Bí Ọ̀ràn Ìrìn-Àjò Afẹ́ Ṣe Máa Rí Lọ́jọ́ Iwájú
Bí Ọ̀ràn Ìrìn-Àjò Afẹ́ Ṣe Máa Rí Lọ́jọ́ Iwájú
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé káàkiri àgbáyé la ti ń rí àpẹẹrẹ ohun tó lè mú ká sọ pé pípọ̀ táwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ ń pọ̀ sí i lolórí ohun tó ń ba àyíká jẹ́.”—Ìwé An Introduction to Tourism, látọwọ́ Leonard J. Lickorish àti Carson L. Jenkins.
BÍ ÀWỌN tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ ṣe ń pọ̀ sí i báyìí, ìṣòro tí rírìnrìn-àjò afẹ́ ń mú wá ò mọ sórí bíba àyíká jẹ́ nìkan, ó tún ń fa àwọn ìṣòro míì pẹ̀lú. Ẹ jẹ́ ká yẹ díẹ̀ wò nínú àwọn ìṣòro ọ̀hún. Lẹ́yìn náà, a óò wá jíròrò bó ṣe máa ṣeé ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú láti rìnrìn-àjò afẹ́ káàkiri ayé ká sì wo àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà níbẹ̀, pàápàá àwọn èèyàn àtàtà tá a jọ wà láyé.
Àwọn Ìṣòro Tó Ń Dá Sílẹ̀ Láyìíká
Báwọn èèyàn tó ń rìnrìn-àjò ṣe ń pọ̀ sí i ti dá ọ̀pọ̀ ìṣòro sílẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Lickorish àti Jenkins, tí wọ́n jẹ́ olùṣèwádìí kọ̀wé pé: “Lórílẹ̀-èdè Íńdíà, àwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sí ibojì aláruru tí wọ́n ń pè ní Taj Mahal, tí ọba kan kọ́ ní ìrántí ìyàwó rẹ̀, ti ba ibojì náà jẹ́. Bákan náà, ogunlọ́gọ̀ tó ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ilé aboríṣóńṣó bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ onígun mẹ́rin tó wà ní Íjíbítì náà ti ń ba ilé wọ̀nyẹn jẹ́.”
Àwọn òǹkọ̀wé yìí tún kìlọ̀ pé bí kò bá sí ìlànà kan pàtó tó ń darí ìrìn-àjò afẹ́, ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn tó ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀, á máa tẹ àwọn irúgbìn tó ń hù mọ́lẹ̀, ó sì lè mú kí wọ́n kú tàbí kí wọ́n jóná mọ́lẹ̀. Bákan náà, báwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ ṣe ń lọ ṣa ìkarahun tàbí àwọn ohun tó dà bí ìlẹ̀kẹ̀ tàbí báwọn aráàlú alára ṣe ń ṣà wọ́n tà fáwọn arìnrìn-àjò, ó lè mú kí wọ́n tán nínú omi.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń bójú tó àyíká lábẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe ṣírò rẹ̀, àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ máa ń dọ̀tí àyíká, pàǹtírí tí wọ́n máa ń dà sí àyíká máa ń pọ̀ débi pé ó wúwo tó kìlógíráàmù kan. Kódà, ó dà bíi pé wọ́n máa ń da ìdọ̀tí sáwọn ibi tí kò sí nítòsí. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ tó wà fún àbójútó igbó kìjikìji, Rainforest Action Network, sọ pé: “Àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sórí òkè Himalaya ti fi pàǹtírí kún gbogbo ojú ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà lọ síbẹ̀. Bákan náà, àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sáwọn òkè gíga fíofío ti pa igbó tó wà níbẹ̀ run níbi tí wọ́n ti ń wá igi tí wọ́n á fi dáná oúnjẹ tí wọ́n á jẹ àtèyí tí wọ́n á fi se omi ìwẹ̀.”
Yàtọ̀ síyẹn, ìlòkulò làwọn tó ń rìnrìn-àjò máa ń lo àwọn àlùmọ́ọ́nì tó yẹ káwọn ará ibi tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí rí lò. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀gbẹ́ni James Mak sọ nínú ìwé rẹ̀, Tourism and the Economy, pé: “Omi táwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Grenada ń mu tó ìlọ́po méje èyí táwọn tó ń gbébẹ̀ ń mu.” Ó tún fi kún un pé: “Ní ìpínlẹ̀ Hawaii, àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ló ń lo ìdá méjì nínú márùn-ún ohun àmúṣagbára, bóyá ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà, bẹ́ẹ̀
sì rèé, ìdá mẹ́jọ àwọn ará ìpínlẹ̀ yìí ló ń rìnrìn-àjò afẹ́.”Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ lè náwó tabua nígbà tí wọ́n bá ń ṣèbẹ̀wò sáwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, èyí tó pọ̀ jù lọ lára owó náà kì í ṣe àwọn aráàlú lóore kankan. Báńkì Àgbáyé ṣírò rẹ̀ pé kò tó ìdajì lára owó tí wọ́n ń rí lórí ìrìn-àjò afẹ́ tó ń dé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń rìnrìn-àjò lọ, èyí tó pọ̀ jù lára owó yìí ló ń padà sápò àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà nítorí pé àwọn ló ni ilé iṣẹ́ tó ń ṣètò ìrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè míì, àwọn náà ló sì ni ilé táwọn arìnrìn-àjò ń dé sí.
Ìṣòro Tó Ń Dá Sílẹ̀ Láwùjọ
Àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sórílẹ̀-èdè míì láti àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà, níbi tó dà bíi pé àwọn èèyàn ti ń rọ́wọ́ mú tún máa ń dá ìṣòro míì sílẹ̀ fáwọn ará orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí. Àwọn ìṣòro náà lè fara sin tàbí kí wọ́n má fara sin, síbẹ̀ ó máa ń jẹ́ kí wọ́n kó àṣàkaṣà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń mú àwọn nǹkan tó jojú ní gbèsè dání lọ síbi tí wọ́n bá rìnrìn-àjò lọ. Ó lè ya àwọn ará ibẹ̀ lẹ́nu pé èèyàn lè máa jẹ̀gbádùn nínú ọlá tó tó báyẹn. Àwọn wọ̀nyí á sì máa fẹ́ láti ní àwọn nǹkan olówó iyebíye yìí, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn ò lè rówó rà á láìṣe pé wọ́n ṣe kọjá agbára wọn, bíi kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò tọ́.
Ọ̀gbẹ́ni Mak sọ àwọn ìṣòro tí ìyẹn lè fà, ó sọ pé táwọn èèyàn bá ń ṣe báyìí bá ìrìn-àjò afẹ́ lọ, “àwọn èèyàn lè má mọ nǹkan tí wọ́n á fi máa dá àwọn ará ìlú kan mọ̀ yàtọ̀ mọ́, á mú káwọn èèyàn máa tẹ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ lójú lórí bí wọ́n ṣe ń lo ilẹ̀ àtàwọn àlùmọ́ọ́nì tó wà níbẹ̀, á sì tún mú kí ìwà tí kò bójú mu, bí ìwà ọ̀daràn àti iṣẹ́ aṣẹ́wó, gbilẹ̀ sí i.”
Nígbà táwọn míì bá rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sí ìdálẹ̀, kò sóhun tó ń ká wọn lọ́wọ́ kò mọ́, gbogbo ohun tí wọn ò tó dán wò nílé wọn, níbi tójú àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ á ti tó wọn ni wọ́n á máa ṣe. Wàhálà ńlá ló ń bí báwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ṣe ń ṣèṣekúṣe yìí. Ọ̀gbẹ́ni Mak tọ́ka sí àpẹẹrẹ kan tá a mọ̀ dáadáa, ó sọ pé: “Gbogbo ayé ni ominú ń kọ báyìí bí wọ́n ṣe ń fi ìrìn-àjò afẹ́ bojú láti kó àwọn ọmọdé lọ ṣèṣekúṣe.” Lọ́dún 2004, ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n CNN ròyìn pé: “‘Ìṣirò kan tí kò ṣeé já ní koro fi hàn pé ó tó ẹgbàá mẹ́jọ sí ọ̀kẹ́ kan’ àwọn ọmọdé tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ‘agbègbè ibi táwọn èèyàn máa ń ṣèbẹ̀wò lọ nirú ẹ̀ sì pọ̀ sí.’”
Àǹfààní Tó Wà Nínú Rírìnrìn-Àjò
Àgbàyanu mà ni ayé wa yìí o, ohun ẹlẹ́wà tó sì ń yani lẹ́nu pọ̀ níbẹ̀ lọ jàra. Ṣé bójú ọjọ́ ṣe ń rí nígbà tóòrùn bá ń wọ̀ la fẹ́ sọ ni, àbí tàwọn ìràwọ̀ tó ń tàn tó kún ojú sánmà, àbí onírúurú irúgbìn àtàwọn ẹranko? Ibì yòówù ká máa gbé, à ń rí díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn nǹkan àgbàyanu míì tó wà nílé ayé tá a wà yìí. Síbẹ̀, ì bá mà dáa o, ká
ní ó lè ṣeé ṣe fún wa láti rìnrìn-àjò káàkiri ká lè ráwọn nǹkan àgbàyanu míì tó wà láyé!Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń gbádùn rírí tí wọ́n ń ráwọn nǹkan mèremère tó wà láyé, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú wọn sọ pé ohun táwọn gbádùn jù ni rírí táwọn ń ráwọn èèyàn míì tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tàwọn. Kì í pẹ́ tó fi máa ń yé àwọn arìnrìn-àjò pé ohun tí ò dáa táwọn gbà gbọ́ nípa àwọn ẹlòmíì tẹ́lẹ̀ kì í ṣòótọ́. Ìrìn-àjò tí wọ́n lọ báyìí ti jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye àwọn èèyàn tó jẹ́ ara ìran míì tí wọ́n sì ní àṣà tó yàtọ̀, ó sì mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ tó mọyì ara wọn.
Ẹ̀kọ́ kan táwọn arìnrìn-àjò afẹ́ kò ní gbàgbé ni pé dúkìá téèyàn ní kì í fi gbogbo ìgbà fúnni láyọ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ ni àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ìyẹn ni pé a lè mú kí àárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa máa gún régé ká sì yan àwọn ẹni tuntun lọ́rẹ̀ẹ́. Ìtàn kan wà nínú Bíbélì tó dá lórí báwọn ará Málítà, “elédè ilẹ̀ òkèèrè” ṣe fi “inú rere ẹ̀dá ènìyàn” hàn sáwọn tó rìnrìn-àjò gbabẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní ṣùgbọ́n tí ọkọ̀ wọn rì. (Ìṣe 28:1, 2) Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì ti jẹ́ kó yé wọn pé ọmọ ìyá kan náà ni gbogbo àwa èèyàn, ó sì ṣeé ṣe kí gbogbo wa máa gbé pọ̀ lálàáfíà lórí ilẹ̀ ayé.
Ìwọ̀nba làwọn tó láǹfààní àtimáa rìnrìn-àjò kárí ayé báyìí o. Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí gbogbo èèyàn tàbí èyí tó pọ̀ jù lọ láàárín àwa èèyàn láǹfààní láti máa rin irú ìrìn-àjò báyìí?
Bí Ọjọ́ Iwájú Ṣe Máa Rí
Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé inú ìdílé kan náà ni gbogbo àwa èèyàn ti wá. Lóòótọ́, tọkọtaya àkọ́kọ́ ti kú gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe kìlọ̀ fún wọn pé wọ́n á kú bí wọ́n bá ta òun lẹ́nu. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:17; 3:19) Torí èyí, gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn, títí tó fi dórí wa lónìí ló ń darúgbó tó sì ń kú. (Róòmù 5:12) Àmọ́ Ọlọ́run ṣèlérí pé ohun tóun ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀, pé káwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òun máa gbé láyé, ṣì ń bọ̀ wá ṣẹ. Ó sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àní mo ti sọ ọ́ . . . èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.”—Aísáyà 45:18; 46:11; 55:11.
Ronú ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ná! Bíbélì ṣèlérí pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29; Mátíù 6:9, 10) Bíbélì tún sọ bọ́jọ́ iwájú ṣe máa rí fáwọn èèyàn tó máa wà láyé pé: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ronú àgbàyanu ìlérí yẹn ná, pé á ṣeé ṣe láti rìnrìn-àjò káàkiri àgbáyé, kéèyàn sì máa wo oríṣiríṣi nǹkan àwòyanu tó wà nínú ayé, pàápàá jù lọ àwọn èèyàn àtàtà tó ń gbé níbẹ̀. Nígbà yẹn, kò ní sí pé à ń ṣàníyàn lórí ọ̀ràn ààbò mọ́! Gbogbo àwọn tó máa wà láyé nígbà náà máa jẹ́ ọ̀rẹ́ wa, ìyẹn ‘ẹgbẹ́ àwọn ará nínú ayé’ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.—1 Pétérù 5:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àǹfààní pàtàkì kan tí ìrìn-àjò afẹ́ ń ṣe ni pé èèyàn á lè yan ẹ̀yà míì lọ́rẹ̀ẹ́
Kò síbi téèyàn fẹ́ rìnrìn-àjò dé lọ́jọ́ iwájú láti lọ wo àwọn ẹlòmíì tí kò ní lè dé