Ohun Tí “Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà” Ṣèlérí
Ohun Tí “Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà” Ṣèlérí
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN fi tọkọtaya àkọ́kọ́ sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn nínú ọgbà Édẹ́nì. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n bímọ kí wọ́n sì ‘ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé.’ Èyí fi hàn pé wọ́n ní láti máa mú kí Párádísè ilé wọn gbòòrò, bí wọ́n bá ṣe ń pọ̀ sí i. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:15) Ṣé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáwa èèyàn, ìyẹn ni pé ká wà nínú ìgbádùn, ká sì máa gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé á ṣeé ṣe ṣá?
Kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́! Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, “[Jèhófà] yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú” yóò sì “nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” Nígbà tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, “ẹnì kan yóò sì sọ ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀, òun yóò sì gbà wá là. Jèhófà nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a kún fún ìdùnnú kí a sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.’”—Aísáyà 25:8, 9.
Ìwé tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì ṣàpèjúwe bí nǹkan ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Ọlọ́run bá mú ayé Ìṣípayá 21:1-4.
ìsinsìnyí, tàbí ètò àwọn nǹkan tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì yìí kúrò. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ayé tuntun” táwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run á wà nínú ẹ̀, ó sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìlérí yìí mà kọ yọyọ o! Ǹjẹ́ a lè gbà á gbọ́ báyìí? Ronú nípa bí ikú ìrúbọ Jésù àtàwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ṣe lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá ṣèlérí ló máa ṣe láṣepé.—2 Kọ́ríńtì 1:20.
Jésù Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Ṣe Ìràpadà
Nígbà tí Sátánì sún Ádámù dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, gbogbo ọmọ Ádámù ló jogún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.” Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ Bíbélì náà tẹ̀ síwájú pé: “Nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan [Jésù ẹni pípé], ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” (Róòmù 5:12, 19) Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, Jésù ni “Ádámù ìkẹyìn” ẹni tó wá “láti ọ̀run” tó fi ara rẹ̀ ṣe “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”—1 Kọ́ríńtì 15:45, 47; Mátíù 20:28.
Nítorí náà gbogbo ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù ló lè rí “ìtúsílẹ̀ [kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀] nípa ìràpadà” ó sì lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Éfésù 1:7; Jòhánù 3:36) Dájúdájú a lè máa yọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi tó fi fún wa ní Ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà! (Lúùkù 2:10-12; Jòhánù 3:16) Tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù ṣe fún àwọn ọmọ ènìyàn nígbà tó wà láyé, a óò rí bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí. Ohun tí Jésù ṣe sì kàmàmà lóòótọ́!
Bí Ayé Tuntun Ṣe Máa Rí
Kò sẹ́ni tí Jésù ò wò sàn nínú gbogbo àwọn aláìsàn àti aláìlera tí wọ́n gbé déwájú ẹ̀. Ohun yòówù tí ì báà máa ṣe wọ́n, gbogbo wọn pátá ló rí ìwòsàn gbà. Yàtọ̀ síyẹn, ó fi ẹja mélòó kan àti ìṣù búrẹ́dì díẹ̀ bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, ó sì ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tó ṣerú ẹ̀.—Mátíù 14:14-22; 15:30-38.
Nígbà tí Jésù la ojú ẹnì kan tí wọ́n bí ní afọ́jú, àwọn ará àdúgbò àtàwọn ojúlùmọ̀ gbà pé iṣẹ́ ìyanu ló ṣe, ṣùgbọ́n àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ń ṣiyèméjì. Ni ọkùnrin tí Jésù la ojú ẹ̀ bá sọ fún wọn pé: “Láti ìgbà láéláé, a kò gbọ́ ọ rí pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú. Bí kì í bá ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá, kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.”—Jòhánù 9:32, 33.
Lákòókò tí Jésù ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ lórí ilẹ̀ ayé, Jòhánù Oníbatisí, tó jẹ́ ìbátan rẹ̀, tó wà nínú ẹ̀wọ̀n lákòókò yẹn ránṣẹ́ lọ bá a láti wádìí lẹ́nu rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ní wákàtí yẹn, [Jésù] wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ sàn kúrò nínú àwọn àìsàn àti àwọn òkùnrùn burúkú àti àwọn ẹ̀mí burúkú, ó sì ṣe ojú rere sí ọ̀pọ̀ afọ́jú láti ríran.” Jésù wá sọ fáwọn tí Jòhánù rán wá pé: “Ẹ ròyìn ohun tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a ń gbé àwọn òkú dìde.”—Lúùkù 7:18-22.
Rò ó wò ná: Tí ohun rere kan bá ti ṣẹlẹ̀ rí, ṣé kò yẹ kó fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ó ṣì tún lè ṣẹlẹ̀? Bí Jésù ṣe ṣe iṣẹ́ ìyanu yẹn, ńṣe ló fẹ̀rí ráńpẹ́ hàn pé òun á ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tóun bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ló rán an níṣẹ́ àti pé Ọmọ Ọlọ́run ni lóòótọ́.
Nínú Ìjọba Ọlọ́run, a ó rí i kedere táwọn ohun àgbàyanu tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ yóò máa ní ìmúṣẹ. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ojú àwọn afọ́jú á bẹ̀rẹ̀ sí ríran, etí àwọn adití á máa gbọ́ràn, àwọn arọ á fò bí ẹtu, ẹnikẹ́ni ò sì ní ṣàìsàn mọ́. Àlàáfíà àti ààbò á sì wà kárí ayé. Kódà, àlàáfíà yóò wà láàárín àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko tí kò ṣeé sún mọ́ báyìí.—Aísáyà 9:6, 7; 11:6-9; 33:24; 35:5, 6; 65:17-25.
Ṣó o fẹ́ wà láàyè títí láé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, níbi tí ohun gbogbo á ti rí bá a ṣe sọ lókè yìí? Jésù sọ ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe nígbà tó ń gbàdúrà sí baba rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Jọ̀wọ́ má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ọ lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ tó máa mú kó o ní irú ìyè àìnípẹ̀kun bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ọlọ́run ṣèlérí pé bí ilẹ̀ ayé ṣe máa rí rèé