Ṣé Ọlọ́run Ṣojúure Sáwọn Orílẹ̀-èdè Kan Ju Àwọn Míì Lọ ni?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ọlọ́run Ṣojúure Sáwọn Orílẹ̀-èdè Kan Ju Àwọn Míì Lọ ni?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló ń rò pé Ọlọ́run ṣojúure sí orílẹ̀-èdè àwọn ju àwọn orílẹ̀-èdè míì lọ. Bó bá sì di pé kí wọ́n mú ẹ̀rí wá, kí ni wọ́n máa ń rí sọ? Àwọn kan lè sọ nípa àwọn ohun ribiribi tí orílẹ̀-èdè wọn ti gbé ṣe, irú bíi bí wọ́n ṣe máa ń kó ẹrú kó ẹrù lójú ogun tàbí bí ọrọ̀ ajé wọn ṣe ń búrẹ́kẹ́. Kódà, wọ́n lè tọ́ka sí àwọn ètò mímúná dóko tí wọ́n ti ṣe láti máa foúnjẹ bọ́ àwọn tí ebi ń pa, láti máa dáàbò bo àwọn tí nǹkan ò rọgbọ fún, tàbí láti máa rí sí i pé àwọn èèyàn gba ẹ̀tọ́ wọn, kò sì sí ìrẹ́jẹ. Àwọn míì máa ń sọ pé níní tí ìlú ìbílẹ̀ àwọn lẹ́wà jọjọ, fi hàn pé àwọn rí ojúure Ọlọ́run.
Kò sí ibi tí irú gààrù bẹ́ẹ̀ nípa orílẹ̀-èdè ẹni ò sí. Síbẹ̀, ṣé ó wà nínú Bíbélì pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba orílẹ̀-èdè kan ju orílẹ̀-èdè mìíràn lọ?
Ànímọ́ Pàtàkì Kan Tí Ọlọ́run Ní
Ìdáhùn náà á ṣe kedere bá a bá lóye ànímọ́ pàtàkì kan tí Bíbélì tẹnu mọ́ gbọnmọgbọnmọ pé Ọlọ́run Olódùmarè ní. Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Bí àpẹẹrẹ, Ìṣe 10:34 sọ ní kedere pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” Bíbélì tún sọ pé Jèhófà Ọlọ́run “kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò” àti pé “kò sí àìṣòdodo tàbí ojúsàájú . . . lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.” (Diutarónómì 10:17; 2 Kíróníkà 19:7) Ọlọ́run kórìíra ojúsàájú; àìṣòdodo ló tiẹ̀ kà á sí.
Àmọ́ ṣá o, o lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣebí Ọlọ́run ṣojúure sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì ju àwọn orílẹ̀-èdè míì lọ? Ṣé àpẹẹrẹ ojúsàájú kọ́ nìyẹn?’ Lóòótọ́ ni Ọlọ́run yan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láàyò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó sì dáàbò bò wọ́n nínú àwọn ogun kan tí wọ́n bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jà. Láfikún sí ìyẹn, Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ó ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jékọ́bù, ó ń sọ àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn.” (Sáàmù 147:19, 20) Ṣé a lè sọ pé olójúsàájú ni Ọlọ́run nítorí ọ̀nà tó gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò? Ó tì o. Ìdí mẹ́ta rèé tí a kò fi lè sọ bẹ́ẹ̀.
Àkọ́kọ́ ni pé Ọlọ́run ya orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ́tọ̀ kó bàa lè bù kún gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó bá Ábúráhámù, baba ńlá orílẹ̀-èdè náà, dá májẹ̀mú nípa sísọ pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Bẹ́ẹ̀ ni, ìdí tí Ọlọ́run fi ń bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lò ni kó bàa lè mú “irú-ọmọ” kan jáde nípasẹ̀ ẹni tí ìbùkún ńláǹlà yóò gbà wá fún “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé,” kì í ṣe fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo nìkan.
Kókó kejì, ìbùkún Ọlọ́run ò fìgbà kan rí mọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ọlọ́run ò ṣe ojúsàájú, nítorí pé ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún olúkúlùkù èèyàn láti orílẹ̀-èdè míì láti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì jọ máa sin òun. (2 Kíróníkà 6:32, 33) Ọ̀pọ̀ tó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ rí ìbùkún gbà. Àpẹẹrẹ irú ẹ̀ kan, tí gbogbo wa mọ̀ bí ẹní mowó ni ti obìnrin ará Móábù náà, Rúùtù.—Rúùtù 1:3, 16.
Ẹ̀kẹta, ìgbà díẹ̀ ni àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tó wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tara wà fún. Lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi, tó jẹ́ “irú ọmọ” tá a sọ tẹ́lẹ̀ náà jáde wá láti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Gálátíà 3:16) Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú Jésù kọ̀ ọ́ ní Mèsáyà. Ó sọ fún wọn pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:38) Látìgbà náà wá, aráyé lódindi ni Ọlọ́run ń bá lò kì í ṣe orílẹ̀-èdè pàtó kan, kò sì tún ní nǹkan ṣe pẹ̀lú rògbòdìyàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Kàkà bẹ́ẹ̀, jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú ti mú kó nawọ́ ìbùkún sí gbogbo aráyé. Jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Ẹ̀bùn Tí Ọlọ́run Fún Gbogbo Èèyàn
Ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ni ẹ̀bùn títóbi jù lọ tí Ọlọ́run fún aráyé. (Róòmù 6:23) Ẹbọ náà pèsè ọ̀nà àbájáde fún wa kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ó sì ti fún olúkúlùkù wa ní àǹfààní láti jogún ìyè ayérayé. Olúkúlùkù èèyàn “láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” ni ẹ̀bùn yìí wà fún. (Ìṣípayá 5:9) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run fẹ́ kí “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́” nínú Jésù ní “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún àwọn tó bá tẹ́tí sí i. (Ìṣípayá 14:6, 7) Ó mú ká nírètí nípa ọjọ́ iwájú, ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó lè mú kéèyàn máa gbé ìgbé ayé tó túbọ̀ láyọ̀ nísinsìnyí. Nítorí pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ó ti ṣètò pé ká “wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 16:10) Ìhìn rere yẹn wà nínú Bíbélì, ìwé kan tá a lè rí ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọ̀ọ́dúnrún lọ, ì báà tiẹ̀ máà jẹ́ lódindi. Gẹ́gẹ́ bíi Baba onífẹ̀ẹ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó wà láyé ni Jèhófà ń mú kó gbọ́ “àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 6:68; Jóṣúà 1:8.
Ìwọ̀nyí àtàwọn ẹ̀bùn míì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló wà fún gbogbo wa, àní fún àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti àwùjọ èdè. Nítorí náà, ibi tí wọ́n bíni sí àti ibi téèyàn ti ṣẹ̀ wá ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú rírí ojúure Ọlọ́run.
Àwọn Wo Ni Ọlọ́run Ṣojúure Sí?
Nígbà náà, kí wá ló yẹ ká ṣe ká bàa lè rí ojúure Ọlọ́run? Ìdáhùn tí àpọ́sítélì Pétérù fún wa ni pé: “Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ó ṣe kedere pé, wíwulẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní ṣákálá kò tó. A gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ àtọkànwá fún Ọlọ́run, ká sì máa bẹ̀rù láti má ṣe mú un bínú. A tún gbọ́dọ̀ máa “ṣiṣẹ́ òdodo,” tàbí ká máa fi gbogbo ará lépa àtimáa ṣe ohun tó bá dára lójú Ọlọ́run.
Àpèjúwe kan rèé: Ìjọba dá ilé ìwé sílẹ̀ fún gbogbo èèyàn, ṣùgbọ́n kìkì àwọn tó bá ń lọ kàwé níléèwé tí wọ́n sì fára wọn fún ohun tí wọ́n ń kọ́ ló máa jàǹfààní. Bákan náà, gbogbo wa ni Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà, ṣùgbọ́n àwa náà gbọ́dọ̀ sapá tiwa. Irú ìsapá bẹ́ẹ̀ á ní nínú, kíka Bíbélì déédéé, lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, àti gbígbé ìgbé ayé tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Bá a bá ń “wá Jèhófà” nítòótọ́, a óò rí i pé ipa ọ̀nà tí yóò mú ká rí ojúure Ọlọ́run là ń tọ̀.—Sáàmù 105:3, 4; Òwe 2:2-9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọlọ́run ti mú kí àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè gbọ́ “àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun”