Wíwo Ayé
Wíwo Ayé
Ẹni Bá Sùn Dáadáa A Lè Tètè Yanjú Ìṣòro
Ìwé ìròyìn The Times ti ìlú London sọ pé: “Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé ìṣòro téèyàn ò bá lè yanjú kéèyàn tó lọ sùn á ti rọjú tí ilẹ̀ bá fi máa mọ́. Ṣe ló máa dà bíi pé ọpọlọ ti ń wá ojútùú sí i kílẹ̀ tó mọ́.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nílẹ̀ Jámánì sọ pé àwọn ti rí ẹ̀rí pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí báyìí. Wọ́n tẹ àbájáde àwárí wọn sínú ìwé ìròyìn Nature. Wọ́n kọ́ àwọn mẹ́rìndínláàádọ́rin kan tó yọ̀ọ̀da ara wọn ní ọ̀nà méjì tí wọ́n lè gbà dáhùn ìbéèrè kan lórí ìṣirò, ṣùgbọ́n wọn ò sọ ọ̀nà kẹta tó yá jù láti rí ìdáhùn fún wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní káwọn kan lára wọn lọ sùn, wọ́n sì ní káwọn tó kù dá oorun mọ́jú tí ilẹ̀ á fi mọ́ tàbí kí wọ́n má sùn rárá bó bá dojú mọmọ títí tí ilẹ̀ á fi ṣú. Nígbà tí ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti ìlú London ń sọ nípa àbájáde ìwádìí yìí, ó ròyìn pé: “Oorun ṣe gudugudu méje.” Ó sọ síwájú sí i nípa àwọn tó sùn yẹn pé, “wọ́n mọ ọ̀nà kẹta tí wọ́n lè gbà dáhùn ìbéèrè náà dáadáa ju àwọn tí kò sùn lọ.” Láti rí i dájú pé kì í ṣe nítorí pé wọ́n jẹ́ káwọn tó sùn sinmi, kára wọn sì balẹ̀ ni wọn fi rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ṣe ìwádìí kejì. Wọ́n bi àwùjọ méjèèjì ní ìbéèrè kejì yìí lówùúrọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sùn mọ́jú, tàbí lálẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti fi gbogbo ojúmọmọ wà láìsùn. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣèyí tán, wọn ò rí ìyàtọ̀ kankan nínú ìṣesí àwùjọ méjèèjì. Bí ìwé ìròyìn The Times ṣe sọ, èyí fi hàn pé, “ọpọlọ wọn tó silé lẹ́yìn tí wọ́n ti sinmi kọ́ ló mú kí wọ́n rí ìdáhùn, bí kò ṣe pé ọpọlọ wọn mú ara rẹ̀ bọ̀ sípò nígbà tí wọ́n ń sùn lọ́wọ́.” Ọ̀mọ̀wé Ullrich Wagner tó ṣe ìwádìí náà wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nípa báyìí, a lè sọ pé iṣẹ́ tí oorun ń ṣe ni pé ó ń mú kéèyàn lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa.”
Àwọn Ọmọdé Tó Ń Ra Tibí Ra Tọ̀hún
Lóde tòní, àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́langba nílẹ̀ Amẹ́ríkà “ni wọ́n fẹ́ràn àtimáa ra àwọn nǹkan tó lórúkọ ilé iṣẹ́ tó ṣe wọ́n lára jù lọ, àwọn ló wù kí wọ́n máa ra ohunkóhun tí kì í pẹ́ tán, kí wọ́n sì máa kó oríṣiríṣi nǹkan tara jọ.” Juliet Schor, tó sọ̀rọ̀ yìí jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ní ilé ìwé Boston College, ó sì ti ṣèwádìí ipa tí ríra tibí ra tọ̀hún máa ń ní lórí àwọn ọmọdé. Lára àwọn àmì téèyàn fi ń mọ̀ bó bá ti ń wu àwọn ọmọdé pé kí wọ́n máa ra oríṣiríṣi nǹkan ni “kí wọ́n máa ṣàníyàn nípa ìrísí àti àṣọ wọn, kí ìfẹ́ láti gbajúmọ̀ àti ìfẹ́ láti lọ́rọ̀ gbà wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n túbọ̀ máa wo tẹlifíṣọ̀n, kí wọ́n máa lo àkókò púpọ̀ sí i lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí wọ́n sì máa ṣeré ìdárayá orí fídíò,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Globe and Mail ti Kánádà ṣe sọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Schor rí i pé àwọn ọmọdé kan wà tọ́kàn wọn kì í kúrò lórí ohun tí wọ́n ń fẹ́ bọ̀rọ̀, irú wọn kì í sì í yé ronú pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀. “Wọ́n tún máa ń ṣàròyé nípa ara wọn, bí wọ́n sì ṣe ń rí i pé ìgbésí ayé àwọn kò dà bíi tàwọn èèyàn tí wọ́n ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú ìpolówó ọjà, wọn kì í láyọ̀.” Ìwé ìròyìn Globe wá sọ pé, ní tàwọn ọmọ tí kì í fi bẹ́ẹ̀ lé nǹkan tara, wọn kì í sábà dààmú tàbí kí wọ́n ṣàníyàn, ọkàn wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ pòrúurùu, wọ́n túbọ̀ ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, àárín àwọn àtàwọn òbí wọn sì dán mọ́rán.
Àwọn Èèyàn Ń Fòfin Má-Ta-Tẹ́tẹ́ Dera Wọn
Ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ lédè Faransé, Le Figaro, sọ pé: “Wọ́n ti fojú bù ú pé láàárín ọ̀kẹ́ márùndínlógún [300,000] sí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] èèyàn ni tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún nílẹ̀ Faransé.” Àmọ́ ṣá o, àwọn tí tẹ́tẹ́ títa di bárakú fún ti túbọ̀ wá ń mọ̀ ọ́n lọ́ràn pé àfi káwọn yáa jáwọ́ nínú ẹ̀. Ìwé ìròyìn náà sọ pé ẹgbàá mẹ́rìnlá [28,000] èèyàn nílẹ̀ Faransé ló ti mọ̀ọ́mọ̀ fòfin de ara wọn láti má ta tẹ́tẹ́ tí òfin kò dè. Bí wọ́n ṣe ṣe é ni pé wọ́n ní káwọn ọlọ́pàá fòfin de àwọn pé àwọn kò gbọ́dọ̀ lọ sílé tẹ́tẹ́ mọ́ fún ó kéré tán, ọdún márùn-ún. Àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Faransé ròyìn pé ó tó ẹgbẹ̀rún méjì sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn tó ń sọ fáwọn lọ́dọọdún pé kàwọn fòfin de àwọn, ìye náà sì ti ròkè sí i ní ìlọ́po mẹ́fà láàárín ọdún mẹ́wàá. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọn ò lè ṣe kí wọ́n má ta tẹ́tẹ́ gbà pé ńṣe ni tẹ́tẹ́ tó ti di bárakú sáwọn lára “dà bí ọ̀kan lára àìsàn tó ń fogun ja àwọn èèyàn bíi sìgá mímu, ọtí àmupara àti lílo oògùn olóró,” bí ìwé ìròyìn Le Figaro ṣe sọ.
Oògùn Èébì Ni Atalẹ̀
Ìwé ìròyìn Australian sọ pé: “Egbò atalẹ̀ kì í jẹ́ kí èébì gbéni láwọn oṣù tóyún bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dúró síni lára.” Nínú ìwádìí kan tí ilé ẹ̀kọ́ gíga University of South Australia ṣe, wọ́n rí i pé lílo bí ìdajì ṣíbí ìmùkọ atalẹ̀ lóòjọ́ máa ń dín èébì tó máa ń gbé àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lóyún láràárọ̀ kù. Atalẹ̀ làwọn kan máa ń lò sí èébì tó máa ń gbé wọn lówùúrọ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ò tíì sọ bó ṣe lágbára tó. Ìwádìí náà rí i pé iṣẹ́ kan náà tí oògùn fítámì tó ń jẹ́ vitamin B6 ń ṣe béèyàn bá ń lo ẹyọ kan rẹ̀ lóòjọ́ ni atalẹ̀ ń ṣe. Wọ́n sì sábà máa ń júwe fítámì yìí féèyàn láti lò.
Ìgbẹ̀jẹ̀sára Ń Mú Káwọn Èèyàn Tètè Kú
Wọ́n ti rí i nínú àbájáde ìwádìí ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tó jáde nínú ìwé ìròyìn JAMA pé àwọn aláìsàn tó ní ìṣòro ọkàn líle koko, tí wọ́n sì ń fa ẹ̀jẹ̀ sí lára lóòrèkóòrè lè tètè rí ikú he ju àwọn tí kì í gbẹ̀jẹ̀ sára lọ. Ìròyìn náà sọ pé: “Ọ̀ràn ikú tó wé mọ́ ìgbẹ̀jẹ̀sára yìí ṣì wà bẹ́ẹ̀ náà láìka irú àwọn tọ́ràn náà kàn tàbí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn nílé ìwòsàn náà sí, ìyẹn bíi kí ẹ̀jẹ̀ máa dà lára àti fífi abẹ la apá kan nínú ara tàbí kíki ohun èlò ìtọ́jú bọni nínú ara.” Àwọn dókítà tí wọ́n ṣe kòkáárí ìwádìí náà ṣàkópọ̀ ìwádìí wọn báyìí pé: “Ìkìlọ̀ wa ni pé bí aláìsàn tí àìsàn ẹ̀ ń gbọ́ ìtọ́jú bá ní àrùn ọkàn tí ẹ̀jẹ̀ dídì máa ń fà, ẹ má ṣe máa fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára déédéé nítorí kí ẹ̀jẹ̀ ara ẹ̀ lè pọ̀ tó bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ o.”
Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà Yapa Síra
Láìpẹ́ yìí ni olórí ìjọ Áńgílíkà tó wà nílùú Sydney, Philip Jensen, tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn bíṣọ́ọ̀bù tó gbajúmọ̀ jù lọ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà fẹ̀sùn kan Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti Canterbury pé “alágbèrè ẹ̀sìn tó ń fẹ̀tàn gbówó oṣù sápò ni,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà náà, The Age, ṣe sọ. Jensen dẹ́bi yìí fún olórí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ nítorí pé ọwọ́ dẹngbẹrẹ ló fi mú ọ̀rọ̀ ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Ìwé ìròyìn náà wá fi kún un pé: “Gbogbo Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà tó wà lágbàáyé ti yapa síra wọn lórí ọ̀ràn ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ọ̀pọ̀ lára ẹ̀ka ṣọ́ọ̀ṣì náà tó wà ní Áfíríkà àti Éṣíà sì ti yapa kúrò lára àwọn akẹgbẹ́ wọn tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà nítorí pé àwọn tọ̀hún fọwọ́ sí ìgbéyàwó àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Wọ́n sì ti pín gaàrí pẹ̀lú tàwọn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nítorí pé wọ́n ń yan àwọn táráyé mọ̀ sí abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ sípò bíṣọ́ọ̀bù.”
Bílíọ̀nù Kan Ọmọdé Nìyà Ń Jẹ
Ìwé ìròyìn The New York Times ròyìn pé gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń bójú tó owó àkànlò tí àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè fáwọn ọmọdé ṣe sọ, ó ju ìdajì lọ lára àwọn ọmọ tó ń gbé láyé, èyí tó lé ní bílíọ̀nù kan, tó ń ráágó. Ogun, àrùn éèdì àti òṣì ò tiẹ̀ jẹ́ kí àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn yọ rárá. Látọdún 1990 ni ogun, tí márùnléláàádọ́ta nínú wọn jẹ́ ogun abẹ́lé, ti gbẹ̀mí èèyàn tí wọ́n fojú bù pé wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta àtààbọ̀. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ọmọdé ló kó ìdajì lára wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà táwọn ìforígbárí yìí bá sì wáyé, ńṣe làwọn ọlọ̀tẹ̀ máa ń jí àwọn ọmọdé gbé, wọ́n máa ń fipá bá wọn lòpọ̀, tàbí kí wọ́n máa kó wọn jagun. Ọ̀pọ̀ ni kì í róúnjẹ jẹ rárá; ọ̀pọ̀ ìgbà sì làwọn tó ń ṣàìsàn kì í rẹ́ni tọ́jú wọn. Àwọn ọmọ tí àrùn éèdì ti sọ di aláìlóbìí ti wọ mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ́dún 2003. Àwọn ọmọdé tí wọ́n gbà sídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó lé ní mílíọ̀nù méjì. Ìròyìn náà tún wá fi kún un pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tí wọ́n ń ná sórí ohun ìjà ogun lọ́dún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ẹgbẹ̀rún kan bílíọ̀nù dọ́là báyìí, gbogbo ohun tí wọ́n nílò láti kásẹ̀ òṣì nílẹ̀ ò ju nǹkan bí ogójì sí àádọ́rin bílíọ̀nù dọ́là lọ.