Epo Rọ̀bì—Báwo La Ṣe Ń Rí I?
Epo Rọ̀bì—Báwo La Ṣe Ń Rí I?
“KÍ ÌMỌ́LẸ̀ kí ó wà.” Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, wọ́n nílò nǹkan mìíràn tí yóò máa fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ yàtọ̀ sí àtùpà tó ń ríran bàìbàì tí kò sì rọrùn láti lò, èyí tí wọ́n máa ń fi ọ̀rá, epo ara ẹja àbùùbùtán àtàwọn nǹkan mìíràn tàn. Kí ni ojútùú sí ìṣòro yìí? Epo rọ̀bì ni! Àmọ́, ibo ni wọ́n ti lè rí i?
Lọ́dún 1859, Edwin L. Drake, ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin tó ti fẹ̀yìn tì, lo ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ojú irin àtijọ́ kan láti fi gbẹ́ ilẹ̀ tó jìn tó mítà méjìlélógún, ó sì kan epo rọ̀bì tí wọ́n kọ́kọ́ ṣàwárí rẹ̀ nítòsí ìlú Titusville, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èyí ló sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì epo. Bí epo ṣe wá ń di ohun tí wọ́n ń rí lápá ibi púpọ̀ lágbàáyé, ìyípadà kékeré kọ́ lèyí mú bá ètò ọrọ̀ ajé àti ètò òṣèlú. Ó di ojúlówó ohun amúnáwá tí aráyé ti ń fi ìháragàgà dúró dè.
Kò pẹ́ kò jìnnà, dídu ilẹ̀ rà àti gbígbẹ́ ilẹ̀ wá di iṣẹ́ gidi láwọn àgbègbè tí wọ́n pè ní ilẹ̀ ìwapo ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Láwọn ọdún wọ̀nyẹn, ó wọ́pọ̀ láti gbọ́ nípa àwọn èèyàn tó ṣàdéédéé di olówó lójijì àtàwọn mìíràn tí wọ́n tún padà di ẹdun arinlẹ̀ lẹ́yìn náà. Ó yani lẹ́nu pé, Edwin Drake, ọkùnrin tó gbẹ́ kànga ìwapo àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, wà lára àwọn tó padà di ẹdun arinlẹ̀ ọ̀hún.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òwò epo rọ̀bì búrẹ́kẹ́ gan-an, kò pẹ́ tó fi fọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Láti ogún dọ́là tí wọ́n ń ta àgbá kan, ó já wálẹ̀ sí sẹ́ǹtì mẹ́wàá [owó ṣílè ilẹ̀ Amẹ́ríkà]! Bí àwọn èèyàn ṣe ya sídìí iṣẹ́ náà àti ìméfò lóríṣiríṣi nípa èrè tí wọ́n ronú láti jẹ mú kí òwò náà fọ́, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi gbọ́n àwọn kànga ìwapo kan gbẹ. Ìlú Pithole, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania,
èyí tó ti di ahoro lọ́jọ́ òní, jẹ́ ìránnilétí pàtàkì kan nípa àkókò náà. Àárín àkókò yìí ni wọ́n tẹ ìlú náà dó, tí àwọn èèyàn kúnnú rẹ̀ ṣíbáṣíbá, kò sì pẹ́ tí wọ́n tún fi túká kúrò nínú ìlú náà, gbogbo rẹ̀ láàárín ọdún kan àtààbọ̀ péré. Gbogbo àwọn kòtò àti gegele wọ̀nyí ló máa wá di apá pàtàkì nínú ìtàn epo rọ̀bì.Lọ́dún 1870, John D. Rockefeller àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ kan jọ pawọ́ pọ̀ dá iléeṣẹ́ epo kan tó ń jẹ́ Standard Oil Company sílẹ̀. Iléeṣẹ́ yìí nìkan ló ń ta epo kẹrosíìnì kó tó di pé àwọn iléeṣẹ́ mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí yọjú, àgàgà nílẹ̀ Rọ́ṣíà. Ọ̀kan lára àwọn tó bá wọn figagbága ni Marcus Samuel, ẹni tó dá ohun tá a wá mọ̀ lónìí sí iléeṣẹ́ epo Royal Dutch tàbí Shell Group sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, pẹ̀lú ọgbọ́n inú àwọn ọmọ Nobel, a iléeṣẹ́ epo kan tó ń mú owó tabua wọlé di ohun tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nílẹ̀ Rọ́ṣíà nípasẹ̀ epo tí wọ́n ń mú jáde nínú ilẹ̀ ìwapo ìlú Baku.
Bí ìtàn ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ epo ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí. Látìgbà náà wá, wọ́n ti dá àwọn àjọ àtàwọn ẹgbẹ́ sílẹ̀ láti dẹ́kun àìṣedéédéé tó ń bá iye tí wọ́n ń ta epo àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà mú un jáde níbẹ̀rẹ̀. Ọ̀kan lára wọn ni Àjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Ta Epo Sílẹ̀ Òkèèrè (OPEC), tó jẹ́ pé ìkáwọ́ mọ́kànlá lára wọn ni ọ̀pọ̀ jù lọ ilẹ̀ ìwapo tó wà lágbàáyé wà.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 7.
Báwo Ni Epo Rọ̀bì Tó Ṣẹ́ Kù Láyé Ṣe Pọ̀ Tó, Ibo La sì Ti Lè Rí I?
Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún, iná mànàmáná ti ń wà káàkiri, èyí ni ì bá sì mú kí òwò epo dẹnu kọlẹ̀. Àmọ́, ohun kíkàmàmà mìíràn tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀ kò jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ rárá, ìyẹn ni ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ìrìnnà tó ń lo epo. Epo pẹtiróòlù, tí wọ́n ń mú jáde látinú epo rọ̀bì, ti wá di ohun tó ṣe pàtàkì gan-an báyìí fún ọkọ̀ ìrìnnà, èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ lágbàáyé ti bẹ̀rẹ̀ sí lò láti òpin àwọn ọdún 1920. Nísinsìnyí,
aráyé nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ epo kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa lọ káàkiri, àmọ́ ibo ni wọ́n ti lè rí i?Bọ́dún ti ń gorí ọdún, òwò epo bẹ̀rẹ̀ sí mú ipò iwájú lọ́jà àgbáyé, bí wọ́n sì ṣe túbọ̀ ń ṣàwárí àwọn ilẹ̀ ìwapo tuntun káàkiri ayé ni òwò náà ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí i, àwọn ilẹ̀ ìwapo yìí sì ń lọ sí bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000]! Àmọ́, ní ti epo tí wọ́n ń rí, kì í ṣe bí iye ilẹ̀ ìwapo ṣe pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì bí kò ṣe bí wọ́n ṣe tóbi sí. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń tóbi tó?
Àwọn ilẹ̀ ìwapo tí wọ́n lè rí ó kéré tán, bílíọ̀nù márùn-ún àgbá epo tó ṣeé wà jáde nínú wọn ló wà ní ìpele tó ga jù lọ; nígbà táwọn ilẹ̀ ìwapo tó wà ní ìpele kejì jẹ́ àwọn tí wọ́n lè rí àgbá epo tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù sí bílíọ̀nù márùn-ún mú jáde nínú wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “Àyẹ̀wò Lórí Epo Rọ̀bì Àgbáyé ti Ọdún 2000 Látọwọ́ Àjọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ilẹ̀ Ayé Àtàwọn Ohun Tó Wà Nínú Rẹ̀” fi hàn pé nǹkan bí àádọ́rin orílẹ̀-èdè ló ní epo rọ̀bì, díẹ̀ péré nínú wọn ló lè mú epo tó tó iye tá a mẹ́nu kàn lókè yìí jáde. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 7.) Àwọn ilẹ̀ ìwapo tó ń mú epo jáde jù lọ lágbàáyé làwọn tó wà ní gbogbo àgbègbè ilẹ̀ Arébíà àti Iran, ìyẹn ni àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà.
Wíwá àwọn ibi tuntun tí wọ́n ti lè rí epo rọ̀bì kò tíì dáwọ́ dúró o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní wá mú kí èyí túbọ̀ ṣeé ṣe. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àgbègbè Òkun Caspian, níbi tí àwọn orílẹ̀-èdè bí Azerbaijan, Iran, Kazakhstan, Rọ́ṣíà, Turkmenistan àti Uzbekistan wà, làwọn iléeṣẹ́ tó ń mú epo jáde tún ń rọ́ lọ báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni Nípa Àwọn Ohun Àmúṣagbára ṣe sọ, àgbègbè yìí lè mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ epo rọ̀bì àti ògidì gáàsì jáde. Ìwádìí tún ń lọ nípa àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè máa gbé epo náà gbà, irú bí orílẹ̀-èdè Afghanistan. Wọ́n tún ti rí i pé ó ṣeé ṣe láti rí epo rọ̀bì wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, ní erékùṣù Greenland àti láwọn apá ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà. Báa bá ní ká sọ̀rọ̀ lórí yíyí àwọn èròjà inú epo rọ̀bì padà sí ohun àmúṣagbára àtàwọn nǹkan tí èèyàn
lè máa lò ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́, ìyẹn gan-an tó ìtàn lọ́tọ̀.Báwo Ni Wọ́n Ṣe Ń Wa Epo Rọ̀bì?
Àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ àtàwọn wọnlẹ̀wọnlẹ̀ ló máa ń wá àwọn ibi tí epo rọ̀bì wà lábẹ́ ilẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá kọ́kọ́ ṣe àwọn ìdíwọ̀n kan tí wọ́n sì ti yẹ iyẹ̀pẹ̀ ibẹ̀ wò, wọ́n á gbẹ́ ilẹ̀ láti rí i bóyá epo rọ̀bì wà níbẹ̀ lóòótọ́. Nígbà tí iṣẹ́ epo wíwà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, bí wọ́n bá kan epo rọ̀bì báyìí, ó lè tú àpapọ̀ ẹrẹ̀ àti epo sí wọn lára èyí sì máa ń fi epo tó bá kọ́kọ́ tú jáde ṣòfò, bákan náà ni ìbúgbàù tún lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́, nípa lílo àwọn nǹkan ìdíwọ̀n àtàwọn àkànṣe páìpù, àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń wa epo jáde látinú ilẹ̀ lónìí kì í jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ mọ́. Ó tún ti ṣeé ṣe lóde òní láti gbẹ́ ilẹ̀ tó jìn gan-an tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ fẹ̀.
Bí àkókò ti ń lọ, agbára tó ń ti epo rọ̀bì àti gáàsì jáde nínú ilẹ̀ máa ń dín kù, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa fi agbára kún agbára yìí nípa títú omi, àwọn kẹ́míkà, afẹ́fẹ́ carbon dioxide, àtàwọn gáàsì mìíràn, irú bíi náítírójìn sínú kànga ìwapo náà láti lè máa ti epo jáde. Epo rọ̀bì máa ń ki jura wọn lọ, èyí sì sinmi lórí àgbègbè tí wọ́n bá ti wà á. Epo tí kò ki làwọn tó ń wa epo jáde nífẹ̀ẹ́ sí jù, nítorí pé ó máa ń rọrùn láti wà jáde kì í sì í ṣòro láti fọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Elépo Rọ̀bì Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti ṣàlàyé, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti mú kó ṣeé ṣe láti máa gbẹ́ ilẹ̀ ní ìdábùú tí yóò sì sún mọ́ òkè ilẹ̀, dípò gbígbẹ́ ẹ lọ sísàlẹ̀ tààràtà, èyí sì máa ń dín iye kànga ìwapo tó yẹ kí wọ́n gbẹ́ kù. Wíwa epo nínú òkun, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1947 ní Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Mẹ́síkò, mú kí epo tí wọ́n ń rí túbọ̀ pọ̀ gan-an. Ó dájú pé ọ̀nà tí wọ́n bá gbà wa epo jáde nínú ilẹ̀ máa nípa lórí iye tí wọ́n á tà á nígbà tí wọ́n bá ṣe é tán. b
Báwo Ni Wọ́n Ṣe Ń Gbé Epo Rọ̀bì?
Lọ́dún 1863, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, wọ́n ṣe àwọn páìpù onígi tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi láti máa fi gbé epo, nítorí pé wọn kò wọ́n, wọ́n sì tún rọrùn láti lò ju àwọn àgbá oníjáálá méjìlélógójì tí wọ́n máa ń fi ẹṣin fà lọ. c Ìtẹ̀síwájú ti bá bí wọ́n ṣe ń ṣe páìpù lónìí, wọ́n sì ti pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Ríri Páìpù Epo ti sọ, páìpù epo tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà nìkan rì gùn tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà!
Kì í ṣe pé irú àwọn páìpù epo òde òní bẹ́ẹ̀, tí wọ́n fi irin ṣe, máa ń gbé epo rọ̀bì lọ sí ibi tí wọ́n ti ń fọ̀ ọ́ nìkan ni, àmọ́ ó tún ń gbé epo tí wọ́n ti ṣe tán lọ sáwọn iléeṣẹ́ tó ń tà á fún aráàlú. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ní àwọn ohun kan nínú páìpù tí yóò máa díwọ̀n bí epo ṣe ń ṣàn gba inú wọn kọjá. Àwọn ẹ̀rọ kéékèèké tún wà tí wọ́n ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ nínú àwọn páìpù tó gùn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà láti máa ṣàyẹ̀wò inú wọn. Wọ́n tún ń lo ohun tí wọ́n ń pè ní agbára òòfà Magnetic Flux Leakage àti ìró tó ń wá látinú páìpù láti fi mọ àwọn ibi tó sán níta àti nínú àwọn páìpù náà. Síbẹ̀, gbogbo ohun tó ṣeé ṣe kí ẹni tó ń lo àwọn ohun tí wọ́n mú jáde nínú epo rọ̀bì rí kò ju àmì tó ń fi hàn pé wọ́n ri páìpù epo mọ́ abẹ́ ilẹ̀ níbi kan àti ìkìlọ̀ pé ẹnì kankan kò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ilẹ̀ ládùúgbò náà.
Àmọ́, bí páìpù epo ṣe wúlò tó, kò ṣeé lò láti gbé epo tó pọ̀ rẹpẹtẹ lọ sí òkè òkun. Ṣùgbọ́n, àwọn olówò epo àtijọ́ wá nǹkan ṣe sí èyí pẹ̀lú, nípa lílo àwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá tó ń gbé epo. Àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n dìídì ṣe fún epo gbígbé yìí máa ń gùn tó irínwó mítà. Àwọn ló tóbi jù lọ nínú gbogbo ọkọ̀ tó ń rìn lójú òkun wọ́n sì lè gbé ohun tó tó mílíọ̀nù kan àgbá epo tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé bí wọ́n ṣe lágbára tó yìí, wọ́n ní ìṣòro kan tí kò tíì lójútùú, gẹ́gẹ́ bí àpótí náà, “Àlàyé Nípa Ìtúdànù Epo,” ṣe fi hàn. Àwọn ọkọ̀ ojú omi akẹ́rù ńláńlá àtàwọn ọkọ̀ ojú irin tún wà lára àwọn ohun tí wọ́n fi ń gbé epo tó pọ̀ gan-an lẹ́ẹ̀kan. Àmọ́, kí epo tó dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń lò ó, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì kù ní ṣíṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá gbé e kúrò ní ibi tí wọ́n ti wà á.
Iná tó ń gba inú irin gíga kan jáde, èyí tó tún wà fún ààbò, jẹ́ ẹ̀rí pàtàkì tó ń fi hàn pé ilé iṣẹ́ ìfọpo lèèyàn ń wò yẹn. Ní àwọn iléeṣẹ́ ìfọpo tó tóbi gan-an wọ̀nyí, wọ́n máa ń dáná mọ́ epo rọ̀bì nídìí, àtibẹ̀ ni yóò sì ti kọjá lọ sínú àgbá tó ń yọ́ ọ, níbi tí wọ́n á ti mú oríṣiríṣi èròjà inú rẹ̀ jáde. Àwọn èròjà wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tó máa ń dà bí afẹ́fẹ́, ìyẹn àwọn gáàsì, irú bíi butéènì títí lọ dórí àwọn tó máa ń ki gan-an, èyí tí wọ́n á fi ṣe gírísì, láfikún sí àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ń rí nínú rẹ̀. (Wo ojú ìwé 8 àti 9.) Àmọ́, ìbéèrè náà ṣì wà nílẹ̀ pé, Ṣé ìbùkún àti ègún ni epo rọ̀bì?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀kan lára wọn, Alfred Bernhard Nobel, ló wá di olùdásílẹ̀ Ẹ̀bùn Nobel.
b “Wọ́n fojú bù ú pé fífi irin gìrìwò kan, èyí tí wọ́n kọ́ sáàárín omi tó jìn tó ọ̀ọ́dúnrún mítà [1,000 ẹsẹ̀ bàtà], wa epo jáde ní Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Mẹ́síkò, fi ìlọ́po márùnlélọ́gọ́ta wọ́n ju ti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn lọ.”—The Encyclopædia Britannica.
c Láyé ọjọ́un, inú àgbá onígi irú èyí tí wọ́n ń rọ wáìnì sí ni wọ́n ń rọ epo sí, òun náà ni wọ́n sì fi ń gbé e.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 5.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
LÁGBÀÁLÁGBÀÁ ÀBÍ TỌ́Ọ̀NÙTỌ́Ọ̀NÙ?
Àwọn àgbá wáìnì ọlọ́gọ́sàn-án lítà làwọn iléeṣẹ́ tó kọ́kọ́ pọn epo rọ̀bì ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania máa ń lò láti gbé epo. Àmọ́, nígbà tó yá, lítà mọ́kàndínlọ́gọ́jọ [159] ni wọ́n ń rọ sínú àwọn àgbá náà nítorí ṣíṣẹ́ tó máa ń ṣẹ́ dà nù. Àgbá onílítà mọ́kàndínlọ́gọ́jọ yìí ni wọ́n ṣì ń lò títí dòní olónìí fún títa epo rọ̀bì.
Láti ìbẹ̀rẹ̀, orí omi ni wọ́n máa ń gbé epo tó ń lọ ilẹ̀ Yúróòpù gbà, tọ́ọ̀nùtọ́ọ̀nù ni wọ́n sì ń wọ̀n ọ́n, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe títí dòní.
[Credit Line]
Ibi tá a ti mú ìsọfúnni: Àjọ Elépo Rọ̀bì Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
KÍ LÓ Ń DI EPO RỌ̀BÌ?
Èrò tó gbajúmọ̀ láàárín àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti àwọn ọdún 1870 ni ìlànà kan tí wọ́n ń pè ní biogenic, èyí tó túmọ̀ sí “látinú nǹkan ẹlẹ́mìí.” Ìlànà yìí “sọ pé àwọn ohun alààyè tó ti kú ni wọ́n rì lọ sísàlẹ̀ ilẹ̀, tí wọ́n jẹrà, tí wọ́n sì di epo rọ̀bì àti ògidì gáàsì lẹ́yìn àkókò lílọ kánrin, àti pé epo rọ̀bì àti ògidì gáàsì ọ̀hún ló há sínú àwọn pàlàpálá àpáta lábẹ́ [Ilẹ̀].” Wọ́n ní ohun tó mú epo rọ̀bì wá nìyí, èyí tí olórí èròjà rẹ̀ jẹ́ hydrocarbon, ìyẹn àpapọ̀ èròjà hydrogen àti carbon. Àmọ́ ṣá o, láti àwọn ọdún 1970, àwọn àkókò kan wà tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ti gbé ìbéèrè dìde sí èrò yìí.
Nínú ìwé àtìgbàdégbà kan tó ń jẹ́ Proceedings of the National Academy of Sciences, ìtẹ̀jáde ti August 20, 2002, wọ́n tẹ àpilẹ̀kọ kan jáde tí wọ́n pè ní: “Ohun Tó Pilẹ̀ Àwọn Èròjà Inú Epo Rọ̀bì.” Àwọn tó kọ ọ́ jiyàn pé ibi tí epo rọ̀bì ti wá gbọ́dọ̀ jẹ́ “látinú ìsàlẹ̀ Ilẹ̀ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún” pé kò lè jẹ́ gbèrègbéré ilẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn gẹ́gẹ́ bí èrò gbogbo gbòò.
Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ Físíìsì, Thomas Gold, gbé àwọn èròǹgbà kan kalẹ̀ tó ṣì ń fa awuyewuye, ó sì ṣàlàyé àwọn ohun tó fa èròǹgbà yìí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Deep Hot Biosphere—The Myth of Fossil Fuels. Ó kọ̀wé pé: “Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n fara mọ́ èròǹgbà náà pé àtinú àwọn ohun alààyè tó ti kú làwọn èròjà hydrocarbon tó para pọ̀ di epo rọ̀bì ti wá, débi pé wọ́n dáwọ́ ìwádìí dúró lórí èrò tó ta ko èrò yìí. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ rárá láwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́.” Ó “ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ nítorí pé onímọ̀ nípa kẹ́míkà tí àwọn èèyàn ò kóyán rẹ̀ kéré náà, Mendeleyev, fara mọ́ ìlànà abiogenic [ìyẹn ni pé kì í ṣe àtinú àwọn ohun alààyè jíjẹrà ni epo rọ̀bì ti wá]. Àlàyé rẹ̀ tiẹ̀ tún ti wá fìdí múlẹ̀ gan-an lóde òní, tá a bá wo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni tó ti wà nílẹ̀ báyìí.” Kí ló ń jẹ́ ìlànà abiogenic ná?
Ọ̀jọ̀gbọ́n Gold ní: “Ìlànà abiogenic sọ pé àwọn èròjà tó para pọ̀ di epo rọ̀bì jẹ́ ara èròjà tó pilẹ̀ ayé, nípasẹ̀ ìrejọ àwọn nǹkan dídì ní nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn.” Níbàámu pẹ̀lú èròǹgbà yìí, àwọn ohun tó para pọ̀ di epo rọ̀bì ti wà látìgbà tí ayé ti wà. d
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
d Ìwé ìròyìn Jí! kò pọ̀n sẹ́yìn ọ̀kankan nínú àwọn èròǹgbà tó yàtọ̀ síra yìí o. Ó wulẹ̀ ń sọ nípa wọn ni.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
ÀLÀYÉ NÍPA ÌTÚDÀNÙ EPO
◼ Gbogbo tọ́ọ̀nù epo tó tú dà nù látinú àwọn ọkọ̀ òkun agbépo láàárín ọdún 1970 sí ọdún 2000 jẹ́ mílíọ̀nù márùn-ún àti ẹgbàá mọ́kànlélọ́gọ́jọ [5,322,000]
◼ Epo tó pọ̀ jù lọ tó tíì tú dà nù ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1979 nígbà tí ọkọ̀ òkun Atlantic Empress àti ọkọ̀ òkun Aegean Captain forí sọra wọn ní àgbègbè Caribbean, èyí tó mú kí ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin [287,000] tọ́ọ̀nù epo tú dà nù
◼ Ipò kẹrìnlélọ́gbọ̀n péré ni ọkọ̀ òkun Exxon Valdez wà nínú epo tó pọ̀ jù lọ tó tíì tú dà nù nínú ọkọ̀ òkun agbépo
◼ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó fa ọ̀pọ̀ jù lọ ìtúdànù epo ni kíkó o sọ́kọ̀, jíjá a sílẹ̀ tàbí kíkó o síbi ìkẹ́rùsí inú ọkọ̀ òkun, kí ọkọ̀ kọlura tàbí kó rì ló fa ìtúdànù epo tó tíì pọ̀ jù lọ
◼ Àwọn ìtúdànù epo rẹpẹtẹ tí àwọn nǹkan mìíràn yàtọ̀ sí ọkọ̀ òkun agbépo fà:
● Ìbúgbàù kànga ìwapo Ixtoc I lọ́dún 1979, ní Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Mẹ́síkò. Àpapọ̀ epo tó tú dà nù: ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù [500,000,000] lítà epo
● Ìbúgbàù ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ epo wíwà lórí omi lọ́dún 1983, ní Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà. Àpapọ̀ epo tó tú dà nù: ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù [300,000,000] lítà epo
● Epo táwọn kan mọ̀ọ́mọ̀ tú dà nù lọ́dún 1991, ní Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà. Àpapọ̀ epo tó tú dà nù: àádọ́rùn-ún mílíọ̀nù [900,000,000] lítà epo
[Àwòrán]
Ọkọ̀ òkun agbépo “Erika” rì nítòsí Penmarch Point, nílẹ̀ Faransé, December 13, 1999
[Àwọn Credit Line]
Ibi tá a ti mú ìsọfúnni: International Tanker Owners Pollution Federation Limited, “Oil Spill Intelligence Report,” “The Encarta Encyclopedia”
© La Marine Nationale, France
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
BÍ A ṢE Ń MÚ EPO JÁDE—ÀLÀYÉ TÓ RỌRÙN
1—WÍWÁ IBI TÍ EPO WÀ
SÁTẸ́LÁÌTÌ
Ẹ̀rọ Kélébé Tí A Fi Ń Mọ Àgbègbè Èyíkéyìí Lágbàáyé, èyí tó ń bá sátẹ́láìtì ṣiṣẹ́, máa ń pèsè àwọn ìsọfúnni pípé pérépéré tí wọ́n fi ń mọ apá ibi tí nǹkan wà nínú ilẹ̀
MAKIROFÓÒNÙ TÍ WỌ́N Ń LÒ LÓRÍ ILẸ̀
ỌKỌ̀ AMILẸ̀TÌTÌ
MAKIROFÓÒNÙ TÍ WỌ́N Ń LÒ LÁBẸ́ OMI
ỌKỌ̀ ÒKUN AFÌRÓRÁNṢẸ́ SÍSÀLẸ̀ OMI
Lílo ìró tó ń wá láti abẹ́ ilẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti mọ ibi tí epo wà. Wọ́n sábà máa ń lo ohun abúgbàù tàbí àwọn ọkọ̀ amilẹ̀tìtì láti fi ìró ránṣẹ́ sábẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n á sì gbà ohùn ìró náà sílẹ̀
2—WÍWA EPO JÁDE
KÀNGA ÌWAPO ABẸ́ ILẸ̀
IBI TÍ WỌ́N TI Ń ṢIṢẸ́ LÓRÍ OMI
KÀNGA ÌWAPO NÍSÀLẸ̀ OMI
Lára àwọn ibi tí wọ́n ti máa ń wa epo jáde ni abẹ́ ilẹ̀, ìsàlẹ̀ òkun àti nínú ilẹ̀ ìwapo abẹ́ omi. Kí agbára tó ń ti epo jáde látinú ilẹ̀ má bàa lọ sílẹ̀, wọ́n lè tú oríṣiríṣi gáàsì àti omi sínú àwọn kànga ìwapo náà
[Àwòrán]
ILẸ̀ ÌWAPO ABẸ́ OMI
Àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi tí wọ́n ń darí wọn láti ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ń lò láti fi kọ́ àwọn ibi tí wọ́n ti ń wa epo rọ̀bì nísàlẹ̀ agbami òkun
[Àwòrán]
GBÍGBẸ́ ILẸ̀ NÍ ÌDÁBÙÚ
Àwọn ẹ̀rọ tí ẹnjiníà kan ń darí láti ọ̀nà jíjìn máa ń yí ẹnu irin tó ń gbẹ́ abẹ́ ilẹ̀, ohun afìsọfúnni ránṣẹ́ ara ẹ̀rọ náà á sì jẹ́ kó mọ̀ bóyá epo wà níbẹ̀
3—BÍ WỌ́N ṢE Ń GBÉ EPO RỌ̀BÌ
PÁÌPÙ EPO
ỌKỌ̀ ÒKUN AGBÉPO
Inú àwọn páìpù tó wà lórí ilẹ̀, lábẹ́ ilẹ̀, àti lábẹ́ òkun ni epo máa ń gbà. Àwọn ọ̀nà mìíràn tí wọ́n tún ń lò ni ọkọ̀ òkun agbépo, ọkọ̀ ojú omi akẹ́rù àti ọkọ̀ ojú irin
4—FÍFỌ EPO
ILÉEṢẸ́ ÌFỌPO
Wọ́n á dáná mọ́ epo rọ̀bì nídìí, wọ́n á yọ́ ọ, wọ́n á sì mú onírúurú èròjà tí wọ́n lè fi ṣe àwọn nǹkan èlò ojoojúmọ́ jáde nínú rẹ̀
ÀGBÁ TÓ Ń YỌ́ EPO RỌ̀BÌ
Nígbà tí wọ́n bá dáná mọ́ epo rọ̀bì, tó ki tó sì dúdú, nídìí àwọn èròjà hydrocarbon inú rẹ̀ á yí padà sí onírúurú gáàsì. Bí àwọn gáàsì gbígbóná náà bá ṣe ń tutù ni wọ́n á máa di nǹkan olómi. Ọ̀nà yìí ni wọ́n ń gbà mú oríṣiríṣi èròjà inú epo rọ̀bì jáde
20°C. → ÀWỌN GÁÀSÌ TÍ WỌ́N Ń Lára wọn ni mẹtéènì, ẹtéènì,
RÍ BÍ WỌ́N TI Ń FỌ EPO puropéènì àti butéènì
↑ ↑
20° sí 70°C. → PẸTIRÓÒLÙ Wọ́n máa ń lò ó fún epo
ọkọ̀ àti fún ṣíṣe ike
↑ ↑
70° sí 160°C. → NÁFÚTÀ Wọ́n lè fi ṣe ike, epo ọkọ̀
àtàwọn kẹ́míkà mìíràn
↑ ↑
160° sí 250°C. → KẸROSÍÌNÌ Inú rẹ̀ ni wọ́n ti ń rí epo tí
wọ́n ń lò fún àwọn ẹ́ńjìnnì ọkọ̀
òfuurufú kan àti fún sítóòfù
ìdáná
↑ ↑
250° sí 350°C. → EPO GÁÀSÌ Wọ́n ń fi ṣe dísù àti epo tí
wọ́n fi ń dá iná ìléru
↑ ↑
400°C. → RÀLẸ̀RÁLẸ̀ Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń rí epo tí wọ́n
fi ń dáná ìléru tí wọ́n fi ń fọ
epo, ọ́ìlì kíki, èròjà tí wọ́n fi
ń ṣe àbẹ́là, gírísì, àti ọ̀dá
GBÍGBÓNÁ ÌLÉRU ásífáàtì tí wọ́n fi ń ṣe títì
↑ ↑
FÍFI KẸ́MÍKÀ YỌ ÈRÒJÀ INÚ EPO
Wọ́n máa ń lo ooru gbígbóná fún àwọn èròjà inú epo rọ̀bì, wọ́n á sì da àwọn ohun amúṣẹ́yá gbígbóná sí i, irú bí ìyẹ̀fun alumínà òun sílíkà. Èyí á fọ́ àwọn èròjà inú epo rọ̀bì náà sí wẹ́wẹ́ láti túbọ̀ mú àwọn nǹkan mìíràn tó wúlò jáde
Ooru gbígbóná máa ń mú kí kẹ́míkà oníyẹ̀fun yí pọ̀ mọ́ àwọn èròjà inú epo rọ̀bì
↓ ↓ ↓
ẸTANỌ́Ọ̀LÙ IKE ÀWỌN NǸKAN TÍ WỌ́N Ń
LÚ MỌ́ EPO PẸTIRÓÒLÙ
Èròjà yìí ni wọ́n Bí àpẹẹrẹ, dída àwọn Dída èròjà ọkitéènì
máa ń lò láti fi ṣe èròjà styrene tí wọ́n pọ̀ mọ́ epo pẹtiróòlù
ọ̀dà, ohun ìṣaralóge, fi ń ṣe ike pọ̀ mọ́ra ló ni kì í jẹ́ kí epo
lọ́fíńdà, ọṣẹ àti aró máa ń mú èròjà tètè jó jù nínú
polystyrene wá ẹ́ńjìnnì, èyí sì ń mú
kí iṣẹ́ rẹ̀ dára sí i
[Credit Line]
Fọ́tò Nípasẹ̀ Ìyọ̀ǹda Phillips Petroleum Company
[Graph tó wà ní ojú ìwé 7]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÀWỌN IBI TÍ EPO RỌ̀BÌ PỌ̀ SÍ JÙ LỌ LÁGBÀÁYÉ
Àpapọ̀ wọn jẹ́ ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àgbá. Àwọn epo rọ̀bì tí wọn kò tíì ṣàwárí kò sí lára ìwọ̀nyí
▪ Ọmọ ẹgbẹ́ àjọ OPEC
• Àwọn tó ní ilẹ̀ ìwapo híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ
Àwọn tó ń mú epo jáde déédéé
◆ Àwọn tó ní ilẹ̀ ìwapo
▪ • ◆ 332.7 SAUDI ARABIA
• ◆ 216.5 ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
• ◆ 192.6 RỌ́SÍÀ
▪ • ◆ 135.9 IRAN
▪ • ◆ 130.6 VENEZUELA
▪ • ◆ 125.1 KUWAIT
▪ • ◆ 122.8 IRAQ
▪ • ◆ 122.8 UNITED ARAB EMIRATES
• ◆ 70.9 MẸ́SÍKÒ
• ◆ 42.9 ṢÁÍNÀ
▪ • ◆ 41.9 LÍBÍÀ
▪ ◆ 33.4 NÀÌJÍRÍÀ
◆ 21.2 KÁNÁDÀ
▪ ◆ 21.0 INDONESIA
◆ 20.5 KAZAKHSTAN
▪ • ◆ 18.3 ALGERIA
◆ 17.6 NORWAY
◆ 16.9 UNITED KINGDOM
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Kànga ìwapo rọ̀bì àkọ́kọ́, Titusville, Pennsylvania, 1859
Epo ń tú jáde látinú kànga ìwapo kan ní Texas
[Credit Line]
Brown Brothers
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ilẹ̀ ìwapo ayé ọjọ́un, Beaumont, Texas
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Wọ́n ń fi kẹ̀kẹ́ tí ẹṣin ń fà gbé àgbá epo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kànga ìwapo ń jó nílẹ̀ Kuwait
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Gbogbo fọ́tò: Brown Brothers