Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń gbé Kiri Ìṣòro Tí Ń Gbilẹ̀

Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń gbé Kiri Ìṣòro Tí Ń Gbilẹ̀

Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń gbé Kiri Ìṣòro Tí Ń Gbilẹ̀

ÀKÓKÒ ÀTISÙN ti tó nínú ilé kan ní ilẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà. Ìyá kan rọra fi aṣọ bo ọmọ rẹ̀ lára, ó sì kí i pé ó dàárọ̀. Àmọ́ nínú òkùnkùn alẹ́ náà, ìdun kan tí wọ́n ń pè ní ìdun panipani, èyí tí gbogbo gígun rẹ̀ kò tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́ta, rọra jáde látinú ihò kékeré kan lára àjà ilé, lókè bẹ́ẹ̀dì tí ọmọ náà sùn sí. Ẹnikẹ́ni ò rí i tó fi rọra dé orí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ tó ń sùn náà, tó sì ki ẹnu rẹ̀ bọ awọ ara rẹ̀ tó jọ̀lọ̀. Bí ìdun náà ṣe ń fa ẹ̀jẹ̀ ọmọ náà mu ló tún ń pọ kòkòrò àrùn sójú ibi tó ti gé e jẹ. Láìtají lójú oorun, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ pa ojú rẹ̀, ó sì ń fi ìdọ̀tí tí ìdun náà pọ̀ sára rẹ̀ ra ojú ibi tó ti gé jẹ lára rẹ̀.

Ọmọ náà di ẹni tó ní àrùn Chagas látàrí bí kòkòrò yìí ṣe tẹnu bọ̀ ọ́ lára lẹ́ẹ̀kan yìí. Ní ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì sí àkókò náà, akọ ibà ti ń bá a fínra, ara rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí wú. Bí àìsàn yìí kò bá pa á, àwọn kòkòrò àrùn lè fi ara rẹ̀ ṣe ilé, kí wọ́n máa gbógun ti ọkàn rẹ̀, àwọn iṣan rẹ, àtàwọn ẹ̀yà ara mìíràn. Ọdún mẹ́wàá sí ogún ọdún lè kọjá kí àmì kankan má fara hàn. Àmọ́ nígbà yẹn, ìṣòro yìí lè ṣàkóbá fún àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tó ń mú oúnjẹ dà, ó lè ṣèpalára fún ọpọlọ rẹ̀, ó sì tún lè ṣekú pa ẹni náà nígbẹ̀yìngbẹ́yín nígbà tí ọkàn rẹ̀ kò bá ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́.

Ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò tó wà lókè yìí fi hàn ní kedere bí àrùn Chagas ṣe máa ń ranni. Ní ilẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ṣeé ṣe kí wọ́n gba abẹ́rẹ́ oró látọ̀dọ̀ àwọn ìdun panipani yìí.

Àwọn Kòkòrò Tó Ń Bá Ẹ̀dá Èèyàn Gbé

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àìsàn líle tó ń ṣe ẹ̀dá èèyàn kò ṣẹ̀yìn àwọn àrùn tí àwọn kòkòrò ń gbé kiri.” Àwọn èèyàn sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “kòkòrò” láti tọ́ka sí àwọn kòkòrò ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́fà, irú bí eṣinṣin, yọ̀rọ̀, ẹ̀fọn, iná, àti ọ̀bọ̀n-ùnbọn-ùn. Wọ́n tún máa ń lo ọ̀rọ̀ náà fún àwọn kòkòrò ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́jọ, irú bí eégbọn àtàwọn kòkòrò mìíràn.

Ọ̀pọ̀ jù lọ kòkòrò ni kì í ṣèpalára fún ẹ̀dá èèyàn, àwọn kan sì ń ṣe wá láǹfààní gan-an. Láìsí àwọn kòkòrò wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ irúgbìn àti igi tí àwọn èèyàn àti ẹranko gbára lé fún oúnjẹ ni kò ní so èso. Àwọn kòkòrò kan máa ń yí pàǹtírí padà láti di ohun tó wúlò lọ́nà mìíràn. Ọ̀pọ̀ kòkòrò ló jẹ́ pé ewéko ni olórí oúnjẹ wọn, nígbà tó jẹ́ pé àwọn kòkòrò mìíràn ni àwọn kòkòrò kan máa ń jẹ ní tiwọn.

Kò sí àní-àní pé, àwọn kòkòrò mìíràn wà tó máa ń yọ èèyàn àti ẹranko lẹ́nu nítorí bí wọ́n ṣe máa ń gé wọn jẹ tàbí bí wọ́n ṣe máa ń pọ̀ yamùrá nítòsí wọn. Àwọn kan tún máa ń ṣọṣẹ́ fún irè oko. Àmọ́, àwọn tó burú jáì làwọn tó máa ń tan àrùn àti ikú kálẹ̀. Nígbà tí Duane Gubler, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ Ibùdó Tó Ń Ṣèkáwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri, ó sọ pé àwọn “ló ṣokùnfà ọ̀pọ̀ jù lọ àrùn tó ń kọ lu ẹ̀dá èèyàn tó sì ń ṣekú pa wọ́n láti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ju àpapọ̀ gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tó fa àrùn àti ikú lọ.”

Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, nǹkan bí ẹnì kan nínú mẹ́fà ló ní àrùn kan tó jẹ́ pé ara kòkòrò ni wọ́n ti kó o. Yàtọ̀ sí pé àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri máa ń fa ìrora fún ẹ̀dá èèyàn, wọ́n tún máa ń náni lówó rẹpẹtẹ láti wò, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ibẹ̀ kò lówó rárá láti sanwó ìtọ́jú. Kódà bí àrùn yìí bá jà lẹ́ẹ̀kan, owó tabua ló máa ń náni. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó wáyé ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Íńdíà lọ́dún 1994 ni wọ́n sọ pé ó gbọ́n òbítíbitì owó dọ́là lápò ìjọba orílẹ̀-èdè náà, ó sì tún nípa lórí ọrọ̀ ajé àgbáyé. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ, àwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì jù lọ lágbàáyé kò ní lè gòkè àgbà títí dìgbà tí wọ́n bá ṣèkáwọ́ irú àwọn àìsàn bẹ́ẹ̀.

Bí Àwọn Kòkòrò Ṣe Ń Mú Ká Ṣàìsàn

Ọ̀nà méjì pàtàkì làwọn kòkòrò fi máa ń tan àrùn kálẹ̀. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni bí wọ́n ṣe máa ń fara kó àrùn kiri. Bí àwọn èèyàn ṣe máa ń fi bàtà onídọ̀tí kó ìdọ̀tí wọnú ilé, bẹ́ẹ̀ náà làwọn “eṣinṣin máa ń fi ẹsẹ̀ wọn kó àìlóǹkà kòkòrò àrùn kiri, èyí tó jẹ́ pé, bó bá pọ̀ gan-an, ó lè kó àrùn ranni” gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣe sọ. Bí àpẹẹrẹ, eṣinṣin lè gbé ẹ̀gbin tó kún fún kòkòrò àrùn látinú ìyàgbẹ́, kó sì kéèràn ràn wá nígbà tó bá bà lé oúnjẹ tàbí ohun mímu wa. Ọ̀nà yìí làwọn èèyàn ń gbà kó àwọn àrùn tí ń sọ ara di ahẹrẹpẹ tó sì lè ṣekú pani, irú bí ibà jẹ̀funjẹ̀fun, ìgbẹ́ ọ̀rìn àti àrùn onígbá méjì pàápàá. Àwọn eṣinṣin tún máa ń tan àrùn ojú pípọ́n tí ń ṣepin kálẹ̀—tó jẹ́ pàtàkì ohun tó ń fa ìfọ́jú lágbàáyé. Àrùn ojú pípọ́n tí ń ṣepin lè fa ìfọ́jú nípa dídá àpá sí ẹyinjú. Kárí ayé, àwọn èèyàn tó tó ìdajì bílíọ̀nù ni ìṣòro yìí ń bá fínra.

Àwọn aáyán, tó fẹ́ràn àtimáa gbé ibi ìdọ̀tí, làwọn olùṣèwádìí sọ pé àfàìmọ̀ ni wọn kì í fara kó àrùn kiri. Láfikún sí i, àwọn ògbógi sọ pé ikọ́ fée tó ṣàdédé lọ sókè sí i lẹ́nu àìpẹ́ yìí, pàápàá láàárín àwọn ọmọdé, kò ṣẹ̀yìn àwọn aáyán tó ń fa àìsàn fún àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wo ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tó ń jẹ́ Ashley, ẹni tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni kò fi lè sùn mọ́jú nítorí pé ikọ́ fée tó kọ lù ú kò jẹ́ kó mí dáadáa. Bí dókítà ṣe ń múra láti fi ẹ̀rọ ṣàyẹ̀wò ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀, ńṣe ni aáyán kan fò jáde látinú ẹ̀wù Ashley, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré kiri orí tábìlì dókítà náà.

Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń Gbé Kiri

Ọ̀nà kejì tí àwọn kòkòrò máa ń gbà tan àrùn kálẹ̀ ni nípa gbígbé fáírọ́ọ̀sì, kòkòrò bakitéríà, tàbí àwọn ohun tó ń fa àrùn tó wà nínú ara wọn kiri, tí wọ́n sì kó o ranni nígbà tí wọ́n bá géni jẹ tàbí láwọn ọ̀nà mìíràn. Kìkì ìwọ̀nba kéréje àwọn kòkòrò ló máa ń kó àrùn ran ẹ̀dá èèyàn lọ́nà yìí. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ oríṣi ẹ̀fọn ló wà, àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà Anopheles nìkan ló ń tàtaré àrùn ibà—èyí tó jẹ́ àrùn kejì tó ń ṣekú pani jù lọ lágbàáyé nínú gbogbo àrùn tí ń ràn (lẹ́yìn ikọ́ ẹ̀gbẹ).

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ẹ̀fọn yòókù máa ń kó ọ̀kan-kò-jọ̀kan àrùn tó yàtọ̀ síra ranni. Àjọ Ìlera Àgbáyé ròyìn pé: “Nínú gbogbo àwọn kòkòrò tó ń tan àrùn kálẹ̀, ẹ̀fọn ló ń ṣeni lọ́ṣẹ́ jù lọ, torí pé ó ń tan ibà malaria, iba dengue (ibà wórawóra) àti ibà pọ́njú kálẹ̀, àwọn àìsàn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ló sì ń fa ikú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, tó tún ń mú kí ìdajì bílíọ̀nù èèyàn máa ṣàìsàn lọ́dọọdún.” Ó kéré tán, nǹkan bí ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn tó wà lágbàáyé ló ṣeé ṣe kó ní àrùn ibà malaria, nǹkan bí ogójì nínú ọgọ́rùn-ún ló sì ṣeé ṣe kó ní ibà wórawóra. Ní ọ̀pọ̀ ibi, ẹnì kan lè ní oríṣi ibà méjèèjì pa pọ̀.

Ká sòótọ́, kì í ṣe ẹ̀fọn nìkan ni kòkòrò tó ń gbé àrùn kiri nínú ara rẹ̀. Àwọn irù máa ń fi àrùn sunrunsunrun ṣeni. Àrùn yìí ń bá nǹkan bí ìdajì mílíọ̀nù èèyàn fínra, ó sì lè mú kí gbogbo èèyàn tó wà ní àrọko kan fi àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá wọn tí wọ́n fi ń dáko sílẹ̀ tipátipá. Nípa títàtaré kòkòrò àrùn kan tó ń fa ìfọ́jú inú odò, àwọn kòkòrò blackfly ti sọ àwọn ará Áfíríkà tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó di afọ́jú. Àwọn kòkòrò kò-tó-nǹkan máa ń fa àrùn leishmania, èyí tó jẹ́ àgbáríjọ àwọn àrùn tó ń sọni di aláàbọ̀ ara, tó ń sọ ara dìdàkudà, tó sì sábà máa ń ṣekú pani. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni àrùn yìí ń bá fínra kárí ayé láìka ọjọ́ orí wọn sí. Yọ̀rọ̀ lè gbé ọ̀pọ̀ nǹkan sára, irú bí aràn, àrùn encephalitis (ìwúlé ọpọlọ), ibà tularemia, àti àrùn plague pàápàá—èyí tí wọ́n sábà máa ń pè ní àrùn Black Death tó jẹ́ pé, láàárín ọdún mẹ́fà péré, ó pa ohun tó lé ní ìdámẹ́ta àwọn èèyàn Yúróòpù ní Sànmánì Ojú Dúdú.

Iná, eégbọn, àtàwọn kòkòrò míì lè gbé onírúurú àrùn typhus sára, yàtọ̀ sí àwọn àrùn mìíràn tó wà nínú ara wọn. Àwọn eégbọn tó wà láwọn ilẹ̀ tí ojú ọjọ́ ti wà déédéé (tí kò tutù jù tàbí gbóná jù) lágbàáyé lè gbé àrùn Lyme tó lè sọni di aláìlágbára sára—àrùn tó jẹ́ pé òun ni àrùn tó wọ́pọ̀ jù lọ tí kòkòrò ń tàn kálẹ̀ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Yúróòpù. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Sweden fi hàn pé àwọn ẹyẹ tó ń ṣí kiri lè gbé eégbọn rìnrìn àjò lọ sí ibi tó jìn tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n tan àwọn àrùn tó wà nínú ara wọn kálẹ̀ ní àwọn àgbègbè tuntun náà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé, “eégbọn ta gbogbo àwọn kòkòrò mìíràn yọ (yàtọ̀ sí ẹ̀fọn) nínú iye àrùn tí wọ́n ń kó ran ẹ̀dá èèyàn.” Àní, eégbọn kan ṣoṣo lè gbé oríṣi kòkòrò àrùn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sára, ó sì lè kó gbogbo rẹ̀ ranni bó bá géni jẹ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo!

“Àkókò Ìsinmi” Kúrò Lọ́wọ́ Àrùn

Ọdún 1877 làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ tó fi ẹ̀rí hàn gbangba pé àwọn kòkòrò máa ń tan àrùn kálẹ̀. Látìgbà náà wá, onírúurú ètò tó kàmàmà láti ṣèkáwọ́ àwọn kòkòrò tó ń tan àrùn kálẹ̀ tàbí láti fòpin sí wọn ni wọ́n ti ṣe. Lọ́dún 1939, wọ́n fi oògùn apakòkòrò tó ń jẹ́ DDT kún ara àwọn ohun tí wọ́n á máa fi gbógun ti àwọn kòkòrò wọ̀nyí, nígbà tó sì fi máa di àárín ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1960, wọn kò fi bẹ́ẹ̀ kà wọ́n sí ewu ńlá mọ́ fún àwọn aráàlú láwọn ilẹ̀ tí kì í ṣe Áfíríkà. Dípò tí wọn ì bá fi fọwọ́ pàtàkì mú ṣíṣèkáwọ́ àwọn kòkòrò wọ̀nyí, ohun tí wọ́n gbájú mọ́ ni fífi oògùn wo àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ pàjáwìrì, bákan náà ni kò sí ìsapá tààrà kan mọ́ lórí ṣíṣèwádìí àwọn kòkòrò àti ibi tí wọ́n ń gbé. Àwọn ògbógi tún ń ṣàwárí àwọn egbòogi tuntun, ó sì dà bíi pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè rí “ìwòsàn gbogboǹṣe” fún àìsàn èyíkéyìí. Gbogbo àgbáyé wá ń gbádùn “àkókò ìsinmi” kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn tí ń gbèèràn. Àmọ́ àkókò ìsinmi náà kò pẹ́ tó fi wá sópin o. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò jíròrò ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Lónìí, nǹkan bí ẹnì kan nínú mẹ́fà àwọn èèyàn tí àrùn ń bá fínra ló kó o láti ara kòkòrò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìdun panipani

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Eṣinṣin máa ń fi ẹsẹ̀ kó àwọn kòkòrò àrùn tí ń fi àrùn ṣeni kiri

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọ̀pọ̀ kòkòrò máa ń gbé àrùn kiri nínú ara wọn

Àwọn kòkòrò “blackfly” máa ń tan ìfọ́jú inú odò kálẹ̀

Ẹ̀fọn máa ń gbé ibà “malaria,” ibà wórawóra àti ibà pọ́njú kiri

Iná máa ń kó àrùn “typhus” ranni

Yọ̀rọ̀ máa ń gbé àrùn ìwúlé ọpọlọ àtàwọn àrùn mìíràn sára

Irù máa ń fi àrùn sunrunsunrun ṣeni

[Àwọn Credit Line]

WHO/TDR/LSTM

CDC/James D. Gathany

CDC/Dr. Dennis D. Juranek

CDC/Janice Carr

WHO/TDR/Fisher

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]

Clemson University - USDA Cooperative Extension Slide Series, www.insectimages.org