Àràmàǹdà Kàlẹ́ńdà Táwọn Máyà Fi Ń Ka Ọjọ́
Àràmàǹdà Kàlẹ́ńdà Táwọn Máyà Fi Ń Ka Ọjọ́
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Mẹ́síkò
ÀWỌN Máyà a ayé ìgbàanì kúndùn kíka ọjọ́. Èèyàn sì lè rí i nínú kàlẹ́ńdà tí wọ́n fi ń kajọ́ pé wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn àkókò pàtó kan nínú ọdún.
Kàlẹ́ńdà kan wà táwọn àgbà ọ̀jẹ̀ kan nínú iṣẹ́ ìwádìí máa ń pè ní kàlẹ́ńdà tzolkin (òǹkà ọjọ́). Ọ̀tàlérúgba [260] ọjọ́ ló wà nínú kàlẹ́ńdà náà. Wọ́n sì pín àwọn ọjọ́ náà sí oṣù mẹ́tàlá tí oṣù kọ̀ọ̀kan ní nọ́ńbà téèyàn lè fi dá a mọ̀. Ogúnjọ́ ló wà nínú oṣù kọ̀ọ̀kan, oṣù kọ̀ọ̀kan sì lórúkọ tiẹ̀. Kàlẹ́ńdà yìí làwọn Máyà máa ń fi mọ ìgbà tí àwọn ààtò ìbílẹ̀ wọn bọ́ sí. Wọ́n sì tún máa ń fi í woṣẹ́.
Kàlẹ́ńdà míì tí wọ́n máa ń lò pọ̀ mọ́ èyí tí wọ́n fi ń woṣẹ́ yìí ni kàlẹ́ńdà ìjọba tàbí ti haab. Kàlẹ́ńdà òṣùpá lèyí ní tiẹ̀, ọjọ́ tó sì wà nínú ẹ̀ jẹ́ ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó lé márùn-ún [365]. Oṣù mọ́kàndínlógún ni wọ́n pín in sí, ogúnjọ́ ló wà nínú méjìdínlógún lára àwọn oṣù náà. Ọjọ́ márùn-ún péré ló sì wà nínú oṣù kan yòókù. Gbogbo ọjọ́ tó wà nínú ẹ̀ wá kú sí ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó lé márùn-ún [365]. Kàlẹ́ńdà òṣùpá yìí ni wọ́n fi ń mọ ìgbà tó yẹ́ kí wọ́n dáko, òun náà ni wọ́n sì fi ń mọ àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n dáwọ́ lé lójoojúmọ́. Àwọn Máyà gbọ́n púpọ̀, wọ́n pa kàlẹ́ńdà méjèèjì yìí pọ̀ ó wá di kàlẹ́ńdà mìíràn táwọn olùṣèwádìí ń pè ní Kàlẹ́ńdà Alákàyípo. Kàlẹ́ńdà méjì tí wọ́n pa pọ̀ yìí ni wọ́n fi ń kajọ́. Àpapọ̀ ọjọ́ tó sì wà nínú ẹ̀ jẹ́ ọdún méjìléláàádọ́ta. b
Kò sẹ́ni tó tíì rí ohun àtayébáyé èyíkéyìí tó ti wà látìgbà táwọn Máyà ti bẹ̀rẹ̀ sí ka ọjọ́ lórí kàlẹ́ńdà wọn. Ohun tó ran àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lọ́wọ́ láti lóye ọ̀nà táwọn Máyà ń gbà ka ọjọ́ lórí kàlẹ́ńdà wọn ni ìwọ̀nba àwọn ìwé tó wà lọ́wọ́ lédè Mayan. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára àwọn wàláà, òpó gbígbẹ́, tàbí àwọn ohun ìrántí.
Lóde òní, lẹ́yìn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún táwọn èèyàn ti fi ṣèwádìí, ó ṣì ń wu àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwádìí pé kí wọ́n mọ púpọ̀ sí i nípa kàlẹ́ńdà àwọn Máyà. Àwọn nǹkan míì wà nínú kàlẹ́ńdà náà tó máa ń ṣòroó lóye, irú bí ìyípadà pàtó tó wáyé lórí gígùn ọdún òṣùpá àti ọ̀nà tó gbà júwe àwọn ìyípadà tó máa ń wáyé nínú ojú ọjọ́ bí òṣùpá àti ayé wa yìí ṣe ń yí. Dájúdájú, àwọn Maya ìgbàanì tí wọ́n kúndùn àtimáa ka ọjọ́ láìfi ọ̀kan pe méjì, ti fi òye tó jinlẹ̀ ṣírò gbogbo rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “The Maya—Yesterday and Today,” nínú ìtẹ̀jáde Jí! (Gẹ̀ẹ́sì) ti September 8, 2001.
b Kàlẹ́ńdà míì ṣì tún wà tí àwọn Máyà máa ń lò. Kàlẹ́ńdà Ọlọ́jọ́ Gbọọrọ ni wọ́n ń pè é. Láti àkókò ìgbàanì kan ló ti ń ka ọjọ́ bọ̀ ní tiẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Tzolkin Haab
6 Caban 5 Pop
Déètì tó hàn ketekete lára owó ṣílè tó wà lókè yẹn ni 6 Caban 5 Pop, èyí tó jẹ́ February 6, 752 Sànmánì Tiwa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
0 1 5
Àwọn Máyà máa ń lo àwọn àmì mẹ́ta tó wà lókè yìí pa pọ̀, ìyẹn ló sì máa ń dúró fún nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan
0 1 2 3 4
5 6 7 8 9
10 11 12 13 14
15 16 17 18 19
Dípò ọjọ́ méje, ogúnjọ́ tó ní àwọn orúkọ àwọn ọjọ́ ọ̀sẹ̀ ló wà nínú kàlẹ́ńdà tzolkin. Díẹ̀ lára àwọn àmì tó dúró fún wọn rèé nísàlẹ̀
Àwọn àmì kan tó dúró fún oṣù mọ́kàndínlógún tó wà nínú kàlẹ́ńdà haab
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Apá ọ̀tún lókè àtàwòrán inú àkámọ́: HIP/Art Resource, NY; àwọn àmì: An Introduction to the Study of the Maya Hieroglyphs/Sylvanus Griswold Morlay/Dover Publications