tẹni lọ̀gá ń gbé lárugẹ, èyí tó ń mú káwọn èèyàn máa dọ́gbọ́n fẹ̀tọ́ du ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ wọn, tún jẹ́ ẹ̀rí tí ń bani nínú jẹ́ pé irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ ló wà nídìí èrò yìí.

Kí ni Bíbélì sọ? “Òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) “Láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 17:26) “Kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo gbogbo èèyàn ni mo fi ń wò wọ́n? Ǹjẹ́ mo máa ń sún mọ́ àwọn kan lára àwọn tó tinú ẹ̀yà tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míì wá, kí n lè mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an?’ Bá a bá sún mọ́ àwọn èèyàn ká bàa lè mọ̀ wọ́n dáadáa, á rọrùn fún wa láti mú èrò búburú tá a ní nípa wọn kúrò.

Ẹ̀sìn. Ìwé kan tó ń jẹ́ The Nature of Prejudice sọ pé: “Báwọn èèyàn bá ń fi ẹ̀sìn wọn ṣe bojúbojú kí wọ́n lè fi hàn pé kò sóhun tó burú nínú [ṣíṣe tinú wọn], tí wọ́n sì ń gbé ẹ̀yà wọn lárugẹ, ohun tí kò tọ́ ló máa ń yọrí sí. Bí ẹ̀sìn ṣe máa ń dá ẹ̀tanú sílẹ̀ nìyẹn.” Ìwé náà wá sọ síwájú sí i pé, ohun tó gbàfiyèsí jù lọ ni bó ṣe máa ń ‘dà bíi pé ó rọrùn fún ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn láti fi ẹ̀tanú rọ́pò ìtara ẹ̀sìn.’ Ẹ̀rí èyí la rí nínú bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ò ṣe fàyè gba ẹ̀yà míì, bí ẹ̀ya ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe ń kórìíra ara wọn tí wọ́n sì ń hùwà ipá, àti bí ìsìn ṣe ń ti àwọn èèyàn lẹ́yìn láti hùwà ìkà tó burú jáì.

Kí ni Bíbélì sọ? “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè [látọ̀dọ̀ Ọlọ́run] . . . lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, . . . kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú.” (Jákọ́bù 3:17) “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́ [tí ẹ̀sìn fi kọ́ni].” (Jòhánù 4:23) “Ẹ . . . nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín” kẹ́ ẹ sì “máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ẹ̀sìn mi ń kọ́ mi láti ní ojúlówó ìfẹ́ fún gbogbo èèyàn, tó fi mọ́ àwọn tó bá fẹ́ ṣèpalára fún mi pàápàá? Ṣé onírúurú èèyàn ló lè wá sí ṣọ́ọ̀ṣì mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá àti àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra, yálà wọ́n jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tálákà tàbí ọlọ́rọ̀, tàbí ipò yòówù kí wọ́n wà láwùjọ?’

Ìgbéraga. Ìgbéraga máa ń mú kéèyàn jọra ẹ̀ lójú tàbí kó máa ṣe fọ́ńté, kò sì ní pẹ́ sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́tanú. Bí àpẹẹrẹ, ìgbéraga lè mú kéèyàn máa rò pé òun sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ tàbí kó kórìíra àwọn tí ò kàwé tó o tàbí tí wọ́n jẹ́ aláìní. Ó tún lè mú kó fẹ́ láti fara mọ́ ìpolongo èyíkéyìí tó bá ń gbé orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà tiẹ̀ lárugẹ ju tàwọn míì lọ. Àwọn tó máa ń ṣe irú ìpolongo ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ bẹ́ẹ̀, irú bí Adolf Hitler aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀, tó jẹ́ olórí ìjọba Násì, mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà ìran tó lọ́lá bíi ti orílẹ̀-èdè àwọn. Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ kó ọ̀pọ̀ èèyàn sòdí kí wọ́n lè gbo ewúro sójú àwọn tí wọ́n gbà pé ó yàtọ̀ sáwọn tàbí tí kò yẹ láwùjọ.

Kí ni Bíbélì sọ? “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Òwe 16:5) “[Ẹ má ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, . . . ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” (Fílípì 2:3) Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń dánú dùn bí mo bá gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ àpọ́nlé nípa ẹ̀yà tàbí ìlú tí mo ti wá, tí wọ́n sì ń fẹnu ba ẹ̀yà tàbí ìlú mìíràn jẹ́? Ṣé mo máa ń jowú àwọn tó bá lẹ́bùn tí mi ò ní, àbí inú mi máa ń dùn sí ohun tí wọ́n lágbára láti ṣe?’

Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Torí náà, máa fojú tó ṣeyebíye wo ọkàn-àyà rẹ, má sì ṣe jẹ́ kí ohunkóhun bà á jẹ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, fi ọgbọ́n Ọlọ́run kọ́ ọ. Lẹ́yìn ìgbà yẹn nìkan ni ‘agbára láti ronú àti ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà.’—Òwe 2:10-12.

Àmọ́, kí lo lè ṣe báwọn èèyàn bá ń ṣe ẹ̀tanú sí ẹ tàbí tí wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mẹ́rẹ̀? Ọ̀rọ̀ tí àpilẹ̀kọ tó kàn dá lé nìyẹn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Bá a bá sún mọ́ àwọn èèyàn ká bàa lè mọ̀ wọ́n dáadáa, á rọrùn fún wa láti mú èrò búburú tá a ní nípa wọn kúrò