Ǹjẹ́ Ìṣọ̀kan Kristẹni Ń Béèrè Pé Kí Ìpinnu Àwọn Kristẹni Dọ́gba?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ìṣọ̀kan Kristẹni Ń Béèrè Pé Kí Ìpinnu Àwọn Kristẹni Dọ́gba?
ÓDÀ bíi pé ìyapa ló kún inú ìsìn lónìí. Kódà àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn pa pọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì kan náà lè ní èròǹgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìsìn àti ìwà híhù. Òǹkọ̀wé kan sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Àní, ó tiẹ̀ ṣòro láti rí àwọn èèyàn méjì tó gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run kan náà. Lóde òní, ńṣe ló dà bíi pé oníkálùkù ni àlùfáà ara rẹ̀.”
Ní òdìkejì pátápátá sí èyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Kọ́ríńtì níyànjú láti máa “sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan” kí wọ́n sì di ẹni tí a so “pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Àwọn kan lónìí ta ko ìṣílétí Pọ́ọ̀lù yìí. Wọ́n ní ‘àwọn èèyàn yàtọ̀ síra wọn, àti pé kò bójú mu láti máa ní dandan ni pé kí àwọn Kristẹni máa ronú bákan náà tàbí kí wọ́n máa hùwà bákan náà.’ Àmọ́ o, ǹjẹ́ ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń dámọ̀ràn pé káwọn Kristẹni máa ṣègbọràn ṣáá láìronú fúnra wọn? Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ fàyè gba òmìnira ara ẹni?
Wíwà Níṣọ̀kan Kò Túmọ̀ sí Bíbáradọ́gba
Nínú lẹ́tà mìíràn tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni, ó rọ̀ wọ́n láti máa sin Ọlọ́run pẹ̀lú “agbára ìmọnúúrò” wọn. (Róòmù 12:1) Nípa bẹ́ẹ̀, ó dájú pé kì í ṣe pé ńṣe ló ń gbìyànjú láti mú kí àwọn tó wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì kàn máa ṣègbọràn ṣáá láìronú fúnra wọn. Kí wá nìdí tó fi sọ fún wọn pé kí wọ́n di ẹni tí a so “pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà”? Ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù fún wọn nímọ̀ràn yìí ni pé, ìṣòro hẹ̀rìmọ̀ kan wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì. Ìyapa ti ṣẹlẹ̀, débi pé àwọn kan ń sọ pé Ápólò làwọ́n mọ̀ ní aṣáájú àwọn nígbà tí àwọn mìíràn ń sọ pé Pọ́ọ̀lù tàbí Pétérù làwọn fara mọ́, tí àwọn mìíràn sì ń sọ pé ti Kristi nìkan làwọ́n jẹ́. Irú ìyapa bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọ̀ràn kékeré o, nítorí pé ó ti fẹ́ fọ́ ìjọ ọ̀hún.
Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti gba àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù níyànjú, ó fẹ́ kí àwọn ará Kọ́ríńtì náà máa “pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfésù 4:3) Ó ń fún àwọn arákùnrin náà níṣìírí láti máa fi ìṣọ̀kan tẹ̀ lé Jésù Kristi, kí wọ́n má ṣe di ẹni tó pín ara wọn sí oríṣiríṣi ẹgbẹ́ tàbí sí onírúurú ẹ̀yà ìsìn. Lọ́nà yìí, wọ́n á gbádùn àlááfíà tó ń wá látinú wíwà níṣọ̀kan nínú ète kan náà. (Jòhánù 17:22) Nípa bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ojú ìwòye wọn ṣe kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan, kì í ṣe pé kí wọ́n bára dọ́gba.—2 Kọ́ríńtì 13:9, 11.
Ìṣọ̀kan tún ṣe kókó nínú ẹ̀kọ́ ìsìn. Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù mọ̀ pé “ìgbàgbọ́ kan” péré ló wà, bó ṣe jẹ́ pé kìkì “Ọlọ́run kan àti Baba” ló wà. (Éfésù 4:1-6) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ń rí i dájú pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ wà níbàámu rẹ́gí pẹ̀lú òtítọ́ tí Ọlọ́run ṣí payá nípa ara rẹ̀ àti nípa àwọn ète rẹ̀, èyí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ṣọ̀kan nínú ìgbàgbọ́ wọn nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tó ń béèrè pé kí wọ́n máa ṣe. Wọ́n tún ń gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ìwà rere tó ṣe kedere tí Ọlọ́run là lẹ́sẹẹsẹ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Lọ́nà yìí, àwọn Kristẹni ń bá a nìṣó láti máa wà níṣọ̀kan, nínú ẹ̀kọ́ ìsìn àti ní ti ìwà rere.
Bíbójútó Èrò Yíyàtọ̀síra
Àmọ́ èyí kò wá túmọ̀ sí pé a óò máa sọ fún Kristẹni kọ̀ọ̀kan nípa bó ṣe gbọ́dọ̀ ronú àti ohun tó gbọ́dọ̀ ṣe nínú gbogbo ipò tó ń dìde nígbèésí ayé. Ọ̀pọ̀ ọ̀ràn ló máa ń dá lórí ìpinnu ara ẹni. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Púpọ̀ nínú àwọn Kristẹni ìlú Kọ́ríńtì ní ọ̀rúndún kìíní ló ń kọminú sí jíjẹ ẹran tó wá láti tẹ́ńpìlì òrìṣà. Àwọn kan gbà gbọ́ lójú méjèèjì pé jíjẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀ kò yàtọ̀ sí lílọ́wọ́ sí ìjọsìn èké nígbà tí àwọn mìíràn gbà pé ibi tí ẹran náà ti wá kò ṣe nǹkan kan. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bójú tó ọ̀ràn tó gbẹgẹ́ yìí, kò gbé òfin kan kalẹ̀ tí yóò máa sọ fún àwọn Kristẹni ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà pé àwọn èèyàn lè ṣe ìpinnu tó yàtọ̀ síra lórí ọ̀ràn náà. a—1 Kọ́ríńtì 8:4-13.
Lónìí, àwọn Kristẹni lè ṣe ìpinnu tó máa yàtọ̀ sí ti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn mìíràn nígbà tó bá dọ̀ràn irú iṣẹ́ tí ẹnì kan máa ṣe, ọ̀ràn ìlera, eré ìnàjú, tàbí láwọn apá ibòmíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìpinnu ara ẹni. Irú àwọn ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ lè kó ìdààmú bá àwọn kan. Wọ́n lè máa wò ó pé irú àwọn èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fa awuyewuye tàbí ìyapa nínú ìjọ. Àmọ́ ṣá o, irú àwọn ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ kò lè ṣe kó máà wáyé. Bí àpẹẹrẹ: àwọn tó máa ń ṣe orin jáde kò ní ju ìró ohùn bíi mélòó kan láti lò, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ orín dídùn ni wọ́n lè fi ìwọ̀nba ìró ohùn náà ṣe jáde. Bákan náà, àwọn Kristẹni máa ń ṣe onírúurú ìpinnu tí kò kọjá ààlà àwọn ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Bó ti wù kó rí, wọ́n ní òmìnira dé àyè kan nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ìpinnu kan tó jẹ́ tara wọn.
Báwo la ṣe lè pa ìṣọ̀kan Kristẹni mọ́ síbẹ̀ tí a óò tún bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe? Lájorí ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni ìfẹ́. Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ló ń sún wa láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ tinútinú. (1 Jòhánù 5:3) Ìfẹ́ tá a ní fún àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa náà ló ń sún wa láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣe àwọn ìpinnu tí kò ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn nínú àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ ti ara ẹni. (Róòmù 14:3, 4; Gálátíà 5:13) Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí nígbà tó fara mọ́ ìpinnu tó wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ọ̀rúndún kìíní lórí ọ̀ràn kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìsìn. (Mátíù 24:45-47; Ìṣe 15:1, 2) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó rọ olúkúlùkù láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn nínú àwọn ọ̀ràn tí kálukú ti lè ṣe ìpinnu tó bá wù ú.—1 Kọ́ríńtì 10:25-33.
Ó ṣe kedere pé, a kò gbọ́dọ̀ dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi fún ṣíṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu èyí tí kò ta ko ìlànà Bíbélì. (Jákọ́bù 4:12) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Kristẹni adúróṣinṣin kò ní wonkoko mọ́ ẹ̀tọ́ wọn débi pé wọ́n á wá ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn tàbí kí wọ́n ṣàkóbá fún ìṣọ̀kan ìjọ. Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì gbọ́dọ̀ rin kinkin pé àwọ́n ní òmìnira láti ṣe ohun kan tó hàn gbangba pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún. (Róòmù 15:1; 2 Pétérù 2:1, 19) Ó yẹ kí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run sún wa láti mú ẹ̀rí ọkàn wa bá ìrònú Ọlọ́run mu. Èyí ni yóò mú kí a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.—Hébérù 5:14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà ṣáájú kí wọ́n tó di Kristẹni ka jíjẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀ sí lílọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà. Kókó pàtàkì mìíràn tó tún lè máa kó ìdààmú bá wọn ni pé, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè lòdì lójú àwọn Kristẹni tí kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nípa tẹ̀mí.