Ìdí Táwọn Èèyàn Fi Ka Erékùṣù Tahiti sí Párádísè Tí Wọ́n Ń Wá Kiri
Ìdí Táwọn Èèyàn Fi Ka Erékùṣù Tahiti sí Párádísè Tí Wọ́n Ń Wá Kiri
Ó ti tó bí ọjọ́ mélòó kan tí ìgbì Òkun Pàsífíìkì ti ń gbá ọkọ̀ ojú omi náà síwá sẹ́yìn. Nínú oòrùn tó mú ganrínganrín làwọn atukọ̀ náà ti ń fagbára ṣe ohun kan náà tí wọ́n ti ṣe láìmọye ìgbà, kò sì sí àní-àní pé wáìnì wọn tó ti kan, omi òkun tó ń rùn kùù, àti oúnjẹ wọn tó ti bà jẹ́ ń kó wọn nírìíra gan-an. Ẹ̀ẹ̀kan náà ni wọ́n ṣàdéédéé gbọ́ tí ẹnì kan pariwo pé: “Ilẹ̀ gbígbẹ! Ilẹ̀ gbígbẹ wà níwájú lápá òsì!” Níwájú wọn lọ́ọ̀ọ́kán lọ́hùn-ún, wọ́n rí erékùṣù kan fírífírí. Nígbà tí wọ́n fi máà tukọ̀ fún wákàtí díẹ̀, ó wá dá wọn lójú gbangba pé erékùṣù lohun tí wọ́n ń rí—kedere báyìí ni wọ́n ń wò ó lọ́ọ̀ọ́kán wọn.
Látìgbà tí àwọn ará Yúróòpù ti fojú gán-án-ní erékùṣù Tahiti, ni wọ́n ti máa ń lò ọ̀rọ̀ náà, párádísè fún erékùṣù náà. Louis-Antoine de Bougainville, ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó jẹ́ olùṣàwárí ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ẹni tó ṣáájú ikọ̀ tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, kọ̀wé lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Ńṣe ló dà bíi pé inú ọgbà Édẹ́nì ni mo bá ara mi.” Ìyẹn ti lé ní igba ọdún báyìí, síbẹ̀, àwọn olùbẹ̀wò kò yéé wá sí erékùṣù Tahiti. Bíi tàwọn ti ìṣáájú, Párádísè ni ọ̀pọ̀ èèyàn wá débẹ̀.
Àmọ́, kí ló fà á tí ọ̀rọ̀ nípa Párádísè fi jẹ ẹ̀dá èèyàn lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Báwo ni Tahiti sì ṣe wá di ibi táwọn èèyàn kà sí párádísè tí wọ́n ti ń fọkàn yàwòrán rẹ̀ tipẹ́tipẹ́? Láti rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká padà sí ìgbà ìwáṣẹ̀ ẹ̀dá èèyàn.
Párádísè Sọ Nù
Kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu pé ọ̀rọ̀ náà “Párádísè” máa ń jẹ wá lọ́kàn gidigidi. Ní ṣókí, inú Párádísè ni Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé! Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ibì kan tó ń jẹ́ “Párádísè,” tó túmọ̀ sí ọgbà ìtura tàbí ọgbà ẹlẹ́wà, ni Ọlọ́run fi jíǹkí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ láti máa gbé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Ó hàn gbangba pé, apá kan àgbègbè tí Bíbélì pè ní Édẹ́nì, èyí tó túmọ̀ sí “Ìgbádùn,” ni ọgbà ìtura yìí wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ òde òní máa ń ka Édẹ́nì sí ìtàn àròsọ lásán, Bíbélì sọ pé ibì kan tó ti wà nígbà kan rí ni, ó sì fún wa láwọn ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé nípa apá ibi tó wà gan-gan lákòókò náà. (Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14) Kò sẹ́ni tó lè sọ pé apá ibi báyìí làwọn ibi méjì tí Bíbélì dárúkọ wà, ìyẹn odò Píṣónì àti Gíhónì. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sẹ́ni tó mọ ọ̀gangan ibi tí ọgbà náà wà mọ́.
Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù Párádísè tí gbogbo wa ì bá máa gbádùn Jẹ́nẹ́sísì 3:1-23) Síbẹ̀, àwọn ẹ̀dá èèyàn ò tíì lè mú ìfẹ́ fún Párádísè kúrò nínú ọkàn wọn. Àní, àwọn ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì tiẹ̀ fara hàn nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Gíríìkì ní ìtàn àròsọ kan tí wọ́n pè ní Sànmánì Ìgbádùn—ìyẹn àkókò kan tó dára gan-an tí aráyé ń gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn àti àlàáfíà.
rẹ̀. (Ọ̀pọ̀ ti gbìyànjú láti wá Édẹ́nì tó ti sọ nù tipẹ́tipẹ́ yìí rí. Àwọn kan wá ọgbà Édẹ́nì náà lọ sí ilẹ̀ Etiópíà, àmọ́ wọn ò rí i. Ìtàn àtẹnudẹ́nu tiẹ̀ sọ pé àlùfáà kan ní ọ̀rúndún kẹfà, Brendan, rí párádísè ní erékùṣù kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Òkun Àtìláńtíìkì. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu mìíràn sọ pé inú pàlàpálá òkè ńlá gíga kan ni párádísè wà. Nígbà tí olùṣàwárí lílókìkí náà, Christopher Columbus kò lè mú àwọn ìtakora tó wà nínú àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu wọ̀nyí mọ́ra mọ́, ó kédàárò pé: “Mi ò tíì rí ohun kan sójú tàbí kí n rí nǹkan kan kà nínú àkọsílẹ̀ àwọn Látìn tàbí ti àwọn Gíríìkì tó sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé apá ibi báyìí lórí ilẹ̀ ayé lèèyàn ti lè rí Párádísè náà.” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó sọ pé ó dá òun lójú pé ibì kan lápá gúùsù agbedeméjì ayé ló wà.
Lẹ́yìn ìrìn-àjò ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Columbus ṣe sí Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì ayé, ó sọ pé: “Ó dà bíi pé ibí yìí ni Párádísè orí ilẹ̀ ayé, nítorí pé ó bá àpèjúwe táwọn ẹni mímọ́ àtàwọn ọ̀mọ̀wé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tí mo ti mẹnu kàn níṣàájú ṣe mu.” Àmọ́ ṣá o, Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì ayé kì í ṣe párádísè tí Columbus fọkàn yàwòrán rẹ̀.
Àwọn Ibi Àìlálèébù Ọjọ́ Iwájú Tí Àwọn Èèyàn Ń Fọkàn Yàwòrán
Síbẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà sú wọn o. Àmọ́, dípò kí wọ́n máa sọ nípa bí ọwọ́ aráyé á ṣe tún padà tẹ Édẹ́nì náà, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbèrò bí wọ́n ṣe lè ṣètò Párádísè kan lọ́jọ́ iwájú, èyí tó máa wá látọwọ́ èèyàn. Àwọn òǹkọ̀wé wá bẹ̀rẹ̀ sí gbé onírúurú èrò kalẹ̀ nípa àwùjọ “tí kò ní lábùkù kankan”—èyí sì dùn mọ́ wọn nínú gan-an nítorí pé ìyẹn á yàtọ̀ sí àwùjọ èèyànkéèyàn tó ti sú wọn tí wọ́n ń gbénú rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ètò fífanimọ́ra tí wọ́n ń finú rò yìí tó dà bí ọgbà Édẹ́nì lóòótọ́. Dípò káwọn tó ń fọkàn yàwòrán yìí máa ronú nípa ìgbésí ayé olómìnira nínú ọgbà ìtura tó máa kárí ayé, ohun tí wọ́n ń fọkàn yàwòrán rẹ̀ ni àwọn ìlú ńlá tó máa dà bíi Párádísè, tó sì máa wà létòlétò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Alàgbà Thomas More sọ nípa ìrìn-àjò kan tó fọkàn yàwòrán rẹ̀, nínú èyí tó sọ pé òun bá ara òun ní ibì kan tó pè ní ibi àìlálèébù. Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni “ibì kan tí kò sí ní ti gidi.”
Ohun tí More fi lélẹ̀ làwọn òǹkọ̀wé tó dé lẹ́yìn rẹ̀ gùn lé, àmọ́ wọ́n wá fi díẹ̀ lára èrò tiwọn kún un. Láwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀ àwọn òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ síí fọkàn yàwòrán “àwọn ibi àìlálèébù.” Àmọ́, bíi tàwọn tó ṣáájú wọn, ọwọ́ wọn ò tẹ àwùjọ “àìlálèébù” tí wọ́n ń fọkàn yàwórán rẹ̀. Àwọn tó ń ṣagbátẹrù ètò yìí gbìyànjú láti mú kí ayọ̀ wà níbẹ̀ nípa fífi ọwọ́ líle mú àwọn èèyàn. Àmọ́, ńṣe ni wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ṣàkóbá fún ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti dá ṣèpinnu àti òmìnira olúkálukú. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Henri Baudet tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ṣe sọ, àwọn àlá nípa ibi àìlálèébù yìí fi hàn pé “aráyé nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí ìgbésí ayé kan tó dára ju ti ìsinsìnyí lọ . . . àti àwùjọ èèyàn kan tó túbọ̀ jẹ́ olódodo ju ti ìsinsìnyí lọ.”
Ohun Tó Fa Ìtàn Àtẹnudẹ́nu Nípa Erékùṣù Tahiti
Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, àwọn Òkun tó wà ní ìhà Gúúsù ayé tí ẹnì kankan ò tíì rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ láti lọ ṣàwárí wọn nìkan ṣoṣo ni ibi tí ìrètí kù sí láti rí Párádísè tó ṣì jẹ́ àwáàrí síbẹ̀. Àmọ́, nígbà tí Bougainville bẹ̀rẹ̀ sí tukọ̀ lọ sí àgbègbè Òkun Pàsífíìkì ní December 1766, ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ kò ju láti lọ ṣàwárí àwọn àgbègbè tuntun, kó ṣẹ́gun wọn, kó sì mú ètò ọrọ̀ ajé gbòòrò débẹ̀.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí Bougainville ti ń tukọ̀ lójú òkun, ó já sí erékùṣù Tahiti. Kò ṣeé ṣe fún un láti dúró láwọn erékùṣù tó ti ń rí lọ́nà nítorí àwọn òkìtì tó wà láwọn etíkun wọn. Àmọ́, Tahiti ní èbúté tí kò léwu. Níbí yìí, àwọn àtukọ̀ tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu náà rí àwọn èèyàn tára wọn yọ̀ mọ́ni àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí wọ́n nílò. Ohun tí àwọn atukọ̀ wọ̀nyí rí jọ wọ́n lójú gidigidi. Kì í ṣe pé Tahiti jẹ́ párádísè ilẹ̀ olóoru nìkan ni, àmọ́ ó tún ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó mú kó fara jọ ibi àìlálèébù tí wọ́n máa ń fọkàn yàwòrán.
Lákọ̀ọ́kọ́, erékùṣù ni Tahiti, kò sì yàtọ̀ sí àwọn ibi àìlálèébù tí wọ́n máa ń ṣàpèjúwe wọn nínú àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu rárá. Bákan náà, ó ní ìrísí tó fara jọ Párádísè gan-an. Àìlóǹkà àwọn odò tó ń yára ṣàn
àtàwọn omi tó ń ṣàn wálẹ̀ láti orí àpáta wà káàkiri àwọn ilẹ̀ ẹlẹ́wà rẹ̀ tó jẹ́ àwòyanu. Àwọn koríko títutù yọ̀yọ̀ máa ń hù láìsí pé ẹnì kan ló gbìn wọ́n. Ohun tó túbọ̀ mú kí ẹ̀wà Tahiti jẹ́ àrímálèlọ ni pé, ipò ojú ọjọ́ máa ń dára gan-an níbẹ̀ kò sì sí àwọn ohun tó sábà máa ń fa ewu láwọn ilẹ̀ olóoru. Ní erékùṣù yìí, kò sí ejò, kò sí àwọn kòkòrò olóró, tàbí àwọn òkè ayọnáyèéfín.Ó tún dà bíi pé àwọn èèyàn Tahiti fúnra wọn gan-an bá àpèjúwe inú ìtàn àròsọ náà mu—wọ́n ga, wọ́n lẹ́wà, ara wọn sì le dáadáa. Eyín àwọn ará Tahiti tó funfun kinniwin tún fa àwọn atukọ̀ òkun náà mọ́ra, àwọn tó jẹ́ pé eyín wọn ti yọ dà nù, àrùn jeyínjeyín sì ti sọ èrìgì wọn di wíwú. Àwọn olùgbé ibẹ̀ tún jẹ́ ẹni tára wọn yọ̀ mọ́ni; kíákíá ni ẹ̀mí àlejò wọn fa àwọn atukọ̀ náà mọ́ra. Téèyàn bá kọ́kọ́ wo àwọn ará Tahiti gààràgà, ńṣe ló dà bíi pé gbogbo wọn ò yàtọ̀ síra—èyí sì jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú ohun táwọn ìwé tó sọ nípa ibi àìlálèébù náà mẹ́nu kàn. Kò sí òṣì láàárín wọn. Kò sì sófin kankan tó ká àwọn ará Tahiti lọ́wọ́ kò láti má ṣe ní ìbálòpọ̀ bó ṣe wù wọ́n. Kódà, àwọn atukọ̀ ojú òkun náà bá díẹ̀ lára àwọn obìnrin ilẹ̀ Tahiti tó jojú ní gbèsè ṣe ìṣekúṣe.
Ká sòótọ́, lójú Bougainville àtàwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, ńṣe ni erékùṣù Tahiti dà bí ọgbà Édẹ́nì tí wọ́n tún padà rí. Nípa bẹ́ẹ̀, bí Bougainville ti ń fi erékùṣù náà sílẹ̀, pẹ̀lú ìháragàgà ló fi ń fẹ́ káráyé mọ̀ nípa párádísè tí òun rí náà. Nígbà tó parí ìrìn-àjò rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ta tó ṣe yíká ayé, ó ṣe ìwé kan jáde tó dá lórí àwọn ohun tó rí náà. Ìwé táwọn èèyàn rà lọ́pọ̀lọpọ̀ yìí ló wá pilẹ̀ èrò náà pé erékùṣù yìí kò ní èkejì, kò sì kù síbì kankan rárá. Párádísè ti sọ nù lóòótọ́, àmọ́ ó wá dà bíi pé Tahiti ni párádísè báyìí!
Àwọn Ewu Tó Ń Wà Nínú Ìtàn Àròsọ
Àmọ́, ìtàn àròsọ kì í fìgbà gbogbo jẹ́ òótọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn Tahiti máa ń ṣàìsàn wọ́n sì máa ń kú bí àwọn èèyàn mìíràn. Dípò tí gbogbo wọn ì bá sì fi wà ní ipò àparò-kan-ò-ga-jùkan-lọ bí ìtàn àròsọ ṣe sọ, inú àwùjọ kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́, tí kò gba gbẹ̀rẹ́, tó sì jẹ́ aninilára ni wọ́n ń gbé. Wọ́n máa ń ja ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, wọ́n sì máa ń fi èèyàn rúbọ. Bíi ti gbogbo èèyàn, kì í ṣe gbogbo àwọn ará Tahiti náà ló kúkú lẹ́wà lọ́nà tójú ò rí rí. Òpìtàn K. R. Howe sì sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n “rán” àwọn obìrin táwọn òṣìṣẹ́ Bougainville bá ní àjọṣepọ̀ náà láti lọ “fi ara wọn tọrẹ fún wọn” láti mú inú àwọn tó dé sí wọn lọ́rùn náà dùn.
Síbẹ̀, ńṣe ni ìtàn àròsọ náà pé “wọ́n ti rí Párádísè tó sọ nù” ń ràn bí iná ọyẹ́. Àwọn òǹkọ̀wé àtàwọn ayàwòrán ya lọ síbẹ̀, irú bí ayàwòrán ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Paul Gauguin. Àwòrán ẹlẹ́wà tí Gauguin yà nípa bí ìgbésí ayé àwọn èèyàn Tahiti ṣe rí túbọ̀ wá jẹ́ kí erékùṣù náà gbayì gan-an. Àmọ́, àwọn àbájáde wo lèyí mú bá Tahiti? Ńṣe ni ìtàn àròsọ náà sọ erékùṣù náà àtàwọn èèyàn ibẹ̀ di ohun yẹpẹrẹ. Nígbà táwọn tó lọ ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ bá padà délé, ohun táwọn èèyàn máa ń bi wọ́n ṣáá ni pé, “Ẹ sọ fún wa nípa bẹ́ẹ ṣe gbádùn àwọn obìnrin Tahiti tó.”
Ṣé Ohun Tọ́wọ́ Ò Lè Tẹ̀ Ni Párádísè?
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ìṣòro mìíràn tún ti kojú erékùṣù Tahiti. Ìjì ńláńlá kọ lu erékùṣù náà léraléra níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, ó sì ba àwọn òkìtì tó wà láwọn etíkun rẹ̀ jẹ́. Àmọ́, àwọn ẹ̀dá èèyàn gan-an ni ewu tó tóbi jù lọ fún erékùṣù yìí. Àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ ti fa ìṣànlọ erùpẹ̀ àti bíba àyíká jẹ́. Donna Leong, tó jẹ́ onímọ̀ nípa àbójútó ẹ̀gbin sọ pé: “Ẹ̀gbin táwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ wá síbẹ̀ ń dá sílẹ̀ kì í ṣe kékeré rárá. . . . Bí àwọn ará Tahiti àtàwọn erékùṣù tó yí i ká kò bá wá nǹkan ṣe sí bí àyíká wọn ṣe ń bà jẹ́ yìí, kò ní sí ilẹ̀ ọlọ́ràá tó ní àwọn ewéko àti ẹranko mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí àwọn adágún omi tó mọ́ tónítóní tó sì fani mọ́ra mọ́.”
Síbẹ̀síbẹ̀, ìrètí náà pé Ọlọ́run máa dá Párádísè náà padà kì í ṣe àlá tí kò ní ṣẹ o. Àní, Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ṣèlérí fún ọ̀daràn kan tó ronú pìwà dà pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”! (Lúùkù 23:43) Kì í ṣe ibi àìlálèébù kan tí kò fún àwọn èèyàn lómìnira, irú èyí tó máa ń wà nínú ìtàn àròsọ ni Jésù ń tọ́ka sí, àmọ́ Párádísè kan tó máa kárí ayé ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èyí tí ìjọba kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yóò máa darí rẹ̀. a Orí Párádísè ọjọ́ iwájú yìí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] tó wà ní erékùṣù Tahiti gbé ìrètí wọn kà. Wọ́n ń lo àkókò wọn láti sọ nípa ìrètí yìí fún àwọn aládùúgbò wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé erékùṣù Tahiti ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó mú kó fara jọ Párádísè, kò jẹ́ nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ Párádísè tó máa kárí ayé tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ wá láìpẹ́. Wíwá tí aráyé ń wá Párádísè yìí kiri kì í ṣe ìrètí tí yóò já sófo.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i nípa àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa Párádísè, wo ìwé náà Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Erékùṣù Tahiti dà bíi párádísè àrímálèlọ
[Àwọn Credit Line]
Àwòrán tí William Hodges yà, ọdún 1766
Yale Center for British Art, Paul Mellon Collection, USA/Photo: Bridgeman Art Library
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ará Tahiti tára wọn yọ̀ mọ́ni tẹ́wọ́ gba Bougainville tọwọ́ tẹsẹ̀
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda National Library of Australia NK 5066
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń sọ fún àwọn aládùúgbò wọn nípa Párádísè tó ń bọ̀
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]
Fọ́tò nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Tahiti Tourisme
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Ojú ìwé 18: Àwọn atukọ̀, omi tó ń ṣàn wálẹ̀ láti orí àpáta, àti àwòrán tí àwọn fótò mìíràn wà lórí rẹ̀: Gbogbo fọ́tò nípasẹ̀ ìyọ̀nda Tahiti Tourisme