Ta Ni “Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà”?
Ta Ni “Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà”?
JÉSÙ sábà máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹni tó pè ní Baba, ó sì kọ́ àwọn ẹlòmíì pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 6:9-11; Lúùkù 11:1, 2) Nínú àdúrà tí Jésù gbà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nígbà tó ku wákàtí mélòó kan kó kú, ó sọ pé: “Baba, wákàtí náà ti dé; ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo. . . . Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:1, 3.
Ẹ ṣàkíyèsí pé “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà” ni Jésù pe Ẹni tó gbàdúrà sí. Bó ṣe ń gbàdúrà náà lọ, ó fi hàn pé Ọlọ́run ga jù òun lọ nígbà tó sọ pé: “Nítorí náà, nísinsìnyí ìwọ, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.” (Jòhánù 17:5) Bó bá jẹ́ pé Ọlọ́run yìí náà ni Jésù ń gbàdúrà sí nígbà tó ń bẹ̀bẹ̀ pé kóun lè wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, báwo wá ni Jésù ṣe tún lè jẹ́ “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà”? Ọ̀rọ̀ rèé, ẹ jẹ́ á jọ gbé e yẹ̀wò.
Ipò Tí Jésù Wà Lọ́run
Kò ju wákàtí mélòó kan lẹ́yìn tí Jésù gbàdúrà yìí tí wọ́n fi pa á. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ nínú ipò òkú, wọ́n pa á lọ́sàn-án Friday, ó sì jíǹde láàárọ̀ Sunday. (Mátíù 27:57–28:6) Àpọ́sítélì Pétérù ròyìn pé: “Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde, òtítọ́ tí gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún.” (Ìṣe 2:31, 32) Ṣó wá lè ṣeé ṣe pé Jésù ló jí ara rẹ̀ dìde ni? Kò lè ṣeé ṣe nítorí Bíbélì sọ pé àwọn òkù “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà,” Baba Jésù tó wà lọ́run ló jí Jésù tó jẹ́ Ọmọ rẹ̀ dìde.—Ìṣe 2:32; 10:40.
Láìpẹ́ sígbà yẹn, àwọn tó ń ṣenúnibíni sí ìsìn Kristẹni pa Sítéfánù tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. Bí wọ́n ṣe fẹ́ máa sọ Sítéfánù lókùúta báyìí, ló rí ìran kan látọ̀run. Ó sọ pé: “Wò ó! mo rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” (Ìṣe 7:56) Sítéfánù tipa báyìí rí Jésù, “Ọmọ ènìyàn,” níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run, ìyẹn “ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run” níbi tó ti wà tẹ́lẹ̀ ‘lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run’ kó tó wá sáyé.—Jòhánù 17:5.
Nígbà tó yá, lẹ́yìn tí wọ́n pa Sítéfánù, Jésù tipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu fara han Sọ́ọ̀lù, tó jẹ́ pé orúkọ Róòmù tàwọn èèyan fi mọ̀ ọ́n jù ni Pọ́ọ̀lù. (Ìsẹ 9:3-6) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Áténì ní Gíríìsì, ó sọ̀rọ̀ nípa “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀.” Ó sọ pé Ọlọ́run yìí, ìyẹn “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà,” yóò “ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 17:24, 31) Pọ́ọ̀lù ń fi ọ̀rọ̀ tó ń sọ yìí ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin kan,” tó rẹlẹ̀ sí Ọlọ́run, ẹni tí Ọlọ́run jí dìde sí ìyè lọ́run.
Àpọ́sítélì Jòhánù náà júwe Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ipò rẹ̀ kéré sí ti Ọlọ́run. Jòhánù sọ ìdí tóun fi kọ ìwé Ìhìn Rere, ó ní torí kàwọn tó bá kà á lè gbà gbọ́ pé “Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run,” kì í ṣe Ọlọ́run. (Jòhánù 20:31) Wọ́n tún fi ìran han Jòhánù láti ọ̀run, inú ìran ọ̀hún ló sì ti rí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ẹni tó pè ní Jésù nínú Ìhìn Rere rẹ̀. (Jòhánù 1:29) Jòhánù sọ pé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró tòun tàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì mìíràn “tí a ti rà [tàbí jí dìde] láti ilẹ̀ ayé wá.” Jòhánù ṣàlàyé pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì mìíràn yìí ‘ní orúkọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.’—Ìṣípayá 14:1, 3.
Ṣó wá lè jẹ́ pé ẹnì kan náà ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” àti “Baba rẹ̀”? Ẹ̀rí fi hàn pé kò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé wọ́n yàtọ̀. Kódà, orúkọ wọn yàtọ̀.
Orúkọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn àti ti Baba
Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, orúkọ tí Bíbélì pe Ọmọ Ọlọ́run tó tún jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni Jésù. (Lúùkù 1:30-32) Àmọ́ kí lorúkọ Baba rẹ̀? Ó lé ní ìgbà ẹgbẹ̀rún mélòó kan tí orúkọ náà fara hàn nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 83:18 sọ pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ó dùn wá pé ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ Bíbélì ló ti yọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà kúrò nínú Bíbélì, tí wọ́n sì ti fàwọn orúkọ bí “OLÚWA” àti “ỌLỌ́RUN” rọ́pò rẹ̀ tí wọ́n á wá máa fi lẹ́tà ńlá kọ ọ́. Ìdí tí wọ́n ṣe ń fi lẹ́tà ńlá kọ ọ́ ni láti lè fìyàtọ̀ sáàárín Jèhófà àtàwọn mìíràn tí wọ́n ń pè ní ọlọ́run àti olúwa. a Síbẹ̀, nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, wọ́n lo Orúkọ Ọlọ́run láwọn ibi tó yẹ kí wọ́n ti lò ó.
Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó dá orúkọ Ọlọ́run Jèhófà padà síbi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì ni American Standard Version, lédè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 1901. Ọ̀rọ̀ ìṣàájú nínú Bíbélì náà nìyìí: “Àwọn tó ṣàtúnṣe sí Bíbélì American Standard Version ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀ dáadáá, gbogbo wọn ló dá lójú pé kò yẹ kí èrò èké àwọn Júù, pé Orúkọ Ọlọ́run ti mọ́ kọjá ohun tó yẹ kéèyàn máa pè jáde, tún wọnú àwọn Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn ìtumọ̀ Májẹ̀mú Láéláé mìíràn. Ó sì dáa tó jẹ́ pé àwọn míṣọ́nnárì ayé òde òní ò jẹ́ kí èrò yìí wọnú ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣe.” b
Ibo Ni Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan Ti Bẹ̀rẹ̀?
Báwo wá ni ti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tó sọ pé Ọlọ́run kan náà ni Jèhófà àti Jésù ṣe jẹ́? Ìwé ìròyìn The Living Pulpit, ẹ̀dà toṣù April sí June, ọdún 1999 sọ ìtumọ̀ Mẹ́talọ́kan pé: “Ọlọ́run kan wà tó jẹ́ Baba, Olúwa kan ló wà, ìyẹn Jésù Krístì, Ẹ̀mí Mímọ́ náà sì tún wà. Àwọn ‘ẹni’ mẹ́ta yìí . . . tí wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà tàbí tí wọ́n ní ara kan náà . . . ; jẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n dọ́gba, gbogbo nǹkan nípa wọn ló bára mu, síbẹ̀ wọ́n yàtọ̀ dáadáa, ànímọ́ olúkúlùkù wọn la fi mọ̀ wọ́n.” c
Níbo ni ìdàrúdàpọ̀ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan yìí ti wá ná? Ìwé ìròyìn Christian Century ti May 20-27, 1998 fa ọ̀rọ̀ pásítọ̀ kan yọ. Pásítọ̀ náà sọ pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan jẹ́ “ẹ̀kọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ láti inú ṣọ́ọ̀ṣì, ọ̀dọ́ Jésù kọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Mẹ́talọ́kan kì í ṣe ẹ̀kọ́ Jésù, ṣé ẹ̀kọ́ náà ò ta ko ẹ̀kọ́ Jésù?
Baba Ju Ọmọ Lọ
Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run; kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ.” Bíbélì sọ pé Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà ṣàgbà Ọmọ rẹ̀ Jésù. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti wà “láti ayérayé.” Àmọ́ Bíbélì sọ pé Jésù ni “àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.” Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ wa pé Jèhófà ju òun lọ nígbà tó sọ pé: “Baba mi tóbi jù mí lọ.” (Mátíù 6:9 ; Sáàmù 90:1, 2; Kólósè 1:15; Jòhánù 14:28, Bíbélì Mímọ́) Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ń kọ́ àwọn èèyàn pé Baba àti Ọmọ jẹ́ “Ọlọ́run tí wọ́n bára dọ́gba.”
Àdúrà tí Jésù máa ń gbà pẹ̀lú fi hàn pé Baba ju Ọmọ lọ àti pé ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn méjèèjì. Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ni èyí tó gbà nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n pa á, ó ní: “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí [ìyẹn ikú ẹ̀sín] kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Bí Ọlọ́run àti Jésù bá “ní ara kan náà” bó ṣe wà nínú ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, báwo ló ṣe wá dà bíi pé ìfẹ́ Jésù fẹ́ yàtọ sí ti Baba rẹ̀?—Hébérù 5:7, 8; 9:24.
Òmíì tún rèé, bó bá jẹ́ pé ẹnì kan náà ni Jèhófà àti Jésù, báwo ni ọ̀kan nínú wọn ṣe lè mọ ohun kan tí èkejì ò ní mọ̀ ọ́n? Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò ìdájọ́ ayé yìí, ó sọ pé: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba.”—Ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀sì Ni Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan
Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kì í ṣe ẹ̀kọ́ Jésù kì í sì í ṣe ẹ̀kọ́ àwọn tó kọ́kọ́ ṣe ìsìn Kristẹni. Bá a ṣe rí lẹ́ẹ̀kan, “ẹ̀kọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ láti inú ṣọ́ọ̀ṣì” ni. Ìwé ìròyìn The Living Pulpit, tọdún 1999 sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń dà bíi pé gbogbo èèyàn ló gba ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan sí òpómúléró ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni,” àmọ́ ìwé ìròyìn náà fi kún un pé “kò sí nínú Bíbélì.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia (1967) ṣe àrúnkúnná àlàyé lórí Mẹ́talọ́kan, ó wá sọ pé: “Nígbà tá a ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan dáadáa, ní àbárèbábọ̀, a wá rí i pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sàn [1,700] ọdún sẹ́yìn ni ẹ̀kọ́ yìí wọnú ìsìn Kristẹni. . . . A ò lè rí ẹ̀kọ́ ‘Ọlọ́run kan nínú Ẹni mẹ́ta’ nínú ẹ̀kọ́ Kristẹni ṣáájú àkókò yẹn, àwọn Kristẹni àkókò yẹn ò gbà á, kò sì sí lára ìgbàgbọ́ wọn.”
Martin Werner tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Bern lórílẹ̀-èdè Switzerland sọ pé: “Níbikíbi tí Májẹ̀mú Tuntun bá ti sọ nípa bí Jésù ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run, ìyẹn Baba, ì báà jẹ́ nípa bó ṣe wá gẹ́gẹ́ bí èèyàn ni o tàbí jíjẹ́ tó jẹ́ Mèsáyà, Májẹ̀mú Tuntun máa ń fi hàn kedere pé Jésù kò tó Ọlọ́run.” Ó ṣe kedere pé ohun tí Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà gbọ́ yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni lónìí. Níbo wá ni ẹ̀kọ́ yìí ti wá?
Àwọn Ibi Tí Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan Ti Ṣẹ̀ Wá
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́run àtàwọn abo ọlọ́run táwọn èèyàn ń jọ́sìn, irú bí Áṣítórétì, Mílíkómù, Kémóṣì àti Mólékì. (1 Àwọn Ọba 11:1, 2, 5, 7) Àní ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ fìgbà kan rí gbà gbọ́ pé Báálì ni Ọlọ́run tòótọ́. Nítorí náà, Èlíjà wòlíì Jèhófà pè wọ́n níjà pé kí wọ́n wádìí òótọ́ kí wọ́n sì yan ẹni tí wọ́n bá fẹ́ nígbà tó sọ fún wọn pé: “Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”—1 Àwọn Ọba 18:21.
Ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé, àwọn tó máa ń sin àwọn ọlọ́run àwọn kèfèrí sábà máa ń pín wọn sí mẹ́ta mẹ́ta. Òpìtàn Will Durant sọ pé: “Ilẹ̀ Íjíbítì ni èrò ọlọrun mẹ́talọ́kan ti wá.” James Hastings ṣàlàyé sínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia of Religion and Ethics pé: “Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́run mẹ́talọ́kan tó ń jẹ́ Brahmā, Siva, àti Viṣṇu wà nínú ẹ̀sìn àwọn Íńdíà; àwọn Íjíbítì náà ní ọlọ́run mẹ́talọ́kan tó ń jẹ́ Osiris, Isis, àti Horus.”
Èyí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́run ló wà. Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà bẹ́ẹ̀? Ṣé wọ́n ka Jésù sí Ọlọrun Olódùmarè?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí àpẹẹrẹ, wo Sáàmù 110:1 nínú Bíbélì Mímọ́. Jésù àti Pétérù mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ yìí.—Mátíù 22:42- Ìṣe 2:34-36.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ó Yẹ Ká Lo Orúkọ Ọlọ́run?” tó wà lójú ìwé 31 nínú ìwé ìròyìn yìí.
c Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ Athanasius, baba sọ́ọ̀ṣì, ẹni mímọ́ tó jẹ́ Gíríìkì, èyí tí wọ́n kọ ní bí ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ikú Jésù ṣàlàyé Mẹ́talọ́kan báyìí: “Ọlọ́run ni Baba: Ọlọ́run ni Ọmọ: Ọlọ́run náà ni Ẹ̀mí Mímọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí kì í ṣe Ọlọ́run mẹ́ta bí kò ṣe Ọlọ́run kan.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
ÍJÍBÍTÌ
Àwọn ọlọ́run mẹ́talọ́kan Horus, Osiris àti Isis, ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
PÁLÍMÍRÀ, SÍRÍÀ
Àwọn ọlọ́run mẹ́talọ́kan ti ọlọ́run òṣùpá, Olúwa Ọ̀run, àti ọlọ́run oòrùn, nǹkan bí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
ÍŃDÍÀ
Àwọn ọlọ́run olórí mẹ́ta, nǹkan bí ọ̀rúndún keje Sànmánì Kristẹni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
NORWAY
Mẹ́talọ́kan (Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́), nǹkan bí ọ̀rúndún kẹtàlá Sànmánì Kristẹni
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwòrán méjì tó wà lókè: Musée du Louvre, Paris